ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/1 ojú ìwé 8-9
  • “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Pílátù Sọ Pé: “Ẹ Wò Ó! Ọkùnrin Náà Nìyí!”
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Lati Ọ̀dọ̀ Pilatu Sọdọ Hẹrọdu A sì Tún Rán an Pada
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/1 ojú ìwé 8-9

Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu

“Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”

BI A ti ṣí i lórí nipa ọ̀nà ìhùwà Jesu ti o si ri àìmọwọ́mẹsẹ̀ rẹ̀ dájú ṣáká, Pilatu wa ọ̀nà miiran lati tú u silẹ. “Ẹyin ní àṣà kan,” ni oun sọ fun awọn ogunlọgọ naa, “pe kí emi ki o da ọ̀kan silẹ fun yin nigba àjọ ìrékọjá.”

Barabba, òṣìkàpànìyàn olókìkí burúkú kan, ni a tún mú gẹgẹbi ẹlẹ́wọ̀n, nitori naa Pilatu beere pe: “Tani ẹyin nfẹ́ kí emi dá sílẹ̀ fun yin? Barabba, tabi Jesu tí a ńpè ní Kristi?”

Bi o ti jẹ pe awọn olórí alufaa ti yí wọn lérò padà tí wọn sì ti ru wọn sókè, awọn ènìyàn naa beere fun ìtúsílẹ̀ Barabba ati fun pípa Jesu. Láìjuwọ́sílẹ̀, Pilatu dáhùnpadà, ní bibeere lẹẹkan síi: “Ninu awọn mejeeji, ewo ni ẹyin fẹ́ kí emi da silẹ fun yin?”

“Barabba,” ni wọn kígbe.

“Kinni emi yoo ha ṣe sí Jesu ẹni tí a ńpè ní Kristi?” Pilatu beere ninu ìdààmú oun ibẹru.

Pẹlu ìkéramúramù adinilétí kan, wọn dahun pe: “Jẹ́ kí ó di kíkàn mọ́gi!” “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”

Ní mímọ̀ pe wọn ńfi dandan béèrè ikú ọkunrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan, Pilatu jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe: “Eeṣe, búburú kinni ọkunrin yii ṣe? Emi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nitori naa emi yoo nà án, emi yoo sì jọwọ rẹ lọwọ lọ.”

Láìka awọn ìgbìdánwò rẹ̀ sí, ogunlọgọ oníbìínú naa tí awọn aṣaaju isin wọn rusoke ńbá kíkérara lọ: “Jẹ́ kí ó di kíkàn mọ́ igi!” Bi awọn alufaa ti fipamú wọn lati ní ìgbónára ewèlè, ogunlọgọ naa ńfẹ́ ẹ̀jẹ̀. Kí a ronu nipa rẹ̀ ná, kìkì ọjọ́ márùn-ún ṣaaju, diẹ ninu wọn ni ó ṣeeṣe kí wọn ti wà lára awọn wọnni tí wọn kí Jesu káàbọ̀ sí Jerusalẹmu gẹgẹbi Ọba! Ni gbogbo àkókò naa, awọn ọmọ-ẹhin Jesu, bí wọn bá wà níbẹ̀, wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ a kò sì lè kiyesi wọn.

Ní ríri i pe ìfọ̀rànlọ̀ oun kò ṣe rere kankan ṣugbọn, kàkàbẹ́ẹ̀, irukerudo ni ó bẹsilẹ, Pilatu bu omi ó sì fọ ọwọ́ rẹ̀ niwaju ogunlọgọ naa, ó sì wipe: “Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ̀ ènìyàn olóòótọ́ yii: ẹ maa bójútó o.” Ní bayii awọn ènìyàn naa dáhùn pe: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, ati lórí awọn ọmọ wa.”

Nitori naa, ní ìbámu pẹlu ohun ti wọn fi dandangbọ̀n béèrè—ati fífẹ́ lati tẹ́ ogunlọgọ naa lọ́rùn ju lati ṣe ohun tí ó tọ̀nà lọ—Pilatu tú Barabba silẹ fun wọn. Oun mú Jesu ó sì jẹ́ kí wọn bọ́ ọ ní aṣọ ki wọn sì nà án lọ́rẹ́ lẹhin naa. Eyi kii ṣe nínà ní pàṣán ṣákálá. The Journal of the American Medical Association ṣàpèjúwe àṣà ìnanilọ́rẹ́ awọn ará Romu:

“Ohun-èèlò ti a saba maa nlo ni pàṣán tẹ́ẹ́rẹ́ (flagrum tabi flagellum) kòbókò awọ ẹlẹ́yọkọọkan melookan tabi alahunpọ tí gígùn wọn kò báradọ́gba, ti a wa so awọn irin ródóródó kéékèèké tabi awọn eegun àgùtàn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ mímú mọ́ kaakiri. . . . Bí awọn ọmọ-ogun Romu ti ńlu ẹ̀hìn òjìyà naa léraléra pẹlu ipá, awọn irin ródóródó naa yoo dá awọn ìdáranjẹ̀ jíjìn, kòbókò aláwọ naa ati awọn egun àgùtàn yoo sì bẹ́ awọ ara naa ati awọn ẹran isalẹ awọ. Nigbanaa, bí ìnàlọ́rẹ́ naa ti nbaalọ, ara ti nbẹ naa yoo fayakan awọn iṣu-ẹran ti wọn wà lara eegun yoo sì sọ ẹran-ara di ẹlẹ́jẹ̀ jálajàla.”

Lẹhin nínà onídàálóró yii, Jesu ni a mú wọnú ààfin gómìnà lọ, a si pe gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun jọ. Nibẹ ni awọn ọmọ-ogun ti hàn án léèmọ̀ siwaju síi nipa híhun adé ẹ̀gún kan tí wọn sì tì í bọ orí rẹ̀. Wọn fi esùsú bọ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, wọn sì wọ̀ ọ́ láṣọ elése-àlùkò, irú eyi tí awọn ọlọ́ba maa ńwọ̀. Nigba naa ni wọn wí fun un lọna ìfiniṣẹlẹ́yà pe: “Kábíyèsí ọba awọn Júù.” Wọn tún tutọ́ sí i lára wọn sì gbá a lójú pẹlu. Ni bibọ èsùsú líle naa ní ọwọ́ rẹ̀, wọn lò ó lati fi lù ú ní orí, ní fífi awọn ẹ̀gún mímú ti “adé” atẹ́nilógo rẹ̀ gún un siwaju síi pẹlu.

Iyì ọlá ati okun pípẹtẹrí Jesu lójú ìfojú-ẹni-gbolẹ̀ wú Pilatu lórí tobẹẹ tí a fi sún un lati ṣe ìgbìdánwò miiran lati tún un ràpadà. “Ẹ wò ó! Mo mú un jáde tọ̀ yin wá, kí ẹyin baa lè mọ̀ pe, emi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀,” ni oun sọ fun awọn ogunlọgọ naa. Ó ṣeeṣe kí ó wòye pe ìrísí ipò ìdálóró Jesu yoo rọ awọn ènìyàn naa lọkan. Bí Jesu ti dúró niwaju àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn aláìláàánú naa, ni wíwọ adé ẹlẹ́gùn-ún ati ẹwu elésè-àlùkò pẹlu ojú rẹ̀ tí ńṣẹ̀jẹ̀ pẹlu ìrora, Pilatu pòkìkí pe: “Ẹ wò ó! Ọkunrin naa!”—New World Translation.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe a dọgbẹ sii lara ti a si ti han an leemọ ika, níhìn-ín ni sàràkí ẹ̀dá títayọ julọ ninu gbogbo ìtàn dúró, ọkunrin títóbi jùlọ nitootọ tí ó tíì gbé láyé rí! Bẹẹni, Jesu fi iyì-ọlá dídákẹ́rọ́rọ́ ati ìparọ́rọ́ han eyi tí ó tọka si ìtóbilọ́lá kan tí Pilatu pàápàá gbọdọ jẹ́wọ́, nitori awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọna tí ó hàn gbangba jẹ́ ìdàpọ̀mọ́ra ọ̀wọ̀ ati ìkáàánú. Johanu 18:39–19:5; Matiu 27:15-17, 20-30, NW; Maaku 15:6-19; Luku 23:18-25.

◆ Ní ọ̀nà wo ni Pilatu fi gbìdánwò lati tú Jesu silẹ?

◆ Bawo ni Pilatu ṣe gbìyànjú lati tú araarẹ̀ silẹ kuro lọwọ ẹrù-iṣẹ́?

◆ Kinni jíjẹ́ ẹni tí a nàlọ́rẹ́ ní ninu?

◆ Bawo ni a ṣe fi Jesu ṣẹlẹ́yà lẹhin tí a ti nà án lọ́rẹ́?

◆ Ìgbìdánwò siwaju síi wo ni Pilatu ṣe lati tú Jesu silẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́