ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/1 ojú ìwé 30-31
  • Ẹ Kaabọ Si Awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Kaabọ Si Awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira”!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Maṣe Tàsé Ète Ominira Tí Ọlọrun Fi Funni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run Tí Ń Fúnni Ní Òmìnira
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Pipejọ Pẹlu Awọn Olùfẹ́ Ominira Ti Ọlọrun Fifunni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/1 ojú ìwé 30-31

Ẹ Kaabọ Si Awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira”!

OMINIRA! Iru ìró ohùn ti o dun gbọ wo ni ọrọ yẹn ni! Ko si ẹni kan ti o gbadun wiwa ninu ide tabi ninu igbekun. Awọn ọdun aipẹ yii ti ri igbesẹ pupọ sii siha ireti fun ominira iṣelu ju awọn ọdun miiran ti o wà ninu akọsilẹ iranti.

Bi o ti wu ki o ri, bi ominira iṣelu ti jẹ ọkan ti o fani lọkan mọra to, ominira kan wa ti o tubọ ṣe pataki ti o si fani lọkan mọra jù. O jẹ ominira ti Jesu Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun, sọrọ nipa rẹ nigba ti o sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ pe: “Bi ẹyin ba duro ninu ọrọ mi, nigba naa ni ẹyin jẹ ọmọlẹhin mi nitootọ. Ẹ o si mọ otitọ, otitọ yoo si sọ yin di ominira.” (Johanu 8:31, 32) Eyi jẹ ominira kuro ninu awọn igbagbọ isin eke, ominira kuro ninu ibẹru eniyan, ominira kuro ninu ẹru si awọn baraku ẹṣẹ, ati pupọpupọ sii.

Ominira yii ni o jẹ́ ẹsin-ọrọ awọn Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira” ti awọn Ẹlẹrii Jehofa jakejado aye yoo ṣe bẹrẹ lati igba-ẹẹrun 1991. Lati ọdun naa 1919, eyi ti a sami si nipa mimu awọn ikalọwọko ijọba kuro lori awọn wọnni ti wọn mu ipo iwaju laaarin wọn, awọn eniyan Ọlọrun ti ngbadun ominira ti npọsii ti o niiṣe pẹlu ijọsin mimọgaara wọn.

O ba a mu rẹgi julọ pe, koko ọrọ ti ominira ni a tẹnumọ ni awọn ọdun ti o ti kọja ni awọn apejọpọ iṣakoso Ọlọrun, nipasẹ iru awọn ẹṣin-ọrọ bii “Apejọpọ Iṣakoso Ọlọrun ti Awọn Orilẹ ede Olominira” ati “Awọn Apejọpọ Agbegbe Awọn Ọmọ Ominira ti Ọlọrun.” Ominira pẹlu ni a jiroro lọna gbigbooro ninu awọn iwe itẹjade iru bii “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira” ati “Iye Ainipẹkun—Ninu Ominira Awọn Ọmọ Ọlọrun.”

Ominira ti Ọlọrun fifunni ti awọn iranṣẹ Jehofa ni kii wulẹ ṣe fun wiwa ni alaafia ati igbadun tiwọn funraawọn nikan. Gẹgẹbi a ti ka a ni Galatia 5:13: “Nitori a ti pe yin si ominira, ara; kiki pe ki ẹ maṣe lo ominira yin fun aye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ maa fi ifẹ sin ọmonikeji yin.” Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olufẹ Ominira” ran wa lọwọ lati mọriri ete ominira wa, o mu ki o ṣeeṣe fun wa lati di ominira wa ti o ṣọwọn mu, ati lati fihan wa bi a ṣe le lo o lọna ti o dara julọ.

Apejọpọ naa yoo bẹrẹ ni owurọ ọjọ Friday ni 9:20 pẹlu itolẹsẹẹsẹ orin ti yoo fiwa sinu ipo ero-inu ti o dara fun ounjẹ tẹmi ti yoo tẹle. Ẹṣin ọrọ ọjọ akọkọ ni “Mimọ Otitọ Naa Ti O nsọ wa Di Ominira,” ti a gbekari Johanu 8:32. Ọsan yoo gbe ọrọ ikini kaabọ alaga jade ati ọrọ asọye pataki, “Ete ati Ilo Ominira Wa Ti Ọlọrun Fifunni.” Asọye yii yoo tẹnumọ koko iyatọ ti o wa laaarin ominira patapata ti Jehofa ati ominira alaala ti Ọlọrun fifun wa. Yoo fun wa niṣiiri pẹlu lati lo ominira ti a ni lọna didara julọ ti o ṣeeṣe. Itolẹsẹẹsẹ ọsan yoo jiroro oriṣiriṣi awọn apa ẹka ominira wa ati iṣẹ isin wa ti a o si pari rẹ pẹlu awokẹkọọ kan, A Da Wọn Silẹ Lominira lati Gbé Ijọsin Tootọ Ga.

Ẹṣin-ọrọ naa fun ọjọ keji jẹ “Diduro Gbọnyingbọnyin ninu Ominira Wa Ti Ọlọrun Fifunni,” ti a gbekari Galatia 5:1. Itolẹsẹẹsẹ owurọ yoo gbe apinsọ ọrọ asoye jade ti o nfihan bi olukuluku mẹmba idile ṣe le gbadun ominira ti Ọlọrun fifunni laaarin agbo idile. Awọn wọnni ti wọn ṣetan lati ṣe iribọmi paapaa julọ yoo mọriri awọn ọrọ akiyesi naa ti o nii ṣe pẹlu bi ọwọ ṣe le tẹ ominira nipasẹ iyasimimọ ati iribọmi. Afikun ninu itolẹsẹẹsẹ ti ọsan yoo jẹ ijiroro kan ti nru ọkan soke lori yala igbeyawo jẹ kọkọrọ naa si ayọ tabi bẹẹkọ. Apinsọ ọrọ asọye yoo wa pẹlu lori oriṣiriṣi awọn apa ẹka ominira lẹhin naa asọye ipari ti a fun lakori naa Olori Aṣoju Ọlọrun fun Pipese Ominira ati Iye Ayeraye.

Ọjọ Sunday ni ẹṣin-ọrọ naa “Lilo Ominira Wa ni Ibamu Pẹlu Ẹmi Ọlọrun,” ti a gbekari 2 Kọrinti 3:17. Itolẹsẹẹsẹ naa yoo gbe apinsọ ọrọ asọye ti o ru ọkan ifẹ soke julọ lori akawe Jesu ti kọ silẹ ni Matiu 13:47-50, ti o nṣipaya bi awọn Ẹlẹrii Jehofa ti nṣiṣẹsin gẹgẹbi awọn apẹja eniyan. Ọrọ asọye fun gbogbo eniyan naa ni ọsan yoo jẹ “Yiyin Aye Titun Olominira Ti Ọlọrun!” Apa ẹka titun kan fun apejọpọ agbegbe ni yoo tẹle e: akopọ ọrọ ẹkọ inu Ilé-ìṣọ́nà fun ti ọsẹ yẹn. Itolẹsẹẹsẹ naa yoo pari pẹlu ọrọ iyanju ti o ba iwe mimọ mu fun gbogbo wa lati maa baa lọ ni titẹsiwaju ninu lilo ominira wa ti Ọlọrun fifunni lọna rere ninu iwa wa ati ninu ijẹrii wa.

Si gbogbo awọn olufẹ ominira, awa sọ ninu awọn ọrọ Dafidi onisaamu naa pe: Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe rere ni Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Saamu 34:8) Ṣe gbogbo ohun ti o ba le ṣe ninu awọn isapa rẹ lati wa si apejọpọ yi. Jẹ ki o jẹ idaniyan rẹ lati wa nibẹ bẹrẹ lati akoko ijokoo ibẹrẹ ni owurọ ọjọ Friday titi di ọrọ-asọye ipari ni ọsan ọjọ Sunday. Bi iwọ ba wá pẹlu ìyánhànhàn onilera tẹmi, ti awọn aini rẹ nipa tẹmi jẹ ọ lọkan lẹkun-unrẹrẹ, iwọ nitootọ yoo jẹ alayọ! (Matiu 5:3) Ẹ ma sì jẹ ki a gbojufo ilana naa dá, “Ẹni ti o ba furugbin ni yanturu pẹlu yoo karugbin ni yanturu.” Eyi pẹlu ṣee fisilo niti bi awa ṣe nfi pẹlu itara murasilẹ ṣaaju lati wá, bi awa ṣe nfarabalẹ fetisilẹ si itolẹsẹẹsẹ naa bi a ṣe ngbe e kalẹ, ati bi awa ṣe nfi pẹlu itara ọkan nawọ gan anfaani eyikeyi ti iṣẹ isin iyọnda ara ẹni ti a ṣi silẹ gbayawu fun wa ni isopọ pẹlu Apejọpọ Agbegbe wa “Awọn Olufẹ Ominira.”—2 Kọrinti 9:6, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́