Ẹ Di Igbagbọ ati Ẹri-ọkan Rere Mu
Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati Inu Timoti Kìn-ínní
NI NNKAN bii 56 C.E., apọsteli Pọọlu kilọ fun awọn alagba ijọ ni Efesu pe “ikooko buburu” yoo dide laaarin wọn yoo si maa “sọrọ òdì, lati fa awọn ọmọ ẹhin sẹhin wọn.” (Iṣe 20:29, 30) Ni awọn ọdun diẹ, ẹkọ ipẹhinda ti wá lewu rinlẹ debi pe Pọọlu rọ Timoti lati ja ija ogun tẹmi ninu ijọ lati pa ìmọ́gaara rẹ̀ mọ́ ki o si ran awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ lọwọ lati duro ninu igbagbọ. Iyẹn ni lajori idi ti Pọọlu fi kọ lẹta rẹ akọkọ si Timoti lati Masidonia ni nnkan bii 61-64 C.E.
Timoti ni a fun ni itọni nipa awọn ila-iṣẹ alagba, ati àyè ti Ọlọrun yan fun awọn obinrin, awọn ẹ̀rí ìtóótun ti awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ ojiṣẹ, ati awọn ọran miiran. Irufẹ itọni bẹẹ tun ṣanfaani lonii.
Igbaniniyanju si Igbagbọ
Pọọlu beere pẹlu imọran lati di igbagbọ ati ẹri ọkan rere mu. (1Ti 1:1-20) Oun fun Timoti ni iṣiri lati duro ni Efesu ki o si “paṣẹ fun awọn kan, ki wọn ki o maṣe kọni ni ẹkọ miiran.” Pọọlu fi imoore han fun iṣẹ ojiṣẹ ti a yan fun un, ni gbigba pe oun ti fi aimọkan ati aini igbagbọ huwa nigba ti oun ṣe inunibini si awọn ọmọlẹhin Jesu. Aposteli naa paṣẹ fun Timoti lati maa baa lọ ni jija ija ogun tẹmi ‘didi igbagbọ ati ẹri ọkan rere mu’ ki o ma si dabi awọn wọnni ti wọn “rì ọkọ̀ igbagbọ wọn.”
Imọran lori Ijọsin
Lẹhin naa, Pọọlu funni ni imọran gẹgẹ bi “olukọ awọn keferi [“orilẹ ede,” NW] ní igbagbọ ati otitọ.” (2:1-15) Awọn adura ni a nilati gba fun awọn wọnni ti wọn wà ni ipo giga ki awọn Kristian baa le maa gbe ni alaafia. O jẹ ifẹ inu Ọlọrun pe ki a gba oriṣiriṣi eniyan la, ẹkọ pataki kan si ni pe Kristi “fi araarẹ ṣe irapada fun gbogbo eniyan.” Pọọlu fihan pe obinrin kan nilati ṣe araarẹ lọṣọọ niwọntunwọnsi ko si gbọdọ lo ọla-aṣẹ lori ọkunrin.
Ijọ ni a gbọdọ ṣetojọ daradara. (3:1-16) Nitori naa Pọọlu ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ẹri ìtóótun awọn alaboojuto ati iranṣẹ iṣẹ ojiṣẹ. Lati inu awọn ohun ti apọsteli naa kọ, Timoti yoo wá mọ bí oun yoo ṣe dari ara oun ninu ijọ naa, “ọwọ̀n ati ìpìlẹ̀ [“itilẹhin,” NW] otitọ.”
Pọọlu fun Timoti ni imọran ara ẹni lati ran an lọwọ lati ṣọra fun ẹkọ èké. (4:1-16) Ni awọn akoko ọjọ iwaju awọn kan yoo ṣubu kuro ninu igbagbọ. Ṣugbọn nipa fifiyesi ara rẹ̀ ati ẹkọ rẹ̀ leralera, Timoti yoo ‘gba ara rẹ̀ ati awọn ti ngbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ là.’
Timoti tun gba imọran lori biba awọn ẹni kọọkan lò, èwe ati àgbà. (5:1-25) Fun apẹẹrẹ, awọn ìpèsè yiyẹ ni a nilati ṣe fun awọn àgbà opó ti wọn ni orukọ Kristian rere. Dipo ṣíṣòfófó, awọn ọ̀dọ́ opó nilati ṣegbeyawo ki wọn si bi awọn ọmọ. Awọn agba ọkunrin ti wọn nṣakoso ni ọna rere ni a nilati kà kun awọn ti o yẹ fun ọlá ilọpo meji.
Ifọkansin Oniwa-bi-Ọlọrun Pẹlu Ẹmi Ohun Moní Tómi
Imọran lori ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun ni o pari lẹta Pọọlu. (6:1-21, NW) “Ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun papọ pẹlu ẹmi ohun moní tómi” jẹ ọna èrè ńlá, ṣugbọn ipinnu lati di ọlọrọ maa nṣamọna si iparun yán-ányán-án. Pọọlu rọ Timoti lati ja ija rere ti igbagbọ ati ‘ki o di iye ainipẹkun mu ṣinṣin.’ Lati le di iye tootọ yẹn mú, awọn ọlọ́rọ̀ nilati “gbe ireti wọn, kii ṣe lori ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
A Gbà á Là Nipasẹ Ọmọ Bíbí: Pọọlu kò jiroro igbala sinu iye ayeraye ṣugbọn o nsọrọ nipa iṣẹ titọna ti obinrin oniwa-bi-Ọlọrun kan nigba ti oun kọwe: “A o pa a mọ lailewu ninu ọmọ bibi, bi wọn ba nbaa lọ ninu igbagbọ ati ifẹ ati isọdimimọ pẹlu ero inu yiyekooro.” (1 Timoti 2:11-15, NW) Nipasẹ ọmọ bibi, bibojuto awọn ọmọ rẹ̀, ati bibojuto agbo-ile kan daradara, obinrin kan ni a o “pamọ lailewu” kuro ninu didi olofoofo ọlọ́wọ́ dídilẹ̀ ati alatojubọ ninu awọn àlámọ̀rí awọn eniyan miiran. (1 Timoti 5:11-15, NW) Awọn igbokegbodo rẹ ninu ile yoo ṣe alekun iṣẹ-isin rẹ̀ si Jehofa. Dajudaju nitootọ, gbogbo awọn Kristian nilati sọ́ iwa wọn ki wọn si lo akoko wọn pẹlu ọgbọ́n.—Efesu 5:15, 16.