Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
◼ Johanu 18:15 mẹnukan ọmọ-ẹhin kan ti alufaa agba mọ̀. Ṣe ẹni yii ni ọmọ-ẹhin kan naa ti ó salọ “níhòòhò,” ni iṣaaju gẹgẹ bi Maaku 14:51, 52 ti rohin rẹ̀?
Bẹẹkọ, o dabi ẹni pe ẹni ti alufaa agba na mọ̀ ni apọsteli Johanu, nigba ti o jẹ pe ọmọ-ẹhin naa Maaku ni o salọ “níhòòhò.”
Ni mimu awọn irohin iṣẹlẹ wọnyi bi akoko wọn ti tẹlera, a o bẹrẹ ni Ọgba Gẹtisemani. Awọn apọsteli fi ibẹru huwapada nigba ti a fi aṣẹ ọba mu Jesu. “Gbogbo wọn fi í silẹ wọn sì sá lọ.” Ẹsẹ ti o tẹle e gan-an ninu akọsilẹ Maaku mu iyatọ kan jade: “Ọmọkunrin kan si ntọ ọ lẹhin, ti o fi aṣọ ọgbọ bo ìhòòhò rẹ̀; awọn ọmọ-ogun sì gba a mu: o si jọwọ aṣọ ọgbọ naa lọwọ, ó sì sá kuro lọdọ wọn níhòòhò.”—Maaku 14:50-52.
Nipa bayii, idahunpada akọkọ awọn apọsteli mọkanla ni a fi iyatọ rẹ wera pẹlu ọmọ-ẹhin ti a ko darukọ rẹ yii, nitori naa o ba ọgbọn mu lati pari ero pe oun kii ṣe ọkan lara awọn apọsteli. Iṣẹlẹ yii ni a ṣe akọsilẹ rẹ kiki sinu Ihinrere ti a kọ lati ọwọ ọmọ-ẹhin ijimiji naa Johanu Maaku, mọlẹbi Barnaba. Nitori eyi, idi wa lati nilọkan pe Maaku ni “ọmọkunrin kan” ti o bẹrẹ si tẹle Jesu ti a ti fi aṣẹ ọba mu ṣugbọn ti o salọ laisi aṣọ ibora rẹ nigba ti awujọ eniyan keniyan gbiyanju lati gbá a mú.—Iṣe 4:36; 12:12, 25; Kolose 4:10.
Lori koko kan ni alẹ ọjọ yẹn, apọsteli Peteru tun tẹle Jesu, ni iwọn aye ti o laabo. Lọna yii ohun kan ti o farajọra wa; ọ̀dọ́ ọmọ-ẹhin naa (Maaku) bẹrẹ si tẹle Jesu ṣugbọn o duro, nigba ti lẹhin naa awọn apọsteli meji ti wọn ti salọ bẹrẹ si tẹle Ọga wọn ti a ti faṣẹ ọba mu. Ninu Ihinrere apọsteli Johanu, a ka pe: “Simoni Peteru si ntọ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miiran kan: ọmọ-ẹhin naa jẹ ẹni mimọ fun olori alufaa, o si ba Jesu wọ afin olori alufaa lọ.”—Johanu 18:15.
Apọsteli Johanu lo orukọ naa “Johanu” ni titọkasi Johanu Arinibọmi ṣugbọn ko tọka sí araarẹ rara nipa lilo orukọ. Fun apẹẹrẹ, oun kọwe nipa “ọmọ-ẹhin naa, ti o jẹrii nǹkan wọnyi, ti o si kọwe nǹkan wọnyi.” Bakan naa: “Ẹni ti o rí i si jẹrii, otitọ si ni ẹri rẹ̀: o si mọ pe ootọ ni oun wi.” (Johanu 19:35; 21:24) Ṣakiyesi Johanu 13:23 pẹlu: “Njẹ ẹnikan rọ̀gún sí aya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹni ti Jesu fẹran.” Iyẹn jẹ kete ṣaaju igba ti a faṣẹ ọba mú Jesu. Lẹhin naa ni ọjọ yẹn Jesu ti a ti kan mọ́gi naa dá ọmọ-ẹhin kan ya sọtọ, ẹni ti Johanu mẹnuba ni lilo ede isọrọ ti o farajọra: “Nigba ti Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin naa duro, ẹni ti Jesu fẹran, [Jesu] wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wo ọmọ rẹ!”—Johanu 19:26, 27; fiwera pẹlu Johanu 21:7, 20.
Animọ kan naa yii ti ṣiṣai mẹnuba orukọ araarẹ han kedere ni Johanu 18:15. Siwaju sii, Johanu ati Peteru ni a sọrọ kan papọ ninu akọsilẹ ẹhin ajinde ti o wa ni Johanu 20:2-8. Awọn itọkasi wọnyi mú un wá sọkan pe apọsteli Johanu ni “ọmọ-ẹhin naa [ti o] jẹ́ ẹni mímọ̀ fun olori alufaa [“alufaa agba,” NW].” Bibeli ko pese isọfunni ipilẹ kankan nipa bi apọsteli ara Galili naa (Johanu) ti lè mọ̀, tabi bi o ti wa di ẹni mímọ̀ fun, alufaa agba naa. Ṣugbọn bi o ti jẹ ẹni mímọ̀ fun agbo ile alufaa agba naa mú kí o ṣeeṣe fun Johanu lati kọja lọdọ awọn oluṣọna naa wa sinu agbala ati lati mú kí Peteru le wọle pẹlu.