ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • CO-pgm25 ojú ìwé 8
  • Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Agbègbè ti Ọdún 2025
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Agbègbè ti Ọdún 2024
  • Ohun tá a fẹ́ kí àwọn tó wá sí àpéjọ yìí mọ̀
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Agbègbè ti Ọdún 2023
  • Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá sí Àpéjọ Yìí Mọ̀
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àgbègbè ti Ọdún 2020
  • Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àgbègbè ti Ọdún 2019
Àwọn Míì
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Agbègbè ti Ọdún 2025
CO-pgm25 ojú ìwé 8

Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀

ÀWỌN OHUN TÓ SỌ NÙ TÁ A RÍ HE Gbogbo ohun tó o bá rí he ni kó o mú lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Sọ Nù Tá A Rí He. Tó o bá sọ ohunkóhun nù, lọ wò ó ní ẹ̀ka yìí. Tó o bá rí ọmọ kékeré tó ń rìn kiri tí kò sì mọ ibi táwọn òbí rẹ̀ jókòó sí, mú un lọ sí ẹ̀ka yìí. Àmọ́, kì í ṣe pé ká kúkú wá sọ ẹ̀ka yìí di ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ o! Jọ̀wọ́ bójú tó àwọn ọmọ rẹ, kó o sì jẹ́ kí wọ́n máa wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo.

ÀWỌN TÓ Ń BÓJÚ TÓ ÈRÒ Iṣẹ́ àwọn tó ń bójú tó èrò ni láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, kó o gbé ọkọ̀ ẹ síbi tí wọ́n bá ní kó o gbé e sí, gba ibi tí wọ́n bá ní kó o gbà, sì tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ nípa àyè ìjókòó àtàwọn ohun míì.

ÌJÓKÒÓ Jọ̀wọ́ ro tàwọn míì mọ́ tìẹ. Rántí pé kìkì àwọn tẹ́ ẹ jọ wọkọ̀ kan náà àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbélé tàbí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gba àyè sílẹ̀ fún. Jọ̀wọ́ má ṣe gbé ohunkóhun sórí ìjókòó, àfi tó o bá fẹ́ gba àyè náà sílẹ̀ fún ẹnì kan.

ÌRÌBỌMI Àwọn ìjókòó tó wà níwájú pèpéle la yà sọ́tọ̀ fún àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi, àyàfi tá a bá ṣe ìfilọ̀ míì tó yàtọ̀ sí èyí. Kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ti jókòó síbẹ̀ kí àsọyé ìrìbọmi tó bẹ̀rẹ̀ láàárọ̀ Saturday. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú aṣọ ìnura àti aṣọ tó bójú mu tó máa fi ṣèrìbọmi dá ní.

IṢẸ́ ÌYỌ̀ǸDA ARA ẸNI Tó o bá fẹ́ yọ̀ǹda ara ẹ láti ṣe nínú àwọn iṣẹ́ tó wà ní àpéjọ yìí, jọ̀wọ́ lọ sí Ẹ̀ka Ìsọfúnni àti Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni.

ÌTỌ́JÚ RÁŃPẸ́ Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé ìtọ́jú pàjáwìrì nìkan ni ẹ̀ka yìí wà fún.

ỌRẸ Owó kékeré kọ́ la ná láti pèsè ìjókòó tó pọ̀ tó, ẹ̀rọ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ àtèyí tó ń gbé fídíò jáde, tó fi mọ́ àwọn nǹkan míì tó mú kí àpéjọ yìí gbádùn mọ́ni, kí á sì lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọrẹ àtinúwá tó o bá ṣe jẹ́ ara ohun tá a fi máa kájú àwọn ìnáwó yìí, á sì tún jẹ́ ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tá à ń ṣe. Kó lè rọ̀ ẹ́ lọ́rùn, a ti gbé àwọn àpótí ọrẹ sí ọ̀pọ̀ ibi káàkiri Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí. O sì tún lè fowó ṣètìlẹyìn lórí ìkànnì donate.jw.org. A mọrírì gbogbo ọrẹ tá a bá rí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín lórí ọrẹ àtinúwá tẹ́ ẹ bá ṣe kẹ́ ẹ lè ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn.

Tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣètò

© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́