ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/15 ojú ìwé 30
  • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Johanu Keji Tẹnumọ Otitọ
  • Johanu Kẹta Tẹnumọ Ifọwọsowọpọ
  • Bí Gáyọ́sì Ṣe Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jòhánù Kìíní, Jòhánù Kejì, Jòhánù Kẹta àti Ìwé Júúdà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 3 Jòhánù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/15 ojú ìwé 30

Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ

Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Johanu Keji ati Ikẹta

ÌMỌ̀ otitọ jẹ ami idanimọ fun awọn olujọsin Jehofa. (Johanu 8:31, 32; 17:17) Ririn ninu otitọ atọrunwa ṣe koko fun igbala. Awọn iranṣẹ Ọlọrun sì gbọdọ jẹ alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.

Lẹta keji ati ikẹta apọsteli Johanu ti a misi sọrọ nipa “ririn ninu otitọ.” (2 Johanu 4; 3 Johanu 3, 4) Johanu ikẹta pẹlu fun ifọwọsowọpọ ni iṣiri gẹgẹ bi “awọn alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.” (3 Johanu 5-8) O ṣeeṣe ki a kọ awọn lẹta mejeeji ni Efesu tabi nitosi rẹ̀ ni nǹkan bii 98 C.E. Ṣugbọn awọn ohun ti wọn sọ lè ṣanfaani fun awọn eniyan Jehofa lonii.

Johanu Keji Tẹnumọ Otitọ

Johanu keji kọkọ tẹnumọ otitọ ati ifẹ o sì kilọ lodisi “awọn aṣodisi Kristi.” (Ẹsẹ 1-7) Lẹta naa ni a dari si “ayanfẹ obinrin ọlọla” boya eniyan kan. Ṣugbọn bi a ba ti fi ranṣẹ si ijọ, “awọn ọmọ” rẹ̀ jẹ awọn Kristian ti a fi ẹ̀mí bí “ti a yàn” nipasẹ Ọlọrun fun iye ti ọrun. (Roomu 8:16, 17; Filipi 3:12-14) Johanu yọ̀ pe awọn kan bayii “nrin ninu otitọ” ti wọn tipa bayii dena ipẹhinda. Sibẹsibẹ, aini wà fun wọn lati ṣọra lodisi awọn “aṣodisi Kristi,” ti wọn sẹ́ pe Jesu wá ninu ẹran ara. Awọn Ẹlẹrii Jehofa lonii nkọbiara si iru awọn ikilọ bawọnyi lodisi ipẹhinda.

Johanu funni ni imọran tẹle e lori biba awọn apẹhinda lo ó sì pari lẹta rẹ̀ lẹhin naa pẹlu idaniyanfẹ ati awọn ikini ti ara-ẹni. (Ẹsẹ 8-13) Nipa iru awọn làálàá gẹgẹ bi wiwaasu, oun ati awọn miiran ti mu eso ti nyọrisi iyilọkan pada awọn wọnni ti oun fi lẹta rẹ̀ ranṣẹ si jade, kiki nipa ‘kikiyesara’ fun ara wọn nipa tẹmi ni wọn yoo to lè “ri èrè kikun gbà,” ti o ni “adé” ti ọrun ninu lọna hihan gbangba eyi ti a pamọ́ fun awọn ẹni ami-ororo oluṣotitọ. (2 Timoti 4:7, 8) Bi ẹnikẹni ‘ti kò duro ninu ẹkọ Kristi’ ba tọ̀ wọn wá, wọn ‘kò nilati gbà á sinu ile wọn tabi kí i’ ki wọn baa lè yẹra fun jijẹ alajumọ kẹgbẹ pọ ninu “awọn iṣẹ́ buburu” rẹ̀. Lẹhin sisọ ireti naa pe oun yoo wá ki oun sì ba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ wọnni sọrọ pọ ni ojukoju, Johanu pari lẹta rẹ̀ pẹlu awọn ikini.

Johanu Kẹta Tẹnumọ Ifọwọsowọpọ

Johanu Kẹta ni a dari rẹ̀ si Gayọsi o sì kọkọ ṣakiyesi nǹkan ti oun nṣe fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀. (Ẹsẹ 1-8) Gayọsi “nrin ninu otitọ” nipa didirọ mọ́ gbogbo awọn ẹkọ Kristian pata. Oun tun “nṣe iṣẹ igbagbọ” pẹlu ninu ṣiṣetilẹhin fun awọn arakunrin olubẹwo. Johanu kọwe pe: “Awa . . . wa labẹ aigbọdọmaṣe lati gba iru awọn ẹni bẹẹ pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe, ki awa baa le di alajumọ ṣiṣẹ pọ ninu otitọ.” Awọn Ẹlẹrii Jehofa nnawọ ẹmi alejo ṣiṣe ti o farajọ eyi si awọn alaboojuto arinrin ajo lonii.

Lẹhin ṣiṣe ifiwera iwa buburu Diotirefe pẹlu ti Demetiriọsi, Johanu pari lẹta rẹ̀. (Ẹsẹ 9-14) Diotirefe tí nwa ògo kò fi ọ̀wọ̀ eyikeyii hàn fun Johanu ani o tilẹ gbiyanju lati le awọn wọnni ti wọn ngba awọn arakunrin pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe kuro ninu ijọ paapaa. Ṣugbọn, Demetiriọsi kan bayii ni a tọkasi gẹgẹ bi apẹẹrẹ rere. Johanu nireti lati ri Gayọsi laipẹ o sì pari rẹ̀ pẹlu ikini ati idaniyanfẹ pe ki Gayọsi gbadun alaafia.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Pẹlu Tákàdá, Gègé, ati Tàdáwà: Johanu ńfẹ́ lati bẹ “ayanfẹ obinrin naa” ati “awọn ọmọ rẹ̀” wò dipo kikọ awọn ohun pupọ si wọn “pẹlu tákàdá ati tàdáwà.” Dipo bibaa lọ ni kikọwe si Gayọsi “pẹlu tàdáwà ati gègé,” apọsteli naa tun nireti lati rí i laipẹ. (2 Johanu 1, 12; 3 Johanu 1, 13, 14) Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “gègé” (kaʹla·mos) tọkasi ikàn kan tabi esùsú a sì lè tumọ rẹ̀ si “esùsú ikọwe.” Laaarin awọn ara Giriiki ati Roomu, gègé esùsú rí ṣonṣo o sì là tẹẹrẹ gẹgẹ bi awọn kálàmù ìyẹ́ ti awọn akoko igba naa. Ọrọ Giriiki naa meʹlan, ti a tumọ si “tàdáwà,” jẹ ẹ̀yà kòṣakọ-kòṣabo ti ọrọ apọnle naa meʹlas, ti a nlo kìkì fun akọ, ti o tumọsi “dúdú.” Ninu awọn tàdáwà ogbologboo julọ, àwọ̀ rẹ̀ jẹ dúdú bii èédú—yala ẹ̀yà ti màjàlà ti a ri lati inu epo tabi igi ina ti njo, tabi èédú oni kristali lati orisun eweko tabi ẹranko. Gẹgẹ bi o ti saba maa njẹ, tàdáwà ni a ntọju pamọ gẹgẹ bi awọn ọ̀pá gbọọrọ gbigbẹ tabi bi awọn àkàrà, eyi ti akọwe ofin yoo mu ki o tutù ti yoo sì fi igi wẹ́wẹ́ tabi esùsú rẹ̀ lò ó. Tákàdá awọn ọjọ wọnni jẹ ohun eelo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a sọ di awọn abala pẹlẹbẹ lati inu èèpo ti a rí lati ara eweko papirọsi. Awọn Kristian ijimiji lo iru tákàdá bẹẹ fun awọn lẹta, akajọ iwe, ati awọn iwe afọwọkọ alábala.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́