Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
Jesu Walaaye!
NIGBA ti awọn obinrin naa ri iboji Jesu ti o ṣofo, Maria Magidaleni sare lọ lati sọ fun Peteru ati Johanu. Bi o ti wu ki o ri, o han gbangba pe awọn obinrin miiran duro si ibi iboji naa. Laipẹ, angẹli kan farahan o sì kesi wọn wọle.
Nihin-in awọn obinrin naa tun ri angẹli miiran, ọkan lara awọn angẹli naa sì wi fun wọn pe: “Ẹ maṣe bẹru, nitori mo mọ̀ pe ẹyin nwa Jesu ẹni ti a kàn mọgi. Oun kò si nihin-in, nitori a ti ji i dide, gẹgẹ bi o ti wi. Ẹ wa, ẹ wo ibi ti o ti dubulẹ si. Ẹ sì lọ kiakia ki ẹ sì sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe a ti gbe e dide kuro ninu oku.” Nitori naa pẹlu ibẹru ati ayọ, awọn obinrin wọnyi tun sare lọ.
Ni akoko yii, Maria ti ri Peteru ati Johanu, o sì rohin fun wọn pe: “Wọn ti gbe Oluwa lọ kuro ninu iboji iranti, awa kò sì mọ ibi ti wọn tẹ ẹ si.” Lọ́gán awọn apọsteli mejeeji bẹrẹ eré sisa. Johanu jẹ ẹlẹ́sẹ̀ ehoro—ni jijẹ ẹni ti o kere ju lọna ti o han gbangba—o si de iboji naa ṣaaju. Ni akoko yii awọn obinrin naa ti lọ, nitori naa ko si ẹni kankan ni ayika. Ni bibẹrẹ mọlẹ, Johanu bẹjuwo inu iboji naa o sì ri awọn ọ̀já-ìdìkú, ṣugbọn o duro sita.
Nigba ti Peteru de, oun kò jáfira ṣugbọn o wọnu ile lọ. Oun ri awọn ọ̀já-ìdìkú ti wọn wà nílẹ̀ nibẹ ati awọn aṣọ ti a fi di ori Jesu. A yí i pọ si oju kan. Nisinsinyi Johanu pẹlu tun wọ inu iboji naa, o sì gba irohin Maria gbọ. Ṣugbọn yala Peteru tabi Johanu ko loye pe Jesu ni a ti ji dide, ani bi o tilẹ jẹ pe Oun ti fi igba gbogbo sọ fun wọn pe oun yoo ji dide. Ninu iṣekayeefi, awọn mejeeji pada sile, ṣugbọn Maria, ẹni ti o ti pada sibi iboji naa, duro nibẹ.
Laaarin akoko naa, awọn obinrin yooku nyara lati lọ sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe Jesu ti ji dide, gẹgẹ bi angẹli naa ti paṣẹ fun wọn lati ṣe. Nigba ti wọn nsare lọ loju ọna kikankikan bi wọn ti lè ṣe to, Jesu pade wọn o sì wipe: “Ẹ pẹlẹ o!” Ni wiwolẹ sibi ẹsẹ rẹ̀, wọn wárí fun un. Nigba naa Jesu wipe: “Ẹ ma bẹru! Ẹ lọ, ẹ rohin fun awọn arakunrin mi ki wọn lè lọ si Galili; nibẹ ni wọn yoo sì ri mi.”
Ṣaaju, nigba ti ìsẹ̀lẹ̀ sẹ ti awọn angẹli naa sì farahan, awọn ọmọ-ogun ti wọn ńṣọ́ ẹ̀ṣọ́ ni èrirì mu wọn sì dabi oku eniyan. Lẹhin ti ara wọn ti kọ́fẹ, wọn lọ sinu ilu naa lọgan wọn sì sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ fun awọn olori alufaa. Lẹhin fifi ikùn lukùn pẹlu “awọn àgbà ọkunrin” awọn Juu, ipinnu ni a ṣe lati gbiyanju lati ma jẹ ki awọn eniyan mọ̀ nipa ọran naa nipa fifun awọn ọmọ-ogun naa ni àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọn fun wọn ni itọni pe: “Ẹ wipe, ‘Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá ni òru wọn sì jí i gbe nigba ti awa nsun.’”
Niwọnbi o ti jẹ pe awọn ọmọ-ogun Roomu ni a lè fiya iku jẹ fun sisun ni ẹnu iṣẹ wọn, awọn alufaa ṣeleri pe: “Bi eyi [irohin pe ẹ sun] ba sì de etí gomina awa yoo yí i lọkan pada yoo sì da yin silẹ lominira kuro ninu wahala.” Niwọnbi iye owo abẹtẹlẹ naa ti pọ̀ lọna ti o tẹrun, awọn ọmọ-ogun naa ṣe gẹgẹ bi a ti fun wọn ni itọni. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, irohin eke naa nipa jíjí ara Jesu gbé di eyi ti o tankalẹ lọna gbigbooro laaarin awọn Juu.
Maria Magidaleni, ẹni ti o duro sẹhin nibi iboji naa, ni ẹ̀dùn ọkàn ti bori rẹ̀. Nibo ni Jesu le wa? Ni títẹ̀ba siwaju lati wo inu iboji naa, oun ri awọn angẹli meji ninu aṣọ funfun, ti wọn ti tun farahan! Ọkan jokoo nibi ori ati ekeji nibi ẹsẹ nibi ti a gbe ara Jesu si. “Obinrin, eeṣe ti iwọ fi nsunkun?” ni wọn beere.
“Maria dahun pe: “Wọn ti gbe Oluwa mi lọ, emi kò sì mọ ibi ti wọn tẹ́ ẹ si.” Lẹhin naa oun yipada o si ri ẹnikan ti o tun ibeere naa beere pe: “Obinrin, eeṣe ti iwọ fi nsunkun?” Ẹni yii tun beere pe: “Ta ni iwọ nwa?”
Ni riro ẹni yii sí olùṣọ́gbà ibi ti iboji naa wà, o sọ fun un pe: “Ọgbẹni, bi iwọ ba ti gbe e kuro, sọ ibi ti iwọ tẹ ẹ si fun mi, emi yoo sì gbe e lọ.”
Ẹni naa wipe: “Maria!” Lọ́gán oun sì mọ pe Jesu ni, nipa ọna ti oun mọ̀ daadaa ti ẹni naa gbà sọrọ si i. Maria fi imọlara ké jade pe: “Rab·boʹni!” (ti o tumọsi “Olukọ!”) Ati pẹlu ayọ ti kò láàlà, o gbá a mu. Ṣugbọn Jesu wipe: “Dẹkun rírọ̀ mọ mi. Nitori emi kò tii goke lọ sọdọ Baba sibẹ. Ṣugbọn mu ọna rẹ pọ̀n lọ si ọ̀dọ̀ awọn arakunrin mi ki o sì wi fun wọn pe, ‘Emi ngoke lọ sọdọ Baba mi ati Baba yin ati sọdọ Ọlọrun mi ati Ọlọrun yin.’”
Nisinsinyi Maria sare lọ si ibi ti awọn apọsteli ati awọn ọmọ-ẹhin ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti korajọ si. O fi irohin tirẹ̀ kun irohin tí awọn obinrin yooku ti sọ nipa riri Jesu ti a ji dide. Sibẹ, awọn ọkunrin wọnyi, ti wọn kò gba awọn obinrin akọkọ gbọ́, lọna ti o han gbangba ko gba Maria gbọ́ pẹlu. Matiu 28:3-15, NW; Maaku 16:5-8; Luuku 24:4-12; Johanu 20:2-18, NW.
◆ Lẹhin biba iboji naa ni ṣiṣofo, ki ni Maria Magidaleni ṣe, iriri wo sì ni awọn obinrin yooku naa ni?
◆ Bawo ni Peteru ati Johanu ṣe huwapada ni biba iboji naa lofo?
◆ Ki ni awọn obinrin yooku ba pade loju ọna wọn lati rohin ajinde Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin?
◆ Ki ni o ṣẹlẹ si ẹṣọ ọmọ-ogun, ki sì ni idahunpada awọn alufaa si irohin wọn?
◆ Ki ni o ṣẹlẹ nigba ti Maria Magidaleni dá nikan wà nibi iboji naa, ki sì ni iṣarasihuwa awọn ọmọ-ẹhin si irohin awọn obinrin naa?