Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi omi pa àwọn èèyàn burúkú run, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn díẹ̀ tó jọ́sìn Jèhófà. Lára wọn ni Ábúráhámù tí Bíbélì pè ní ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tí Bíbélì fi pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà? Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, ó sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Bí Ábúráhámù, Lọ́ọ̀tì, Jékọ́bù àtàwọn olóòótọ́ míì, àwa náà lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ.