ORIN 21
Ẹ Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ohun kan tó ṣeyebíye,
Tó ń mú Jèhófà láyọ̀,
Ni Ìjọba Jésù Kristi
Tó máa mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,
Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.
2. Má jẹ́ k’áníyàn rẹ pọ̀ jù;
‘Kí la máa jẹ, kí la ó mu?’
Jèhófà máa pèsè fún wa,
Ká fi tirẹ̀ sákọ̀ọ́kọ́.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,
Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.
3. Ká wàásù ìhìnrere náà.
Ká jẹ́ kí ẹni yíyẹ
Mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà
Nìkan ló ṣeé gbọ́kàn lé.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé,
Ká sì máa fòtítọ́ sìn ín.
(Tún wo Sm. 27:14; Mát. 6:34; 10:11, 13; 1 Pét. 1:21.)