Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀—Ọna Eniyan Tabi Ti Ọlọrun?
LAAARIN awọn Katoliki, ìjẹ́wọ́ ti yipada lọna ti o gba afiyesi la awọn ọrundun kọja. Ni awọn ọdun ijimiji ti Ṣọọṣi Katoliki, ìjẹ́wọ́ ati iṣẹ ironupiwada ni a beere fun kiki fun ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo. Nipa eyi, iwe naa Religion in the Medieval West wipe: “Titi di ipari ọrundun kẹfa eto iṣẹ ironupiwada lekoko gan-an: sakramẹnti ni a le fifunni kiki lẹẹkan ni akoko igbesi-aye, ìjẹ́wọ́ jẹ ni gbangba, iṣẹ ironupiwada naa gùn o si múná.”
Bawo ni iru ijiya ẹ̀ṣẹ̀ bẹẹ ṣe múná to? Ni 1052 ẹnikan ti nṣiṣẹ ironupiwada ni a sọ fun lati rìn laiwọ bàtà lati Bruges ni Belgium lọ si Jerusalem! “Ni 1700 awọn Katoliki ni a ṣì lè ri ni eti awọn kanga ati orisun omi mimọ, ti wọn kúnlẹ̀ sinu omi yìnyín ti o mù wọn de ibi ọrùn lati gba awọn adura iṣẹ ironupiwada wọn,” ni iwe naa Christianity in the West 1400-1700 wi. Niwọnbi o ti jẹ pe ni akoko yẹn idariji ẹ̀ṣẹ̀ ni a fasẹhin titi di igba ipari iṣẹ ironupiwada naa, ọpọlọpọ maa nfi ìjẹ́wọ́ wọn falẹ titi di akoko tí wọn ńkú lọ.
Nigba wo ni àṣà ìjẹ́wọ́ ti ode oni bẹrẹ? Religion in the Medieval West wipe: “Iru iṣẹ ironupiwada titun ni a dasilẹ ni ipari ọrundun kẹfa lati ọwọ awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anikandagbe ti Celtic ni France. . . . Eyi ni ìjẹ́wọ́ ìdákọ́ńkọ́, ninu eyi ti ẹni ti nṣiṣẹ ironupiwada yoo jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níkọ̀kọ̀ fun awọn alufaa, o si jẹ ṣiṣe amulo àṣà fifunni ni imọran tẹmi lọna miiran eyi tí awọn ọkunrin ajẹjẹẹ anikandagbe maa nṣe.” Ni ibamu pẹlu àṣà awọn ọkunrin ajẹjẹẹ anikandagbe atijọ, awọn ọkunrin ajẹjẹẹ anikandagbe maa njẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fun araawọn ẹnikinni keji lati gba iranlọwọ tẹmi ki wọn baa lè ṣẹpa awọn ailera wọn. Bi o ti wu ki o ri, ninu ìjẹ́wọ́ idakọnkọ titun, ṣọọṣi naa fi “agbara tabi ọlá-àṣẹ” ti o pọ julọ “lati dari awọn ẹ̀ṣẹ̀ ji” fun alufaa.—New Catholic Encyclopedia.
Njẹ Jesu fun diẹ lara awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni iru agbara bẹẹ niti gidi bi? Ki ni oun sọ ti o ṣamọna awọn kan si ipari ero yii?
“Awọn Kọkọrọ Ijọba”
Ni akoko kan, Jesu Kristi sọ fun apọsteli Peteru pe: “Emi yoo fun ọ ni awọn kọkọrọ ijọba ti ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè lori ilẹ-aye ni a o kasi eyi ti a dè ni ọrun; ohunkohun ti o ba tu silẹ lori ilẹ-aye ni a o kasi ohun ti a tu silẹ ni ọrun.” (Matiu 16:19, The Jerusalem Bible) Ki ni Jesu ni lọkan nipa “awọn kọkọrọ ijọba”? Awa le loye eyi daradara bi a ba wo akoko miiran nigba ti Jesu lo ọ̀rọ̀ naa “kọkọrọ.”
Jesu sọ fun awọn aṣaaju isin Juu ti wọn ni imọ ninu Ofin Mose pe: “O ṣe fun yin ẹyin amofin ti ẹ ti mu kọkọrọ ìmọ̀ lọ! Ẹyin funraayin kò tii wọle, ẹ sì ti ṣediwọ fun awọn miiran ti wọn fẹ lati wọle.” (Luuku 11:52, JB) ‘Ṣediwọ fun awọn miiran lati maṣe wọle’ sibo? Jesu sọ fun wa ni Matiu 23:13 pe: “O ṣe fun yin, ẹyin akọwe ati Farisi, ẹyin agabagebe! Ẹyin ti ẹ sé ilẹkun ijọba ọrun mọ awọn eniyan loju, bẹẹ ni ẹ ko wọle funraayin tabi yọnda awọn miiran ti wọn fẹ ṣe bẹẹ lati wọle.” (JB) Awujọ alufaa Juu ti ilẹkun mọ ọpọlọpọ, gẹgẹ bi o ti ri, nipa fifi anfaani wíwà pẹlu Jesu Kristi ni ọrun dù wọn. “Kọkọrọ” naa ti awọn aṣaaju isin wọnyi ti ‘mu lọ’ kò ni nnkankan ṣe pẹlu idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀. O jẹ kọkọrọ si imọ ti a pese lati ọrun wa.
Lọna ti o farajọra, “awọn kọkọrọ ijọba” ti a fifun Peteru ko duro fun agbara lati fi to Ọlọrun leti niti ẹ̀ṣẹ̀ awọn wo ni a nilati dariji tabi mu ki o wà niṣo. Kaka bẹẹ, wọn duro fun anfaani titobi Peteru ti ṣíṣí ọna ọrun silẹ nipa títan ìmọ̀ ti a pese lati ọrun wa kálẹ̀ nipasẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀. Oun kọ́kọ́ ṣe eyi fun awọn Juu ati fun awọn aláwọ̀ṣe Juu, lẹhin naa fun awọn ara Samaria, ati nikẹhin fun awọn Keferi.—Iṣe 2:1-41; 8:14-17; 10:1-48.
“Ohun Yoowu Ti Ẹyin Dè lori Ilẹ-aye”
Nigba ti o ya, ohun ti Jesu sọ fun Peteru ni a tun sọ fun awọn ọmọ-ẹhin miiran. Jesu wipe, “mo sọ fun yin láìdápàárá pe, ohun yoowu ti ẹyin dè lori ilẹ-aye ni a kasi ohun ti a dè ni ọrun! Ohun yoowu ti ẹyin tu silẹ lori ilẹ-aye ni a o kasi ohun ti a tu silẹ ni ọrun.” (Matiu 18:18. JB) Ọla-aṣẹ wo ni Jesu fi lé awọn ọmọ-ẹhin lọwọ? Ayika ọrọ naa fihan pe oun nsọrọ nipa yiyanju awọn iṣoro laaarin awọn onigbagbọ lẹnikọọkan ati pipa awọn oluṣe buburu alaironupiwada mọ́ kuro ninu ijọ.—Matiu 18:15-17.
Ninu awọn ọran ti o wemọ títàpásí ofin Ọlọrun ti o wuwo, awọn ọkunrin ti wọn ni ẹru iṣẹ ninu ijọ ni yoo nilati ṣedajọ awọn ọ̀ràn ki wọn sì pinnu boya oniwa aitọ naa ni a nilati “dè” (ki a wò ó bi ẹlẹbi) tabi ‘tú silẹ’ (da a lare). Njẹ eyi tumọsi pe Ọlọrun yoo tẹle ipinnu awọn eniyan? Bẹẹkọ. Gẹgẹ bi ọmọwe akẹkọọ jinlẹ ninu Bibeli Robert Young ti fihan, ipinnu eyikeyii ti awọn ọmọ-ẹhin ṣe yoo tẹle ipinnu Ọlọrun, ki yoo ṣaaju rẹ̀. Oun wipe ẹsẹ 18 nilati kà lọna olówuuru pe: Ohun ti ẹyin dè lori ilẹ-aye “yoo jẹ ohun ti a ti dè (tẹlẹ)” ni ọrun.
Niti tootọ, kò bọgbọnmu lati ronu pe ẹda-eniyan alaipe eyikeyii yoo ṣe awọn ipinnu ti yoo de awọn wọnni ti wọn wà ninu awọn ìgà idajọ ti ọrun. O ba ọgbọ́n mu julọ lati wipe awọn aṣoju ti Kristi yan yoo tẹle awọn idari rẹ̀ lati mu ki ijọ rẹ̀ wà ní mímọ́. Wọn yoo ṣe eyi nipa ṣiṣe ipinnu ti a gbekari awọn ipilẹ ti a ti fi lelẹ tẹ́lẹ̀ ni ọrun. Jesu fúnraarẹ̀ yoo dari wọn ninu ṣiṣe eyi.—Matiu 18:20.
Ẹnikẹni ha lè “ṣoju fun Kristi gẹgẹ bi baba onidaajọ” de iwọn aye pipinnu ọjọ ọla ayeraye olujọsin ẹlẹgbẹ kan? (New Catholic Encyclopedia) Awọn alufaa ti wọn ngbọ ìjẹ́wọ́ ni o fẹrẹẹ jẹ pe nigba gbogbo laisi iyatọ kankan ni wọn maa ndari ẹ̀ṣẹ̀ jì, ani bi o tilẹ jẹ pe “o dabi ẹni pe igbagbọ ti a kò sọ jade kan wà [laaarin awọn ẹlẹkọọ isin Katoliki] pe ṣàṣà eniyan ni o kabaamọ niti gidi fun awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (The New Encyclopædia Britannica) Nitootọ, nigba wo kẹhin ni o gbọ́ ti alufaa kan kọ̀ lati fi idariji ẹ̀ṣẹ̀ funni tabi lati dá oniwa aitọ kan lare? Boya, eyi jẹ nitori pe alufaa naa kò rò pe oun ni agbara lati dajọ yala ẹlẹṣẹ kan ronupiwada tabi bẹẹkọ. Ṣugbọn bi iyẹn ba jẹ bẹẹ, eeṣe ti oun fi sọ pe oun ni agbara lati dari ẹ̀ṣẹ̀ jì?
Ronu nipa ile ẹjọ ofin kan ninu eyi ti onidaajọ kan tí ó ní iyọnu ti da awọn ọdaran lare leralera, ani awọn arufin ti wọn jingíri paapaa, nitori pe wọn ṣe gẹgẹ bi wọn ti maa nṣe leralera ní jijẹwọ awọn iwa ọdaran wọn ti wọn sì nsọ pe o ba awọn lọkan jẹ. Nigba ti eyi lè tẹ́ awọn oniwa aitọ lọrun, iru oju iwoye aanu ti ko tọna bẹẹ yoo jìn ọ̀wọ̀ fun idajọ ododo lẹ́sẹ̀ lọna wiwuwo. Njẹ ó ha lè jẹ pe ìjẹ́wọ́ gẹgẹ bi a ti nṣe e ninu Ṣọọṣi Katoliki nmu awọn eniyan yigbì ni ipa ọna ẹ̀ṣẹ̀ niti tootọ ni bi?—Oniwaasu 8:11.
“Ìjẹ́wọ́ kò pese itẹsi eyikeyii lati gbiyanju lati yẹra fun ẹ̀ṣẹ̀ ni ọjọ iwaju,” ni Ramona wi, ni sisọrọ lati inu iriri rẹ̀ ti jíjẹ́wọ́ gẹgẹ bi Katoliki kan lati igba ti oun ti jẹ ẹni ọdun meje. O fikun un pe: “Ìjẹ́wọ́ nmu ero naa pe Ọlọrun jẹ adarijini nigba gbogbo dàgbà ati pe ohun yoowu ti ẹran-ara aipe rẹ bá mú ọ ṣe oun yoo dariji ọ. Ko mu ifẹ-ọkan jijinlẹ lati ṣe ohun ti o tọ́ dagba.”a
Ṣugbọn ki ni nipa awọn ọ̀rọ̀ Jesu ti a ṣakọsilẹ ni Johanu 20:22, 23? Nibẹ ni o ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ gba Ẹmi Mimọ. Nitori ẹ̀ṣẹ̀ awọn wọnni ti ẹyin dariji, a dari wọn jì; ẹ̀ṣẹ̀ awọn wọnni ti ẹyin mu ki o wa niṣo, a o mu ki ó wà niṣo.” (JB) Njẹ Jesu nihin-in kò fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni aṣẹ lati dari awọn ẹ̀ṣẹ̀ jì ni pato?
Ti a ba mú un ni oun nikan, àyọkà Bibeli yii lè jọ bi ẹni pe o sọ bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a gbe awọn ọ̀rọ̀ wọnyi yẹ̀wò papọ pẹlu akọsilẹ ti o wà ni Matiu 18:15-18 ati ohun gbogbo miiran ti Bibeli fi kọni nipa ìjẹ́wọ́ ati idariji, ki ni awa gbọdọ pari ero si? Pe ni Johanu 20:22, 23, Jesu fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati le awọn ti wọn nda ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo laironupiwada kuro ninu ijọ. Ni akoko kan naa, Kristi fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni ọla-aṣẹ lati nawọ́ aanu ki wọn sì dariji awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ronupiwada. Dajudaju Jesu kò sọ pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nilati jẹwọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ fun alufaa kan.
Awọn ẹni ti wọn ni ẹrù iṣẹ́ ninu ijọ ni a tipa bayii fun ni àṣẹ lati pinnu bi wọn yoo ṣe ba awọn wọnni ti wọn da ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo lò. Iru awọn ipinnu bẹẹ ni a o ṣe labẹ idari ẹmi mimọ Ọlọrun ati ni ibamu pẹlu awọn itọsọna Ọlọrun ti a fifunni nipasẹ Jesu Kristi ati Iwe Mimọ. (Fiwe Iṣe 5:1-5; 1 Kọrinti 5:1-5, 11-13.) Awọn ọkunrin ti wọn ni ẹru-iṣẹ wọnni yoo tipa bẹẹ dahunpada si idari lati ọ̀run, gbigbiyanju lati mú ki ọ̀run gba awọn ipinnu wọn.
“Ẹ Jẹwọ Awọn Ẹ̀ṣẹ̀ Yin fun Araayin Ẹnikinni Keji”
O dara, nigba naa, nigba wo ni o bojumu fun awọn Kristian lati jẹwọ awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn fun araawọn ẹnikinni keji? Bi ọran ba di ti ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo (kii ṣe gbogbo aṣiṣe keekeeke), ẹni kan nilati jẹwọ fun awọn alaboojuto ti o ni ẹru-iṣẹ ninu ijọ. Ani bi ẹ̀ṣẹ̀ kan kò ba wuwo paapaa ṣugbọn ti ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹṣẹ naa ńdà á láàmú lemọlemọ jù, anfaani titobi nbẹ ninu jíjẹ́wọ́ ati wiwa iranlọwọ tẹmi.
Nipa eyi onkọwe Bibeli naa Jakọbu wipe: “Bi ẹni kan ninu yin ba ṣàárẹ̀ [nipa tẹmi], oun nilati ranṣẹ si awọn alagba ṣọọṣi, wọn sì gbọdọ fi ami ororo kùn ún ni orukọ Oluwa ki wọn sì gbadura le e lori. Adura igbagbọ yoo gba alaisan là Oluwa yoo sì gbe e dide lẹẹkan sii; bi oun ba sì ti da ẹ̀ṣẹ̀ eyikeyii, a o dariji i. Nitori naa ẹ maa jẹwọ awọn ẹ̀ṣẹ̀ yin fun araayin ẹnikinni keji, ki ẹ si maa gbadura fun araayin ẹnikinni keji.”—Jakọbu 5:14-16, JB.
Ninu awọn ọrọ wọnyi, ko si ero ìjẹ́wọ́ onídàákọ́ńkọ́, eleto àṣà, aláàtò isin kankan nibẹ. Kaka bẹẹ, nigba ti ẹru ẹ̀ṣẹ̀ ba di inira sọ́rùn Kristian kan tobẹẹ ti oun fi nimọlara pe oun kò le gbadura, oun nilati pe awọn alagba, tabi awọn alaboojuto ti a yansipo, ninu ijọ, wọn yoo si gbadura fun un. Lati ran an lọwọ lati kọ́fẹpadà nipa tẹmi, wọn yoo tun fi òróró Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kùn ún lara.—Saamu 141:5; fiwe Luuku 5:31, 32; Iṣipaya 3:18.
Ohun ti o yẹ fun afiyesi ni iṣileti Johanu Arinibọmi lati “so eso ti o yẹ fun ironupiwada.” (Matiu 3:8; fiwe Iṣe 26:20.) Oniwa aitọ kan ti o ronupiwada nitootọ yoo pa ipa-ọna rẹ̀ ti o kun fun ẹ̀ṣẹ̀ tì. Gẹgẹ bi Ọba Dafidi ti Israẹli igbaani, ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada ti o jẹwọ ìṣìnà rẹ̀ fun Ọlọrun yoo ri idariji gbà. Dafidi kọwe pe: “Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ni emi kò fi pamọ. Emi wipe, emi yoo jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ mi fun Oluwa [“Jehofa,” NW]: iwọ sì dari ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.”—Saamu 32:5.
Awọn igbesẹ ti wọn jẹ ti ironupiwada kò le gba iru idariji bẹẹ funni. Ọlọrun nikan ni o lè fifunni. Oun fi èrò sí ohun ti idajọ-ododo pipe beere fun, ṣugbọn idariji rẹ̀ fi ifẹ rẹ̀ fun araye hàn. Idariji rẹ̀ tun jẹ ifihan jade inurere ailẹtọọsi ti a gbe kari ẹbọ irapada Jesu Kristi ti a sì mu gbòòrò kìkì de ọ̀dọ̀ awọn ẹlẹṣẹ onironupiwada ti wọn ti yipada kuro ninu ohun ti o buru loju Ọlọrun. (Saamu 51:7; Aisaya 1:18; Johanu 3:16; Roomu 3:23-26) Kiki awọn wọnni ti Jehofa Ọlọrun dariji ni yoo jere iye ayeraye. Ati lati ri iru idariji bẹẹ gbà, awa gbọdọ ṣe ìjẹ́wọ́ ni ọna Ọlọrun, kii ṣe ti eniyan.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni iyatọ ifiwera, wo Maaku 3:29; Heberu 6:4-6; 10:26. Ninu awọn ẹsẹ iwe mimọ wọnyi, awọn onkọwe Bibeli fihan pe dajudaju Ọlọrun kii dari gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ jì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Dafidi jẹwọ fun Jehofa, ẹni ti o fi idariji fun un