ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/15 ojú ìwé 19-22
  • Ta ni Ó ní Ìpè ti Ọ̀run Niti Gidi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta ni Ó ní Ìpè ti Ọ̀run Niti Gidi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Alufaa ati Ọba Oníyọ̀ọ́nú
  • Ijẹrii ti Ẹ̀mí
  • Idi Ti Wọn Fi Nṣajọpin
  • Ki Ni O Fa Awọn Ìléròpé Ti Kò Tọna?
  • Ayẹwo Kínníkínní Ṣe Pataki
  • Ranti Ẹni Ti O Nṣe Yíyàn Naa
  • Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Òmìnira Ológo fún Àwọn Ọmọ Ọlọ́run Láìpẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ẹ̀mí Ń Jẹ́rìí Pẹ̀lú Ẹ̀mí Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Jèhófà Ń Mú Ọ̀pọ̀ Ọmọ Wá Sínú Ògo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/15 ojú ìwé 19-22

Ta ni Ó ní Ìpè ti Ọ̀run Niti Gidi?

JEHOFA nifẹẹ iran eniyan. Họwu, ifẹ yii pọ̀ tobẹẹ gẹẹ debi pe oun fi Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi funni, gẹgẹ bi irapada lati tun ohun ti babanla wa Adamu ti gbe sọnu rapada! Ki sì ni nnkan naa? Iwalaaye ẹda-eniyan pipe, titi ayeraye, pẹlu gbogbo awọn ẹ̀tọ́ ati ireti ohun rere rẹ̀. (Johanu 3:16) Irapada tun jẹ ifihanjade ifẹ Jesu fun araye.—Matiu 20:28.

Ifẹ atọrunwa ni a ti fihan ni ṣiṣi awọn ireti meji tí Ọlọrun fifunni silẹ ti a gbekari itoye ẹbọ irapada Jesu. (1 Johanu 2:1, 2) Ṣaaju ki Jesu to ku gẹgẹ bi eniyan, ireti kanṣoṣo ti o ṣi silẹ fun awọn wọnni ti wọn ni ojurere Ọlọrun ni iye ninu Paradise ti ilẹ-aye. (Luuku 23:43) Bi o ti wu ki o ri, lẹhin Pẹntikọsti 33 C.E., Jehofa fi ireti ti ọ̀run fun “agbo kekere” kan. (Luuku 12:32) Ṣugbọn ki ni o ti ṣẹlẹ ni awọn akoko lọọlọọ? Lati 1931 ihin-iṣẹ Ijọba ti kori afiyesi pupọ sii jọ sori “awọn agutan miiran,” ati lati 1935 siwaju Ọlọrun ti nfa “ogunlọgọ nla” ti iru awọn ẹni bi agutan bẹẹ mọ ara rẹ̀ nipasẹ Kristi. (Johanu 10:16; Iṣipaya 7:9, NW) Ọlọrun ti fi ireti ti iye ayeraye ninu paradise ti ilẹ aye kan sinu ọkan wọn. Wọn fẹ lati jẹ ounjẹ pipe, ki wọn fi ifẹ jọba lori awọn ẹranko, ki wọn sì gbadun ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn ti wọn jẹ́ olododo titilae.

Awọn Alufaa ati Ọba Oníyọ̀ọ́nú

Niwọnbi ifẹ ti sun Jesu lati fi iwalaaye rẹ̀ funni gẹgẹ bi irapada kan, dajudaju oun nilati jẹ Ọba ọ̀run oníyọ̀ọ́nú kan. Sibẹ, Jesu ki yoo danikan wà ninu gbigbe araye dide si ijẹpipe laaarin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun rẹ̀. Jehofa ti ṣe ipese fun awọn ọba oníyọ̀ọ́nú miiran ni ọ̀run. Bẹẹni, “wọn yoo jẹ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn yoo sì maa jọba pẹlu rẹ̀ ni ẹgbẹrun ọdun.”—Iṣipaya 20:1-6.

Awọn alajumọ ṣakoso meloo ni Kristi yoo ni, bawo sì ni a ṣe yàn wọn fun iru anfaani ti o kun fun ibẹru ọlọwọ bẹẹ? O dara, apọsteli Johanu ri 144,000 lori Oke Sioni ti ọ̀run pẹlu Ọdọ-agutan, Jesu Kristi. Ni jijẹ awọn ti “a ti rapada lati inu aye wa,” wọn yoo mọ ohun ti o tumọsi lati ni iriri awọn adanwo, lati farada awọn ẹrù-ìnira aipe, lati jìyà, ati lati ku gẹgẹ bi ẹda-eniyan. (Iṣipaya 14:1-5; Joobu 14:1) Nitori naa, iru awọn ọba ati alufaa oniyọọnu wo ni wọn yoo jẹ!

Ijẹrii ti Ẹ̀mí

Awọn 144,000 “ní ìfòróróyàn lati ọdọ ẹni mimọ ni,” Jehofa. (1 Johanu 2:20) O jẹ ìfòróróyàn si ireti ti ọ̀run. Ọlọrun ti ‘fi èdídí rẹ̀ sori wọn o sì ti fun wọn ni àmì ohun ti nbọ, iyẹn ni, ẹmi, ninu ọkan-aya wọn.’—2 Kọrinti 1:21, 22, NW.

Bẹẹni, awọn wọnni ti wọn ni ipe ti ọ̀run ní ikede ẹri ti ẹmi Ọlọrun pẹlu itumọ yẹn. Nipa eyi, Pọọlu kọwe ni Roomu 8:15-17 pe: “Nitori ẹyin ko tun gba ẹmi ẹrú lati maa bẹ̀rù mọ́: ṣugbọn ẹyin ti gba ẹmi isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pe, Abba, Baba. Ẹmi tikaraarẹ ni o nba ẹmi wa jẹrii pe, ọmọ Ọlọrun ni awa nṣe: bi awa ba sì jẹ ọmọ, njẹ ajogun ni awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọjogun pẹlu Kristi; bi o ba ṣe pe awa ba a jiya, ki a sì lè ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.” O jẹ nipasẹ ẹmi Ọlọrun, tabi ipa agbékánkánṣiṣẹ́, ni awọn ẹni-ami-ororo fi nke jade pe, “Abba, Baba!”

Ẹri pataki pe a ti fi ami òróró yan ẹnikan si ipe ti ọ̀run ni ẹmi, tabi imọlara ti o bori, ti ipo jijẹ ọmọ. (Galatia 4:6, 7) Iru ẹni kọọkan bẹẹ ni idaniloju hán-únhán-ún pe Ọlọrun ti bí oun si ipo jijẹ ọmọ nipa tẹmi gẹgẹ bi ọkan lara awọn 144,000 ajumọjogun ti Ijọba ọ̀run. Oun le jẹrii sii pe ireti rẹ̀ ti ọ̀run kii ṣe ero-ọkan tirẹ ti o mu dagba funraarẹ tabi ti o woye rẹ̀; kaka bẹẹ, o jẹ lati ọ̀dọ̀ Jehofa gẹgẹ bi iyọrisi iṣiṣẹ ẹmi mimọ siha ọ̀dọ̀ rẹ̀.—1 Peteru 1:3, 4.

Labẹ agbara idari ẹmi mimọ Ọlọrun, ẹmi naa, tabi ẹmi-ironu ti o bori, ti awọn ẹni-ami-ororo nṣiṣẹ gẹgẹ bi ipá kan ti ndari ẹni. O sun wọn lati dahunpada lọna pato si ohun ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nipa ireti ti ọ̀run. Wọn tun dahunpada ni ọna pato si awọn ibalo Jehofa pẹlu wọn nipa ẹmi mimọ. Nipa bayii, wọn ni idaniloju pe awọn jẹ ọmọ tẹmi tabi ajogun Ọlọrun.

Nigba ti awọn ẹni-ami-ororo ba ka ohun ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nipa awọn ọmọ rẹ̀ tẹmi ati ireti ti ọ̀run, itẹsi-ọkan wọn ojú ẹsẹ ni lati sọ ninu araawọn pe, ‘Eyi nba mi wi!’ Bẹẹni, wọn dahunpada lọna ti o kun fun ayọ nigba ti Ọ̀rọ̀ Baba wọn ṣeleri èrè ti ọ̀run. Wọn wipe, ‘Iyẹn nba mi wi!’ nigba ti wọn ba kà pe: “Olufẹ, ọmọ Ọlọrun ni awa nṣe nisinsinyi.” (1 Johanu 3:2) Nigba ti awọn ẹni-ami-ororo ba sì kà pe Ọlọrun ti mu awọn eniyan jade wa ‘ki wọn ki o le jẹ akọso awọn ẹda rẹ̀,’ itẹsi ero ori wọn ni lati dahunpada pe, ‘Bẹẹni, o mu mi jade fun ète yẹn.’ (Jakọbu 1:18) Wọn mọ̀ pe a ti ‘baptisi awọn sinu Kristi Jesu’ ati sinu iku rẹ̀. (Roomu 6:3) Nitori naa wọn ni idaniloju fifidimulẹ gbọnyingbọnyin ti jijẹ apakan ara tẹmi Kristi wọn sì di ireti nini iriri iru iku rẹ̀ ati didi awọn ti a ji dide si iye ti ọ̀run mú.

Lati jogun Ijọba ti ọ̀run, awọn ẹni-ami-ororo gbọdọ ‘maa ṣe aisinmi lati sọ ìpè ati yíyàn wọn di eyi ti o daju.’ (2 Peteru 1:5-11) Wọn rin nipa igbagbọ wọn sì nbaa lọ ni didagba nipa tẹmi, gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye ti nṣe. Nitori naa, ki ni ohun ti o tun ku si ijẹrii ti ẹmi?

Idi Ti Wọn Fi Nṣajọpin

Awọn Kristian ẹni ami-ororo ko fẹ lọ si ọ̀run nitori aini itẹlọrun lori igbesi-aye ti ori ilẹ-aye ode oni. (Fiwe Juuda 3, 4, 16.) Kaka bẹẹ, ẹmi mimọ ba ẹmi wọn jẹrii pe wọn jẹ ọmọ Ọlọrun. O tun da wọn loju pe a ti mu wọn wọnu majẹmu titun. Awọn ẹni ti wọn wà ninu majẹmu yii ni Jehofa Ọlọrun ati Israẹli tẹmi. (Jeremaya 31:31-34; Galatia 6:15, 16; Heberu 12:22-24) Majẹmu yii, ti a mu ki o ṣiṣẹ nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a tasilẹ, mu awọn eniyan jade fun orukọ Jehofa o si sọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo wọnyi di apakan “iru-ọmọ” Abrahamu. (Galatia 3:26-29; Iṣe 15:14) Majẹmu titun wa lẹnu iṣẹ titi di igba ti a ba ji gbogbo awọn Israẹli tẹmi si iye aileku ninu ọ̀run.

Siwaju sii pẹlu, awọn wọnni ti wọn ni ìpè ti ọ̀run nitootọ kò ni iyemeji pe awọn pẹlu tun wa ninu majẹmu fun Ijọba ti ọ̀run. Jesu tọka si majẹmu yii laaarin ara rẹ̀ ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nigba ti o wipe: “Ẹyin ni awọn ti o ti duro ti mi ninu idanwo mi. Mo sì yan Ijọba fun yin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn án fun mi; ki ẹyin ki o lè maa jẹ, ki ẹyin ki o sì lè maa mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹyin ki o lè jokoo lori ìtẹ́, ati ki ẹyin ki o lè maa ṣe idajọ fun awọn ẹ̀yà Israẹli mejila.” (Luuku 22:28-30) Majẹmu yii ni a filọlẹ lọdọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu nipa fifi ami-ororo yàn wọn pẹlu ẹmi mimọ ni ọjọ Pẹntikọsti 33 C.E. O nṣiṣẹ titilọ laaarin Kristi ati awọn ọba alabaakẹgbẹ rẹ̀ titilae.—Iṣipaya 22:5.

Awọn wọnni ti wọn ni ìpè ti ọ̀run ni idaniloju pe wọn wà ninu majẹmu titun ati ninu majẹmu fun Ijọba kan. Nitori naa, lọna titọ wọn nṣajọpin ninu akara ati waini iṣapẹẹrẹ nibi ayẹyẹ Iṣe-iranti Ounjẹ Alẹ Oluwa, tabi Iṣe-iranti iku Jesu Kristi lọdọọdun. Àkàrà alaiwu ṣapẹẹrẹ ara eniyan alailẹṣẹ ti Jesu, waini naa sì ṣapẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ pipe rẹ̀ ti o tujade ninu iku ti o sì nfi ẹsẹ majẹmu titun naa mulẹ.—1 Kọrinti 11:23-26.

Bi Jehofa ba ti mu ireti didaju ti iye ti ọ̀run dagba ninu rẹ, iyẹn ni iwọ yoo maa gbáralé. Iwọ ngba awọn adura ni sisọrọ jade nipa ireti yẹn. O ti kún ọ lọkan patapata, iwọ kò sì lè mú un kuro ninu ara rẹ. Iwọ ni awọn ilepa ti ẹmi ti o kun ọkan rẹ jinlẹjinlẹ. Ṣugbọn bi o ba ni iyemeji, ti kò sì da ọ loju, nigba naa dajudaju iwọ kò nilati ṣajọpin ninu awọn ohun apẹẹrẹ ti Ounjẹ Alẹ Oluwa.

Ki Ni O Fa Awọn Ìléròpé Ti Kò Tọna?

Awọn kan lè ṣajọpin ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti lọna ti kò tọna nitori pe wọn kò tẹwọgba otitọ naa pe ìfàmì ororo yan “kii ṣe ti ẹni ti o fẹ, kii sii ṣe ti ẹni ti nsare, bikoṣe ti Ọlọrun.” (Roomu 9:16) Kii ṣe ti ẹni naa lati pinnu pe oun lọkunrin tabi lobinrin yoo fẹ lati di ẹni ti a mu wọnu majẹmu titun naa ki o sì di ajumọjogun pẹlu Kristi ninu Ijọba ti ọ̀run. Yiyan tí Jehofa ṣe ni ohun ti o ṣe pataki. Ni Israẹli igbaani, Ọlọrun yan awọn wọnni ti wọn yoo sìn gẹgẹ bi alufaa rẹ̀, o sì fi ìyà iku jẹ Kora fun fifi ọ̀yájú wa ipo alufaa ti a fi si idile Aaroni lati ọ̀run wa. (Ẹkisodu 28:1; Numeri 16:4-11, 31-35; 2 Kironika 26:18; Heberu 5:4, 5) Lọna ti o farajọra, ki yoo dùn mọ Jehofa ninu bi ẹnikan ba gbe ara rẹ̀ kalẹ gẹgẹ bi ẹnikan ti a pe lati wà laaarin awọn ọba ati alufaa ti ọ̀run nigba ti Ọlọrun kò fun un ni iru ìpè yẹn.—Fiwe 1 Timoti 5:24, 25.

Ẹnikan lè fi aṣiṣe lero pe oun ni ìpè ti ọ̀run nitori imọlara ti o lagbara ti o jẹyọ lati inu awọn iṣoro lilekoko. Iku olubaṣegbeyawo tabi àjálù miiran lè mu ki ẹnikan sọ ifẹ ninu iwalaaye lori ilẹ-aye nù. Tabi alabaakẹgbẹ ẹni timọtimọ kan lè fẹnujẹwọ lati jẹ ẹni-ami-ororo, ẹni naa sì lè fẹ iru kádàrá kan naa. Iru awọn koko abajọ bẹẹ le mu ki o nimọlara pe iye ninu ọ̀run wà fun oun. Ṣugbọn eyi kii ṣe ọna ti Ọlọrun gba nfun ẹnikẹni ni ẹmi jíjẹ́ ọmọ. Yoo fi aini imoore hàn fun ète Ọlọrun nipa ilẹ-aye bi ẹnikan ba fẹ lati lọ si ọ̀run nitori awọn ipo ti ko fanilọkan mọra tabi idaamu ìmí ẹ̀dùn ti o tanmọ́ iwalaaye ti ori ilẹ-aye.

Awọn oju-iwoye isin ti tẹlẹri tun le mu ki ẹnikan pari ero lọna ti kò tọna pe oun ni ìpè ti ọ̀run. Boya oun ti nkẹgbẹpọ tẹlẹ pẹlu isin eke ti o nawọ iye ti ọrun jade gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun awọn oloootọ. Fun idi yii, Kristian kan nilo lati ṣọra lodisi jijẹ ẹni ti imọlara ati awọn oju-iwoye ti kò tọna ti igba atijọ lo agbara idari lori rẹ̀.

Ayẹwo Kínníkínní Ṣe Pataki

Koko pataki kan ni apọsteli Pọọlu mẹnukan nigba ti o kọwe pe: “Ẹnikẹni ti o ba jẹ àkàrà, ti o sì mu aago Oluwa laiyẹ, yoo jẹbi ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa. Ṣugbọn ki eniyan ki o wadii ara rẹ̀ daju, bẹẹ ni ki o sì jẹ ninu àkàrà naa, ki o sì mu ninu aago naa. Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba sì nmu laimọ ara Oluwa yatọ, o njẹ o sì nmu ẹ̀bi fun ara rẹ̀.” (1 Kọrinti 11:27-29) Nitori naa, Kristian kan ti o ti ṣe baptisi ti o bẹrẹ sii ronu lẹnu awọn ọdun aipẹ yii pe oun ti gba ipe ti ọ̀run nilati fun ọran naa ni ironu kínníkínní kan ki o kun fun adura gidigidi.

Iru ẹni bẹẹ tun le bi ara rẹ̀ pe: ‘Awọn miiran ha ti lo agbara idari lori mi lati di ironu iye ti ọ̀run mu bi?’ Eyi ki yoo tọna, nitori Ọlọrun kò yan ẹnikẹni lati wa awọn miiran ṣàjọ fun iru anfaani yẹn. Itẹsi ìgbéra ẹni gun ẹṣin aáyán kì yoo jẹ itọkasi ìfàmì ororo yanni lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, oun kii sii fami ororo yàn awọn ajogun Ijọba nipa mimu wọn gbọ awọn ohùn pẹlu ihin-iṣẹ si itumọ yẹn.

Awọn kan le bi araawọn leere pe: ‘Ṣaaju ki nto di Kristian, mo ha lọwọ ninu lilo oogun ni ilokulo bi? Mo ha nlo awọn oogun itọju ti o nipa lori imọlara mi bi? Mo ha ti gba itọju iṣegun fun awọn iṣoro ti ọpọlọ tabi ti imọlara bi?’ Awọn kan ti sọ pe awọn kọkọ ba ohun ti wọn nro si ireti ti ọ̀run jà. Awọn miiran ti sọ pe fun akoko kan Ọlọrun mú ireti ti ilẹ-aye wọn lọ o sì fun wọn ni ti ọ̀run nikẹhin. Ṣugbọn iru ọna iṣiṣẹ bẹẹ lodisi awọn ibalo atọrunwa. Ju bẹẹ lọ, igbagbọ kii ṣe eyi ti ko daju; o daju.—Heberu 11:6.

Ẹnikan tun le bi ara rẹ̀ leere pe: ‘Mo ha fẹ́ ipo ẹni ti o yọri bi? Mo ha nlepa ipo aṣẹ kan nisinsinyi tabi gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọba ati alufaa ni isopọ pẹlu Kristi?’ Ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E., nigba ti a nkesi gbogbogboo lati wa ọna ati wọle sinu Ijọba ti ọ̀run, kii ṣe gbogbo awọn Kristian ẹni-ami-ororo ni wọn di ipo ẹru iṣẹ mu gẹgẹ bi awọn mẹmba ẹgbẹ oluṣakoso tabi alagba tabi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Ọpọlọpọ ni wọn jẹ obinrin, wọn kò sì ni aṣẹ akanṣe; bẹẹ ni fifi ami ororo yàn ni pẹlu ẹmi kii mu iloye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lọna ara ọtọ wá, nitori Pọọlu rii pe o pọndandan lati kọ́ ki o si gba awọn ẹni-ami-ororo kan nimọran. (1 Kọrinti 3:1-3; Heberu 5:11-14) Awọn wọnni ti wọn ni ipe ti ọ̀run kii wo ara wọn gẹgẹ bi ẹni ti o yọri ọla, wọn kò sì fa afiyesi si jijẹ ti wọn jẹ́ ẹni-ami-ororo. Kaka bẹẹ, wọn fi ẹmi irẹlẹ ti a fojusọna fun lọna titọ lati ọ̀dọ̀ awọn wọnni ti wọn ni “inu Kristi” hàn. (1 Kọrinti 2:16) Wọn tun mọ pe awọn ohun ododo ti Ọlọrun beere fun ni gbogbo awọn Kristian gbọdọ de oju ila wọn, yala ireti wọn jẹ ti ọ̀run tabi ti ilẹ-aye.

Fifẹnujẹwọ níní ìpè ti ọ̀run kò mu awọn iṣipaya akanṣe wa fun ẹnikan. Ọlọrun ni ọna ibanisọrọpọ nipasẹ eyi ti oun npese ounjẹ tẹmi fun eto-ajọ rẹ̀ ti ori ilẹ-aye. (Matiu 24:45-47) Nitori naa ko si ẹnikẹni ti o nilati ronu pe jijẹ Kristian ẹni-ami-ororo fun oun ni ọgbọ́n gigalọla ju ti “ogunlọgọ nla” ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye. (Iṣipaya 7:9, NW) Fifami ororo yanni pẹlu ẹmi ni a ko fihan nipa ijafafa ninu jijẹrii, didahun awọn ibeere ti Iwe Mimọ, tabi sisọ awọn asọye Bibeli, nitori pe awọn Kristian ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye nṣe daradara pẹlu ni awọn apa-iha wọnyi. Gẹgẹ bi awọn ẹni-ami-ororo, awọn pẹlu ngbe igbesi-aye Kristian àwòfiṣàpẹẹrẹ. Nipa eyi, Samsoni ati awọn miiran ṣaaju akoko Kristian ní ẹmi Ọlọrun wọn sì kún fun itara ati oye. Sibẹ, ko si eyikeyii ninu ‘awọsanma nla ti awọn ẹlẹrii’ wọnyẹn ti o ni ireti ti ọ̀run.—Heberu 11:32-38; 12:1; Ẹkisodu 35:30, 31; Onidaajọ 14:6, 19; 15:14; 1 Samuẹli 16:13; Esekiẹli 2:2.

Ranti Ẹni Ti O Nṣe Yíyàn Naa

Bi onigbagbọ ẹlẹgbẹ kan ba beere nipa ìpè ti ọ̀run, alagba ti a yansipo kan tabi Kristian ògbóṣáṣá kan le jiroro ọ̀ràn naa pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikan ko le ṣe ipinnu fun ẹlomiran, Jehofa sì ni ẹni ti nfunni ni ireti ti ọ̀run. Ẹni kan ti o ni ìpè ti ọ̀run nitootọ ko nilo lati beere lọwọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ lae bi oun ba ni iru ireti bẹẹ. Awọn Kristian ẹni-ami-ororo ‘ni a ti fun ni ìbí titun, kii ṣe nipa iru-ọmọ [ti ibimọ] ti a le sọ di ibajẹ, bikoṣe eyi ti a kò lè sọ di ibajẹ, nipa ọ̀rọ̀ Ọlọrun alaaye ti o si wa titi.’ (1 Peteru 1:23, NW) Nipa ẹmi ati Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọlọrun gbin “iru-ọmọ” ti o sọ ẹni naa di “ẹda titun” sinu rẹ̀, pẹlu ireti ti ọ̀run. (2 Kọrinti 5:17) Bẹẹni, Jehofa ni nṣe yiyan naa.

Nitori naa, nigba ti a ba nkẹkọọ Bibeli pẹlu awọn ẹni titun, ko dara lati damọran pe ki wọn gbiyanju lati pinnu yala wọn ni ìpè ti ọ̀run. Ṣugbọn ki ni bi Kristian ẹni-ami-ororo kan ba di alaiṣootọ ti a sì nilo ifidipo? Nigba naa yoo ba ọgbọ́n mu lati pari èrò pe Ọlọrun yoo fi ìpè ti ọ̀run fun ẹnikan ti o ti jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu ṣiṣe iṣẹ-isin oloootọ si Baba wa ọ̀run fun ọdun gbọgbọrọ.

Lonii, olori ète ihin-iṣẹ Ọlọrun kii ṣe fun awọn eniyan lati di mẹmba iyawo Kristi ni ọ̀run. Kaka bẹẹ, “ẹmi ati iyawo nbaa niṣo ni wiwipe: ‘Maa bọ!’” Eyi jẹ ikesini si iye ninu paradise ilẹ-aye kan. (Iṣipaya 22:1, 2, 17, NW) Bi awọn ẹni-ami-ororo ti nmu ipo iwaju ninu igbokegbodo yii, wọn nfi “irẹlẹ ero-inu” han wọn sì nṣiṣẹ ‘lati mu pípè ati yíyàn wọn daju.’—Efesu 4:1-3; 2 Peteru 1:5-11, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́