Nisinsinyi ni Akoko naa Lati Wá Jehofa
“Niti Jehofa, oun ti boju wolẹ lati ọrun funraarẹ wo awọn ọmọkunrin eniyan, lati rí i yala ẹnikẹni wà tí ó ní ijinlẹ òye, ẹnikẹni tí nwa Jehofa.”—SAAMU 14:2, NW.
1, 2. (a) Oju wo ni ọpọlọpọ fi nwo Ọlọrun tootọ naa, Jehofa? (b) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Jehofa kiyesi idagunla araye?
LONII, Ọlọrun tootọ naa, Jehofa, ni a ti ṣátì lati ọ̀dọ̀ awọn alaigbọlọrungbọ, onigbagbọ Ọlọrun kò ṣeé mọ̀, awọn olujọsin ọlọrun èké, ati araadọta ọkẹ tí wọn sọ pe awọn gbagbọ ninu Ọlọrun ṣugbọn tí wọn sẹ́ ẹ nipa awọn iṣẹ́ wọn. (Titu 1:16) Ọpọlọpọ gbagbọ bii ọ̀mọ̀ràn ará German ti ọrundun kọkandinlogun naa Nietzsche pe “Ọlọrun ti kú.” Jehofa kò ha mọ nipa iwa ainaani omugọ yii bí? Bẹẹkọ, nitori oun mísí Dafidi lati kọwe pe: “Oponu eniyan ti wi ninu ọkan aya rẹ̀ pé: ‘Kò sí Jehofa.’ Wọn ti huwa lọna iparun, wọn ti huwa lọna irira ninu ibalo wọn. Kò sí ẹni kan ti nṣe rere.”—Saamu 14:1, NW.
2 Dafidi nbaa lọ pe: “Niti Jehofa, oun ti boju wolẹ lati ọrun funraarẹ wo awọn ọmọkunrin eniyan, lati rí i yala ẹnikẹni wà tí ó ní ijinlẹ òye, ẹnikẹni tí nwa Jehofa.” Bẹẹni, Oluwa Ọba-alaṣẹ naa kiyesi awọn wọnni tí wọn nwa ọna lati mọ̀ ọ́ kí wọn si ṣiṣẹsin-in. Nipa bayii, wíwá ti a nwá a pẹlu ifọkansin nisinsinyi ṣe pataki. Yoo tumọsi iyatọ laaarin iye ainipẹkun ati ìmúpòórá ainipẹkun.—Saamu 14:2, NW; Matiu 25:41, 46; Heberu 11:6.
3. Ṣiṣeeṣe wo ni ó wà fun ọjọ iwaju?
3 Nitori naa, awa le ri idi ti o fi ṣe pataki gan-an pe ki a ran awọn ẹlomiran lọwọ lati wá Jehofa nisinsinyi. Araadọta ọkẹ awọn eniyan ni wọn ṣi wà sibẹ ti wọn ko tíì ba awọn Ẹlẹrii Jehofa pade tabi gbọ́ “ihinrere ijọba” naa rí. Bí iye awọn “ogunlọgọ nla” yoo si ṣe wá pọ̀ tó ṣaaju “ipọnju nla,” ni awa kò mọ́. Ṣugbọn ó daju pe ṣiṣeeṣe naa wà fun pupọ sii lati wá kí wọn si ri Jehofa Ọlọrun ní ọjọ iwaju ti ko jinna mọ ki o to di pe o pẹ ju. Ibeere naa nisinsinyi ni pe, Ki ni awa le ṣe lati ran ọpọlọpọ sii lọwọ lati ri Ọlọrun?—Matiu 24:14; Iṣipaya 7:9, 14.
4, 5. Ninu iwakiri wọn fun ọlọrun kan, ki ni ọpọlọpọ yàn?
4 Ọpọlọpọ awọn eniyan ninu aye lonii nṣe iwakiri, ṣugbọn ki ni wọn nwa kiri? Iwọnba diẹ ṣíún ni nwa Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, Jehofa nitootọ. Aimọye ni wọn yan ọlọrun kan tí o bá ifẹ ọkan ati itẹsi tiwọn funraawọn mu. Gẹgẹ bi George Gallup, Jr., oluwadii èrò ara U.S. ti wi: “Iwọ ko tilẹ le ri iyatọ laaarin awọn ẹni ti nlọ si ṣọọṣi ati awọn ti kii lọ sí ṣọọṣi niti irẹnijẹ, yíyẹ owó orí, ṣíṣàfọwọ́rá, ni pataki julọ nitori pe ọgọọrọ isin ẹgbẹ-oun-ọgba ni o wà.” O fi kun un pe “ọpọlọpọ wulẹ̀ ńdá isin tí ó tù wọn lara ti o si dun mọ́ wọn silẹ . . . Ẹnikan pè é ni isin yàn bí o ṣe fẹ́.”
5 Awọn miiran yoo sọ pe, “Isin mi dara tó fun mi.” Dajudaju, ibeere naa niti gidi yẹ ki o jẹ, “Isin mi ha dara tó fun Ọlọrun bí?” Loootọ, ọpọ julọ ninu Kristẹndọm ati isin Hindu nitẹẹlọrun lati kúnlẹ̀ bọ awọn ère ati oriṣa wọn. Ọpọ julọ awọn Kristian alafẹnujẹ ríi pe ọlọrun Mẹtalọkan ti ko lorukọ ti tó fun wọn. Iye ti o si ju 900 million awọn Musulumi gbagbọ ninu Allah. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, araadọta ọkẹ awọn alaigbọlọrungbọ sọ pe kò sí Ọlọrun kankan.
Awọn Wọnni Ti Wọn Nilo Iranlọwọ
6. Ki ni ọpọlọpọ awọn onkawe Ilé-ìṣọ́nà ṣawari rẹ̀?
6 Ṣugbọn ki ni nipa awọn wọnni ninu wa tí wọn nka iwe irohin yii deedee? Awa ti wá Ọlọrun tootọ naa kiri a sì ti ríi. A ti mú kí awọn ọ̀rọ̀ Jakọbu 4:8 jásí otitọ: “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun o si sunmọ yin.” Nipa ibakẹgbẹgbọ alakitiyan iṣẹ pẹlu ijọ Kristian, awa ti sunmọ Ọlọrun pẹkipẹki sii, awa funraawa si ti niriiri bí Jehofa ti sunmọ wa pẹkipẹki.—Johanu 6:44, 65.
7. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe ọpọlọpọ awọn eniyan ní wọn wà tí wọn ṣì nifẹẹ si didi agbékánkán ṣiṣẹ ninu otitọ?
7 Bi o ti wu ki o ri, awa mọ̀ pe ọpọlọpọ ṣi wà tí wọn layọ lati kẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan Jehofa lẹẹkọọkan ṣugbọn sibẹ tí wọn kò tíì gbe igbesẹ pato lati sunmọ Jehofa nipa iyasimimọ ati iribọmi. Bawo ni a ṣe mọ eyi? Ni 1990 oun ti o sunmọ million mẹwaa awọn eniyan wa sí Iṣe-iranti iku Jesu. Ṣugbọn awọn meloo ní wọn nkede ihinrere Ijọba naa pẹlu aapọn? Ó fi diẹ kọja million mẹrin. Iyẹn tumọsi pe a ni nǹkan bíi million mẹfa tí wọn nfi ifẹ han sí otitọ ti wọn sì gbadun kikẹgbẹpọ pẹlu wa nigba miiran ṣugbọn wọn kò tíì bẹrẹ lati fọwọsi èdè mímọ́gaara ti otitọ nipa wiwaasu ihinrere Ijọba naa. Laisi iyemeji, ní awọn akoko akọsẹba ọpọlọpọ nsọ ero wọn jade fun itilẹhin Jehofa ati iṣakoso Ijọba rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò tíì da araawọn wọn yatọ kedere gẹgẹ bi Ẹlerii Jehofa. Awọn wọnyi pẹlu ni a fẹ́ ràn lọwọ.—Sefanaya 3:9; Maaku 13:10.
8, 9. (a) Ki ni Jehofa fun wa niṣiiri lati ṣe? (b) Eeṣe tí kò fi bọ́gbọ́nmu lati ṣainaani imọran Jehofa?
8 A fẹ fun awọn wọnyi ni iṣiri lati di Ẹlẹrii alayọ, agbekankan ṣiṣẹ fun Jehofa ninu apa ti o kẹhin ninu iṣẹ titobi ti a nṣaṣepari rẹ̀ yika aye nisinsinyi. Jọwọ ṣakiyesi ikesini onifẹẹ ti Jehofa ni Owe 1:23: “Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi, emi o da ẹmi mi sinu yin; emi o fi ọrọ mi han fun yin.” (Fiwe Johanu 4:14.) Bawo ni o ti funni ní iṣiri tó lati mọ̀ pe Jehofa yoo dahunpada sí gbigbe awọn igbesẹ pato lati fi araawa han pẹlu orukọ ati ijọsin rẹ̀! Dajudaju, awa ko fẹ́ lati wà laaarin awọn wọnni ti a ṣapejuwe ni Owe 1:24, 25: “Nitori ti emi pè, ti ẹyin sì kọ̀; ti emi nawọ mi, ti ẹnikan kò sì kà á sí: ṣugbọn ẹyin ti ṣa gbogbo igbimọ [“imọran,” NW] mi ti, ẹyin kò sì fẹ́ ibawi mi.”
9 Awọn wọnni tí wọn ṣainaani imọran Jehofa pe kí wọn wá a kiri nigba ti wọn lè rí i tí wọn sì nsun ipinnu wọn siwaju titi di igba ti wọn yoo fi rí ibẹrẹ ipọnju nla niti gidi yoo ri pe wọn ti duro pẹ ju. Iru ipa ọna bẹẹ yoo fi aini igbagbọ ati ọgbọn ati àìlọ́wọ̀ fun inurere ailẹtọọsi Jehofa han.—2 Kọrinti 6:1, 2.
10. Eeṣe ti aibikita ati idagunla fi lewu?
10 Lati ṣakawe idi ti igbesẹ kiakia fi jẹ ọranyan, iwọ yoo ha tẹle imọran rere dokita kìkì nigba ti iwọ ba tó ni aisan otútù àyà ti o mú ẹ̀dọ̀fóró mejeeji? Tabi, kaka bẹẹ, nigba ti iwọ ba ṣakiyesi awọn ami akọkọ ti aisan naa? Nigba naa eeṣe ti o fi nilati duro pẹ́ sii lati le ya araarẹ sọtọ kuro ninu ayé Satani ti nṣaisan ki o si faramọ apa ọdọ Jehofa ati awọn Ẹlẹrii rẹ̀? Awọn iyọrisi aibikita, idagunla, ati ainaani ni a mú ṣe kedere ní Owe 1:26-29: “Emi pẹlu yoo rẹrin-in idamu yin; emi o ṣe ẹ̀fẹ̀ nigba ti ibẹru yin bá dé; . . . nigba naa ni ẹyin o kepe mi, ṣugbọn emi kì yoo dahun; wọn o ṣafẹri mi ni kutukutu, ṣugbọn wọn kì yoo rí mi: nitori tí wọn koriira imọ wọn, ko si yan ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW].” Ẹ maṣe jẹ́ kí a ri wa ki a ṣẹṣẹ maa ‘ṣafẹri Oluwa [“Jehofa,” NW]’ nigba ti o ti pẹ́ ju!
11. Iranlọwọ wo ni ó wa larọọwọto fun awọn wọnni tí wọn nwa lati ṣiṣẹsin Ọlọrun?
11 Awọn kan tí wọn nka iwe irohin yii ṣì lè wà lori wíwá Ọlọrun tootọ naa kiri sibẹ. Awa layọ pe ẹyin ntẹramọ iwakiri yin. A gbadura pe imọ Bibeli yin yoo sún yin lati gbé igbesẹ pato siwaju sii lati duro gbọnyin fun otitọ. Ẹ ni idaniloju pe ijọ awọn Ẹlẹrii Jehofa kọọkan wà ní sẹpẹ́ lati ran yin lọwọ ninu iwakiri yin.—Filipi 2:1-4.
Akoko fun Itara ati Igbegbeesẹ
12, 13. Eeṣe ti a fi nilati gbégbèésẹ̀ nipa ijọsin tootọ?
12 Eeṣe ti o fi ṣe pataki kí gbogbo wa gbé igbesẹ lati fi ara wa han pẹlu Jehofa Ọlọrun ati isin tootọ rẹ̀? Nitori pe awọn iṣẹlẹ ayé forile ogogoro opin. Awọn oju-iwe itan nyara ṣí ju bi eniyan ti ṣe le ka wọn. Isinsinyi kii ṣe akoko naa lati jẹ́ alaifẹ ṣe ipinnu tabi kò gbóná kò tutù. Jesu sọ ni kedere pe: “Ẹni ti kò bá wà pẹlu mi, o nṣe odì si mi: ẹni ti ko ba si ba mi kó pọ̀, o nfunka.” Oun tun sọ pe: “Ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ̀ mi, oju rẹ̀ ni ọmọ eniyan yoo sì ti, nigba ti ó ba dé inu ogo tirẹ, ati ti Baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ.”—Matiu 12:30; Luuku 9:26.
13 Isinsinyii ni akoko naa fun itara ati ìgbégbèésẹ̀! Awa mọ ọ̀nà ibi ti awọn iṣẹlẹ ayé forile, Amagẹdọni sì rọ̀dẹ̀dẹ̀ sí ọ̀kánkán. Nitori naa, ìpè naa ni lati wá Jehofa nisinsinyi ṣaaju ‘ọjọ́ ibinu rẹ̀,’ nigba ti a ṣì lè rí i. Yoo ti pẹju ní igba ipọju nla.—Sefanaya 2:2, 3; Roomu 13:11, 12; Iṣipaya 16:14, 16.
14. Awọn ìdí wo ni a ní fun wiwa Ọlọrun?
14 Niti gidi, gbogbo araye nilati maa wá ojurere Ọlọrun nisinsinyi. Apọsteli Pọọlu sọ ọ́ lọna ti ó ba a mu ni Iṣe 17:26-28, (NW): “[Ọlọrun] . . . dá lati inu ọkunrin kan olukuluku orilẹ-ede eniyan, lati gbe ni gbogbo ori ilẹ aye, o si paṣẹ awọn akoko ti a yan tẹlẹ ati awọn aala ibugbe awọn eniyan, fun wọn lati wá Ọlọrun, bí wọn bá lè táràrà fun un kí wọn sì rí i nitootọ, bi o tilẹ jẹ́ pé, niti tootọ, oun kò jinna sí ọ̀dọ̀ ẹnikọọkan wa. Nitori nipasẹ rẹ̀ awa ni iye a ńrìn a sì wà.” Ọrọ ti ó kẹhin yẹn, “nitori nipasẹ rẹ̀ awa ní ìyè a ńrìn a sì wà,” fun wa ni ìdí tí ó kun tó fun wíwá Ọlọrun. Ọpẹ ni fun inurere ailẹtọọsi Jehofa, awa ngbe ní apá pataki ti o mọniwọn, ṣugbọn tí ó ṣeégbé lori ilẹ aye bíńtín yii. Kò ha yẹ ki a kun fun imoore sí Oluwa Ọba-alaṣẹ agbaye bí? Kò ha si yẹ lati fi imoore wa han fun un ní awọn ọ̀nà tí wọn gbéṣẹ́?—Iṣe 4:24.
15. (a) Ki ni opitan Arnold Toynbee nimọlara pe ó jẹ́ ète isin gigaju? (b) Ki ni a gbọdọ ṣe kí a baa lè fi ogo fun Ọlọrun?
15 Opitan Arnold Toynbee kọwe lẹẹkanri pe: “Ète tootọ ti isin gigaju ni lati tan awọn imọran ati otitọ tẹ̀mí tí ó jẹ́ koko pataki rẹ̀ sinu ọpọlọpọ ọkàn ti o lè dé, ki o ba le ṣeeṣe fun ọkọọkan awọn ọkàn wọnyi lati tipa bẹẹ mú ète tootọ ti eniyan ṣẹ. Ète tootọ ti eniyan ni lati fi ogo fun Ọlọrun ati lati gbadun Rẹ̀ titilae.” (An Historian’s Approach to Religion, oju-iwe 268 sí 269) Kí a baa lè fi ogo fun Ọlọrun, awa gbọdọ kọ́kọ́ wá a kí a sì jèrè ìmọ̀ pipeye nipa rẹ̀ ati awọn ète rẹ̀. Nipa bayii, ikesini Aisaya baamu gan-an pe: “Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW] nigba ti ẹ lè ri, ẹ pè é, nigba ti ó wà nitosi. Jẹ́ kí eniyan buburu kọ ọ̀nà rẹ̀ silẹ, kí ẹlẹṣẹ sì kọ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ́ ki o yipada sí Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ó sì ṣaanu fun un, ati sí Ọlọrun wa, yoo si fi jì í ní ọpọlọpọ.”—Aisaya 55:6, 7.
Iranlọwọ Ti Ó Ṣeémúlò Wo Ni Awa Lè Pese?
16. (a) Ipenija wo ni ó dojukọ ijọ Kristian? (b) Ọna tí ó gbeṣẹ wo ni a le gbà ran awọn ẹlomiran lọwọ lati ṣiṣẹsin Jehofa?
16 Araadọta ọkẹ awọn eniyan olufifẹhan wọnyi tí wọn kò tii di akede agbékánkán ṣiṣẹ́ sibẹ gbé ipenija kan siwaju gbogbo wa. Ki ni a nṣe ní ọ̀nà tí ó gbeṣẹ gẹgẹ bi alagba, iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, aṣaaju ọna, ati akede lati ran awọn wọnni ti wọn fi fẹhan sí otitọ lọwọ lati di olukopa agbekankan ṣiṣẹ ninu ijọsin tootọ pẹlu wa? Ọna kan lati pese iranlọwọ tí ó gbéṣẹ́ nibi ti a ti nilo rẹ̀ ni lati lọ si ile wọn kí a sì mú wọn lọ sí ipade ní Gbọngan Ijọba kí awọn pẹlu baa lè gbadun anfaani ẹmi Jehofa deedee. Imọran Pọọlu sí awọn ara Heberu, ní ori 10, ẹsẹ 24 ati 25, jẹ́ kanjukanju lonii gẹgẹ bi o ti ri nigba naa lọ́hùn-ún: “Ẹ jẹ́ ki a yẹ araawa wo lati ru ara wa sí ifẹ ati sí isẹ rere: ki a má maa kọ ipejọpọ araawa silẹ, gẹgẹ bi aṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a maa gba ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bí ẹyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile.” A fun gbogbo awọn tí wọn bá daniyan lati ni iriri ifẹ inurere Jehofa niṣiiri lati maa darapọ mọ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa deedee ní Gbọngan Ijọba adugbo wọn.
17. Bí awa ba nilati ran awọn akẹkọọ Bibeli lọwọ lati tẹsiwaju ninu iwakiri wọn fun Jehofa, awọn ibeere wo ni wọn nilo idahun?
17 Bí awa bá nkẹkọọ Bibeli pẹlu ẹnikan ti nwa sí ipade deedee, njẹ a lè ran ẹni yẹn lọwọ lati tootun gẹgẹ bi akede ihinrere kan? (Wo Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, oju-iwe 97 sí 99.) Ati lọ́gán ti oun lọkunrin tabi lobinrin ba ti di akede ti ko tii ṣe iribọmi, a ha nawọ ikesini sí i lati ba wa lọ deedee sí iṣẹ ijẹrii itagbangba ati diẹ lara awọn ikẹkọọ Bibeli ati ipadabẹwo wa? (Wo itẹjade Ilé-ìṣọ́nà, December 1, 1989, oju-iwe 31.) Ni èdè miiran, gbara ti iru awọn ẹni titun bẹẹ ba ti tootun, njẹ awa nfun wọn niṣiiri nipa jijẹki wọn rí diẹ lara awọn ojulowo iyọrisi rere ti igbokegbodo iwaasu wa ni tààràtà?—Matiu 28:19, 20.
Jehofa Yẹ Ní Wiwa
18. Bawo ni Jehofa ṣe fi aanu rẹ̀ han sí araye?
18 Nitori ẹbọ irapada Kristi Jesu, Jehofa kii fi awọn ẹṣẹ ati aibikita wa igba atijọ bi wá bí awa bá ronupiwada tí a sì mú igbagbọ lò. Ṣakiyesi awọn ọ̀rọ̀ Dafidi: “Oun kii ṣe sí wa gẹgẹ bi ẹṣẹ wa; bẹẹ ni kii san an fun wa gẹgẹ bi aiṣedeedee wa. Nitori pe, bi ọrun ti ga sí ilẹ, bẹẹ ni aanu rẹ̀ tobi sí awọn tí ó bẹru rẹ. Bi ila-oorun ti jinna sí iwọ-oorun, bẹẹ ni o mú ẹṣẹ wa jinna kuro lọdọ wa. Bí Baba tii ṣe ìyọ́nú sí awọn ọmọ, bẹẹ ni Oluwa [“Jehofa,” NW] nṣe iyọnu sí awọn tí ó bẹru rẹ̀. Nitori ti ó mọ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.”—Saamu 103:10-14; Heberu 10:10, 12-14.
19. Iṣiri wo ni ó wa fun awọn wọnni tí wọn ti lè súlọ kuro ninu otitọ?
19 Jehofa jẹ́ Ọlọrun oninuure ati alaanu niti tootọ. Bí awa bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu irẹlẹ ati ironupiwada, oun a dariji wá a si gbagbe. Oun kìí ni ìkùnsínú ayeraye ti o ni ìmújoró ina ọrun apaadi ainipẹkun gẹgẹ bi iyọrisi. Bẹẹkọ, nṣe ni o rí gẹgẹ bi Jehofa ti sọ ọ́ pe: “Emi, ani emi ni ẹni ti o pa aiṣedeedee rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalaraami, emi kì yoo si ranti ẹṣẹ rẹ.” Iru iṣiri wo ni iyẹn nilati jẹ́ fun ẹnikẹni tí ó ti lè súlọ kuro ninu otitọ tí ó sì ti ṣainaani ipo ibatan rẹ pẹlu Jehofa! Awọn pẹlu ni a fun niṣiiri lati wá Jehofa nisinsinyi kí wọn sì pada sinu ibakẹgbẹpọ alaapọn pẹlu awọn eniyan ti a nfi orukọ rẹ̀ pè.—Aisaya 43:25.
20, 21. (a) Apẹẹrẹ afunni ni iṣiri wo ni a ní ninu Juda igbaani? (b) Ki ni awọn olugbe Juda nilati ṣe lati gba ibukun Jehofa?
20 Ní ọna yii a ni apẹẹrẹ ti nfunni niṣiiri ninu Ọba Asa ni Juda igbaani. Oun pa gbogbo ijọsin èké run patapata kuro ninu ijọba rẹ̀, ṣugbọn ipa àmì ijọsin oloriṣa ṣì kù. Akọsilẹ ti o wà ninu 2 Kironika 15, ẹsẹ 2 sí 4 (NW), sọ ohun tí wolii Asaraya sọ fun Asa gẹgẹ bi irannileti: “Jehofa wà pẹlu rẹ niwọn igba ti iwọ bá fi ẹ̀rí hàn pe o wà pẹlu rẹ̀; bí iwọ bá sì wá a kiri, oun yoo jẹ ki iwọ rí oun, ṣugbọn bí iwọ ba fi í silẹ oun yoo fi ọ silẹ. Ọpọlọpọ ọjọ sì ni Israẹli ti wà laisi Ọlọrun tootọ . . . Ṣugbọn nigba ti wọn wà ninu isorikọ wọn wọn pada sọdọ Jehofa Ọlọrun Israẹli wọn sì wá a, nigba naa ni oun jẹ́ kí wọn rí oun.”
21 Jehofa kò ṣere bojuboju pẹlu Ọba Asa ṣugbọn “ó jẹ́ kí wọn rí oun.” Bawo ni ọba naa ṣe huwa pada sí ihin iṣẹ yii? Ni ori kan naa, ẹsẹ 8 ati 12 (NW) dahun pe: “Ní gbàrà tí Asa ti gbọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi . . . , o mú ọkan le ó sì bẹrẹ sii jẹ́ kí awọn ohun ìríra poora kuro ninu gbogbo ilẹ naa . . . ati lati sọ pẹpẹ Jehofa tí ó wà niwaju ìloro Jehofa dọtun. Siwaju sii, [Juda] wọnu majẹmu lati wá Jehofa Ọlọrun babanla wọn kiri pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn ati gbogbo ọkan wọn.” Bẹẹni, wọn fi pẹlu ifọkansin wá Jehofa “pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn ati gbogbo ọkan wọn.” Ki ni o yọrisi fun orilẹ-ede naa? Ẹsẹ 15 (NW) sọ fun wa pe: “Gbogbo Juda sì bú sayọ lori ohun tí wọn bura; nitori ó jẹ́ pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn ní wọn fi bura ati pẹlu ẹkunrẹrẹ inudidun ni iha ọdọ wọn ní wọn fi wá a, tí o fi jẹ́ pe oun jẹ́ kí wọn rí oun; Jehofa sí nbaa lọ lati fun wọn ní isinmi yíká gbogbo.”
22. Ki ni o fun wa niṣiiri lati jẹ́ agbékánkán ṣiṣẹ́ nisinsinyi ninu iṣẹ-isin Jehofa?
22 Nisinsinyi, iyẹn kò ha jẹ́ iṣiri fun gbogbo wa lati gbé igbesẹ pato niti ijọsin mímọ́gaara ti Jehofa? Awa mọ pe ṣiṣeeṣe wa fun araadọta ọkẹ pupọ sii lati yin Jehofa. Laisi iyemeji ọpọlọpọ ninu awọn wọnyi nṣe iyipada ninu igbesi aye wọn kí wọn baa lè dé oju awọn ìlà ohun ti Iwe Mimọ beere fun fun iṣẹ-isin Jehofa. Awọn miiran ndagba ninu ijinlẹ oye ati igbagbọ, wọn nwa Jehofa, a o si sun wọn laipẹ lati ṣajọpin ninu èdè mímọ́gaara naa pẹlu awọn ẹlomiran nipa gbigbe oye otitọ nipa Jehofa ati awọn ète Ijọba rẹ̀ ti o jinlẹ dé ọ̀dọ̀ wọn. Eesitiṣe ti o fi ṣe pataki pe ki gbogbo wa wá Jehofa kiri nisinsinyi nigba ti a le rii? Nitori aye titun rẹ̀ ti ó ṣeleri ti sunmọle!—Aisaya 65:17-25; Luuku 21:29-33; Roomu 10:13-15.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Awọn wo ni wọn fi idagunla han sí Ọlọrun tootọ naa, Jehofa?
◻ Dé aye wo ni isin saba maa nnipa lori iwa?
◻ Ṣiṣeeṣe wo ni o wa fun ibisi ninu awọn Ẹlẹrii agbekankan ṣiṣẹ?
◻ Eeṣe ti o fi jẹ́ pe isinsinyi ni akoko naa fun itara ati igbegbeesẹ?
◻ Eeṣe ti Jehofa fi yẹ ni wiwa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa tí wọn wá sí Iṣe-iranti jẹ́ awọn iranṣẹ Ọlọrun lọla
Awọn tí wọn wa sí Iṣe-iranti 1990: 9,950,058
Gongo akede 1990: 4,017,213
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ní ọjọ Ọba Asa, orilẹ-ede naa yijusi Jehofa