ORIN 102
Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbogbo wa pátá la ní
Ibi tá a kù sí.
Síbẹ̀, Jèhófà ń fìfẹ́
Ṣèrànwọ́ fún wa.
Bàbá aláàánú ni;
Ó nífẹ̀ẹ́ wa púpọ̀.
Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jáà;
Ká máa ṣèrànwọ́.
2. Lójú tiwa, àwọn kan
Lè má níṣòro.
Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn lè
Má tó bá a ṣe rò.
Ó yẹ ká gbé wọn ró,
Ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà
Yóò tún ṣèrànwọ́.
3. Àwọn tó j’áláìlera
Nílò ìrànwọ́.
Ká má ṣe dá wọn lẹ́bi,
Ká mára tù wọ́n.
Ká máa kíyè sí wọn,
Ká lè máa gbé wọn ró.
Tí a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́,
A ó rí ‘bùkún gbà.
(Tún wo Àìsá. 35:3, 4; 2 Kọ́r. 11:29; Gál. 6:2.)