ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 12
  • Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • ‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 12

SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN

Ọkùnrin kan kúnlẹ̀ síwájú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, Jésù sì ń fìfẹ́ bá a sọ̀rọ̀.

Máàkù 10:17-22

Ẹ̀KỌ́ 12

Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀

Ìlànà: “Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.”—Òwe 27:9.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Ọkùnrin kan kúnlẹ̀ síwájú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, Jésù sì ń fìfẹ́ bá a sọ̀rọ̀.

FÍDÍÒ: Jésù Gba Ọ̀dọ́kùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan Nímọ̀ràn

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 10:17-22. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Àwọn ìwà dáadáa wo ló ṣeé ṣe kí Jésù rí lára ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà?

  2. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin náà, kí nìdí tí kò fi yẹ kó bẹ̀rù láti bá a sòótọ́ ọ̀rọ̀?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó tún yẹ ká máa bá wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe àti bó ṣe máa ṣe é.

  1. a. Ẹ máa jíròrò apá tá a pè ní “Ohun tó yẹ kó o ṣe” ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

  2. b. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kó ṣe, kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ̀ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

  3. d. Máa gbóríyìn fún un bó ṣe ń tẹ̀ síwájú.

4. Mọ àwọn ohun tí kò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ tẹ̀ síwájú, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè borí wọn.

  1. Bi ara ẹ pé:

    • ‘Kí ló ń dí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ tí kò fi gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi?’

    • ‘Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?’

  2. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fìfẹ́ tọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ sọ́nà, kó o má sì bẹ̀rù láti bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.

5. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.

  1. Kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, bi ara ẹ pé:

    • ‘Ṣé ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’

    • ‘Ṣó máa ń wá sípàdé, ṣó sì máa ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì?’

    • ‘Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débì kan, ṣó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’

  2. Tí kò bá wu ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tó máa jẹ́ kó tẹ̀ síwájú:

    • Ní kó ronú lórí ohun tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú.

    • Fìfẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

    • Jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó yẹ kó ṣe, kó tó lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.

TÚN WO

Sm. 141:5; Òwe 25:12; 27:6; 1 Kọ́r. 9:26; Kól. 4:5, 6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́