ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 6
  • Jẹ́ Onígboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Onígboyà
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ǹjẹ́ O Ń Wàásù Láìṣojo?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • ‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nìṣó Láìṣojo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 6

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Jésù rí Sákéù lórí igi, ó sì sọ fún un pé kó sọ̀ kalẹ̀. Èyí ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu.

Lúùkù 19:1-7

Ẹ̀KỌ́ 6

Jẹ́ Onígboyà

Ìlànà: “Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le kí a lè sọ ìhìn rere . . . fún yín.”—1 Tẹs. 2:2.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù rí Sákéù lórí igi, ó sì sọ fún un pé kó sọ̀ kalẹ̀. Èyí ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu.

FÍDÍÒ: Jésù Wàásù fún Sákéù

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Lúùkù 19:1-7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn kan kórìíra Sákéù?

  2. Kí ló mú kí Jésù wàásù fún un?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. A gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà ká tó lè wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ran Jésù lọ́wọ́ láti wàásù, ẹ̀mí mímọ́ lè ran ìwọ náà lọ́wọ́. (Mát. 10:19, 20; Lúùkù 4:18) Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti bá àwọn kan sọ̀rọ̀, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígboyà.—Ìṣe 4:29.

4. Má ṣe rò pé wọn ò ní gbọ́. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má wàásù fáwọn kan torí ìrísí wọn, bí wọ́n ṣe ń hùwà, ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, ipò tí wọ́n wà láwùjọ àbí torí pé wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà. Àmọ́, fi sọ́kàn pé:

  1. A ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, Jèhófà àti Jésù nìkan ló mọ̀ ọ́n.

  2. Kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè ràn lọ́wọ́.

5. Jẹ́ onígboyà, àmọ́ máa ṣọ́ra. (Mát. 10:16) Má ṣe máa bá àwọn èèyàn jiyàn. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ tàbí tó o rí i pé ó léwu láti máa bá ọ̀rọ̀ ẹ lọ pẹ̀lú ẹni náà, á dáa kó o rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀.—Òwe 17:14.

TÚN WO

Ìṣe 4:31; Éfé. 6:19, 20; 2 Tím. 1:7

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́