ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 102-103
  • Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1919—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Wọ́n Bọ́ Lọ́wọ́ Ìsìn Èké
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Àwọn “Egungun Gbígbẹ” Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 102-103
Àpéjọ agbègbè táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún 1919

Àpéjọ agbègbè mánigbàgbé tá a ṣe ní 1919 jẹ́ ẹ̀rí tó mú kó ṣe kedere pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ti kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá pátápátá

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9B

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919

Kí nìdí tá a fi ń sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919? Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọdún 1914 ni Jésù di Ọba ní ọ̀run, ìyẹn sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò búburú Sátánì. Kí ni Jésù ṣe ní gbàrà tó di Ọba? Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá? Ṣé ọdún 1914 ló yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkórè ńlá náà?​—Mát. 24:45.

Rárá o. Ẹ má gbàgbé ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti sọ, ó ní ìdájọ́ máa “bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.” (1 Pét. 4:17) Bákan náà, wòlíì Málákì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí Jèhófà máa wá sí ibi ìjọsìn rẹ̀ pẹ̀lú “ìránṣẹ́ májẹ̀mú,” ìyẹn Ọmọ Ọlọ́run. (Mál. 3:1-5) Ọlọ́run máa yẹ àwọn èèyàn rẹ̀ wò lákòókò yẹn ó sì máa yọ́ wọn mọ́. Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn mu?

Bẹ́ẹ̀ ni! Ọdún 1914 títí dé apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919 jẹ́ àkókò àdánwò àti ìyọ́mọ́ fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn. Lọ́dún 1914, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni inú wọn ò dùn nígbà tí ohun tí wọ́n ń retí kò ṣẹlẹ̀, ìyẹn bí òpin kò ṣe dé bá ètò àwọn nǹkan. Ohun míì tó tún bà wọ́n nínú jẹ́ gan-an lọ́dún 1916 ni ikú Arákùnrin Charles T. Russell tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn kan tó ti mọwọ́ Arákùnrin Russell dáadáa kò tiẹ̀ gba ti Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó rọ́pò Russell, tó sì ń múpò iwájú. Ìyapa fẹ́rẹ̀ẹ́ pín ètò Ọlọ́run sí méjì lọ́dún 1917. Lọ́dún 1918, ìjọba fòfin mú Arákùnrin Rutherford àti méje lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn wọ́n, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ó dájú pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ló wà nídìí ọ̀rọ̀ náà. Bó ṣe di pé wọ́n ti oríléeṣẹ́ tó wà nílùú Brooklyn pa nìyẹn. Láìsí àní-àní, àwọn èèyàn Ọlọ́run ò tíì kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá ní gbogbo ìgbà yẹn!

Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919? Ṣàdédé ni nǹkan yí pa dà! Níbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn, wọ́n dá Arákùnrin Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ lójú ẹsẹ̀! Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi ṣètò àpéjọ mánigbàgbé kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìròyìn tuntun kan, ìyẹn The Golden Age (tí à ń pè ní Jí! báyìí). Wọ́n dìídì ṣe ìwé ìròyìn tuntun náà fún iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yan ẹnì kan nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan tí á máa ṣètò iṣẹ́ ìwàásù, tí á sì máa múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ọdún yẹn kan náà ni wọ́n mú ìwé kan tó ń jẹ́ Bulletin (tí à ń pè ní Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ báyìí) jáde, ìtẹ̀jáde náà sì ran àwọn ará lọ́wọ́ gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn? Ó fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé Kristi ti mú àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá. Ó ti yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Iṣẹ́ ìkórè sì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Láti ọdún mánigbàgbé yẹn, ìyẹn ọdún 1919, ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lọ́nà tó kàmàmà.

Pa dà sí orí 9, ìpínrọ̀ 25 àti 26

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́