ORIN 25
Àkànṣe Ìní
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ìṣẹ̀dá tuntun làwọn
Ẹni àmì òróró.
Inú ọmọ aráyé
L’Ọlọ́run ti rà wọ́n.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe ìní ni
Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.
Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.
Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.
2. Orílẹ̀-èdè mímọ́
Tó jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n.
Jèhófà mú wọn kúrò
Lókùnkùn sí ‘mọ́lẹ̀.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe ìní ni
Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.
Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.
Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.
3. Wọ́n ń pe àgùntàn mìíràn,
Wọ́n sì ń kó gbogbo wọn jọ.
Wọ́n dúró gbọn-in ti Jésù.
Wọ́n ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe ìní ni
Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà.
Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́.
Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé.
(Tún wo Àìsá. 43:20b, 21; Mál. 3:17; Kól. 1:13.)