Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Ni Matiu 10:21, Jesu ha nkilọ fun wa pe ọpọlọpọ awọn arakunrin ninu ijọ yoo yiju pada lodisi awọn arakunrin wọn nipa tẹmi bi?
Bẹẹkọ, iyẹn kii ṣe koko ikilọ Jesu, eyi ti o ka pe: “Arakunrin yoo si fi arakunrin rẹ fun pipa, ati baba yoo si fi ọmọ rẹ fun pipa: awọn ọmọ yoo si dide si awọn obi wọn wọn o si mu ki a pa wọn.”—Matiu 10:21.
Gbolohun ọrọ naa fihan pe Jesu sọ eyi si awọn apọsteli mejila bi o ṣe ran wọn lọ ninu irin ajo iwaasu ni Isirẹli. Ọpọ ninu ohun ti oun sọ ni itumọ ni pataki fun awọn apọsteli naa. Fun apẹẹrẹ, oun sọ pe awọn ni a fun lagbara lati ṣe awọn iwosan oniṣẹ iyanu, lé awọn ẹmi eṣu jade, ati jiji oku dide paapaa. (Matiu 10:1, 8; 11:1) Itan fihan pe kii ṣe gbogbo awọn Kristian ni o gba iru agbara oniṣẹ iyanu bayi, ti o fidii rẹ̀ mulẹ pe Jesu nihin in nba awujọ kan pato sọrọ—awọn apọsteli rẹ.
Sibẹ, diẹ ninu ohun ti Jesu sọ rekọja irin ajo iwaasu awọn apọsteli. Oun sọ fun wọn pe: “Ẹ ṣọra lọdọ awọn eniyan; . . . a o fipa fa yin lọ si iwaju awọn gomina ati awọn ọba nitori temi, fun ẹri si wọn ati awọn orilẹ-ede.” (Matiu 10:17, 18, NW) Ninu irin ajo yẹn, awọn mejila naa ni o ṣeeṣe ki wọn dojukọ iṣatako, ṣugbọn ko si ẹri eyikeyii pe a mu wọn lọ “si iwaju awọn gomina ati awọn ọba” lati fun awọn orilẹ-ede ni ijẹrii.a Ni awọn ọdun ti o tẹle, awọn apọsteli farahan niwaju awọn alakooso, iru bi awọn Ọba Hẹrọdu Agiripa Kin-inni ati keji Sergius Paulus, Galio, koda Olu-Ọba Nero paapaa. (Iṣe 12:1, 2; 13:6, 7; 18:12; 25:8-12, 21; 26:1-3) Nitori naa awọn ọrọ Jesu ni ifisilo diẹ lẹhin naa.
Imọran Jesu nbaa lọ pẹlu ikilọ naa: “Arakunrin yoo si fi arakunrin rẹ fun pipa.” Oun ko tọka si awọn arakunrin nipa tẹmi bi ko ti tọka si awọn baba tabi awọn ọmọ nipa tẹmi pẹlu awọn ọrọ rẹ ti o tẹle e ni ẹsẹ 21: “Baba yoo si fi ọmọ rẹ fun pipa, awọn ọmọ yoo si dide si awọn obi wọn wọn o si mu ki a pa wọn.” Jesu nilọkan pe awọn apọsteli le reti iṣọta tabi atako koda lati ọdọ awọn ibatan.—Matiu 10:35, 36.
Awọn apọsteli naa yoo nilo iforiti ninu irin ajo iwaasu yẹn. Jesu nbaa lọ pe: “Gbogbo eniyan ni yoo si koriira yin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹni ti o ba forítì í titi de opin, ohun naa ni a o gbala.”—Matiu 10:22.
Diẹ ninu awọn ohun ti Jesu sọ ni akoko yẹn ni itumọ fun wa gẹgẹ bi Ẹlẹrii Jehofa lonii. Itẹnumọ iwaasu wa jẹ lori Ijọba naa. Awa nṣe iṣẹ ojiṣẹ wa lọfẹẹ laigbowo ti a si nwa awọn eniyan ti wọn lọkan ifẹ ninu ihin iṣe naa tabi ti wọn tootun fun un. Iṣọra jẹ eyi ti o bojumu. Awọn alatako pọ kaakiri. Ni awọn igba miiran awọn ibatan, aladugbo, tabi awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ ẹni le fa awọn iṣoro lilekenka, paapaa julọ fun awọn oloootọ ọkàn ti wọn ti bẹrẹ sii lepa ipa ọna Kristian tootọ. Jesu kilọ leralera nipa iru iṣatako bayii nigba ti o nṣapejuwe “ami” wíwànihin-in rẹ. (Matiu 24:3, 9, 10; Luuku 21:16, 17) Oun pẹlu tun tẹnumọ aini wa lati ‘forítì í titi de opin ki a ba le gba wa la.’ Bẹẹni, awa nilati foriti titi di opin igbesi-aye wa isinsinyi tabi titi di igba ti eto igbekalẹ awọn nǹkan yii ba dopin ti a o si le wọnu aye titun naa.—Matiu 24:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Awọn itumọ miiran tumọ eyi gẹgẹ bi “awọn Oloriṣa” (The Jerusalem Bible), “awọn Keferi” (New International Version ati awọn ẹda-itumọ lati ọwọ Moffatt ati Lamsa), ati “abọriṣa” (The New English Bible).