Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Eeṣe ti Jesu fi da ayẹyẹ Iṣe Iranti silẹ pẹlu awọn apọsteli nikan, ti kii sii ṣe pẹlu awọn ọmọ-ẹhin miiran ti a o mu wọnu majẹmu titun?
Ibeere yii jọ bi eyi ti a gbe kari àṣìrò naa pe Jesu péjọ pẹlu awọn apọsiteli rẹ ni alẹ ọjọ yẹn lati dá Ounjẹ Oluwa silẹ pẹlu ijọ Kristẹni ti awọn ẹni ami ororo ti wọn ti wa ninu majẹmu titun tẹlẹ. Kaka bẹẹ, ni Nisan 14, 33 C.E., ijọ Kristẹni ni a ko tii da silẹ, Jesu si wa papọ pẹlu awọn apọsiteli rẹ fun ounjẹ Irekọja ọdọọdun ti awọn Juu.
Dajudaju, Jesu ni awọn ọmọ-ẹhin miiran yatọ si awọn mejila ti a mọ si apọsiteli. Ni ọdun ti o ṣaaju iku rẹ, o ran awọn ọmọ-ẹhin 70 jade ninu irin ajo iwaasu. Lẹhin ajinde rẹ, “ó fara han awọn ará ti o ju ẹẹdẹgbẹta lọ lẹẹkan naa.” “Nǹkan bi ọgọfa” awọn ọmọ-ẹhin ni wọn si kora jọ ni ọjọ Pẹntikọsi. (1 Kọrinti 15:6; Iṣe 1:15, 16, 23, NW; Luuku 10:1-24) Sugbọn ẹ jẹ ki a ṣagbeyẹwo awujọ ti o wa pẹlu Jesu nigba ti o da ayẹyẹ ọdọọdun ti a mọ si Ounjẹ Alẹ Oluwa silẹ.
Luuku 22:7, 8 funni ni imọ akoko naa ni wiwipe: “Ọjọ iwukara pé, nigba ti wọn ko le ṣe aiṣẹbọ Ajọ-irekọja. O si ran Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ pese Ajọ-irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ.” Akọsilẹ naa nbaa lọ wipe: “Ki ẹ si wi fun baale ile naa pe, Olukọni wi fun ọ pe, nibo ni Gbọngan apejẹ naa gbe wa nibi ti emi yoo gbe jẹ Ajọ-irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi?” Nitori naa ni alẹ ọjọ yẹn Jesu wa pẹlu awọn mejila fun ayẹyẹ Juu kan. O sọ fun wọn pe: “Tinutinu ni emi fẹ fi ba yin jẹ Ajọ-irekọja yii, ki emi ki o to jiya.”—Luuku 22:11, 15.
Lati ibẹrẹ rẹ ni Ijibiti, Irekọja jẹ ayẹyẹ idile kan. Ni dida Irekọja silẹ, Ọlọrun sọ fun Mose pe agbo ile kọọkan nilati pa agutan kan. Bi idile naa ba kere ju lati jẹ odidi agutan kan tan, idile aladuugbo kan ni a le kesi lati ṣajọpin ounjẹ naa. Nipa bayii, o ba ọgbọn mu pe fun Irekọja ti 33 C.E., ọpọjulọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu yoo ti pejọ lọna yiyẹ pẹlu awọn idile tiwọn funraawọn fun ounjẹ yii.
Ṣugbọn Jesu ‘fẹ tinutinu’ lati ṣajọpin ohun ti yoo di Irekọja ikẹhin ti o bofin mu ati alẹ ikẹhin ti yoo ṣaaju iku rẹ, pẹlu awọn ọmọlẹhin rẹ timọtimọ, ti wọn ti rinrin ajo pẹlu rẹ lakooko ti o pọ julọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ rẹ. Lopin Ounjẹ Irekọja yẹn, Jesu sọ fun wọn nipa ayẹyẹ titun kan ti gbogbo awọn ọmọlẹhin rẹ nilati ṣe ni ọjọ iwaju. Waini ayẹyẹ Kristẹni ti o jẹ ti ọjọ iwaju yẹn yoo duro fun ẹjẹ “majẹmu titun” ti yoo rọpo majẹmu Ofin.—Luuku 22:20.
Bi o ti wu ki o ri, majẹmu titun naa ni ko gbeṣẹ ni alẹ Nisan 14, 33 C.E., nitori ẹbọ ti yoo fidi rẹ mulẹ lọna ofin—Jesu—ni a ko tii rú. Majẹmu Ofin ṣì wa ni ẹnu iṣẹ sibẹ. A ko tii kan an léṣòó sara òpó igi. Siwaju sii, ki yoo han gbangba titi di ọjọ Pẹntikọsti pe majẹmu laelae pẹlu Isirẹli ti ara ni a ti rọpo pẹlu majẹmu titun pẹlu Isirẹli tẹmi.—Galatia 6:16; Kolose 2:14.
Fun idi yii, ko si ẹnikẹni yala awọn apọsiteli oluṣotitọ mọkanla naa tabi awọn ọmọ-ẹhin eyikeyi miiran ti o wa ninu majẹmu titun naa ni alẹ yẹn. Jesu ko si fihan pe oun ko fọwọsi eyikeyi ninu awọn ọmọ-ẹhin Juu miiran nipa jijẹ ki wọn pejọ pẹlu idile wọn lati ṣayẹyẹ Irekọja naa.