Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Wọn Di Ẹni Ti A Mu Ọran Dá Loju Ni Kathmandu
AYAWORAN KAN bẹrẹ iwakiri rẹ̀ fun otitọ ni Brittany, France, ni 1980. O ni ijiroro pẹlu awọn isin Pẹntikosta o sì kẹkọọ nipa awọn isin iha Ila-oorun—laini itẹlọrun. Lẹhin naa o ní ijumọsọrọpọ diẹ pẹlu ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣugbọn ó dawọ duro laipẹ. O ṣalabaapade ayaworan miiran o si bẹrẹ sii ba a ṣiṣẹ o si ńgbé pẹlu rẹ̀.
Ni kété lẹhin eyi ọkunrin ati obinrin alaiṣegbeyawo naa pinnu lati bẹ Nepal wò. A wú wọn lori gidigidi nipa ẹwa ati alaafia ilẹ yẹn ṣugbọn a já wọn kulẹ nipa eto-igbekalẹ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti kò bá idajọ ododo mu loju tiwọn gẹgẹ bi ará Iwọ oorun.
Lẹhin ti wọn pada si France, obinrin naa dá a lábàá fun ẹnikeji rẹ̀ pe ki awọn kẹkọọ Bibeli papọ, ati si iyalẹnu rẹ̀ ó fohunṣọkan. Wọn ranṣẹ si Ẹlẹrii naa ti oun ti bá ní ijiroro ni ọdun meji ṣaaju. Bibeli nikan ni wọn nlo ni ibẹrẹ, ṣugbọn ni asẹhinwa asẹhinbọ wọn fohunṣọkan lati lo iwe naa Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye ati lẹhin naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Laaarin ọdun kan wọn ti dawọ ilokulo oogun duro.
Lẹhin ṣiṣebẹwo si Nepal lẹẹkansii fun oṣu meji, tọkọtaya naa pada si France nibi ti wọn ti nba ikẹkọọ wọn lọ. Wọn dawọ siga mimu ati lilọ si ile ọti ati awọn apejọ alẹ duro wọn si bẹrẹ sii lọ si ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti wọn pari iwe Walaaye Titilae, wọn pinnu lati dawọ kikẹkọọ duro.
Wọn lọ si Nepal lẹẹkansii, wọn sì gbe ninu ile kekere kan ni ẹsẹ̀ awọn Oke Himalaya. Ni ọjọ kan ọkunrin agbalagba kan, ti o wọ ẹwu kootu ati táì, kan ilẹkun wọn. Obinrin naa nikan ni ó wà ninu ile, o sì rò pe o gbọdọ jẹ alagbata iṣẹ ọnà ni o wá lati rí awọn aworan wọn. Si iyalẹnu rẹ̀ o jẹ Ẹlẹrii kan ti o ṣe ikesini ni orukọ ẹni naa ti ó ti kẹkọọ pẹlu wọn ni France. Laipẹ alabaaṣiṣẹpọ rẹ pada si ile, ijiroro oniwakati meji si ṣẹlẹ lẹhin naa.
Ọjọ diẹ lẹhin naa, tọkọtaya naa lọ si ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ni Kathmandu a sì wú wọn lori nipa irisi mimọ tonitoni awọn wọnni ti wọn wà nibẹ. Wọn ṣakiyesi ifẹni ará ati ayọ kan naa ti wọn ti ri ni awọn ipade ni France. Wọn tun ṣakiyesi isopọṣọkan awọn eniyan Nepal ti wọn wá, bi o tilẹ jẹ pe awọn wọnyi ti wá lati inu awujọ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ọtọọtọ. Nisinsinyi a mu un dá wọn lójú pe eyi gbọdọ jẹ eto-ajọ Jehofa.
Oṣu kan lẹhin naa wọn pada lọ si France wọn sì tun bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli ati lilọ si awọn ipade lẹsẹkẹsẹ. Wọn ṣegbeyawo, wọn bẹrẹ sii ṣajọpin ninu iṣẹ jijẹrii, ati nikẹhin wọn gba iribọmi. Ọkọ naa jẹ́ iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ nisinsinyi, aya rẹ si nṣajọpin ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna oluranlọwọ deedee. Loootọ, awọn wọnni ti wọn ní ipo ọkan-aya títọ́ ni ẹmi Jehofa yoo ràn lọwọ lati tẹ̀síwájú ki wọn sì di olujọsin rẹ̀.—Iṣipaya 7:15-17.
[Àpótí/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]
NEPAL
Iye Eniyan Ilu - 17,712,221
Gongo Akede ni 1990 - 63
Ipin, Akede 1 si - 281,146
Ipindọgba Awọn Akede Aṣaaju-ọna - 10
Iye Awọn Ijọ - 1
Ipindọgba Awọn Ikẹkọọ Bibeli - 107
Iye Ti O Wá Si Iṣe-iranti - 220
[Àwòrán ilẹ̀]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
NEPAL
INDIA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ibi ọja ni Kathmandu, Nepal