Ẹ̀KỌ́ 101
Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù
Ìlú Jerúsálẹ́mù ni Pọ́ọ̀lù parí ìrìn àjò ẹ̀ kẹta sí, torí pé wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan níbi tí Jésù ti sọ fún un pé: ‘O máa lọ sí Róòmù, o sì máa wàásù níbẹ̀.’ Nígbà tó yá, wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Kesaríà, ó sì lo ọdún méjì lẹ́wọ̀n níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbé ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ gómìnà tó ń jẹ́ Fẹ́sítọ́ọ̀sì, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: ‘Ẹ jẹ́ kí Késárì fúnra ẹ̀ dá ẹjọ́ mi ní Róòmù.’ Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá dáhùn pé: ‘Késárì lo fẹ́ kó dá ẹjọ́ ẹ, ọ̀dọ̀ ẹ̀ náà ni wàá sì lọ.’ Wọ́n wá fi Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ ojú omi tó ń lọ sí Róòmù, àwọn arákùnrin méjì, ìyẹn Àrísítákọ́sì àti Lúùkù sì tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù.
Nígbà tí wọ́n wà lórí omi, ìjì ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ìjì náà sì jà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà rò pé àwọn máa kú. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé áńgẹ́lì kan sọ fóun lójú àlá pé: ‘Má bẹ̀rù Pọ́ọ̀lù. Ìwọ àti gbogbo àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ọkọ̀ ojú omi yìí máa dé Róòmù láyọ̀ àti àlàáfíà. Torí náà, ẹ má bẹ̀rù! Kò sẹ́ni tó máa kú.’
Ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) ni ìjì náà fi jà. Nígbà tó yá, wọ́n rí ibi kan tí ilẹ̀ wà lọ́ọ̀ọ́kán, ìyẹn erékùṣù Málítà. Bí ọkọ̀ òkun náà ṣe fàyà sọlẹ̀ nìyẹn, ó fọ́ yángá, ó sì bà jẹ́. Àmọ́ kò sẹ́ni tó kú nínú gbogbo àwọn igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (276) tó wà nínú ọkọ̀ òkun náà. Àwọn kan wẹ̀ nínú omi dé etíkun, àwọn míì sì di pákó mú títí wọ́n fi dé etíkun ìlú Málítà. Àwọn aráàlú Málítà tọ́jú wọn dáadáa, wọ́n sì bá wọn dá iná kí wọ́n lè fi gbọn òtútù dà nù.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, àwọn sójà fi Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ òkun míì, wọ́n sì gbé e lọ sí Róòmù. Nígbà tó débẹ̀, àwọn ará wá pàdé ẹ̀. Nígbà tó rí wọn, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù, wọ́n gbà á láyè kó máa gbé láyè ara ẹ̀, wọ́n sì ní kí ọmọ ogun kan máa ṣọ́ ọ. Ọdún méjì ni Pọ́ọ̀lù lò níbẹ̀. Táwọn èèyàn bá ti wá Pọ́ọ̀lù wá, ó máa ń wàásù fún wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù tún kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré àti Jùdíà. Ó dájú pé Jèhófà lo Pọ́ọ̀lù láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn níbi gbogbo.
“Ní gbogbo ọ̀nà, à ń dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú ìṣòro.”—2 Kọ́ríńtì 6:4