ORIN 60
Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Lákòókò tá a wà yìí,
gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ gbọ́
Pé ọjọ́ ìbínú Jáà
máa dé, kò ní pẹ́ mọ́.
(ÈGBÈ)
Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́.
Àwa náà sì máa ríyè.
Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì.
Dandan ni ká sọ fáráyé,
Dandan ni.
2. Ohun kan wà tí à ńsọ
fún gbogbo aráyé.
À ń pe gbogbo èèyàn wá
di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́.
Àwa náà sì máa ríyè.
Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì.
Dandan ni ká sọ fáráyé,
Dandan ni.
(ÀSOPỌ̀)
Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì.
Ká tètè lọ, ká sọ fún wọn.
Ká kọ́ wọn ní òtítọ́
Tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ríyè.
(ÈGBÈ)
Wọ́n máa ríyè, tí wọ́n bá gbọ́.
Àwa náà sì máa ríyè.
Ìgbọràn wọn ṣe pàtàkì.
Dandan ni ká sọ fáráyé,
Dandan ni.
(Tún wo 2 Kíró. 36:15; Àìsá. 61:2; Ìsík. 33:6; 2 Tẹs. 1:8.)