ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/1 ojú ìwé 16-19
  • Iwakiri Araye fun Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwakiri Araye fun Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Eelo Gbigbeṣẹ Kan
  • Ipilẹ fun Ikẹkọọ Bibeli
  • Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Láti Inú Gbogbo Èdè àti Ẹ̀sìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Èrò Náà Wọnú Àwọn Ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ṣé Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Wa Ń sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Rò Pé Ìsìn Ò Lè Mú Kí Aráyé Wà Níṣọ̀kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/1 ojú ìwé 16-19

Iwakiri Araye fun Ọlọrun

EEṢE ti a fi “èdè mímọ́gaara” fun wa, gẹgẹ bi Ẹlẹrii Jehofa? Dajudaju, kii ṣe lati fi mọ si ọ̀dọ̀ araawa nikan. Kii sii ṣe ki a baa lè gbadun ọna igbesi-aye didẹrun ti o farajọra pẹlu ipa ọna rirọrun oní gbà fun mi kí ngbà fun ọ tí Kristẹndọm ńtọ̀. Kaka bẹẹ, ó jẹ́ nitori ki ‘gbogbo eniyan baa lè maa ke pe orukọ Jehofa, lati lè maa ṣiṣẹsin-in ni ifẹgbẹkẹgbẹ.’ (Sefanaya 3:9, NW) Bẹẹni, èdè mímọ́gaara wemọ igbokegbodo ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu araadọta ọkẹ awọn Kristian arakunrin ati arabinrin wa—lati inú gbogbo ẹya iran, orilẹ-ede, ati ede—tí wọn nfi iṣotitọ ihinrere naa ṣaaju ki opin to de.—Maaku 13:10; Roomu 13:11; Iṣipaya 14:6, 7.

Nigba miiran iwaasu wa lonii maa ngbe awọn ipenija ara ọtọ kalẹ. Eeṣe ti iyẹn fi ri bẹẹ? Ni ọgọrun-un ọdun lọna ogun yii, ìṣíkiri rẹpẹtẹ ninu awọn eniyan gẹgẹ bi iyọrisi awọn ogun, inilara, ikimọlẹ isunna-owo, ati fun awọn idi miiran ti wa. Gẹgẹ bi abajade, awọn eniyan ọpọlọpọ ede ati isin ti ṣilọ sinu aṣa miiran ti o yatọ si tiwọn. Nipa bayii, awujọ titobi ti awọn onisin Hindu, Isin Buddha, ati Musulumi ti ṣi lọ si Iwọ-oorun. Gẹgẹ bi a ti nṣajọpin èdè mímọ́gaara lati ile de ile, awa nba awọn eniyan wọnyi pade. Nigba miiran o maa nru wa loju nitori pe ohun ti a mọ̀ nipa ìpìlẹ̀ isin wọn kere pupọ. Ki ni a le ṣe nipa rẹ̀?—Fiwe Iṣe 2:5-11.

Bawo ni a ṣe le ṣajọpin otitọ pẹlu Musulumi tabi Juu kan? Bawo ni wọn ṣe yatọ sí araawọn? Ki ni onisin Hindu kan gbagbọ niti gidi? Eeṣe tí awọn onisin Sikh fi ńwé láwàní? Ki ni iwe mimọ wọn? Bawo ni onisin Buddha kan ṣe yatọ si onisin Hindu? Ki ni onisin Shinto ara Japan gbagbọ? Njẹ onisin Tao ara China tabi onisin Confucius gbagbọ ninu Ọlọrun bi?a Bawo ni Juu Arinkinkin mọ ilana isin ti a mu ba ode oni mu ṣe yatọ sí Juu Amúlànà isin rọrun tabi Juu Arinkinkin mọ ilana isin atijọ? Ki a baa le de ọdọ awọn eniyan ọ̀kan-kò-jọ̀kan pupọ yii, awa gbọdọ kọkọ loye oju iwoye wọn lẹhin naa ki a si mọ bi a o ṣe dari wọn ni ọna oninuure ati ọlọgbọn ẹ̀wẹ́ sọdọ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa.—Iṣe 17:22, 23; 1 Kọrinti 9:19-23; Kolose 4:6.

Lati ran wa lọwọ lati loye ti o tubọ ṣe kedere sii nipa awọn isin miiran, awọn ẹkọ wọn, ati ìpìlẹ̀ wọn ninu itan, Watch Tower Society mú iwe atẹjade titun kan ti a fun ni akọle naa Mankind’s Search for God jade yika aye ni awọn Apejọpọ “Èdè Mímọ́gaara” ti ọdun 1990. Ni mimura wa silẹ pẹlu ohun eelo yii, awa yoo le waasu fun awọn eniyan ni ilẹ ti kii ṣe ti Kristian ati pẹlu awọn wọnni tí wọn jẹ́ ti Kristẹndọm daradara sii.

Ohun Eelo Gbigbeṣẹ Kan

Iwe oloju-ewe 384 yii ni ori iwe 16 ninu ti o sọ itan iwakiri araye fun Ọlọrun la ẹgbẹrun mẹfa ọdun ti o ti kọja já. O dahun ọgọrọọrun awọn ibeere nipa awọn isin aye. Apẹẹrẹ diẹ ninu wọn niyii: Awọn kókó wo ni o saba maa npinnu isin ẹnikan? Eeṣe ti ko fi ṣaitọna lati yẹ awọn igbagbọ miiran wo? Awọn ifarajọra wo ni wọn wà laaarin isin Katoliki ti Rome ati isin Buddha? Ipa wo ni arosọ atọwọdọwọ ńkó ninu ọpọlọpọ isin? Eeṣe ti ọpọlọpọ eniyan fi ni igbagbọ ninu idan pipa, ibẹmiilo, ati iworawọ? Eeṣe ti awọn onisin Hindu fi ni awọn ọlọrun ati abo-ọlọrun tí wọn pọ̀ tobẹẹ? Eeṣe ti awọn onisin Sikh fi yatọ sí awọn onisin Hindu? Ta ni Buddha jẹ, ki ni o si fi kọni? Eeṣe ti isin Shinto fi jẹ́ isin awọn ara Japan ni pataki? Eeṣe ti awọn Juu fi ni awọn ofin ọlọrọ-ẹnu ati ti alakọsilẹ? Bawo ni a ṣe mọ pe Kristi kii ṣe arosọ atọwọwọdọwọ kan? Bawo ni Kuraani ṣe yatọ si Bibeli? Eeṣe ti awọn Katoliki fi sọ pe Peteru ni Poopu akọkọ? Eeṣe ti alufaa Katoliki naa Luther fi yapa kuro ninu Ṣọọṣi Katoliki ti Roomu?

Awọn ibeere naa fẹrẹ ma lopin, iwe atẹjade yii si ní awọn idahun ninu lẹkun-unrẹrẹ ki a baa lè waasu lọna gbigbeṣẹ sii fun awọn eniyan tí wọn ni ìpìlẹ̀ isin yiyatọsira wọnyi. Iwe naa mọ̀ pe ọpọlọpọ awọn eniyan ní isin tiwọn funraawọn ati pe isin jẹ́ ọran ti ara-ẹni. Sibẹ, ni oju-iwe 8, o wipe: “O fẹrẹ jẹ lati igba ìbí ni a ti gbin awọn ero isin tabi ti iwarere sí wa lọkan lati ọwọ awọn òbí ati ibatan wa. Gẹgẹ bi abajade, awa saba maa ntẹle awọn ero isin awọn òbí wa ati òbí wa àgbà.” Iyẹn tumọsi pe “ninu ọpọlọpọ ọran awọn miiran ti yan isin wa fun wa. O wulẹ ti jẹ́ ọran ibi tí a bí wa sí ati igba tí a bí wa.”—Fiwe Filipi 3:4-6.

Lẹhin naa iwe naa gbe ibeere ti o ba ọgbọn mu dide. “O ha lọgbọn ninu lati lérò pé isin ti a gbekari wa nigba ìbí fi ọranyan jẹ́ gbogbo otitọ naa?” Nipa bayii, olukuluku eniyan ni a fun niṣiiri lati yẹ awọn isin miiran wò pẹlu ero inu ti o ṣisilẹ. Gẹgẹ bi a ti sọ loju-iwe 10: “Liloye oju iwoye ẹnikinni keji lè ṣamọna sí ijumọsọrọpọ ati ifọrọwerọ ti o nitumọ laaarin awọn eniyan onigbagbọ ọtọọtọ.” O nbaa lọ pe: “Loootọ, awọn eniyan lè ṣai fohunṣọkan lọna lilekoko nipa awọn igbagbọ isin wọn, ṣugbọn ko si ipilẹ kankan fun kikoriira ẹnikan kìkì nitori pe oun lọkunrin tabi lobinrin di oju iwoye yiyatọ mú.”—Matiu 5:43, 44.

Ibeere apilẹ ṣekoko kan ti o dide latokedelẹ ninu iwe naa ni, njẹ eniyan ni aileku ọkan ti o la iku rẹ̀ já tí ó sì nbaa lọ ninu iye lẹhin iku bi? Ni iru ọna kan tabi omiran, o fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo isin ni o kọni ni ero igbagbọ yẹn. Gẹgẹ bi Mankind’s Search for God ti wi (oju-iwe 52): “Ninu iwakiri rẹ̀ fun Ọlọrun, eniyan ti gbiyanju lati gba ara rẹ̀ là kuro lọwọ iyọnu ni títọ ọ̀nà ti ko le yọri si rere, oun ni a ti fi ìṣújú igbagbọ aileku ọkan mú ṣina. . . . Igbagbọ ninu aileku ọkan tabi awọn iyatọ diẹdiẹ sii jẹ́ ogún ti o ti wa jẹ́ tiwa la ọ̀pọ̀ ẹgbẹrundun kọja.” Awọn ibeere miiran ni: Njẹ irú ibikan ti a npe ni ọrun apaadi nibi ti a ti nda awọn ọkan loro wa? Ki ni ireti tootọ fun awọn oku? Njẹ Ọlọrun kanṣoṣo ni o wa, tabi ọpọlọpọ awọn ọlọrun ni nbẹ?—Jẹnẹsisi 2:7; Esekiẹli 18:4.

Ipilẹ fun Ikẹkọọ Bibeli

Ni bí wọn ti farahan ninu iran aye ni ọna itotẹlera akoko wọn, iwe naa jiroro bi awọn isin jàǹkànjàǹkàn araye ṣe dide—isin Hindu, Buddha, Tao, Confucius, Shinto, isin awọn Juu, isin Kristian, Kristẹndọm, ati Islam. Ninu ori-iwe kọọkan iwe mimọ awọn isin wọnyi ni a fayọ kí onigbagbọ olotiitọ inu eyikeyii baa le lọ ṣayẹwo awọn ọrọ ti a fayọ naa fúnraarẹ̀. Fun ori-iwe ti o sọ̀rọ̀ lori Islam, itumọ Kuraani lede Gẹẹsi mẹta ọtọọtọ ni a lò. Itumọ ti o ṣẹ̀ṣẹ̀ jade lati ọwọ́ Jewish Publication Society ti Tanakh—A New Translation of the Holy Scriptures ni a fayọ ninu ori-iwe ti o sọrọ lori isin awọn Juu.—Fiwe Iṣe 17:28; Titu 1:12.

Ki ni ó wa nibẹ fun alaigbọlọrungbọ ati onigbagbọ Ọlọrun kò ṣee mọ̀? Ori-iwe 14 dálórí ainigbagbọ ninu Ọlọrun ode-oni ati ìdí ti awọn Ẹlẹrii Jehofa fi gba pe Ọlọrun wa. Ni ori-iwe kọọkan, onkawe ni a dari rẹ̀ sinu Bibeli. Nipa bayii, bi a ti nlo iwe-atẹjade yii Mankind’s Search for God, a mura wa silẹ daradara lati bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn eniyan olukuluku igbagbọ tabi pẹlu awọn wọnni tí wọn ko jẹ́wọ́ igbagbọ kankan rara. O sọrọ lori isin kọọkan tọwọtọwọ ati pẹlu ọgbọn ẹwẹ, ṣugbọn ó gbé awọn ibeere wọnni dide ti o le ṣamọna ẹnikan sí Jehofa ati otitọ. Fun awọn wọnni tí wọn nfi tọkantọkan ṣe iwakiri fun Ọlọrun, iwe yii yoo jẹ́ ibukun gidi kan.—Saamu 83:18; Johanu 8:31, 32; 2 Timoti 3:16, 17.

Awọn apoti ikọnilẹkọọ ti nlaniloye ni a fikun ori-iwe kọọkan. Fun apẹẹrẹ, ni awọn oju-iwe 226 ati 227, apoti kan wà lori “Judaism—A Religion of Many Voices” [“Isin awọn Juu—Isin Ọlọ́pọ̀ Ohùn”] ti o ṣalaye awọn iyapa nlanla ninu igbagbọ awọn Juu. Labẹ “Hinduism—A Search for Liberation,” [“Isin Hindu—Iwakiri Fun Idande,”] apoti kan wa ni oju-iwe 116 ati 117, “Hinduism—Some Gods and Goddesses.” [“Isin Hindu—Awọn Ọlọrun ati Abo-ọlọrun Diẹ.”] Eyi funni ni itolẹsẹẹsẹ kìkì diẹ lara ohun tí o ju 330 million ọlọrun ti awọn onisin Hindu njọsin. Njẹ awọn onisin Buddha nigbagbọ ninu Ọlọrun gẹgẹ bi awọn eniyan ilẹ Iwọ-oorun ṣe loye ede yẹn? Apoti naa “Buddhism and God” [“Isin Buddha ati Ọlọrun”] ni oju-iwe 145 dahun ibeere yẹn. Iwe naa tun ni atọka ti o gbeṣẹ fun itọkasi awọn ẹṣin ọrọ pataki kiakia. Akọsilẹ orisun awọn iwe pataki ti a lo ninu iwadii tun jẹ́ ipilẹ fun ikawe siwaju sii bí ẹnikan ba fẹ́ kulẹkulẹ sii.

Iwe naa ni ohun ti o ju 200 awọn fọto ati aworan alafọwọya, ṣugbọn wọn kò wà nibẹ lasan fun ọ̀sọ́. Awọran kọọkan ní kókó ikọnilẹkọọ kan lati fihan ti o mu isin ti a njiroro ṣe kedere siwaju sii. Fun apẹẹrẹ, ni oju-iwe 238 ọ̀wọ́ awọn fọto ti o ṣapejuwe diẹ lara awọn òwe àkàwé ti Jesu fi kọni wà. Nibomiran, ọ̀wọ́ aworan yiya marun-un ti o ṣapejuwe apa iha ọtọọtọ ti iṣẹ-ojiṣẹ Kristi wà—awọn iṣẹ-iyanu rẹ̀, iyirapada rẹ̀, iku irubọ rẹ̀, ati fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni iṣẹ lati waasu ni gbogbo aye.

Ni oju-iwe 289 itotẹlera awọn fọto wa ti awọn Musulumi yoo nifẹẹ si. O mu ẹni ti nwo o lọ si Mẹka, sinu mọṣalaṣi titobi naa nibi ti Kaaba wà ati lẹhin naa sí ibi okuta dúdú naa gan-an tí awọn Musulumi nbọwọ fun. Ijọsin ọtọọtọ ti isin Buddha ni a ṣapejuwe ni oju-iwe 157. Awọn onisin Hindu yoo nifẹẹ lati rí awọn aworan gbajumọ ọlọrun wọn naa Ganesa ati Krishna ni oju-iwe 96 ati 117.

Awọn ojiṣẹ Kristian tí wọn tootun jakejado aye ni a wadii ọ̀rọ̀ wò lẹnu wọn kí o ba le jẹ pe igbeyẹwo akanṣe ni a ṣe fun isin pataki kọọkan. Fun apẹẹrẹ, ọrọ ẹkọ oniyebiye wá lati Israel fun awọn akori lori isin awọn Juu ati igbagbọ awọn Bahaʼi. Awọn Ẹlẹrii ní awọn orilẹ-ede Musulumi fi tiṣọratiṣọra wadii otitọ awọn ọ̀rọ̀ tí ó wa ninu ori-iwe ti o dálórí Islam. Awọn ọ̀rọ̀ wiwulo ti a ṣayẹwo lati bá otitọ mu wá lati India lori isin Hindu, Sikh ati Jaine. Awọn ojiṣẹ ni ilẹ Gabasi ri i daju pe akori lori Shinto jẹ́ eyi ti o peye, wọn si tun funni ni imọran lori isin Buddha, Tao, ati Confucius.

Nitori fifi ti iwe naa fi tiṣọratiṣọra kari isin kọọkan, awọn wọnni tí wọn ní in ní ede wọn yoo lè bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli ninu akori ti o ṣe wẹku pẹlu ìpìlẹ̀ isin ẹnikọọkan. Lẹhin naa wọn lè fẹ lati tẹsiwaju lọ sinu akori ti o dalori ìdìde isin Kristian ijimiji ati awọn ìdí fun gbigbagbọ pe Kristi jẹ́ Aṣoju tootọ fun Ọlọrun, ẹni naa ti a lo lati fa araye sunmọ Ọlọrun. Awọn akori ti o ṣalaye bi ipẹhinda ṣe waye wà, ti nyọrisi ọpọlọpọ iyapa ati awọn ẹ̀yà isin Kristẹndọm. Akori meji ti ó gbẹhin fi bi a ṣe mu isin tootọ padabọsipo ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi ati ohun ti ọjọ ọla ti ko jinna ni ní ipamọ fun Babiloni Nla, ilẹ ọba isin eke agbaye ti Satani. Lẹhin iyẹn, aye titun ati ireti ajinde ti Bibeli ni a tẹnumọ.—Johanu 5:28, 29; 12:44-46; 14:6; Iṣipaya 21:1-4.

Nitootọ eyi jẹ́ iwe atẹjade kan ti o nilati ran ọpọlọpọ yika aye lọwọ lati sunmọ Ọlọrun timọtimọ, gẹgẹ bi Jakọbu ti sọ ni ori 4 lẹta rẹ̀, ẹsẹ 8 pe: “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun o si sunmọ yin. Ẹ wẹ ọwọ yin mọ, ẹyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkan yin ni mimọ, ẹyin oniyemeji.” Bẹẹni, gẹgẹ bi Aisaya ti wi: “Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW] nigba ti ẹ lè ri i, ẹ pè é, nigba ti ó wa nitosi.”—Aisaya 55:6; Johanu 6:44, 65.

Ẹ jẹ ki gbogbo wa maa baa lọ lati jẹ kí a maa yi wa sí iha titọna, siha ọdọ Oluwa Ọba-alaṣẹ agbaye, Jehofa Ọlọrun. Ati pẹlu àrànṣe itẹjade yii, Mankind’s Search for God, ẹ jẹ ki a ran ẹgbẹẹgbẹrun sii lọwọ lati jọsin Jehofa “ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:23, 24) Njẹ ki a maa foriti i ninu wiwa awọn olùwá otitọ rí ki a si sọ fun wọn nipa Ọlọrun otitọ, nitori, nitootọ, a le rí i!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Taoist” ni pipe rẹ jẹ́ dow-ist; o dun bakan naa pẹlu now.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Eniyan ti wa Ọlọrun kiri ni ọpọlọpọ ọ̀nà

[Àwòrán]

Awọn Katoliki olotiitọ inu yijusi Maria

[Àwòrán]

Awọn Hindu bọwọ fun odò Ganges

[Credit Line]

Harry Burdich, Transglobe Agency, Hamburg

[Àwòrán]

Awọn Juu olufọkansin maa nwọ awọn apo kólóbó ti o ní iwe mimọ ninu

[Credit Line]

GPO, Jerusalem

[Àwòrán]

Awọn ọkunrin Musulumi rinrin ajo lọ sí Mẹka

[Credit Line]

Camerapix

[Àwòrán]

Ọpọlọpọ kunlẹbọ Buddha

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jesu lo owe akawe lati ran awọn eniyan lọwọ lati ri Ọlọrun tootọ

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́