ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 98 ojú ìwé 228-ojú ìwé 229 ìpínrọ̀ 1
  • Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apẹẹrẹ Onimiisi Ti Iṣẹ Ijihin-Iṣẹ-Ọlọrun Kristian Ni Ilẹ Ajeji
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Wọ́n “Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípasẹ̀ Àṣẹ Jèhófà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Tímótì—Olùrànlọ́wọ́ Tuntun Fún Pọ́ọ̀lù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 98 ojú ìwé 228-ojú ìwé 229 ìpínrọ̀ 1
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń wàásù fún Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ gómìnà ìlú Sápírọ́sì

Ẹ̀KỌ́ 98

Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa fún wọn pé kí wọ́n wàásù káàkiri ayé. Lọ́dún 47 Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni tó wà nílùú Áńtíókù rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pé kí wọ́n lọ wàásù. Àwọn ọkùnrin méjì yìí fìtara wàásù káàkiri gbogbo ilẹ̀ Éṣíà Kékeré. Lára àwọn ìlú tí wọ́n ti wàásù ni Déébè, Lísírà àti Íkóníónì.

Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wàásù fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn olówó àti tálákà àti ọmọdé àti àgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì di Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fẹ́ wàásù fún Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ gómìnà ìlú Sápírọ́sì, ọkùnrin kan fẹ́ dí wọn lọ́wọ́. Ọkùnrin náà máa ń pidán, ìyẹn ni pé ó máa ń lo ẹ̀mí èṣù láti tan àwọn èèyàn jẹ. Pọ́ọ̀lù wá sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Kí Jèhófà bá ẹ wí.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ojú ọkùnrin náà fọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí gómìnà náà di onígbàgbọ́.

Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wàásù káàkiri, wọ́n wàásù láti ilé dé ilé, nínú ọjà, lójú ọ̀nà àti nínú sínágọ́gù. Ìgbà kan wà tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìyanu kan ní Lísírà tó mú kí arọ kan rìn. Báwọn èèyàn ṣe ríṣẹ́ ìyanu yìí, wọ́n rò pé òrìṣà ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì fẹ́ jọ́sìn wọn. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ pé kí wọ́n má jọ́sìn àwọn, wọ́n ní: ‘Èèyàn bíi ti yín ni wá, Ọlọ́run nìkan ni kẹ́ ẹ máa jọ́sìn!’ Nígbà tó yá, àwọn Júù kan wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú káwọn èèyàn kórìíra Pọ́ọ̀lù. Àwọn èèyàn náà sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ jáde nílùú, wọ́n rò pé ó ti kú. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò kú! Àwọn ará wá gbé e kúrò níbi tí wọ́n wọ́ ọ sí, wọ́n sì mú un pa dà wọnú ìlú. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù pa dà sí Áńtíókù.

Lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù tún rìnrìn àjò míì. Lẹ́yìn tó pa dà dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ní Éṣíà Kékeré, ó tún ń wàásù dé àwọn ibi tó jìnnà gan-an títí kan Yúróòpù. Ó dé Áténì, Éfésù, Fílípì, Tẹsalóníkà àtàwọn ibòmíì. Sílà, Lúùkù, àti ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Tímótì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn àjò yìí. Wọ́n sì ṣiṣẹ́ pọ̀ láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀ àti láti mú káwọn ìjọ náà lágbára. Pọ́ọ̀lù dúró ní Kọ́ríńtì fún ọdún kan àtààbọ̀ kó lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Ó wàásù, ó kọ́ni, ó tún kọ lẹ́tà sí ọ̀pọ̀ ìjọ. Ó máa ń rán aṣọ tí wọ́n fi ń pàgọ́, ó sì tún máa ń báwọn èèyàn pàgọ́ kó lè rówó bójú tó ara ẹ̀. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù pa dà sí Áńtíókù.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń wàásù nínú ọjà

Lọ́dún 52 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù tún rìnrìn àjò láti lọ wàásù nígbà kẹta, ó sì bẹ̀rẹ̀ ní Éṣíà Kékeré. Ó rìnrìn àjò láti ìlú Fílípì títí dé Kọ́ríńtì. Pọ́ọ̀lù lo ọ̀pọ̀ ọdún ní Éfésù, ó kọ́ni, ó ń mú àwọn èèyàn lára dá, ó sì ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́. Ó tún máa ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ níbì kan táwọn èèyàn máa ń kóra jọ sí láti kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fetí sílẹ̀, wọ́n sì yíwà pa dà. Níkẹyìn, lẹ́yìn tó wàásù ìhìn rere ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọjá sí Jerúsálẹ́mù.

“Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”​—Mátíù 28:19

Ìbéèrè: Ṣé o lè fi àwòrán ilẹ̀ tó wà lẹ́yìn Bíbélì (Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, Àfikún B13) wo àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò dé?

Ìṣe 13:1–23:35

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́