ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 2/1 ojú ìwé 25-29
  • Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kikẹkọọ Awọn Otitọ Bibeli
  • Ṣiṣajọpin Imọ Awari Titun
  • Ijẹrii Opopona
  • Iṣiri lati Bori Ibẹru
  • A Fun Mi Lokun A Si Bukun Mi
  • Mimu Ẹru-iṣẹ Wà Deedee
  • Itunu Titi Ọjọ-aye
  • Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbé Ìgbàgbọ́ Ró ní Íńdíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 2/1 ojú ìwé 25-29

Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ

Gẹgẹ bi a ti sọ ọ lati ẹnu Lily Arthur

Ọ̀dọ́ ojiṣẹ kan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa nṣe ikesini lati ile de ile ni apakan Ootacamund, India. Gẹgẹ bi àṣà awọn obinrin naa kò ṣi ilẹkun fun iru ajeji bẹẹ. Lẹhin wakati diẹ, o ti sú u o si dabi ẹni pe o rẹwẹsi, o yipada lati lọ si ile. Ṣugbọn o duro, o ni imọlara bi ẹni ti a sun bakan ṣaa lati ṣe ikesini si ẹnu ọna ti o tẹle e. Gbe ohun ti o ṣẹlẹ yẹwo, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ lati ẹnu obinrin naa ti o ṣi ilẹkun fun un.

PẸLU ọmọ mi oloṣu meji ni ọwọ mi ati ọmọkunrin mi ẹni oṣu mejilelogun ni ẹgbẹ mi, mo ṣi ilẹkun naa lọgan mo sì ri ajeji kan ti o duro nibẹ. Gan-an ni oru ṣaaju mo ti ni idaamu lọna mimuna. Ni wiwa itunu, mo ti gbadura: “Baba ọrun, jọwọ tù mi ninu nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ.” Nisinsinyi, si iyalẹnu mi, ajeji naa ṣalaye pe: “Emi mu ihin iṣẹ itunu ati ireti lati inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa fun ọ.” Mo nimọlara pe oun gbọdọ jẹ wolii kan ti Ọlọrun ran. Ṣugbọn ipo wo ni o ti fa adura mi fun iranlọwọ?

Kikẹkọọ Awọn Otitọ Bibeli

A bi mi ni 1922 ni abule Gudalur ni Nilgiri Hills ẹlẹ́wà ti guusu India. Iya mi ku nigba ti mo jẹ ẹni ọdun mẹta. Lẹhin naa, Baba, ẹni ti o jẹ alufaa ṣọọṣi Protestant kan, tun igbeyawo ṣe. Gbàrà ti a ti le sọrọ, Baba kọ́ awọn arakunrin ati arabinrin mi ati emi lati gbadura. Ni ẹni ọdun mẹrin, nigba ti Baba bá jokoo nidii tabili rẹ̀ ti o nka Bibeli, emi yoo jokoo nilẹ lati ka Bibeli temi naa.

Nigba ti mo dagba, mo di olukọ kan. Lẹhin naa, nigba ti mo di ẹni ọdun mọkanlelogun, baba mi ṣeto igbeyawo mi. Ọkọ mi ati emi ni a bukun pẹlu ọmọkunrin kan, Sunder, ati lẹhin naa ọmọbinrin kan, Rathna. Bi o ti wu ki o ri, ni nnkan bi akoko ti a bi Rathna, ọkọ mi ṣaisan gan-an, ati laipẹ lẹhin naa o ku. Lojiji mo di opo ni ẹni ọdun mẹrinlelogun, pẹlu ẹru iṣẹ awọn ọmọde kekere meji.

Lẹhin iyẹn mo beere lọwọ Ọlọrun pe ki o tù mi ninu lati inu Ọrọ rẹ̀. Ọjọ ti o si tẹle e ni ojiṣẹ awọn Ẹlẹrii Jehofa naa ṣe ikesini. Mo pe e wọle mo si gba iwe naa “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ.” Ni alẹ yẹn nigba ti mo nka a, mo nri orukọ naa Jehofa leralera, eyi ti o jẹ ohun ajeji gan-an si mi. Lẹhin naa ojiṣẹ naa pada wa o si fi han mi ninu Bibeli pe eyi ni orukọ Ọlọrun.

Laipẹ mo tun kẹkọọ pe iru awọn ẹkọ bii Mẹtalọkan ati ina ọrun apaadi ni a ko gbekari Bibeli. Itunu ati ireti de ba mi nigba ti mo kẹkọọ pe labẹ Ijọba Ọlọrun aye yoo di paradise ati pe awọn olufẹ ti wọn ti ku yoo pada ninu ajinde. Ni pataki julọ, mo bẹrẹ sii mọ̀ ati nifẹẹ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa, ẹni ti o gbọ adura mi ti o si wá ran mi lọwọ.

Ṣiṣajọpin Imọ Awari Titun

Mo bẹrẹ sii ṣe kayefi bi mo ṣe tàsé kika awọn ẹsẹ Bibeli wọnni ti wọn ni orukọ Ọlọrun. Eeṣe ti emi kò sì ti ri ireti ṣiṣekedere ti iye ainipẹkun lori paradise ilẹ-aye ninu Bibeli kika ti emi funraami? Mo nkọni ni ile ẹkọ ti a ndari nipasẹ awọn ojiṣẹ Ọlọrun Protestant nitori naa mo fi awọn ẹsẹ Bibeli naa hàn fun oludari ile ẹkọ. (Ẹksodu 6:3; Saamu 37:29; 83:18; Aisaya 11:6-9; Iṣipaya 21:3, 4) Mo mẹnukan an pe lọna kan ṣaa awa ti gbojufo wọn da. Ṣugbọn si iyalẹnu mi ko dabi ẹni pe o tẹ ẹ lọrun.

Lẹhin naa mo kọwe si olori ile ẹkọ naa ẹni ti o wà ni ilu miiran, ni fifa awọn ẹsẹ Bibeli wọnyi yọ. Mo beere fun anfaani lati ba a sọrọ. O fesipada pe baba oun, alufaa ṣọọṣi kan ti a mọ daradara lati England, yoo jiroro ọran naa pẹlu mi. Arakunrin olori ile ẹkọ naa jẹ biṣọọbu ayọri ọla kan.

Mo mura gbogbo awọn koko ati iwe mimọ naa silẹ mo sì mu ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” mi ati awọn ọmọ mi lọ si ilu keji. Pẹlu itara mo ṣalaye ẹni ti Jehofa jẹ, pe ko si Mẹtalọkan, ati awọn nnkan miiran ti mo ti kẹkọọ. Wọn fetisilẹ fun igba diẹ ṣugbọn wọn ko sọ ọrọ kan. Lẹhin naa alufaa ṣọọṣi lati England naa wipe: “Emi yoo gbadura fun ọ.” Nigba naa o gbadura fun mi o si ni ki emi maa lọ.

Ijẹrii Opopona

Ni ọjọ kan ojiṣẹ awọn Ẹlẹrii Jehofa kesi mi lati ṣe ijẹrii opopona pẹlu iwe-irohin Ilé-ìṣọ́nà ati Ji! Mo sọ fun un pe iyẹn ni ohun kan ti emi ko le ṣe lae. Wòó, ni India awọn eniyan yoo ro ohun ti o buru julọ si obinrin kan ti o duro ni opopona tabi lọ lati ile de ile. Yoo mu ẹ̀gàn wa sori ifusi obinrin naa ati ti idile rẹ paapaa. Niwọnbi mo ti nifẹẹ ti mo si bọwọ fun baba mi lọna jijinlẹ, emi ko fẹ lati mu ẹgan wa sori rẹ.

Ṣugbọn ojiṣẹ naa fi ẹsẹ Bibeli kan hàn mi ti o wipe: “Ọmọ mi, ki iwọ, ki o gbọn, ki o si mu inu mi dùn. Ki emi ki o le da ẹni ti o ngan mi lohun.” (Owe 27:11) Oun wipe: “Iwọ mu ọkan-aya Jehofah layọ nipa fifihan ni gbangba pe iwọ wa fun oun ati Ijọba rẹ̀.” Ninifẹ sii ju ohunkohun miiran lọ lati mu ọkan-aya Jehofa layọ, mo gbe apo iwe-irohin mo si baa lọ si iṣẹ ijẹrii òpópónà. Ani nisinsinyi paapaa emi ko le ronu bi mo ti ṣe e. Iyẹn jẹ ni 1946, ni nnkan bii oṣu mẹrin lẹhin ti a pade mi.

Iṣiri lati Bori Ibẹru

Lati 1947 mo gba iṣẹ ikọnilẹkọọ ni ẹhin odi Madras, ni Ila-oorun etikun India, mo si ṣilọ sibẹ, pẹlu awọn ọmọ mi. Awujọ kekere awọn Ẹlẹrii Jehofa tí iye wọn jẹ nnkan bi mẹjọ npadepọ deedee ninu ilu. Lati lọ si awọn ipade wọnni, a nilati rinrin-ajo ibusọ mẹrindinlogun. Ni India nigba naa lọhun-un, awọn obinrin kii saba maa ndanikan rinrin ajo. Wọn darade awọn ọkunrin lati mu wọn lọ. Emi ko mọ bi a ṣe nwọnu ọkọ, beere fun tikẹẹti, ati bi a ṣe nsọkalẹ ninu ọkọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Mo nimọlara pe o yẹ fun mi lati ṣiṣẹsin Jehofa, ṣugbọn bawo ni? Nitori naa mo gbadura pe: “Jehofa Ọlọrun, emi ko le walaaye lai ṣiṣẹsin ọ, ṣugbọn o jẹ ohun ti ko ṣeeṣe rara fun mi gẹgẹbi obinrin ara India lati lọ lati ile de ile.”

Mo reti pe Jehofa yoo jẹ ki emi ku lati gba mi kuro lọwọ ijakadi yii. Bi o ti wu ki o ri, mo pinnu lati ka ohun kan lati inu Bibeli. Lairo tẹlẹ mo ṣi i si Jeremaya, nibi ti o ti ka pe: “Ma wipe, ọmọde ni emi: ṣugbọn iwọ yoo lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi yoo ran ọ si, ati ohunkohun ti emi yoo paṣẹ fun ọ ni iwọ yoo sọ. Ma bẹru niwaju wọn nitori emi yoo pẹlu rẹ lati gba ọ.”—Jeremaya 1:7, 8.

Mo nimọlara pe Jehofa ni o nba mi sọrọ nitootọ. Nitori naa mo mọkanle mo si lọ si idi ẹrọ iranṣọ mi lọgan mo si ran apo kan lati lo fun kiko awọn iwe-irohin. Lẹhin adura ti mo fi taratara gbà, mo danikan lọ lati ile de ile, mo fi gbogbo awọn iwe ikẹkọọ mi sode, mo si bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli ni ọjọ yẹn paapaa. Mo wa pinnu lati fun Jehofa ni ipo akọkọ ninu igbesi-aye mi, mo si fi igbẹkẹle ati igbọkanle mi patapata sinu rẹ. Iṣẹ iwaasu ita gbangba di apakan ti o ṣedeedee ninu igbesi-aye mi laifi ti ẹgan ọlọrọ ẹnu pe. Laika atako si, igbokegbodo mi tẹ ero lilagbara kan mọ awọn kan lọkan.

Eyi ni a ṣakawe nigba ti ọmọbinrin mi ati emi nlọ lati ile de ile ni Madras ni ọpọ ọdun lẹhin naa. Ọkunrin ọmọluwabi Hindu kan, adajọ kan ni ile-ẹjọ giga, ni ṣiṣi ọjọ-ori mi loye, o wipe: “Mo ti mọ awọn iwe-irohin wọnyi ani ṣaaju ki a to bi ọ! Ni ọgbọn ọdun sẹhin obinrin kan maa nduro lẹba Mount Road deedee ti o si maa nfi wọn lọni.” Oun fẹ lati san asansilẹ-owo.

Ni ile miiran Brahman ti Hindu kan, oṣiṣẹ oloye kan ti o ti fẹhinti lẹnu iṣẹ, kesi wa wọle o si wipe: “Ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin obinrin kan maa nfi Ilé-ìṣọ́nà lọni ni Mount Road. Emi yoo gba ohun ti o fi nlọ mi nitori rẹ̀.” Mo nilati rẹrin-in musẹ nitori pe mo mọ̀ pe emi ni obinrin naa ti awọn mejeeji ntọkasi.

A Fun Mi Lokun A Si Bukun Mi

Ni October 1947 ni mo ṣapẹẹrẹ iyasimimọ mi si Jehofa nipasẹ baptism inu omi. Ni akoko yẹn emi nikan ni Ẹlẹrii obinrin ti nsọ èdè Tamil ni gbogbo ipinlẹ naa, ṣugbọn nisinsinyi ọgọrọọrun awọn obinrin ara Tamil ti wọn jẹ onigbagbọ, Ẹlẹrii Jehofa agbekankanṣiṣẹ ni wọn wà.

Lẹhin ti mo ṣe baptism, atako wá lati gbogbo ìhà. Arakunrin mi kọwe pe: “Iwọ ti gbegbeesẹ kọja ohun ti o tọ ati ohun ti o ni ẹ̀yẹ.” Mo tun ri atako ni ile-ẹkọ nibi ti mo ti nṣiṣẹ ati lati adugbo. Ṣugbọn mo rọ̀ mọ́ Jehofa ani timọtimọ sii nipa adura afitaratara gba leralera. Bi mo ba ji laaarin ọganjọ, emi yoo tan ina láńtánì elepo kẹrosini emi yoo sì kẹkọọ.

Gẹgẹ bi a ti fun mi lokun, mo wà ni ipò didara lati tu awọn ẹlomiran ninu ki emi si ran wọn lọwọ. Agba obinrin Hindu kan ẹni ti mo ba kẹkọọ mu iduro gbọnyingbọnyin fun ijọsin Jehofa. Nigba ti o ku, obinrin miiran ninu agbo ile naa wipe: “Ohun ti o mu wa layọ gan-an ni iduroṣinṣin rẹ ti Ọlọrun ẹni ti oun yàn lati jọsin titi de opin.”

Obinrin miiran ti mo nba kẹkọọ kii rẹrin-in. Oju rẹ nfi aniyan ati ibanujẹ han ni gbogbo ìgbà. Ṣugbọn lẹhin kikọ ọ lẹkọọ nipa Jehofa, mo gbà á niyanju lati gbadura si i, niwọnbi oun ti mọ̀ awọn iṣoro wa ti o si bikita fun wa. Ni ọsẹ ti o tẹle e irisi oju rẹ kun fun ayọ. O jẹ igba akọkọ ti mo ti rii ki o rẹrin-in musẹ. O ṣalaye pe, “Mo ti ngbadura si Jehofa, mo si ni alaafia ero-inu ati ọkan-aya.” Oun ya igbesi-aye rẹ si mimọ lati ṣiṣẹsin Jehofa o si duro gẹgẹ bi oloootọ laika ọpọlọpọ iṣoro si.

Mimu Ẹru-iṣẹ Wà Deedee

Pẹlu awọn ọmọ kekere meji lati tọju, mo nimọlara pe riri imuṣẹ ifẹ ọkan mi lati ṣiṣẹsin Jehofa ni akoko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ni ko le ṣeeṣe. Ṣugbọn lẹhin naa ọna abayọ titun fun iṣẹ-isin ṣisilẹ nigba ti a nilo ẹnikan lati tumọ iwe ikẹkọọ Bibeli si èdè Tamil. Pẹlu iranlọwọ Jehofa mo le bojuto iṣẹ yẹn ati, ni igba kan naa mo nṣiṣẹ ounjẹ oojọ gẹgẹbi olukọ, mo nmojuto awọn ọmọ, mo nṣe iṣẹ ile mi, lọ si gbogbo awọn ipade, mo sì nnipin-in ninu iṣẹ-isin pápá. Nikẹhin, nigba ti awọn ọmọ dàgbà, mo di aṣaaju-ọna akanṣe kan, anfaani kan ti mo ti gbadun fun ọdun mẹtalelọgbọn ti o ti kọja.

Ani lati igba kekere, mo gbiyanju lati tẹ ifẹ fun Jehofa mọ Sunder ati Rathna lọkan ati ifẹ-ọkan lati fi awọn ire rẹ̀ si akọkọ ninu gbogbo apa igbesi-aye wọn. Wọn mọ pe ẹni akọkọ ti wọn nilati ba sọrọ nigba ti wọn ba ji ni Jehofa, ati pe Oun ni ẹni ikẹhin ti wọn nilati ba sọrọ ki wọn to lọ sùn. Wọn sì mọ pe imurasilẹ fun awọn ipade Kristian ati iṣẹ-isin pápá ni a kò nilati gbójúfò dá nitori iṣẹ ilé lati ile-ẹkọ. Nigba ti mo fun wọn ní iṣiri lati ṣe gbogbo ohun ti wọn le ṣe ninu iṣẹ ile-ẹkọ wọn, emi ko fi dandan le e ri pe ki wọn gba ipo giga, ni bibẹru pe wọn yoo sọ iyẹn di pataki julọ ninu igbesi-aye wọn.

Lẹhin ti a baptisi wọn, wọn lo awọn akoko isinmi kuro ni ile-ẹkọ lati ṣe aṣaaju-ọna. Mo fun Rathna ni iṣiri lati ni igboya, ki o ma bẹru tabi tiju gẹgẹbi emi ti jẹ. Lẹhin ti oun pari ile-ẹkọ giga rẹ ati idalẹkọọ lori iṣowo, oun bẹrẹ sii ṣe aṣaaju-ọna, ati lẹhin naa oun di aṣaaju-ọna akanṣe. Laipẹ, o fẹ alaboojuto arinrin ajo kan, Richard Gabriel, ẹni ti o nṣiṣẹsin nisinsinyi gẹgẹbi oluṣekokaari Igbimọ Ẹka fun Watch Tower Society ni India. Awọn ati ọmọbinrin wọn, Abigail, nṣiṣẹ alakooko kikun ni ẹka India, ọmọkunrin wọn kekere, Andrew, si jẹ akede ihinrere.

Bi o ti wu ki o ri, ni ẹni ọdun 18, Sunder, mu mi ni irobinujẹ ọkan, nigba ti o dawọ didarapọ mọ awọn Ẹlẹrii Jehofa duro. Awọn ọdun ti o tẹle e jẹ ti onirora fun mi. Mo nbaa lọ lati bẹ Jehofa leralera lati fori aṣiṣe eyikeyii ti mo ti le ṣe ninu titọ ọ jì mi ati lati pe ọpọlọ Sunder wale ki oun baa lè pada. Ṣugbọn, laipẹ, mo sọ gbogbo ireti nù. Lẹhin naa ni ọjọ kan ni ọdun mẹtala lẹhin naa o wa o si sọ fun mi pe: “Mama, ẹ maṣe daamu, emi yoo pada sipo.”

Laipẹ lẹhin naa, Sunder sapa lọna akanṣe lati dagbadenu nipa tẹmi. Oun tẹsiwaju de gongo ti didi ẹni ti a fi ẹru iṣẹ iṣabojuto le lọwọ ninu ijọ awọn Ẹlẹrii Jehofa. Lẹhin naa oun fi iṣẹ ti o nmowowọle daradara silẹ lati di aṣaaju-ọna kan. Nisinsinyi oun ati aya rẹ, Esther, nṣiṣẹsin papọ ninu iṣẹ yii ni Bangalore ni apa iha guusu India.

Itunu Titi Ọjọ-aye

Niye igba mo ndupẹ lọwọ Jehofa fun yiyọnda mi lati bọ sabẹ ijiya ati awọn iṣoro la awọn ọdun ja. Laisi iru awọn iriri bẹẹ emi ki yoo ti ni anfaani ṣiṣeyebiye ti títọ́ iwarere iṣeun, aanu, ati awọn ifihanjade itọju onijẹlẹnkẹ ti ifẹni Jehofa wo de iru aye yẹn. (Jakọbu 5:11) O munilọkan yọ lati ka ninu Bibeli nipa itọju ati idaniyan Jehofa “fun ọmọ alainibaba ati fun opó.” (Deuteronomi 24:19-21) Ṣugbọn ko jẹ nnkankan ni ifiwera pẹlu itunu ati inudidun ti níní iriri itọju ati idaniyan rẹ niti tootọ.

Mo ti kẹkọọ lati fi igbẹkẹle ati igbọkanle kikun sinu Jehofa, lai sinmi le oye temi funraami, ṣugbọn ninu gbogbo awọn ọna mi mo nkiyesi i. (Saamu 43:5; Owe 3:5, 6) Gẹgẹbi ọdọ opó kan, mo gbadura si Ọlọrun fun itunu lati inu Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nisinsinyi, ni ẹni ọdun 68, mo le wí nitootọ pe ni liloye Bibeli ati fifi imọran rẹ silo, emi ti ri itunu kọja ìwọ̀n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Lily Arthur pẹlu awọn mẹmba idile rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́