Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Eeṣe ti itumọ 2 Peteru 1:19 ninu New World Translation of the Holy Scriptures fi yatọ si ti awọn Bibeli miiran?
Ni titẹnumọ iniyelori ọ̀rọ̀ onimiisi ti Ọlọrun, apọsteli Peteru kọwe pe: “Nitori naa a mu ki ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ naa tubọ daniloju; ẹyin sì nṣe daradara ni fifiyesi i gẹgẹbi si fitila ti ntan ni ibi ṣiṣokunkun kan, titi ojumọ fi mọ ti irawọ ọsan sì yọ ninu ọkan-aya yin.”—2 Peteru 1:19, NW.
Ṣakiyesi pe àpólà ọ̀rọ̀ naa “titi ojumọ fi mọ ti irawọ-ọsan si yọ” ni a yasọtọ nipa ami idanuduro diẹ. Pupọ julọ awọn itumọ Bibeli ko ṣe eyi.
Fun apẹẹrẹ, Dokita James Moffatt ṣetumọ apa ti o gbẹhin ẹsẹ-iwe naa: “. . . o ntan bi àtùpà laaarin ibi okunkun kan; titi ti ojumọ fi mọ ti irawọ-ọsan si yọ laaarin ọkan-aya yin.” Awọn itumọ bii iru eyi ṣamọna si oju-iwoye naa pe yiyọ irawọ ọsan ṣẹlẹ ninu ọkan-aya awọn onigbagbọ, gẹgẹ bi ẹni pe wọn ni iriri oriṣi itanmọlẹ tẹmi kan bayii.
Bi o ti wu ki o ri, ani pada sẹhin ni ọjọ Mose, itọka kan wa pe ‘irawọ Jakọbu kan’ yoo yọ. (Numeri 24:17; fiwera pẹlu Saamu 89:34-37.) Ni kedere Jesu da fi araarẹ han yatọ gẹgẹbi “iru ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ ti ntan.”—Iṣipaya 22:16.
Idanimọyatọ “irawọ ọsan” yii, tabi “irawọ owurọ,” bá ayika ọrọ ohun ti apọsteli Peteru njiroro mu. Oun ṣẹṣẹ tọkasi iran ipalarada naa ti oun ti ri ni nǹkan bii 30 ọdun ṣaaju. (Matiu 16:28–17:9) Iran ologo yẹn tọkasi akoko naa nigbati Jesu yoo ‘de ninu ijọba rẹ,’ tabi ti a o ṣe e logo ninu agbara ijọba. Oun ti Peteru ti ri tẹnumọ iniyelori ọ̀rọ̀ Ọlọrun; lọna ti o farajọra, awa Kristian lonii nilo lati fi afiyesi si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ yẹn.
Nigba ti ọkan-aya awọn araye ni gbogbogboo wà—ti o ṣì wà—ninu okunkun sibẹsibẹ, iyẹn ko yẹ ki o ri bẹẹ pẹlu awọn Kristian tootọ. Nṣe ni o dabi ẹni pe wọn ni àtùpà ti ntan nibi ti iba ti ṣokunkun, ọkan-aya wọn. Peteru mọ̀ pe nipa kikiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun ti nfunni ni imọlẹ, awọn Kristian yoo wà lojufo a o sì la wọn lọyẹ si imọlẹ ọjọ titun kan. Iyẹn yoo jẹ akoko ti “irawọ ọsan,” tabi “irawọ owurọ ti ntan,” yoo jọba niti gidi ninu agbara Ijọba.
O dunmọni pe E. W. Bullinger kọwe lori 2 Peteru 1:19: “Nihin-in, o ṣekedere pe àkámọ́ gbọdọ wa nihin-in, nitori asọtẹlẹ ni imọlẹ naa ti o tàn, Kristi ati ifarahan Rẹ̀ ni irawọ Ọsan ati ojumọ ti o mọ́ naa. Dajudaju, itumọ naa ko le jẹ pe a gba wa niyanju lati kọbiara si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ titi di igba ti a ba ṣipaya Kristi ninu ọkan-aya wa! Bẹẹkọ; ṣugbọn awa nilati fi ọkan wa si ọrọ alasọtẹlẹ yii, titi di igba ti imuṣẹ rẹ yoo fi de ninu ifarahan Kristi—yiyọ Ẹni naa ti a npe ni ‘Irawọ Owurọ.’”—Figures of Speech Used in the Bible, 1898.
Ni ibamu pẹlu eyi, iye awọn itumọ Bibeli melookan lo awọn àkámọ́ ni 2 Peteru 1:19.a New World Translation of the Holy Scriptures di ọ̀nà igbekalẹ ti ipilẹ ti a ri ninu Giriiki ipilẹṣẹ mu. Ṣugbọn o lo ami idanuduro diẹ lati fi iyatọ si àpólà ọ̀rọ̀ naa “titi ojumọ fi mọ ti irawọ ọsan sì yọ” lati inu igbaniniyanju naa lati fiyesi ọ̀rọ̀ naa ‘gẹgẹbi si fitila ti ntan ni ibi ṣiṣokunkun kan, ninu awọn ọkan-aya yin.’
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun apẹẹrẹ ẹ wo The Twentieth Century New Testament (ẹda itẹjade 1904), The Emphatic Diaglott (ẹda itẹjade 1942), Concordant Literal New Testament (1976).