ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 6/1 ojú ìwé 8-9
  • Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Parí Iṣẹ́ Rẹ̀, Ó sì Máa Sọ Ayé Di Párádísè
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Nígbà Tí Ìmọ̀ Ọlọrun Yóò Bo Ilẹ̀-Ayé
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 6/1 ojú ìwé 8-9

Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu

Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun

NIGBA ti Ọba Ajagun naa Jesu Kristi ba mu Satani ati aye alaiṣootọ rẹ kuro, iru idi fun idunnu wo ni yoo wa! Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun alalaafia ti Jesu bẹrẹ nígbẹ̀hìngbẹ́hín!

Labẹ idari Jesu ati awọn alajumọ jẹ́ ọba pẹlu rẹ̀, awọn olula Amagẹdọn ja yoo palẹ awọn awoku ti a ti fi silẹ nipasẹ ogun ododo naa mọ́. O ṣeeṣe pe, awọn olulaaja lori ilẹ-aye yoo bi awọn ọmọ fun akoko kan, awọn wọnyi yoo si ṣalabaapin ninu iṣẹ onidunnu ti sisọ ori ilẹ-aye di ọgba itura ẹlẹwa jingbinni kan.

Bi akoko ti nlọ Jesu yoo mu araadọta ọkẹ ti a ko le sọ iye rẹ jade kuro ninu iboji wọn lati gbadun Paradise ẹlẹwa yii. Yoo ṣe eyi ni imuṣẹ ifidaniloju tirẹ funraarẹ pe: “Wakati nbọ ninu eyi ti gbogbo awọn ti o wa ni isa oku yoo . . . jade wa.”

Lara awọn ti Jesu ji dide yoo jẹ oluṣe buburu tẹlẹri ti o ku lẹgbẹẹ rẹ lori opo-igi idaloro. Ranti pe Jesu ṣeleri fun un pe: “Lootọ ni mo wi fun ọ lonii, Iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.” Bẹẹkọ, ọkunrin yẹn ni a ki yoo mu lọ si ọrun lati ṣakoso gẹgẹ bi ọba pẹlu Jesu, bẹẹ ni Jesu ki yoo di eniyan lẹẹkansiki o si maa gbe lori Paradise ilẹ-aye pẹlu rẹ̀. Kaka bẹẹ, Jesu yoo wa pẹlu oluṣe buburu tẹlẹri yii ni itumọ ti pe oun yoo jí i dide si iye ninu Paradise ti yoo si ri si pe awọn aini rẹ̀, nipa ti ara ati tẹmi, ni a bojuto, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe ni oju-iwe yii.

Ronu nipa rẹ ná! Labẹ afiyesi onifẹẹ ti Jesu, gbogbo idile eniyan—awọn olula Amagẹdọn ja, awọn ọmọ wọn, ati ẹgbẹẹgbẹrun araadọta ọkẹ awọn oku ti a ji dide ti o ṣegbọran sii—yoo dagba si ìjẹ́pipe eniyan. Jehofa, nipasẹ Ọmọkunrin rẹ ọba, Jesu Kristi, yoo maa gbe nipa tẹmi pẹlu iran eniyan. Gẹgẹ bi ohùn ti Johanu gbọ lati ọrun wá ti wi pe, “Oun [Ọlọrun] yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ.” Ko si ẹnikan lori ilẹ-aye ti yoo jiya tabi ti yoo ṣaisan.

Nigba ti o ba fi maa di ipari Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu, ipo naa yoo dà gẹgẹ bi Ọlọrun ti pete ni ipilẹṣẹ gan an nigba ti o sọ fun tọkọtaya akọkọ, Adamu ati Efa, lati bi sii ki wọn si kun ilẹ-aye. Bẹẹni, aye ni a o kún pẹlu iran olododo ti awọn eniyan pipe. Eyi jẹ nitori pe anfaani ẹbọ irapada Jesu ni a o ti fisilo fun gbogbo eniyan. Iku nitori ẹṣẹ Adamu ki yoo si mọ!

Nipa bayii, Jesu yoo ti ṣaṣepari gbogbo ohun ti Jehofa beere lọwọ rẹ. Nitori naa, ni opin ẹgbẹrun ọdun naa, oun yoo gbé Ijọba naa ati idile eniyan ti a ti mu de ijẹpipe pada fun Baba rẹ. Ọlọrun nigba naa yoo tu Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ silẹ lati inu ọgbun ti o dabi ipo iku láìleta pútú. Fun ete wo ni?

O dara, ni igba opin ẹgbẹrun ọdun naa, eyi ti o pọ julọ ninu awọn ti wọn wa ninu Paradise yoo jẹ awọn ẹni ti a jí dide ti a ko tii dan igbagbọ wọn wò ri. Ṣaaju kiku, wọn ko tii figba kan ri mọ awọn ete Ọlọrun nitori naa wọn ko le ṣaṣefihan igbagbọ ninu wọn. Nigba naa, lẹhin ti a ti ji wọn dide ti a si ti kọ́ wọn lẹkọọ otitọ Bibeli, o rọrun fun wọn ninu paradise, laisi atako eyikeyi, lati ṣiṣẹsin Ọlọrun. Ṣugbọn bi a ba fun Satani ni anfaani lati gbiyanju lati dá wọn duro ni bibaa lọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun, wọn yoo ha fi araawọn han lati jẹ aduroṣinṣin labẹ idanwo bi? Lati yanju ibeere yii, Satani ni a o tu silẹ.

Iṣipaya ti a fun Johanu fihan pe lẹhin Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu, Satani yoo ṣaṣeyọrisi rere ni yiyi iye awọn eniyan ti a ko mọ iye wọn pada kuro ninu ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun. Ṣugbọn nigba yẹn, ti idanwo ikẹhin naa ba pari, Satani, awọn ẹmi eṣu rẹ, ati gbogbo awọn wọnni ti oun ṣaṣeyọri ni ṣíṣì lọna ni a o parun titi lae. Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn ti a ti danwo ni kikun, awọn olulaaja aduroṣinṣin yoo wà laaye niṣo lati gbadun awọn ibukun Baba wọn ọrun titi ayeraye.

Ni kedere, Jesu ti kó ipa ṣiṣekoko, ti yoo si maa baa lọ lati maa kó ipa ninu ṣiṣaṣepari awọn ete ologo Ọlọrun. Iru ọjọ ọla titobilọla wo ni awa le gbadun gẹgẹ bi iyọrisi gbogbo ohun ti oun ti ṣaṣepari rẹ gẹgẹ bi Ọba nla ọrun ti Ọlọrun! Sibẹsibẹ, awa ko le gbagbe gbogbo ohun ti oun ti ṣe nigba ti o jẹ eniyan.

Jesu fi tifẹtifẹ yọnda lati wa sori ilẹ-aye ó si kọ́ wa lẹkọọ nipa Baba rẹ. Rekọja eyi oun fapẹẹrẹ awọn animọ oniyebiye ti Ọlọrun lelẹ. Ọkan-aya wa ni a sun nigba ti a ba ronu nipa igboya ati aiṣojo rẹ̀ gigalọla, ọgbọn rẹ alailafiwe, itootun gigadabu rẹ gẹgẹ bi olukọ, ipo aṣiwaju alaibẹru rẹ, ìyọ́nú onijẹlẹnkẹ ati igbatẹniro rẹ. Nigba ti a ba ranti bi oun ṣe jiya laiṣeefẹnusọ bi oun ṣe npese irapada naa, nipasẹ ọna kanṣoṣo ti a le gba jere iwalaaye, dajudaju ọkan-aya wa ni a sun pẹlu imọriri fun un!

Nitootọ, Ẹ wo iru ọkunrin naa ti a ti ri ninu ikẹkọọ yii ti igbesi-aye Jesu! Itobilọla rẹ ṣe kedere ó si bonimọlẹ. Awa ni a sun lati ṣe gbohungbohun awọn ọrọ gomina Roomu naa Pọntu Pilatu pe: “Ẹ wòó! Ọkunrin naa!”

Nipa titẹwọgba ipese ẹbọ irapada rẹ, ẹru ẹṣẹ ati iku ti a jogun lati ọdọ Adamu ni a le mu kuro lọdọ wa, ti Jesu si le di “Baba Ayeraye” fun wa. Gbogbo awọn ti yoo jere iye ayeraye gbọdọ gba imọ sinu kii ṣe kiki nipa Ọlọrun ṣugbọn bakan naa nipa Ọmọkunrin rẹ, Jesu Kristi. Ó jẹ ireti wa pe kika ati kikẹkọọ rẹ ninu awọn ọ̀wọ́ ọrọ-ẹkọ yii lori igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu yoo ti ran ọ lọwọ lati gba iru imọ afunni ni iwalaaye bẹẹ sinu! 1 Johanu 2:17; 1:7; Johanu 5:28, 29; 3:16; 17:3; 19:5; Luuku 23:43; Jẹnẹsisi 1:28; 1 Kọrinti 15:24-28; Iṣipaya 20:1-3, 6-10; 21:3, 4; Aisaya 9:6.

◆ Ki ni yoo jẹ anfaani alayọ awọn olula Amagẹdọn ja ati awọn ọmọ wọn?

◆ Awọn wo ni yoo gbadun Paradise ni afikun si awọn olula Amagẹdọn ja ati awọn ọmọ wọn, ni itumọ wo si ni Jesu yoo fi wa pẹlu wọn?

◆ Ki ni yoo jẹ ipo naa ni opin ẹgbẹrun ọdun, ati ki ni Jesu yoo ṣe nigba naa?

◆ Eeṣe ti a o fi tu Satani silẹ kuro ninu ọgbun naa, ki ni yoo si ṣẹlẹ nígbẹ̀hìngbẹ́hín si oun ati gbogbo awọn ti o tẹle e?

◆ Bawo ni Jesu ṣe le di “Baba Ayeraye” fun wa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́