ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 95 ojú ìwé 222-ojú ìwé 223 ìpínrọ̀ 1
  • Kò Sóhun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Sóhun Tó Lè Dá Wọn Dúró
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Alákòóso Dípò Èèyàn”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ìdáǹdè Kúrò Nínú Túbú
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • ‘A Ò Lè Dẹ́kun Sísọ̀rọ̀ Nípa Jésù’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ta Ni Ìwọ Ń Ṣègbọràn Sí—Ọlọ́run Ni Tàbí Ènìyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 95 ojú ìwé 222-ojú ìwé 223 ìpínrọ̀ 1
Pétérù àti Jòhánù ń fìtara wàásù láìka àtakò látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà àtàwọn Sadusí

Ẹ̀KỌ́ 95

Kò Sóhun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Ọkùnrin kan wà tí kò lè rìn, ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì ló sì ti máa ń tọrọ owó lójoojúmọ́. Lọ́sàn-án ọjọ́ kan, ó rí Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n ń lọ sí tẹ́ńpìlì. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fún mi lóhun tẹ́ ẹ bá ní.’ Pétérù dáhùn pé: ‘Màá fún ẹ lóhun tó dáa ju owó lọ. Lórúkọ Jésù, dìde kó o sì máa rìn!’ Pétérù wá fa ọkùnrin náà sókè, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn! Inú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bí àwọn àlùfáà àtàwọn Sadusí nínú gan-an. Torí náà, wọ́n mú àwọn àpọ́sítélì náà, wọ́n sì gbé wọn lọ sílé ẹjọ́, wọ́n wá bi wọ́n pé: ‘Ta ló fún yín lágbára tẹ́ ẹ fi wo ọkùnrin yìí sàn?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Jésù Kristi tẹ́ ẹ pa ló fún wa lágbára.’ Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn wá pariwo mọ́ wọn pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́!’ Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì náà dáhùn pé: ‘A ò lè dákẹ́, a gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa Jésù.’

Nígbà tí wọ́n fi Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀, àwọn méjèèjì lọ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù, wọ́n sì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Gbogbo wọn wá jọ gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n sì bẹ Jèhófà pé: ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ ká nígboyà ká lè máa bá iṣẹ́ rẹ lọ.’ Jèhófà dáhùn àdúrà wọn, ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́, wọ́n wá ń bá a lọ láti máa wàásù, wọ́n sì tún ń wo àwọn èèyàn sàn. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àwọn Sadusí wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn débi pé, wọ́n mú àwọn àpọ́sítélì yìí, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Àmọ́ nígbà tó di òru, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan kó lọ tú wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Áńgẹ́lì náà ṣílẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ pa dà sí tẹ́ńpìlì, kẹ́ ẹ sì máa wàásù níbẹ̀.’

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn kan wá sílé ẹjọ́ Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n sì sọ fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn pé: ‘Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ṣì wà ní títì pa, àmọ́ àwọn tẹ́ ẹ jù síbẹ̀ ò sí níbẹ̀ mọ́! Tẹ́ńpìlì ni wọ́n wà tí wọ́n tí ń wàásù fáwọn èèyàn!’ Ni wọ́n bá tún lọ mú àwọn àpọ́sítélì náà, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn. Àlùfáà àgbà wá sọ fún wọn pé: ‘Ṣebí a ti pàṣẹ fún yín pé ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́!’ Pétérù dáhùn pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”

Inú bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn gan-an débi pé wọ́n fẹ́ pa àwọn àpọ́sítélì náà. Ṣùgbọ́n Farisí kan tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì dìde, ó sì sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra o! Ó lè jẹ́ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn ọkùnrin yìí. Kò sì yẹ ká bá Ọlọ́run jà.’ Wọ́n gba ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n na àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, lẹ́yìn náà wọ́n dá wọn sílẹ̀. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì yẹn ò jáwọ́ láìka gbogbo ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà ṣe fún wọn. Wọ́n ń bá a lọ láti máa fìgboyà wàásù nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé.

“A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”​—Ìṣe 5:29

Ìbéèrè: Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò fi dá iṣẹ́ ìwàásù dúró? Báwo ni Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

Ìṣe 3:1–4:31; 5:12-42

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́