ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 152-153
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Gbé Ìjọsìn Mímọ́ Ga, Ó sì Dáàbò Bò Ó
  • Ìbùkún Ayérayé
  • Ìlànà Kan Náà fún Gbogbo Èèyàn
  • Oúnjẹ Lórí Tábìlì Jèhófà
  • Ọlọ́run Mú Kó Dá Wa Lójú
  • “Òfin Tẹ́ńpìlì Náà Nìyí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Tẹ́ńpìlì Náà” Àti “Ìjòyè Náà” Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 152-153

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 14A

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí

Bíi Ti Orí Ìwé
Àwòrán àwọn ibi pàtàkì nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí lójú ìran. Lára rẹ̀ ni: 1. Òkè tó ga fíofío. 2. Ògiri ọgbà tẹ́ńpìlì. 3. Ọgbà tó tóbi yí tẹ́ńpìlì náà ká. 4. Odò tó ń ṣàn jáde láti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì. 5. Ẹnubodè ìta. 6. Ògiri tẹ́ńpìlì. 7. Àgbàlá ìta. 8. Àwọn yàrá ìjẹun ní ìta. 9. Ẹnubodè inú. 10. Àgbàlá inú. 11. Pẹpẹ. 12. Ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì. Àwòrán bí ọkọ̀ òfúrufú ńlá ṣe gùn tó (ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ [250] ẹsẹ̀ bàtà) àti bí gígùn rẹ̀ ṣe kéré tó tá a bá fi wé gígùn ọgbà tẹ́ńpìlì náà (tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún kan [5,100] ẹsẹ bàtà).

Ọlọ́run Gbé Ìjọsìn Mímọ́ Ga, Ó sì Dáàbò Bò Ó

‘Orí òkè tó ga fíofío’ (1) ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran wà. Ṣé àwa náà ti gbé ìjọsìn mímọ́ ga, ṣé a sì ń fi sípò àkọ́kọ́ láyé wa?

Ògiri tó yí tẹ́ńpìlì náà ká (2), tó mú kó wà láàárín ọgbà tó tóbi (3) rán wa létí pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun kó ẹ̀gbin bá ìjọsìn wa sí Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ohun “tó jẹ́ ti gbogbo èèyàn” sún mọ́ tòsí ìjọsìn mímọ́, ìyẹn àwọn nǹkan tara tó jẹ mọ́ ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́, mélòómélòó wá ni ìwà àìmọ́ tàbí ìwà ìbàjẹ́! Àwa olùjọ́sìn Jèhófà lóde òní ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ìwàkiwà yìí kó àbààwọ́n bá ìgbésí ayé wa lọ́nàkọnà.​—Ìsík. 42:20.

Ìbùkún Ayérayé

Omi kan ń sun jáde láti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì náà, ó sì wá di odò ńlá tó ń yára ṣàn, ó sọ ilẹ̀ náà di alààyè, ó sì mú kó méso jáde (4). A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tó mú wá ní Orí 19 ìwé yìí.

Ìlànà Kan Náà fún Gbogbo Èèyàn

Àwọn ẹnubodè gíga tó wà níta (5) àti inú (9) tẹ́ńpìlì náà rán wa létí pé ìlànà gíga ni Jèhófà fi lélẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ṣe ìjọsìn mímọ́. Ẹ kíyè sí i pé, bákan náà ni gíga àti fífẹ̀ àwọn ẹnubodè àgbàlá ìta àti ti inú tẹ́ńpìlì náà. Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, torí pé ìlànà òdodo kan náà ni Jèhófà fi lélẹ̀ fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, láìka ipò tí wọ́n wà tàbí ojúṣe wọn sí.

Oúnjẹ Lórí Tábìlì Jèhófà

Àwọn yàrá ìjẹun (8) rán wa létí pé nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn náà láǹfààní láti jẹ lára ẹbọ tí wọ́n mú wá sí tẹ́ńpìlì, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹun pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí táwa Kristẹni ti ń jọ́sìn lóde òní, torí pé Kristi ti rú “ẹbọ kan ṣoṣo” tá a nílò. (Héb. 10:12) Àmọ́, a ṣì ń rú ẹbọ ìyìn.​—Héb. 13:15.

Ọlọ́run Mú Kó Dá Wa Lójú

Gbogbo bí wọ́n ṣe ń wọn tinú-tòde tẹ́ńpìlì náà lè fẹ́ kani láyà. Àmọ́ ó kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan: Ó fi dá wa lójú pé mìmì kan ò ní mi ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn pé òun fẹ́ mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò. Bí wọ́n ṣe wọn tẹ́ńpìlì náà lọ́nà tó gún régé, bẹ́ẹ̀ làwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ, kò ní yí pa dà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìsíkíẹ́lì ò sọ pé òun rí èèyàn kankan nínú ìran yẹn, ó sọ ìbáwí tó lágbára tí Jèhófà fún àwọn àlùfáà, àwọn ìjòyè àtàwọn èèyàn náà. Gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà òdodo Rẹ̀.

Pa dà sí orí 14, ìpínrọ̀ 13 àti 14

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́