ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/15 ojú ìwé 24-29
  • Èdè Mímọ́gaara So Ogunlọgọ Nla Awọn Olùjọsìn Pọ̀ Ṣọ̀kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èdè Mímọ́gaara So Ogunlọgọ Nla Awọn Olùjọsìn Pọ̀ Ṣọ̀kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Èdè Mímọ́gaara fun Gbogbo Awọn Orilẹ-ede”
  • Kikọ Èdè Mímọ́gaara Naa
  • Ounjẹ Lile Nipa Tẹmi
  • Sisọ Èdè Mímọ́gaara Naa Tumọsi Fifi Ifẹ Ara Han
  • Sisọ Èdè Mímọ́gaara Naa Tumọsi Kikiyesi Iwa Wa
  • Imọran Èdè Mímọ́gaara fun Awọn Idile
  • Sisọ Èdè Mímọ́gaara naa fun Awọn Ẹlomiran
  • Awọn Itẹjade Apejọpọ
  • Ọrọ Asọye Fun Gbogbo Eniyan ati Awọn Ọ̀rọ̀ Ìparí
  • Sọ Èdè Mímọ́gaara naa Ki O Si Walaaye Titilae!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Èdè Mímọ́gaara fun Gbogbo Awọn Orilẹ-Ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹ Nà ni Iṣọkan Nipasẹ Èdè Mímọ́gaara Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/15 ojú ìwé 24-29

Èdè Mímọ́gaara So Ogunlọgọ Nla Awọn Olùjọsìn Pọ̀ Ṣọ̀kan

ÈDÈ mímọ́gaara ti Ọlọrun fifunni jẹ ipá kan fun iṣọkan Kristian. Ẹri iyẹn han kedere sí gbogbo eniyan ti wọn wá si apejọpọ awọn Ẹlẹrii Jehofa ti a ṣe ni Iwọ-oorun Berlin lati Tuesday titi de Friday, July 24 sí 27, 1990, niwọnbi o ti jẹ pe awọn Ẹlẹrii lati 64 awọn ilẹ orilẹ ede ọtọọtọ ni wọn  wa.

Nigba ti a ṣe Apejọpọ Agbegbe “Ifọkansin Oniwa-bi-Ọlọrun” ni Poland nigba ẹ̀rùn ti 1989, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ayanṣoju wá lati Russia ati Czechoslovakia, ṣugbọn kiki iwọnba ọgọrun-un diẹ lati Ila-oorun Germany ni wọn wanibẹ. Bawo ni ipo ti aye wà niti ọran oṣelu ti yipada lati igba naa to! Lọ́tẹ̀ yii, awọn ayanṣaṣoju ti a fojudiwọn iye wọn si 30,000 lati Ila-oorun Germany pade pẹlu awọn Ẹlẹrii ninu Papa Iṣere Olympia ni Iwọ-oorun Berlin. Apejọpọ naa jẹ apẹẹrẹ ọgọrọọrun ti a ṣe ni awọn apa ibomiran ni aye, ti o jẹ lati Thursday si Sunday ni ibi pupọ.

Ninu ọ̀rọ̀ ikinnikaabọ rẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ni Tuesday, alaga naa rohin ipa tí awọn apejọpọ ti kó lati 1919 ninu riran awọn Ẹlẹrii Jehofa lọwọ lati ní itẹsiwaju ninu sisọ èdè mímọ́gaara naa. Apejọpọ yii yoo ran gbogbo eniyan ti wọn wàníbẹ̀ lọwọ bakan naa lati mu agbara wọn lati sọ èdè mímọ́gaara naa sunwọn sii ati lati gbe ni ibamu pẹlu rẹ. O ran awọn ayanṣaṣoju naa leti pe nipa iwọṣọ ati iwa wọn gan-an, awọn eniyan Jehofa nfi itẹsiwaju ti wọn ti ni han ninu sisọ èdè mímọ́gaara naa.

“Èdè Mímọ́gaara fun Gbogbo Awọn Orilẹ-ede”

Lọna bibamurẹgi, ọrọ-asọye lajori-ero ti apejọpọ naa gbe ẹṣin-ọrọ ti a mẹnukan ṣaaju naa jade lakanṣe. A gbe e kari Sẹfanaya 3:9 (NW), nibi ti Ọlọrun ti ṣeleri: “Nigba naa ni emi yoo fi iyipada si èdè mímọ́gaara kan fun awọn eniyan nitori ki gbogbo wọn baa le maa kepe orukọ Jehofa, lati le maa ṣiṣẹsin in ni ifẹgbẹkẹgbẹ.” Èdè mímọ́gaara naa wemọ iloye ati imọriri titọna ti otitọ nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀. Jehofa nikan ni o le pese eyi nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀. Ifẹ fun otitọ gbọdọ jẹ isunniṣe fun kikẹkọọ èdè mímọ́gaara naa, ọkan ti o wa bọ lọwọ gbogbo aimọ niti ọ̀nà iwahihu.

Siwaju sii pẹlu, sisọ èdè mímọ́gaara naa kii wulẹ ṣe ọran lilo ọrọ ede kan ni pato. Kaka bẹẹ, ọna igbesi aye wa gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ohun ti o njade lati ẹnu wa. Niti tootọ, ìró ohùn wa, awọn ifihanjade oju wa, ati awọn ifaraṣapejuwe tun ṣepataki, nitori wọn nfi ohun ti a jẹ ninu han. Lati maa wa deedee pẹlu èdè mímọ́gaara naa tí ngbooro sii, awa gbọdọ ní itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọ ti o ṣedeedee ki a si maa lọ si gbogbo awọn ipade ijọ deedee.

Kikọ Èdè Mímọ́gaara Naa

Gẹgẹ bi ọrọ-asọye kan ni ọsan ọjọ Tuesday ti tẹnumọ ọn, kikọ èdè mímọ́gaara tumọsi “Titẹsiwaju Lati Ori awọn Koko-ipilẹ si Idagbadenu.” Idagba ṣekoko bi awa ba nilati maa dagba nipa tẹmi. Iyẹn tumọsi lilo anfaani gbogbo awọn ipese fun itẹsiwaju nipa tẹmi ati fifi awọn ilana Bibeli silo lojoojumọ.

Lati di ogboṣaṣa ninu èdè mímọ́gaara naa, a gbọdọ “Kọ Wa lati Ọdọ Jehofa,” akori apinsọ ọrọ-asọye ni owurọ Thursday. Olubanisọrọ akọkọ fi bi ‘Jesu Kristi ti Jẹ Awofiṣapẹẹrẹ’ eyi han. Pe a kọ Jesu lẹkọọ lati ọdọ Jehofa han kedere lati inu awọn ọrọ ati iṣe rẹ̀. Nitori naa awa fẹ ṣafarawe rẹ ninu bi oun ṣe kọnilẹkọọ. Ati gẹgẹ bi Jesu ti njuwọsilẹ fun ifẹ inu Baba rẹ nigbagbogbo, bẹẹ ni awa gbọdọ ṣe.

Awọn olubanisọrọ mẹta ti wọn tẹle e fi bi Jehofa ti nkọnilẹkọọ han nipasẹ awọn ipade ati apejọ. Awa njere lati inu gbogbo awọn ipade ijọ maraarun a ko si nilati ṣainaani eyikeyii ninu wọn. Ipade kọọkan ṣepataki fun itẹsiwaju wa tẹmi. Jehofa tún nkọ wa lẹkọọ nipasẹ awọn itolẹsẹẹsẹ apejọ ayika, apejọpọ agbegbe, ati ọjọ apejọ akanṣe wa. Lati jere lati inu gbogbo iwọnyi, awa gbọdọ fetisilẹ daradara ki a sì fi ohun ti a kẹkọọ rẹ ṣe iwa hù.

Apinsọ ọrọ-asọye yii ni ọrọ-asọye naa “Fifi Nnkan Rubọ nitori Ibaralẹ-kẹkọọ ti Ara-ẹni” tẹle. Lati wa aye fun un, awa gbọdọ kọbiarasi imọran ti o wà ni Efesu 5:15, 16 lati ra akoko pada lati inu awọn ohun alaiṣepataki.

Gongo ilepa bibọgbọnmu ti kikọ èdè mímọ́gaara wa ni iyasimimọ ati baptism. Otitọ yii ni a tẹnumọ ninu ọrọ-asọye naa “Baptism fun Awọn Wọnni Ti Nkẹkọọ Èdè Mímọ́gaara.” Ede yii nṣamọna ọpọlọpọ si iyasimimọ ati baptism. Bi o ti wu ki o ri, ẹnikan lẹhin naa gbọdọ maa baa lọ lati tẹle awokọṣe Jesu nipa wiwaasu ihinrere naa pẹlu itara, gbigbe animọ iwa titun wọ, ati yiyasọtọ kuro ninu aye.

Ounjẹ Lile Nipa Tẹmi

Awọn olupejọpọ tun ni inudidun lati gba ounjẹ tẹmi lile ti a gbekari imuṣẹ awọn iran ẹ̀kọ́ alasọtẹlẹ. Ni ọsan Thursday, asọye meji ni a gbekari awọn ẹṣin-ọrọ ti a mu lati inu asọtẹlẹ Esekiẹli. Ekinni, “Kẹkẹ-Ẹṣin Oke Ọrun ti Jehofa wa lori Irin,” ṣapejuwe àrágbabú ọkọ oke ọrun, ológo, amuni kun fun ẹ̀rù ti nlọ pẹlu iyarasare manamana. O yaworan eto-ajọ ọrun ti Jehofa, eyi ti Ọlọrun gun niti pe oun nfi ifẹ dari iṣisẹ rẹ ni lilo o lati mu awọn ète rẹ ṣẹ. Esekiẹli ṣapẹẹrẹ aṣẹku ẹni ami ororo ti a fi ẹmi yàn ni pataki lati 1919. Paapaa lati 1935 ni “ogunlọgọ nla” ti darapọ mọ wọn.—Iṣipaya 7:9.

Ọrọ asọye ti o tẹle e ni a fun ni akọle “Maa Ṣisẹrin Ni Ìyára Kan-naa Pẹlu Eto-ajọ Ti A Le Fojuri Naa.” Ko si iyemeji pe eto-ajọ rẹ ti oke-ọrun ti o dabii kẹkẹ-ẹṣin oke ọrun rẹ. Gẹgẹ bi Esekiẹli, awọn iranṣẹ Jehofa lonii gbọdọ mu iṣẹ-aṣẹ alasọtẹlẹ wọn ṣe pẹlu igbọran laika idagunla, ipẹgan, tabi atako paapaa si. Ṣiṣisẹrin pẹlu ìyára kan-naa nṣamọna si ọpọlọpọ ibukun nisinsinyi ati iye ainipẹkun ninu aye titun Ọlọrun ti nyarakankan sunmọle naa.

Ni owurọ Friday, ounjẹ lile nipa tẹmi ni a tun pese nipasẹ asọye mẹta ti a gbekari Aisaya ori-iwe 28. Akọkọ ninu iwọnyi fihan ni awọn ede isọrọ alagbara ipá pe imutipara tẹmi ti Israẹli ati Judah igbaani yaworan ṣapẹẹrẹ imutipara tẹmi ti Kristendom. Ati gẹgẹbi eyi akọkọ ti ni iriri awọn idajọ mimuna ti Jehofa, bẹẹ ni awọn wọnni ti Kristendom yoo ni.

Ọrọ asọye ti o tẹle e, ti lakọle rẹ̀ jẹ “Aabo-isadi Wọn—Irọ Ni!,” ni ikilọ rírorò naa ninu: Gan-an gẹgẹbi igbọkanle Judah igbaani ninu Ijibiti ti jasi aabo-isadi asan, bẹẹ ni ibaṣọrẹ Kristendom pẹlu awọn alagbara oloṣelu ti ọjọ wa. Ọrọ asọye kẹta lori Aisaya ori-iwe 28, “Maa Baa Niṣo Ni Ṣiṣekilọ Aramanda-ọtọ Iṣẹ Jehofa,” ni a dari si awọn eniyan Ọlọrun. Ohun ti Jehofa yoo ṣe si Kristendom ni a pè ni aramanda-ọtọ lọna titọ, nitori yoo de lojiji patapata si i. Lonii, Jehofa jẹ ade ogo fun agbo kekere ti awọn Kristian ẹni ami ororo ati fun “awọn agutan miiran” ti wọn ju aadọta ọkẹ mẹrin. (Johanu 10:16) Olubanisọrọ naa pari ọrọ pẹlu awọn ọrọ arunisoke naa: “Njẹ ki itara, ìpinnu, ati iduroṣinṣin wa fikun iyin ayeraye Ọlọrun wa, Jehofa!”

Sisọ Èdè Mímọ́gaara Naa Tumọsi Fifi Ifẹ Ara Han

Ni ọsan Wednesday awọn olupejọpọ naa ni a mu ṣekedere fun pe sisọ èdè mímọ́gaara tun tumọsi lati “Gba Ti Awọn Ọmọ Alailobi ati Opo Rò ninu Ipọnju Wọn.” Awọn ọmọ alainibaba ni a le ranlọwọ nipa rírí idanilẹkọọ ara ẹni gba. Awa le fi igbatẹniro han fun awọn opo nipa awọn ọrọ oninuure ti iṣiri, nipa fifi wọn kun awọn igbokegbodo Kristian ati awọn ikorajọ ẹgbẹ oun ọgba wa, ati nipa fifun wọn ni itilẹhin ohun ti ara bi wọn ba lẹtọọsi ti wọn si wa ninu aini nitootọ. Awọn ifọrọwanilẹnuwo fi bi a ti nṣe awọn nnkan wọnyi han.

Ni ọsan Thursday, ọrọ-asọye amọkanyọ miiran fi “Bi Awọn Kristian Ṣe Nbikita fun Araawọn Ẹnikinni Keji” hàn. Awọn Ẹlẹrii Jehofa ni akọsilẹ rere ti bibikita fun araawọn, paapaa nigba ti iru awọn jàm̀bá gẹgẹbi ìjì lile ati isẹlẹ ba ṣẹlẹ, nigba ti aini lati kọwe si awọn oṣiṣẹ oloye ba wà, tabi nigba ti awọn aini adugbo ba wà. Ṣugbọn nigba ti awọn iṣoro ba dide nitori aipe ẹda eniyan, awa nilati fi awọn ilana ipilẹ ti o wemọ ọn ninu imọran Jesu ni Matiu 5:23, 24 ati 18:15-17 silo. Paapaa ni pataki nigba ti o ba di iṣẹ aje laaarin awọn arakunrin ni aini fun ọ̀wọ̀ tọtuntosi ati lilo iṣọra wà ki o ba le jẹ pe yala agbanisiṣẹ naa tabi ẹni a gbasiṣẹ kò lo anfaani ipo ibatan tẹmi naa lọna imọtara ẹni nikan.

Sisọ Èdè Mímọ́gaara Naa Tumọsi Kikiyesi Iwa Wa

Aini naa lati kiyesi iwa wa ni a tẹnumọ leralera. Nipa bayii, olubanisọrọ akọkọ ni ọsan Tuesday sọrọ lori ẹṣin-ọrọ naa “Gbigbọ ati Pipa Ọrọ Ọlọrun Mọ.” Oun fihan pe lajori idi meji ni ó wa fun wiwa ti a nwa si awọn apejọpọ: lati gba imọ pipeye ati lati sun wa lati huwa lori imọ yẹn.

Ọrọ asọye akọkọ ni owurọ Wednesday gbe ibeere ti nyẹniwo kinnikinni naa “Kristi ‘Koriira Iwa Ailofin’—Iwọ Ha Koriira Rẹ̀ Bí?” ka iwaju wa. Ko to lati nifẹẹ iwa ododo. Awa gbọdọ tun koriira iwa ailofin ki a baa le ni ẹri-ọkan rere, lati ni ibatan rere titilọ pẹlu Jehofa, lati yẹrafun mimu ẹgan wa sori orukọ rẹ, lati yẹrafun kíká eso iwa ailofin—idibajẹ, ati iku.

Eyi ti o tun farajọ ẹṣin-ọrọ yẹn ni Ọrọ-asọye ti o tẹle e, ti a fun ni akọle naa “Ṣá Awọn Àlá-asán Ayé Tì, Lépa Awọn Otitọ-gidi Ijọba Naa.” Satani, Efa, ati awọn angẹli abẹṣẹ̀, gbogbo wọn lepa awọn àlá asán si iparun wọn. Awọn àlá asan aye, ti o ni ninu awọn àlá ifẹ ọrọ àlùmọ́nì tabi awọn wọnni ti o niiṣe pẹlu awọn àlámọ̀rí takọtabo aláìbófinmu, nyọrisi rírídìí otitọ lọna kikoro nikẹhin bi kii ba ṣe iwa aitọ buburu jai pẹlu. Lati gbejako awọn àlá asán wọnyi, awa gbọdọ lepa awọn otitọ gidi ti Ijọba nipasẹ ikẹkọọ, adura, lilọ si ipade, ati iṣẹ-ojiṣẹ ita gbangba.

Lati gbe igbesi-aye Kristian aduroṣanṣan, awa gbọdọ tun kọbiarasi imọran ti a funni ní ọsan Wednesday ninu ọrọ-asọye naa “Ẹyin Kristian—Ẹ Gbé Ìgbé-ayé Ní Ìbámu Pẹlu Iye-owó-tí-ńwọléwá fun Yin.” Kikuna lati ṣe eyi ni o nilati ni awọn iyọrisi apanilara nipa ti ara ati nipa ti ẹmi. Ipa ọna ọlọgbọn ni lati ṣakoso awọn ìyánhànhàn onimọtara ẹni nikan nipa ṣiṣai kowọnu gbese alainidii ati nipa wiwewee eto inawo ti o ṣee tẹle ki o si rọ̀ mọ ọn. Ni gbogbo igba awa nilo lati mu ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun dagba. Papọ pẹlu ẹmi ohun moni tomi, eyi jẹ ọna ere ńláǹlà.—1 Timoti 6:6-8.

Ijẹpataki kikiyesi awọn alabaakẹgbẹ wa ni a tẹnumọ ninu ọrọ-asọye Tuesday naa “Awọn Ọ̀rẹ́ Rẹ Ha Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jehofa Bí?” Awọn ọ̀rẹ́ wa nilati jẹ Kristian ti wọn ti gbe animọ iwa bii ti Kristi wọ ti wọn si jẹ onitara ninu iṣẹ iwaasu. Awọn ojulumọ ti aye kii ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọrun, awa ko si le kẹgbẹ pẹlu wọn laisi ipalara si araawa. Ani ninu ijọ paapaa, awa gbọdọ ṣe aṣayan bi awọn ibakẹgbẹpọ wa ba nilati jẹ agbeniro nitootọ.

Imọran ti a mẹnukan ṣaaju nipa ihuwasi ni a tẹnumọ apẹẹrẹ nipa awokẹkọọ ti ode oni naa. O ni akọle naa “Kíkojúkápá Awọn Ìṣe Àrékérekè Eṣu.”

Imọran Èdè Mímọ́gaara fun Awọn Idile

Ohun ti a nilo gidigidi ni ọrọ-asọye Wednesday naa “Ẹyin Òbí—Ẹ Mu Awọn Iṣẹ-Aigbọdọmaṣe Yin Ṣẹ!” Awọn òbí funraawọn gbọdọ mọ ifẹ inu Ọlọrun ki wọn sì maa ṣe de ibi ti agbara wọn mọ. Wọn tún gbọdọ fi itẹnumọ gbìn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sinu awọn ọmọ wọn. Ju bẹẹ lọ, kò tó lati wulẹ mu awọn ọmọ lọ si awọn ipade Kristian ati jade ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá. A gbọdọ kọ wọn lati nifẹẹ Jehofa ati lati ri ọgbọ́n aṣeemulo ti o wà ninu ṣiṣe awọn ohun oniwa-bi-Ọlọrun.

Tẹle e ni apinsọ ọrọ-asọye kan lori “Idile ni Ọjọ Wa.” Olubanisọrọ akọkọ fihan pe idile pilẹṣẹ lọdọ Ọlọrun. Awọn Baba gbọdọ maa jumọsọrọpọ daradara nipa awọn ọran tẹmi. Awọn iya gbọdọ jẹ atúnléṣe rere, awọn ọmọ sì gbọdọ fi ọ̀wọ̀ han fun Jehofa nipa fifọwọsowọpọ pẹlu awọn obi wọn.

Olubanisọrọ ti o tẹle e fihan pe idile “Wàlábẹ́ Ìkọlùlójijì lati Ọwọ́ Awọn Elénìní.” Awọn ikimọlẹ ti iṣunna owo ti ńfà àdánù tiwọn. Awọn ibi-iṣẹ́ kun fọfọ awọn ìdẹwò lati huwa aitọ, awọn igbekalẹ ile-iṣẹ irohin si kun fun iwa-ipa, ibalopọ takọtabo alaibofinmu, ati fifi ifẹ ọrọ alumọọni fanimọra. Ìtọni gbọdọ bẹrẹ ni kutukutu, aapọn ńláǹlà ni a sì beere fun lati bori awọn agbara idari aye. A gbọdọ lo awọn ohun eelo ti iṣakoso Ọlọrun ti a pèsè lati ọwọ́ Watch Tower Society lọna rere.

Ọrọ asọye ti o tẹle e, ti o niiṣe pẹlu ‘Itọjupamọ Idile Wọnu Aye Titun,’ tubọ tẹnumọ ẹru-iṣẹ wiwuwo tí awọn òbí ní. Titọ awọn ọmọ ni a gbọdọ ṣe pẹlu ifọkansi titobi julọ. Imọran rere ni a fifunni nipa ikẹkọọ Bibeli idile ati ohun ti a nilati kẹkọọ, gbogbo rẹ pẹlu ète dide inu ọkan-aya awọn ọmọ. Kiki nigba naa ni awọn òbí ati awọn ọmọ to le nireti itọjupamọ wọnu aye titun gẹgẹ bi idile.

Ọrọ asọye naa “Kíkojúkápá Láàárín Agbo-ilé Tí Ó Pín-yẹ́lẹyẹ̀lẹ” pese imọran rere fun ipo idile ninu eyi ti ọpọlọpọ awọn Ẹlẹrii ba araawọn. Awọn wọnni ti wọn wà ninu iru awọn ipò bẹẹ ni a gbànimọran lati maṣe sọretinu pe alaigbagbọ naa le di onigbagbọ ni ọjọ kan. Lo akoko pẹlu alaigbagbọ olubaṣegbeyawo naa ki o si rii daju pe o kun oju oṣuwọn gbogbo ohun ti a beere fun lọwọ Kristian olubaṣegbeyawo kan. Iwọ le ri iranlọwọ gba lati ọwọ awọn alagba tabi boya lati ọwọ awọn miiran ti wọn wà ninu agbo-ile ti o pín-yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

Sisọ Èdè Mímọ́gaara naa fun Awọn Ẹlomiran

Lọna bibamurẹgi julọ, afiyesi pupọ ni a fifun lilo awọn anfaani lati kọ awọn ẹlomiran ni èdè mímọ́gaara naa. Nipa bayii, ni owurọ Wednesday awọn olupejọpọ gbọ ọrọ-asọye naa “Lo Akoko Ṣiṣeyebiye Rẹ Lọna Ọgbọn.” Lati ṣe iyẹn a gbọdọ fìdí awọn ohun akọmuṣe mulẹ, lati wà ni ibamu pẹlu Matiu 6:33, eyi ti o wipe: “Ẹ tete maa wa ijọba Ọlọrun na, ati òdodo rẹ; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o sì fikun yin.” Iyẹn nii ṣe pẹlu yiya akoko sọtọ fun ikẹkọọ Bibeli funra-ẹni, lilọ si gbogbo awọn ipade, ati ṣiṣedeedee ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá. Eyi nbeere pe ki a ra akoko pada lati inu awọn igbokegbodo ti ko fi bẹẹ ṣepataki bi o tilẹ jẹ pe o gbadunmọni. Awọn ifọrọwanilẹnuwo melookan fi bi awọn kan ṣe nṣe eyi han.

Awa ko gbọdọ gbagbe lae pe awa jẹ Ẹlẹrii Jehofa. Ni ọsan Thursday, iye awọn aṣefihan melookan fi koko yẹn gan-an yeni kedere labẹ ẹṣin-ọrọ naa “Maa Sọ Èdè Mímọ́gaara ní Gbogbo Akoko-iṣẹlẹ.” Awọn aṣefihan wọnyi fi bi a ṣe lè ṣe eyi hàn ninu ijẹrii òpópónà, ijẹrii laijẹ bi àṣà, ati nipa lilo tẹlifoonu. Ifẹ ainimọtara ẹni nikan fun Jehofa Ọlọrun ati awọn aladuugbo wa yoo sún wa lati sọ èdè mímọ́gaara ni gbogbo akoko ti o ba ṣisilẹ.

Eyi ti o farajọ ẹṣin-ọrọ yii pẹkipẹki ni igbekalẹ ọrọ ti o tẹle e naa “Awọn Ibukun Awọn Wọnni ti Wọn Kò Tọrọ Gááfárà.” Ni iyatọ gédégédé si Kristendom ni ikọni ètò-àjọ ti awọn Ẹlẹrii Jehofa yika aye. Lẹnikọọkan, awa gbọdọ dena gbogbo awọn ikimọlẹ, iru gẹgẹbi atako awọn alaṣẹ, ẹ̀mí ìdágunlá tí ó tankalẹ, ati awọn iṣoro ti iṣunna owo. Awọn aṣefihan ti a gbekari iwe naa Reasoning From the Scriptures fi bi a ṣe lè bori awọn ikimọlẹ wọnyi hàn.

Eyi ti o tun fun iwaasu onitara ni iṣiri ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa Ṣiṣe Ifẹ-inu Ọlọrun Pẹlu Itara. O fi bi Jehu ti jẹ onitara fun orukọ Jehofa han ati bi o ti ṣepataki to fun wa lati fi igboya ti o farajọra ati itara fun iṣẹ Ọlọrun han.

Awọn Itẹjade Apejọpọ

Awọn itẹjade titayọ meji ni ede Gẹẹsi ati German wà ni apejọpọ naa. Akọkọ ninu awọn itẹjade wọnyi ni a filọ ni isopọ pẹlu ọrọ-asọye ti o ni akọle naa “Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹ̀mí Rẹ Là—Bawo?” Olubanisọrọ naa kọkọ sọ nipa awọn ewu ti o sopọ mọ ifajẹsinilara. Oun tọka jade pe ọpọlọpọ awọn afidipo fun ẹ̀jẹ̀ ni wọn wà ti a lè lò lati fi dipo iṣofo ẹ̀jẹ̀. Ṣugbọn awọn Ẹlẹrii Jehofa fasẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀ kii ṣe nitori pe o jẹ améwulọ́wọ́ ni ṣugbọn nitori pe gbigba a jẹ aláìmọ́. Wọn fasẹhin, kii ṣe nitori pe a ti lè sọ ẹ̀jẹ̀ di eléèérí, ṣugbọn nitori pe o ṣeyebiye si Ọlọrun. Ẹ̀jẹ̀ ti o jẹ agbẹ̀mílà nitootọ ni ẹ̀jẹ̀ aranipada ti Jesu Kristi. Ní ipari olubanisọrọ naa mu inu gbogbo awọn olufetisilẹ rẹ̀ dùn nipa nina ìwé pẹlẹbẹ oloju ewe 32 naa How Can Blood Save Your Life? sita ni gbangba.

Itẹjade aṣeyebiye miiran wa ni isopọ pẹlu ọrọ-asọye naa “Ẹ Wá Jehofa Kínníkínní, Ẹyin Eniyan.” Ni ọpọ julọ, awọn eniyan kò wa Jehofa kínníkínní. Wíwà ọpọlọpọ awọn isin ọtọọtọ fihan bi iwakiri eniyan fun Ọlọrun ti jẹ oníṣìnà to nitori pe oun ti ṣa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tì. Gẹgẹ bi a ti ríi nipasẹ awọn irohin Iṣe-iranti wa lọdọọdun, araadọta ọkẹ ni a nilati ranlọwọ lati mu iduro wọn fun Jehofa. Aisaya 55:6, 7 (NW), fihan pe Jehofa jẹ Ọlọrun onifẹẹ ati alaanu nitootọ, o ṣetan lati “dariji lọna pipọ gan-an.” Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹrii rẹ, a ti fun wa ni èdè mímọ́gaara naa ki a baa le ran awọn ẹlomiran lọwọ lati darapọ mọ wa ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa ni ifẹgbẹkẹgbẹ.

Lonii, awọn eniyan Jehofa dojukọ ipenija kan nitori awọn iṣikaakiri awọn eniyan ilu pupọ jaburata. Gẹgẹ bi iyọrisi, awọn eniyan le fẹnujẹwọ oniruuru isin gbogbo ninu ipinlẹ wa. Ki a baa lè ran awọn onisin Hindu, onisin Buddha, onisin Shinto, ati awọn eniyan ọpọlọpọ isin miiran lọwọ. Society ti pèsè iwe oloju-ewe 384 rere naa Mankind’s Search for God. Oun gbe awọn ẹkọ ti ọla-aṣẹ ipilẹ ti awọn isin jàǹkànjàǹkàn lẹhin ode Kristendom kalẹ. Ṣugbọn o tun tọpasẹ akọsilẹ isin eke laaarin Kristendom. Iwe yii le ṣi ọna silẹ fun bibẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn eniyan ti wọn fẹnujẹwọ ọpọlọpọ isin ọtọọtọ.

Ọrọ Asọye Fun Gbogbo Eniyan ati Awọn Ọ̀rọ̀ Ìparí

“Ẹ Wà Ní Ìsopọ̀ṣọ̀kan nipasẹ Èdè Mímọ́gaara Naa” ni akọle ọrọ-asọye fun gbogbo eniyan ní Friday. Olubanisọrọ naa fihan pe bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹrun mẹta awọn èdè ọtọọtọ nṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn ohun idina fun iṣọkan nisinsinyi, èdè mímọ́gaara naa jẹ ipa asonipọ alagbara kan. O ti daabobo awọn Ẹlẹrii Jehofa lọwọ awọn iṣina Babiloni, o ti kọ wọn ni ọ̀wọ̀ fun ijẹmimọ iwalaaye ati ẹ̀jẹ̀, o si ti ran wọn lọwọ lati gbe ni ibamu pẹlu awọn ilana Bibeli ti o mu wọn jèrè nipa tẹmi ati nipa ti ara. Gbogbo wa ni o jẹ ọranyan fun lati daniyan nipa kikọ ati sisọ èdè mímọ́gaara naa, nitori kiki awọn wọnni ti wọn nṣe bẹẹ ni yoo la Armageddon já. Ko si akoko lati fi ṣofo ninu kikọbiarasi imọran naa ni Sẹfanaya 2:1-3.

Lẹhin imọran rere diẹ ti Iwe Mimọ lori aini naa lati “Wà-lójúfò-rekete Pẹlu Ìpètepèrò fun Gbigba Adura,” ni a funni ni ọrọ akiyesi ipari ti a gbekari ẹṣin-ọrọ naa “Rírìn ní Ìṣọ̀kanbáramu Pẹlu Èdè Mímọ́gaara Naa.” Iye ti o nrin ni ibamu pẹlu èdè mímọ́gaara naa nisinsinyi npọsii nitootọ. Ọ̀wọ̀ fun èdè mímọ́gaara ni a si fihan lati ọwọ awọn wọnni ti wọn pesẹ si awọn apejọpọ wọnyi nipa ìmọ́tónítóní, ìwàlétòlétò, ati ibaramuṣọkan wọn niti eto-ajọ. Awọn itẹjade titun naa yoo ran awọn Ẹlẹrii Jehofa lọwọ lati tan èdè mímọ́gaara naa kalẹ lọna gbigbeṣẹ sii.

Olubanisọrọ ikẹhin fun apejọpọ naa ran gbogbo eniyan leti nipa aini naa fun ifarada. Oun fihan pe gẹgẹ bi iyọrisi apejọpọ yii, gbogbo eniyan ni a nilati funlokun ninu ipinnu wọn lati tẹsiwaju. Lẹhin naa oun pari rẹ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ naa: “Njẹ ki awa maa baa lọ lati maa rin ni ibamu pẹlu èdè mímọ́gaara ti Ọlọrun fifun wa ki awa baa le maa fi ògo fun Baba wa ọrun onifẹẹ, Jehofah Ọlọrun, nisinsinyi ati titi laelae!”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Gongo iye awọn eniyan ti o wà ni apejọpọ ni Iwọ-oorun Berlin jẹ 44,532, ti 1,018 si ṣeribọmi. O gba awọn olùnàgà fun anfaani baptism ni iṣẹju 19 lati to jade kuro ninu Papa-iṣere Olympia naa, ati ni akoko yii, àtẹ́wọ́ ti nbaa lọ ni o wà fun ìgbà pipẹ. Akanṣe ipin kan wa fun awọn ayanṣaṣoju ti nsọ èdè Gẹẹsi. Nnkan bii 6,000 awọn wọnyi gbọ gbogbo itolẹsẹẹsẹ naa ni èdè wọn. Ni apejọpọ yii, awọn 4,500 wá lati Poland pẹlu; laaarin wakati meji ni ọsan, awọn mẹmba Ẹgbẹ Oluṣakoso funni ni awọn ọrọ-asọye ṣoki fun anfaani wọn.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

1. Papa-iṣere Olympia, Iwọ-oorun Berlin

2. Itolẹsẹẹsẹ titẹ ti apejọpọ

3. Ọgọrun-un meji awọn ọkọ̀-èrò gbe awọn ayanṣaṣoju wa lati Ila-oorun Germany

4. Awọn olupejọpọ lati Poland layọ lati gba awọn itẹjade títẹ̀

5. Awọn ìṣelóge olódòdó mu ibi-iran naa tàn yẹbẹyẹbẹ

6. A. D. Schroeder, ọkan lara awọn mẹmba Ẹgbẹ Oluṣakoso lori itolẹsẹẹsẹ ni Iwọ-oorun Berlin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́