ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/1 ojú ìwé 4-7
  • Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipilẹ fun Ọjọ Idajọ
  • Ọjọ Idajọ Naa
  • Nigba wo Ni Yoo Jẹ?
  • Awọn Wo Ni A O Dalẹjọ?
  • Idajọ Naa
  • Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan
  • Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Jí!—2010
  • Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/1 ojú ìwé 4-7

Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan!

BI ero ọjọ idajọ ba dáyà fò ọ́, eeṣe ti o ko fi yẹ ohun ti Bibeli sọ nipa rẹ wo? Fun apẹẹrẹ, o ha jẹ otitọ pe nigba ti Ọlọrun ba mu idajọ ṣẹ lori awọn ẹlẹṣẹ, yoo gbé wọn sọ sinu ina ọrun apaadi bi?

O dara, ọran idajọ atọrunwa ti a kọkọ ṣakọsilẹ rẹ̀ jẹ́ ni ibẹrẹ itan eniyan gan an. Adamu ati Efa ní anfaani gbigbe titilae lori paradise ilẹ-aye kan. (Jẹnẹsisi 1:26-28; 2:7-9, 15-25) Bi o ti wu ki o ri, wọn dẹṣẹ, wọn si bọ sabẹ idajọ mimuna Ọlọrun. Ki ni iyọrisi rẹ? Ọlọrun fa ọwọ ẹbun iye sẹhin. Ni ede miiran, wọn kú. Ọlọrun sọ fun wọn pe: “Ni òógùn oju rẹ ni iwọ o maa jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ ni a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.”—Jẹnẹsisi 3:16-19.

Eyi jẹ idajọ mimuna kan, ṣugbọn o ba ododo mu. Ó sì daju pé ko wemọ ina ọrun apaadi. Nigba ti Adamu ati Efa kú, wọn pada di erupẹ. Wọn kò walaaye mọ. Ko si ibi kankan ti Bibeli ti damọran pe apa kan Adamu tabi eniyan eyikeyii miiran la iku já ki a le dá a lóró nibikan titi ayeraye. Kaka bẹẹ, a kà pe: “Nitori alaaye mọ̀ pe awọn yoo ku; ṣugbọn awọn òkú kò mọ ohun kan.”—Oniwaasu 9:5.

Iwọ ha mọ pe Bibeli sọ eyi bi? Iwọ ha tun mọ, pẹlu, pe Bibeli ko lo ede isọrọ naa “aileku ọkan” ri? Kaka bẹẹ, o wipe: “Ọkan ti o ba ṣẹ, oun yoo ku.” (Esekiẹli 18:4) Ni kikun eyi wà ni ibamu pẹlu ilana Bibeli naa pe: “Iku ni èrè ẹṣẹ.” (Roomu 6:23) Ilana yii kan gbogbo wa. Gbogbo wa jẹ àtìrandíran atẹle Adamu Ẹlẹṣẹ, nitori naa gbogbo wa ṣẹ a si gba èrè ẹṣẹ, iku. Gẹgẹ bi Bibeli ti wi: “Ẹṣẹ ti ipa ọdọ eniyan kan wọ aye, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹ ni iku si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.” (Roomu 5:12) Ọjọ Idajọ jẹ apa pataki ti iṣeto Ọlọrun lati gbà wá là kuro ninu ipo yii.

Ipilẹ fun Ọjọ Idajọ

Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, o ti fẹrẹẹ to 2,000 ọdun sẹhin ti Ọlọrun ti fi ipilẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ ni Ọjọ Idajọ lelẹ. Eyi jẹ nigba ti Jesu wa sori ilẹ-aye ti o si fi iwalaaye eniyan pipe rẹ rubọ nititori wa. Jesu funraarẹ ṣalaye pe: “Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.”—Johanu 3:16.

Bi a ba mu igbagbọ lo ninu Jesu, awa yoo janfaani lati inu ẹbọ rẹ ani nisinsinyi paapaa ni ọna tẹmi. Ọlọrun dari awọn ẹṣẹ wa jì o si nyọnda fun wa lati wá sọdọ rẹ. (Johanu 14:6; 1 Johanu 2:1, 2) Ṣugbọn a ṣì jẹ alaipe, ẹlẹṣẹ, ati gẹgẹ bi bẹẹ, a nṣaisan nipa ti ara a sì nku lẹhin-ọ-rẹhin. A ko tii ni iye ainipẹkun ti Jesu ṣeleri sibẹ. Eyi yoo wa gẹgẹ bi abajade Ọjọ Idajọ.

Ọjọ Idajọ Naa

Apọsiteli Johanu ri iran Ọjọ Idajọ, o si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi o ti tẹle e yii: “Mo si ri itẹ funfun nla kan, ati ẹni ti o jokoo lori rẹ, niwaju ẹni ti aye ati ọrun fò lọ; a kò si ri àyè fun wọn mọ. Mo si ri awọn oku, ati ẹni kekere ati ẹni nla, wọn duro ni iwaju itẹ; a sì ṣí awọn iwe silẹ; a sì ṣí awọn iwe miiran kan silẹ tii ṣe iwe iye: a si ṣe idajọ fun awọn oku lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe naa, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.”—Iṣipaya 20:11, 12.

Bẹẹni, gẹgẹ bi iran Johanu ti fihan, Ọjọ Idajọ ni Ọlọrun yoo ṣabojuto funraarẹ. Ṣugbọn o tun wémọ́ ẹlomiran. Apọsiteli Pọọlu ṣalaye pe: “[Ọlọrun] ti dá ọjọ kan, ninu eyi ti yoo ṣe idajọ aye ni ododo, nipasẹ ọkunrin naa ti o ti yan.” (Iṣe 17:31) Ta ni ọkunrin yẹn? Jesu, ẹni ti oun funraarẹ wipe: “Nitori pe Baba kii ṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ.” (Johanu 5:22) Nitori naa Jesu yoo jẹ Onidaajọ ti Ọlọrun yàn ni Ọjọ Idajọ.

Eyi jẹ́ ihinrere fun awọn eniyan. Awọn Ihinrere fi han pe Jesu jẹ ẹnikan ti o ni ìyọ́nú gidigidi. Oun kii ṣe onigbeeraga tabi atánni ní suuru ṣugbọn “oninututu ati onirẹlẹ ọkan.” (Matiu 11:29; 14:14; 20:34) Inu wa dun lati wà lọwọ iru onidaajọ kan bẹẹ.

Nigba wo Ni Yoo Jẹ?

Bi o ti wu ki o ri, nigba wo ni Ọjọ Idajọ yoo jẹ? Iṣipaya wipe yoo jẹ nigba ti “aye ati ọrun ba [ti] fò lọ.” Eyi mu wa ranti awọn ọrọ apọsiteli Peteru pe: “Ṣugbọn awọn ọrun ati aye, ti nbẹ nisinsinyi, nipa ọrọ kan naa ni a ti tojọ bi iṣura fun ina, a pa wọn mọ de ọjọ idajọ ati iparun awọn aláìwà bi Ọlọrun.” (2 Peteru 3:7) Ilẹ-aye gidi ni a o ha fi ina jórun bi? Bẹẹkọ, Bibeli ṣe kedere lori koko yii. Ilẹ-aye gidi ni a ki yoo parun lae. ‘Aye . . . ni a ki yoo ṣí nipo pada laelae.’ (Saamu 104:5) Ayika awọn ọrọ Peteru fihan pe eto igbekalẹ awọn nǹkan aye alaiwa bi Ọlọrun ti isinsinyi ni a o parun. Awọn eniyan alaiwa bi Ọlọrun, kii ṣe planẹti Ilẹ-aye ni yoo parun.—Johanu 12:31; 14:30; 1 Johanu 5:19.

Awọn eniyan alaiwa bi Ọlọrun wọnyi ni a o parun ninu ohun ti Bibeli pe ni ija ogun Amagẹdọn—eyi ti, gẹgẹ bi iwe-irohin yii ti saba maa nfihan, yoo ṣẹlẹ laipẹ. (Iṣipaya 16:14, 16) Lẹhin naa, Satani funraarẹ ni a o fi sinu ọgbun ainisalẹ ti a o si dí lọwọ kuro ninu didasi iran araye fun ẹgbẹrun ọdun kan, ẹgbẹrun ọdun yii si ni gigun akoko Ọjọ Idajọ niti gidi. (Iṣipaya 19:17–20:3) Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn oloootọ nigba ti awọn eniyan alaiwa bi Ọlọrun ba parun ni Amagẹdọn? Wọn yoo làájá gan an sinu Ọjọ Idajọ. A kà pe: “Ẹni iduro ṣinṣin ni yoo jokoo ni ilẹ naa, . . . ṣugbọn awọn eniyan buburu ni a o ké kuro ni ilẹ-aye.”—Owe 2:21, 22.

Ni itilẹhin eyi, Bibeli sọ nipa “ogunlọgọ nla kan, ti eniyan kankan ko le kaye, lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede ati ẹya ati eniyan ati ahọn” ti yoo farahan lori ilẹ-aye ṣaaju Amagẹdọn. Awọn wọnyi “jade lati inu ipọnju nla wá”; ni ede miiran, wọn la opin aye alaiwa bi Ọlọrun yii já gan an gẹgẹ bi Noa ti la opin aye ọjọ rẹ̀ já. (Iṣipaya 7:9-17, New World Translation; 2 Peteru 2:5) Iwọ ha mọ pe ogunlọgọ nla jakejado aye yii ti awọn Kristẹni agbekankan ṣiṣẹ wà ani nisinsinyi paapaa bi? Awọn wọnyi nreti lati la ipọnju nla naa já ki wọn si wà laaye titilae lori ilẹ-aye. Wiwa wọn jẹ ẹri ti o daju ti isunmọle Ọjọ Idajọ.

Awọn Wo Ni A O Dalẹjọ?

Ogunlọgọ nla yii ni a o dalẹjọ ni Ọjọ Idajọ. Ṣugbọn wọn ki yoo danikan wà. Akọsilẹ Johanu nbaa lọ pe: “Okun si jọ awọn oku ti nbẹ ninu rẹ lọwọ; ati iku ati ipo oku [“hell” ninu Bibeli Gẹẹsi ti King James] si jọ oku ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” (Iṣipaya 20:13) Nihin in ni ẹri siwaju sii wà pe awọn eniyan ko jiya titilae ninu ọrun apaadi. Bi hell ba jọwọ awọn oku wọnni ti wọn kú sinu rẹ lọwọ, bawo ni ẹnikan ṣe le wà nibẹ fun gbogbo ayeraye? Niti tootọ, hell ti Bibeli jẹ́ isa oku araye, nibi ti awọn oku wà laimọ ohunkohun ti wọn nduro de ajinde. Ni Ọjọ Idajọ, hell ni a o kó awọn oku ti nbẹ ninu rẹ kuro.—Oniwaasu 9:10.

Awọn wo ni a o jí dide kuro ninu oku ni Ọjọ Idajọ? Apọsiteli Pọọlu wipe: “Ajinde oku nbọ, ati ti oloootọ, ati ti alaiṣootọ.” (Iṣe 24:15) Fun idi yii, awọn iranṣẹ Ọlọrun oluṣotitọ, tii ṣe “olootọ,” ni a o jí dide. Ṣugbọn bẹẹ pẹlu ni aimọye awọn miiran, “alaiṣootọ.” Ni ọna ti o hàn gbangba, ajinde yoo kó gbogbo awọn wọnni ti wọn ti kú ti wọn ṣì wà ninu iboji mọra—yatọ si awọn eniyan eyikeyii ti ẹṣẹ wọn wuwo tobẹẹ debi pe Ọlọrun ti da wọn lẹjọ patapata gẹgẹ bi awọn ẹni ti ko lẹtọọsi iye.—Matiu 12:31.

Idajọ Naa

Bi o ti wu ki o ri, ki ni yoo ṣelẹ si ogunlọgọ nla awọn olulaaja ati awọn wọnni ti a jí dide ni Ọjọ Idajọ? Bibeli wipe: ‘Awọn oku ni a ṣe idajọ wọn lati inu ohun ti a kọ sinu iwe naa, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.’ Eyi jẹ akoko iyẹwo finnifinni. Gbogbo awọn wọnni ti wọn nifẹẹ lati huwa ni ibamu pẹlu ‘awọn nǹkan wọnni ti a kọ sinu iwe naa’—ti o han gbangba pe o jẹ awọn ohun ti Ọlọrun beere fun lọwọ araye ni akoko naa—ni a o kọ silẹ sinu “iwe iye.” (Iṣipaya 20:12) Wọn yoo wa ni oju ọna lati jere iye ainipẹkun!

Nigba naa, nikẹhin, iku irubọ Kristi yoo mu awọn anfaani ti ara wá! Awọn wọnni ti a kọ silẹ ninu iwe iye ni akoko yẹn ni ki yoo fidi rẹmi sinu aisan ati iku mọ. Kaka bẹẹ, a o mu wọn pada bọsipo ni kẹrẹkẹrẹ si ijẹpipe eniyan, pẹlu iye ainipẹkun ti a ṣeleri fun awọn wọnni ti wọn mu igbagbọ lò ninu Jesu. Iru ifojusọna agbayanu wo ni eyi! Bi o ti wu ki o ri, awọn kan yoo kọ̀ lati ṣegbọran lọna ti o han gbangba si ‘awọn nǹkan wọnni ti a kọ sinu iwe naa.’ Ki ni yoo ṣẹlẹ si wọn? Wọn ki yoo jere iye ayeraye. Kaka bẹẹ, iwe mimọ wipe: “Bi a ba ri ẹnikẹni ti a ko kọ orukọ rẹ sinu iwe iye, a sọ ọ sinu adagun ina.”—Iṣipaya 20:15.

Eyi ha ni ọrun apaadi ti Kristẹndọmu nsọrọ nipa rẹ bi? Bẹẹkọ, nitori ni ẹsẹ ti o ṣaaju, a kà pe: “Ati iku ati ipo oku [hell] ni a sì sọ sinu adagun iná.” (Iṣipaya 20:14) Bi a ba gbé hell jù sinu adagun ina, adagun ina naa funra rẹ ko le jẹ ina ọrun apaadi. Siwaju sii, iku kii ṣe ohun kan ti a le rí ti a le gbe nilẹ ki a si jù sibikan. Nitori naa adagun ina gbọdọ jẹ afiṣapẹẹrẹ. Fun ki ni? Bibeli wipe: “Eyi ni iku keji.” Nigba ti a ba gbé iku ati hades [“hell,” KJ] sọ sinu adagun ina, wọn “kú,” wọn dawọ wiwa duro. Lọna ti o farajọra, awọn eniyan ọlọtẹ ti wọn ba araawọn nibẹ ni asẹhinwa asẹhinbọ kú, tabi dawọ wiwa laaye duro. Bi o ti wu ki o ri, eyi ni iku keji, ti ko ni ireti ajinde.

Ọjọ Idajọ—Akoko Ireti Kan

Nitori naa nigba ti a ba ronu nipa Ọjọ Idajọ, ko yẹ ki o daya fo wa tabi ko wa niriira. Ọjọ Idajọ jẹ akoko ireti kan, akoko kan lati mu iye ainipẹkun ti Adamu gbé sọnu pada bọsipo fun araye. Fetisilẹ si awọn ibukun ti yoo mu wa fun awọn wọnni ti a dá lẹjọ gẹgẹ bi oluṣotitọ: “Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, Oun yoo si maa bá wọn gbé, wọn yoo si maa jẹ eniyan rẹ, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Iṣipaya 21:3, 4.

Ni opin ẹgbẹrun ọdun Ọjọ Idajọ, awọn eniyan oluṣotitọ lati gbogbo apa ilẹ-aye yoo di pipe. Wọn yoo ti “walaaye” ni itumọ kikun, Ọjọ Idajọ yoo sì ti mu ète rẹ ṣẹ. (Iṣipaya 20:5) Nigba naa Bibeli wipe, a o yọnda fun Satani lati wọle tọ araye wá fun igba ikẹhin kan. (Iṣipaya 20:3, 7-10) Awọn wọnni ti wọn ba koju ija si i ni akoko ti o kẹhin yii yoo gbadun imuṣẹ kikun ti ileri Bibeli naa pe: “Olododo ni yoo jogun aye, yoo si maa gbe inu rẹ laelae.”—Saamu 37:29.

Iru agbayanu ipese wo ni Ọjọ Idajọ jẹ! Bawo ni o si ti pẹtẹrí tó pe a lè mura silẹ fun un ani nisinsinyi gan an, nipa kikẹkọọ Bibeli, kikọ ifẹ-inu Ọlọrun, ati fifi ifẹ atọrunwa yii silo ninu gbogbo igbesi-aye wa! Abajọ ti onisaamu naa fi sọ ayọ ti o wà ninu rironu nipa idajọ Ọlọrun jade nigba ti o kọwe pe: “Jẹ ki ọrun ki o yọ, jẹ ki inu aye ki o dun; jẹ ki okun ki o maa hó pẹlu ìkún rẹ̀. Jẹ ki oko ki o kun fun ayọ, ati ohun gbogbo ti nbẹ ninu rẹ: nigba naa ni gbogbo igi igbo yoo maa yọ̀, niwaju Oluwa [“Jehofa,” NW]: nitori ti o nbọwa, nitori ti nbọ wa ṣe idajọ aye.”—Saamu 96:11-13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́