Ẹyin Ọdọ Kristẹni Ẹ Duro Gbọnyin Ninu Igbagbọ
“ẸSẸ olukuluku gbọdọ pé.” Iyẹn ni ifilọ naa. Gbogbo awọn akẹkọọ ni ile-ẹkọ Japan kan nilati wà nibẹ ni apejọ gbogbogboo ninu gbọngan iṣere nla. Ọdọ Kristẹni akẹkọọ kan ko le fọwọsi awọn ero diẹ ti a gbéyọ ninu orin ile-ẹkọ naa. Oun ronu pe, “O dara, mo mọ pe orin ile-ẹkọ naa ni a o kọ. Ṣugbọn emi ki yoo ní iṣoro eyikeyi. Emi yoo wulẹ jokoo lẹhin gẹgẹ bi mo ti maa nṣe.”
Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ọdọ Ẹlẹrii ti Jehofa naa wọnu gbọngan iṣere nla naa, oun ri pe gbogbo awọn olukọ ile-ẹkọ naa ti jokoo ni ila ijooko ẹhin. Fun idi yii, oun nilati jokoo ni iwaju wọn. Nigba ti awọn akẹkọọ yooku dide fun orin ile-ẹkọ naa, oun fi tọwọtọwọ wà ni ijokoo. Ṣugbọn awọn olukọ naa binu si eyi. Wọn gbiyanju lati fipa fà á dide duro. Iwọ ha le ronu araarẹ ninu iru ipo kan bẹẹ bi? Ki ni iwọ iba ti ṣe?
Idi Ti A Fi Nilo Igbagbọ Ti Ó Lagbara
Ìbá dara bi awọn eniyan ba fi awọn Kristẹni silẹ ki wọn si yọnda wọn lati gbé ni ibamu pẹlu ẹri ọkan wọn ti a fi Bibeli kọ́. Bi o ti wu ki o ri, niye igba, awọn Kristẹni nilati dojukọ awọn ipo ti o kun fun idaamu. Eyi ko nilati yà wá lẹnu, nitori Ọmọkunrin Ọlọrun funraarẹ, Jesu Kristi, wi pe: “Bi wọn ba ti ṣe inunibini si mi, wọn o ṣe inunibini si yin pẹlu.” (Johanu 15:20) Yatọ si inunibini taarata, awọn iranṣẹ Jehofa ndojukọ oniruuru awọn adanwo igbagbọ miiran.
Awọn ọdọ Kristẹni niye igba nilo igbagbọ ti o lagbara lati dojukọ awọn adanwo ti wọn nba pade ni ile-ẹkọ. A le fipa mu wọn lati kẹgbẹ pẹlu awọn ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ wọn ti nlo ede aimọ tabi ti wọn ni awọn iṣesi ti ko bọla fun Ọlọrun. Awọn ọdọ Kristẹni ni a le dojukọ pẹlu itẹnumọ ti npọ sii lori ifẹ orilẹ-ede ẹni ati ikimọlẹ lati kowọnu ẹgbẹ, oṣelu ile-ẹkọ, tabi awọn igbokegbodo miiran ti o le panilara nipa tẹmi. Awọn olukọ tabi awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ wọn le gbiyanju lati fi awọn ọdọ Kristẹni sabẹ ikimọlẹ lati juwọ silẹ. Fun idi yii, awọn ọdọ oniwa bi Ọlọrun gbọdọ gbarale ẹmi Jehofa fun igbagbọ ti wọn nilo lati funni ni igbeja ṣiṣe kedere ti ireti wọn.—Matiu 10:19, 20; Galatia 5:22, 23.
‘Ẹ Muratan lati Gbeja’
Imọran apọsteli Peteru ba a mu fun awọn Kristẹni ọdọ ati agba. Oun wipe: “Ẹ muratan nigba gbogbo lati gbeja niwaju olukuluku ti nfi dandangbọn beere lọwọ yin idi fun ireti ti nbẹ ninu yin, ṣugbọn ki ẹ ṣe bẹẹ pẹlu ọkan tutu ati ọ̀wọ̀ jijinlẹ.” (1 Peteru 3:15, NW) Ki ni o nbeere lati muratan lati ṣe iru igbeja kan bẹẹ? Lakọọkọ, iwọ gbọdọ loye ohun ti Iwe mimọ fi kọni. Lati mu iduro gbọnyin ni ile-ẹkọ lori awọn ọran iru bi ifẹ orilẹ-ede ẹni, iṣelu, ilokulo oogun, tabi iwa rere, iwọ gbọdọ kọkọ loye idi fun iduro Kristẹni o si gbọdọ fi ootọ-inu nigbagbọ ninu rẹ.
Fun apẹẹrẹ, apọsteli Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ki a ma tan yi jẹ: ẹgbẹ buburu ba iwa rere jẹ́.” (1 Kọrinti 15:33) Iwọ ha fohunṣọkan pẹlu iyẹn bi? Gẹgẹ bi Pọọlu ti fihan, o rọrun lati di ẹni ti a tanjẹ ninu ọran ẹgbẹ kiko. Ẹnikan le farahan lọna ọrẹ ki o si ṣee faramọ. Ṣugbọn bi oun ko ba ṣajọpin aniyan rẹ fun iṣẹ-isin Jehofa tabi ki o tilẹ gbagbọ ninu awọn ileri Bibeli paapaa, oun jẹ olubakẹgbẹ buburu kan. Eeṣe? Nitori pe igbesi-aye rẹ̀ ni a gbekari awọn ilana yiyatọ, awọn ohun ti o si ṣe pataki gan an fun Kristẹni le ma ṣepataki fun un.
Eyi ko yanilẹnu, nitori Jesu sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ pe: “Wọn kii ṣe ti aye, gẹgẹ bi emi kii ti ṣe ti aye.” (Johanu 17:16) Ko ṣeeṣe fun ẹnikan lati jẹ Kristẹni tootọ ki o si jẹ apakan aye yii nigba kan naa, eyi ti Satani jẹ ọlọrun rẹ. (2 Kọrinti 4:4) Iwọ ha ri bi iru iyasọtọ bẹẹ kuro ninu aye ṣe daabobo Kristẹni kan kuro ninu idibajẹ ati rogbodiyan ti o nyọ ọpọlọpọ lẹnu lonii bi? Bi o ba ri bẹẹ, nigba naa iwọ le loye idi ti iwọ fi gbọdọ pa iyasọtọ rẹ mọ, ani bi eyi ba tilẹ tumọ si pe iwọ ko le darapọ ninu awọn igbokegbodo ile-ẹkọ kan pato paapaa.a
Ijẹpataki diduro gbọnyin ninu igbagbọ ati pipa awọn ire Ijọba mọ lakọọkọ ninu igbesi-aye ni a fihan ninu ọran ọmọbinrin Kristẹni ọdọ kan bayii. (Matiu 6:33) Nigba ti a ṣefilọ aṣedanrawo ayẹyẹ igboyejade rẹ, oun ri pe o bọ si ọjọ kan naa pẹlu ọjọ apejọ ayika ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti oun ti wewee lati lọ. O kọ lẹta onirẹlẹ kan ti nṣalaye idi ti oun ki yoo fi wà nibẹ fun aṣedanrawo naa o si fi fun olukọ rẹ ṣaaju ki akoko ẹkọ ní kilaasi to bẹrẹ. Lẹhin akooko ẹkọ kilaasi naa, olukọ naa pe e si ìdákọ́ńkọ́ o si beere lọwọ rẹ lati ṣalaye lẹẹkan si idi ti oun ki yoo fi wà nibẹ fun aṣedanrawo naa. Ọmọbinrin naa wi pe: “Ó fẹ́ mọ̀ bi awọn ọrọ mi ba baramu. Eyi ha jẹ imọlara mi, tabi lẹta naa wulẹ jẹ kiki awọn ọrọ mama mi? Ni riri idaniloju temi funraami ninu ọran naa, oun ko ta kò mi.”
‘Ẹ Gbeja Niwaju Olukuluku’
Awọn ọdọ Kristẹni niye igba ri i pe bi awọn ba mu ipo wọn ṣe kedere fun awọn olukọ ile-ẹkọ ati awọn akẹkọọ ṣaaju ki ọran kan to dide, ikimọlẹ naa kii fẹrẹẹ pọ tobẹẹ nigba ti wọn ba nilati dojukọ awọn iṣoro. Ọdọ Kristẹni ara Japan kan rohin pe nigba ti oun jẹ ẹni ọdun 11, ile-ẹkọ rẹ beere pe ki gbogbo awọn akẹkọọ wá si àpèjẹ Keresimesi kan. Awọn akẹkọọ ni kilaasi giga fi i sabẹ ikimọlẹ lati kopa, ṣugbọn oun ko wa sibẹ, olukọ rẹ si loye iduro rẹ. Eeṣe? Nitori pe kete ni ibẹrẹ ọdun ile-ẹkọ naa, Ẹlẹrii naa ati awọn obi rẹ ti pade pọ pẹlu olukọ naa wọn si ti ṣalaye oniruuru iha ipo Kristẹni wọn.
Nigba ti wọn ba nlọwọ ninu iṣẹ-isin papa, awọn Kristẹni ọdọ kan maa nbẹru pipade awọn ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ tabi olukọ wọn. Iwọ ha nimọlara ni ọna yẹn bi? Bi o ba ri bẹẹ, eeṣe ti o ko fi lo idanuṣe ki o si jẹ ki awọn ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ rẹ mọ pe iwọ nwaasu lati ile de ile ati idi ti o fi nṣe bẹẹ. Ẹlẹ́rìí Jehofa ẹni ọdun 14 kan rohin pe: “Gbogbo eniyan ni ile-ẹkọ mọ ipo mi gẹgẹ bi Ẹlẹrii kan. Dajudaju, wọn mọ ọn daadaa debi pe bi mo ba pade ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ mi kan nigba ti mo ba nlọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa, emi ko nimọlara itiju. Awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ mi maa nfeti silẹ nigba gbogbo, ati ni ọpọlọpọ igba wọn maa ngba iwe ikẹkọọ Bibeli.” Ẹni ọdun 12 kan rohin pe oun fojusọna si pipade awọn ọmọ kilaasi rẹ nigba ti oun ba nkopa ninu iṣẹ-ojiṣẹ. Dipo jijẹ ẹni ti a dáyà fò nitori ero yii, oun nṣe idanrawo deedee ohun ti oun yoo sọ nigba ti o ba ṣẹlẹ. Nipa bayii, o ti mura silẹ lati funni ni awọn idi ti o yè kooro fun igbagbọ rẹ.
Ni ọpọlọpọ awọn ile-ẹkọ, awọn igbokegbodo ẹhin ile-ẹkọ ni a sọ pe o jẹ ọran yàn-bí-o-bá-fẹ́. Ṣugbọn niti gidi, awọn olukọ ati akẹkọọ maa nfi awọn ẹnikọọkan sabẹ ọpọlọpọ ikimọlẹ lati darapọ ninu iru awọn igbokegbodo bẹẹ. Kristẹni ẹni ọdun 20 kan ṣawari ọna rere kan lati koju ikimọlẹ yii. O wipe: “Mo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi oluranlọwọ aṣaaju ọna la gbogbo akooko ile-ẹkọ giga já. Gbogbo eniyan mọ pe ọwọ mi ti dí ju pẹlu awọn igbokegbodo isin mi lati darapọ ninu awọn nǹkan miiran.” Aburo obinrin Ẹlẹrii yii tẹle ipa ọna kan naa. Awọn Kristẹni ọdọ diẹ lọ taarata lati ori iṣẹ-isin aṣaaju-ọna oluranlọwọ lakooko awọn ọdun ile-ẹkọ sinu igbokegbodo aṣaaju-ọna deedee gẹgẹ bibi olupokiki Ijọba alakooko kikun nigba ti wọn ba ti pari ẹkọ wọn.
Maṣe gbojufo awọn ipa rere ti iwa rere ati ijẹrii onigboya rẹ nko. Dipo wiwa ni idakẹjẹẹ, eeṣe ti o ko fi fihan pe iwọ duro gbọnyin ninu igbagbọ nipa sisọrọ pẹlu ọ̀wọ̀ ṣugbọn tigboyatigboya? Ohun ti ọdọmọbinrin Isirẹli kan ṣe niyẹn ẹni ti a ti mu gẹgẹ bi ẹru ti o si wá wà ninu agbo-ile ọgagun Asiria naa Namaani. (2 Ọba 5:2-4) Orukọ Jehofa ni a yin logo nitori idanuṣe ọdọmọbinrin yẹn. Igbagbọ ti o farajọra ni apa ọdọ rẹ tun le mu ọlá wa fun Ọlọrun o si le ran awọn miiran lọwọ lati mu iduro wọn gẹgẹ bii oluyin orukọ rẹ̀.
Otitọ naa ni pe awa ko le fi igbagbọ wa banidọrẹẹ ki a si jẹ Kristẹni sibẹ. Jesu wipe: “Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju eniyan, oun ni emi yo jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti nbẹ ni ọrun. Ṣugbọn bi ẹnikan ba sẹ́ mi niwaju eniyan, oun naa ni emi yoo sẹ́ pelu niwaju Baba mi ti nbẹ ni ọrun.” (Matiu 10:32, 33) Jijẹ aduro gbọnyin ninu igbagbọ gẹgẹ bi ọmọlẹhin Jesu jẹ ẹru-iṣẹ wiwuwo, abi bẹẹkọ?
Itilẹhin Ti Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Ki o ba le mu iduro gbọnyin gẹgẹ bi ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, iwọ nilo igbagbọ ti o lagbara. Si ete yẹn, iwọ gbọdọ fi taapọntaapọn kẹkọọ Bibeli, lọ si awọn ipade Kristẹni, ki o si lọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ papa. Bi iwọ ba ṣì nimọlara pe ohun kan ṣaito, ki ni iwọ le ṣe? Ọmọ-ẹhin Jakọbu wipe: “Bi o ba ku ọgbọn fun ẹnikan, ki o beere lọwọ Ọlọrun, ẹni tii fi fun gbogbo eniyan ni ọpọlọpọ, ti kii si bani wi; a o si fi fun un.” (Jakọbu 1:5) Ba Jehofa sọrọ ninu adura nipa iṣoro rẹ; oun le fun ọ lokun lati doju kọ awọn adanwo ati idanwo igbagbọ rẹ.
Ki tun ni Kristẹni ọdọ kan le ṣe? Iwe Owe sọ fun wa pe: “Fetisi baba rẹ ti o bí ọ, ma si ṣe gan iya rẹ, nigba ti o ba gbó.” (Owe 23:22) Apọsteli Pọọlu ti imọran yii lẹhin, nitori oun wipe: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn obi yin ni ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa.” (Kolose 3:20) Awọn obi Kristẹni le ran ọ lọwọ lati jẹ aduro gbọnyin ninu igbagbọ. Fetisilẹ si awọn imọran wọn. Pẹlu iranlọwọ wọn, wa inu Iwe mimọ ati awọn itẹjade ti a gbe kari Bibeli, ni wiwa awọn oye, imọran, ati iriri. Iwọ ati awọn obi rẹ yoo gbadun eyi, yoo si ran ọ lọwọ lati ṣẹpa ojo tati ibẹru.—2 Timoti 1:7.
Lo ẹkunrẹrẹ anfaani awọn ipese ti Jehofa Ọlọrun ti ṣe nipasẹ ijọ Kristẹni. Mura silẹ daradara fun awọn ipade. Ba awọn alagba ti a yan sipo ati awọn miiran ti wọn ti la iriri ti o jọra pẹlu awọn wọnni ti iwọ ndojukọ nisinsinyi sọrọ. Solomọni wipe: “Ọlọgbọn yoo gbọ́, yoo si maa pọ sii ni ẹkọ; ati ẹni oye yoo gba igbimọ ọgbọn.” (Owe 1:5) Nitori naa kẹkọọ lara awọn ẹni agba wọnyi. Pẹlupẹlu, iwọ le kẹkọọ lara awọn ọdọ Kristẹni ti wọn nkoju awọn iṣoro bii tirẹ lọna aṣeyọrisi rere.
Iṣotitọ Nmu Awọn Ibukun Wa
Nipa diduro gbọnyin ninu igbagbọ, iwọ yoo maa fi imọran Pọọlu silo lati ‘maa duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki o maa pọ sii ni iṣẹ Oluwa nigba gbogbo, niwọn bi o ti mọ pe iṣẹ rẹ kii ṣe asan ninu Oluwa.’ (1 Kọrinti 15:58) Jehofa mọ̀ o si loye awọn iṣoro ti o dojukọ. O ti fun ọpọlọpọ ti wọn ti doju kọ awọn iṣoro ti o farajọra lokun, 0un yoo si fun ọ lokun. Bi iwọ ba gbarale Ọlọrun, oun yoo ti ọ lẹhin, nitori Onisaamu naa wipe: “Ko ẹru rẹ lọ si ara Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ni yoo si mu ọ duro: Oun ki yoo jẹ ki ẹsẹ olododo ki o yẹ̀ lae.”—Saamu 55:22.
Peteru kọwe pe: “Ẹ di ẹri ọkan rere mu, pe ninu ohun pàtó naa ninu eyi ti wọn nsọrọ lodi si yin ki oju le ti wọn awọn ti nsọrọ iwa rere yin lọna yẹpẹrẹ ni isopọ pẹlu Kristi.” (1 Peteru 3:16, NW) Bi iwọ ba kọ̀ lati juwọ silẹ niti awọn ofin ati ilana ododo Ọlọrun, iwọ yoo ni ẹri-ọkan rere, eyi ti o jẹ ibukun gidi lati ọdọ Jehofa. Ju bẹẹ lọ, iwọ yoo gbe apẹẹrẹ rere kalẹ fun awọn ọdọ Kristẹni ti igbagbọ wọn le jẹ alailagbara. (1 Timoti 4:15, 16) Iwa rẹ le fun wọn niṣiiri lati sapa lati duro gbọnyin ninu igbagbọ ki wọn si tipa bayii le farada awọn adanwo.
Iwọ tilẹ le ran awọn wọnni ti wọn tako iduro Kristẹni rẹ ni ibẹrẹ lọwọ. Ranti awọn ọrọ amuni nì ìrètí wọnyi: “Ni kutukutu fun irugbin rẹ, ati ni aṣalẹ maṣe dá ọwọ rẹ duro: nitori iwọ ko mọ eyi ti yoo ṣe rere, yala eyi tabi eyiini, tabi bi awọn mejeeji yoo dara bakan naa.” (Oniwaasu 11:6) Ta ni o mọ iyọrisi rere ti o le jade lati inu gbingbin eso rere rẹ nipa iṣe ododo rẹ?
Lara awọn ibukun titobi julọ ti iwọ yoo ká ni iduro rere pẹlu Jehofa. Nikẹhin, jijẹ aduro gbọnyin ninu igbagbọ yoo yọrisi iye ayeraye. (Johanu 17:3; fiwe Jakọbu 1:12.) Ko si isinmi ráńpẹ́ kuro ninu adanwo ti a jere nipasẹ ijuwọsilẹ ti o yẹ fun sisọ ẹbun yẹn nù.
Ki ni nipa ọdọ ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ọrọ-ẹkọ yii? O dara, o farada idanwo lile rẹ. Lẹhin ti apejọ ile-ẹkọ naa dopin, oun fi ọgbọn ẹwẹ gbiyanju lati ṣalaye ipo rẹ fun awọn olukọ naa. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọrọ rẹ ko tà, oun ni itẹlọrun ti mimọ pe oun ti mu inu Jehofa dun. (Owe 27:11) O nbaa lọ lati gbeja igbagbọ rẹ titi di igba ti o pari ẹkọ rẹ. Lẹhin naa o di aṣaaju-ọna. Njẹ ki ifarada pẹlu iṣotitọ rẹ ni abajade alayọ ti o jọra. Yoo ri bẹẹ bi o ba fẹri han lati jẹ aduro ṣinṣin ninu igbagbọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun ijiroro iwọnyi ati awọn ilana Bibeli miiran, wo iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work, ti a tẹ̀ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
ÌTÌLẸ́HÌN TÍ Ó WÀ LÁRỌ̀Ọ́WỌ́TÓ
◻ Fetisilẹ si ọgbọn awọn obi rẹ olubẹru-Ọlọrun
◻ Lo anfaani awọn ipese tẹmi ninu ijọ Kristẹni
◻ Ba awọn alagba ti a yàn sipo ati awọn miiran ti wọn ti ni iṣoro bi tirẹ sọrọ
◻ Ba awọn Kristẹni ọdọ miiran ti wọn nkoju awọn idiwọ ti o farajọra pẹlu aṣeyọrisi rere