ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/15 ojú ìwé 28
  • Iwọ Ha Ranti Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Ranti Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Jésù Ni Máíkẹ́lì Olú Áńgẹ́lì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì Náà?
    Jí!—2002
  • Ta Ni Máíkẹ́lì, Olú-Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/15 ojú ìwé 28

Iwọ Ha Ranti Bi?

Iwọ ha ti ri awọn itẹjade Ilé-ìṣọ́nà ti aipẹ yii pe o ni iniyelori ti o ṣeemulo bi? Nigba naa eeṣe ti o kò fi dán agbara iranti rẹ̀ wo pẹlu awọn ohun ti o tẹle e wọnyi?

◻ Ki ni awọn otitọ ti o tako bíbọ̀wọ̀ fun ibi ti a rò pe o jẹ ibi ti a bi Jesu si?

Bibeli kò mẹnukan ọgangan ibi ti a bi Jesu si ni pato. Awọn akọsilẹ ihinrere ti Matiu ati Luuku funni ni kiki awọn nǹkan ṣiṣekoko. (Matiu 2:1, 5; Luuku 2:4-7) Kika Johanu 7:40-42 fihan pe awọn eniyan ni gbogbogboo jẹ alaimọkan niti ibi ti a gbe bí i si, awọn kan ronu pe oun ni a bi ni Galili. Bakan naa pẹlu, ni akoko igbesi-aye Jesu fúnraarẹ̀ lori ilẹ-aye, oun kò fi ìgbà kan polongo kulẹkulẹ nipa ìbí rẹ̀.—12/15, oju-iwe 5.

◻ Bawo ni Kristian kan ṣe lè pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ nigba ti o ba ndojukọ awọn idanwo ailera ara, isorikọ, ati iṣoro niti iṣunna owó?

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun funni ni itunu ati itọsọna ti a nilo. Kika iwe saamu tabi fifetisilẹ si kíkà rẹ̀ le pese itura ti a nilo. Dafidi gbà wa nimọran pe: “Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ni yoo sì mú ọ duro.” Oun pẹlu mú un da wa loju pe Jehofa nitootọ jẹ “Olùgbọ́ adura.” (Saamu 55:22; 65:2) Eto ajọ Jehofa, nipasẹ awọn itẹjade rẹ̀ ati awọn alagba ijọ rẹ̀, ṣetan ni gbogbo ìgbà lati ran wa lọwọ lati bori awọn iṣoro wa.—1/1, oju-iwe 14 sí 15.

◻ Ki ni ohun ti Jesu ni lọkan ni oju ọna rẹ̀ si ibi ti wọn ti kàn án mọ́gi, nigba ti oun wipe: “Nitori bi wọn ba nṣe nǹkan wọnyi sara igi tútù, ki ni a o ṣe sara gbigbẹ?” (Luuku 23:31)

Jesu ntọkasi igi orilẹ-ede Juu. Nitori wiwa nibẹ Jesu ati wiwa àṣẹ́kù awọn Juu ti wọn nigbagbọ ninu rẹ̀, orilẹ-ede naa sibẹsibẹ naa ṣì ni ọ̀rinrin iwalaaye diẹ ninu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a ba mu awọn wọnyi jade kuro ninu orilẹ-ede naa, kiki igi kan ti o ti ku nipa tẹmi ni yoo ṣẹ́kù, eto-ajọ orilẹ-ede kan ti o ti gbẹ.—1/15, oju-iwe 9.

◻ Bawo ni “ọlọkan aya mimọgaara,” ti a sọrọ nipa rẹ̀ ninu Matiu 5:8, ṣe le “ri Ọlọrun”?

Wọn “ri Ọlọrun” nigba ti wọn ṣakiyesi rẹ̀ ti o ngbegbeesẹ nititori awọn olupawatitọ mọ. (Fiwe Ẹkisodu 33:20; Joobu 19:26; 42:5.) Bi o ti wu ki o ri, ọ̀rọ̀ Giriiki naa ninu Matiu 5:8 ti a tumọ si “ri” pẹlu tumọsi “lati ri pẹlu ero inu, lati fi ìwòye kiyesi, lati mọ̀.” Niwọnbi Jesu ti fi àkópọ̀ animọ Ọlọrun hàn lọna pipe, ijinlẹ oye nipa àkópọ̀ ìwà yẹn njẹ ki “awọn ọlọkan aya mimọgaara ri Ọlọrun.” (Johanu 14:7-9)—1/15, oju-iwe 16.

◻ Eeṣe ti a fi de ipari ero naa pe Jesu ni Maikẹli olori awọn angẹli?

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nipa kiki olori awọn angẹli kanṣoṣo, o sì sọrọ nipa rẹ̀ ni titọkasi Oluwa Jesu ti a ji dide: “Oluwa tikaraarẹ yoo sọkalẹ lati ọrun wá ti oun ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli [“olú angẹli,” NW], ati pẹlu ìpè Ọlọrun.” (1 Tẹsalonika 4:16) Ni Juuda 9 awa rii pe orukọ olori angẹli yii ni Maikẹli.—2/1, oju-iwe 17.

◻ Ki ni awọn apa mẹrin nibi ti awa ti nilati fi ọla hàn fun awọn eniyan miiran?

Awa nilati bu ọla fun awọn oluṣakoso oṣelu, fun awọn agbanisiṣẹ, si awọn mẹmba agbo idile wa, ati si awọn wọnni ti wọn wà ninu ijọ.—2/1, oju-iwe 20 si 22.

◻ Ni kete ṣaaju iku Jesu, apẹẹrẹ rere wo ni Jesu pese fun awọn wọnni ti wọn ni awọn òbí ọlọ́jọ́lórí?

Nigba ti Jesu ṣì sorọ̀ sibẹsibẹ ninu irora lori òpó igi idaloro naa, oun fi idaniyan hàn fun ire alaafia iya rẹ̀ nipa ti ara ati nipa ti ẹmi nipa gbigbe itọju rẹ̀ le apọsteli Johanu olufẹ ọ̀wọ́n rẹ̀ lọwọ. (Johanu 19:25-27)—2/15, oju-iwe 8.

◻ Eeṣe ti Jesu fi nilati jìyà?

Ijiya Jesu ṣiṣẹ lati yanju ariyanjiyan ti iwatitọ awọn iranṣẹ Ọlọrun. O tun mura rẹ̀ silẹ pẹlu fun iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ Alufaa Àgbà fun araye. (Heberu 4:15)—2/15, oju-iwe 14 si 15.

◻ Ki ni awọn ariyanjiyan pataki ti a gbe dide nipa ìṣọ̀tẹ̀ ni Edeni?

Eniyan ha lè ṣakoso araarẹ̀ pẹlu aṣeyọrisi rere laisi labẹ Ọlọrun bi? O ha tọ́ ni apa ọ̀dọ̀ Ọlọrun lati fi dandangbọn beere ijuwọ silẹ fun ipo ọba alaṣẹ rẹ̀? Lọna ti o tubọ gbooro, eniyan eyikeyii yoo ha fi aimọtara ẹni nikan yàn lati ṣiṣẹsin lati inu ominira ifẹ inu tiwọn funraawọn?—3/1, oju-iwe 6.

◻ Eeṣe ti awọn diẹ lọna aitọ fi nṣalabaapin ninu ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti?

Awọn kan ti wọn kò tii dagbadenu lè ma tii ni imọriri ti o wa deedee nipa awọn ète Ọlọrun. Wọn lè ma tii wa mọ pe fifi ami ororo yàn ẹnikan, “kii ṣe ti ẹni ti o fẹ́, kii sì ṣe ti ẹni ti nsare, bikoṣe ti Ọlọrun ti nṣaanu.” (Roomu 9:16) Kò wa lọwọ ẹni naa lati pinnu pe oun yoo fẹ́ lati di ẹni ti a muwọle sinu majẹmu titun naa ati lati di ajumọjogun pẹlu Kristi. Yiyan ti Jehofa ni ohun ti o ṣe pataki, ẹmi rẹ̀ sì njẹrii si yiyan yẹn. (Roomu 8:16; 1 Kọrinti 12:18)—3/15, oju-iwe 21.

◻ Ki ni “èdè mimọgaara” naa ti a nsọrọ nipa rẹ̀ ninu Ṣefanaya 3:9?

O jẹ oye otitọ ti o tọ̀nà nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀.—4/1, oju-iwe 21 si 22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́