Ẹ̀KỌ́ 102
Ìran Tí Jòhánù Rí
Wọ́n fi àpọ́sítélì Jòhánù sẹ́wọ̀n nílùú Pátímọ́sì. Ibẹ̀ ló wà nígbà tí Jésù fi ìran mẹ́rìndínlógún (16) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ hàn án, ìyẹn àwòrán àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nínú àwọn ìran yìí, Jòhánù rí bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́, bí Ìjọba ẹ̀ ṣe máa dé àti bí ìfẹ́ ẹ̀ ṣe máa ṣẹ láyé bíi ti ọ̀run.
Nínú ìran kan, Jòhánù rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ ológo ní ọ̀run, àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) sì jókòó yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà náà wọ aṣọ funfun, adé wúrà sí wà lórí wọn. Bí àrá ṣe ń sán, bẹ́ẹ̀ ni iná ń tàn yòò láti ibi ìtẹ́ náà. Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) yìí wólẹ̀ fún Jèhófà, wọ́n sì ń jọ́sìn ẹ̀. Nínú ìran míì, Jòhánù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà. Wọ́n wá láti oríṣiríṣi ìlú, wọ́n sì ń sọ oríṣiríṣi èdè. Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ń darí wọn lọ síbi tí omi ìyè wà. Nígbà tó yá, Jòhánù rí ìran míì níbi tí Jésù àtàwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lọ́run. Nínú ìran tó tẹ̀ lé e, Jòhánù rí i tí Jésù bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ jagun. Jésù ṣẹ́gun, ó sì lé wọn kúrò lọ́run wá sáyé.
Jòhánù tún rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n dúró lórí Òkè Síónì. Ó tún rí áńgẹ́lì kan tó ń fò lójú ọ̀run, tó ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì fògo fún un.
Nínú ìran tó tẹ̀ lé e, Jòhánù rí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Nínú ogun yẹn, Jésù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀. Nínú ìran tó kẹ́yìn, Jòhánù rí bí àwọn tó wà lọ́run àtàwọn tó wà láyé ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Ó tún rí bí Sátánì àti gbogbo àwọn ẹni ibi ṣe pa run. Gbogbo àwọn tó wà lọ́run àtàwọn tó wà láyé láá máa ṣe ohun tó buyì kún orúkọ Jèhófà, òun nìkan ni wọ́n á sì máa jọ́sìn.
“Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín, ọmọ rẹ àti ọmọ rẹ̀ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15