Bi Ipalarada Kristi Ṣe Nipa Lori Rẹ
Awọn ọkunrin mẹrin ṣẹṣẹ gun ori oke fíofío kan lọ ni. Ni awọn ibi giga wọnni ohun kan ti nyanilẹnu ṣẹlẹ. Bi awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi ti a mu tagiri ṣe nwo, iyipada kan dé ba a niwaju wọn. Fetisilẹ bi onkọwe Ihinrere naa Maaku ṣe rohin iṣẹlẹ arunisoke yii:
“JESU mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọwọ lọ, o si mu wọn wa si oke giga kan ni awọn tikaraawọn nikan. A si pa a larada niwaju wọn, awọn ẹwu awọleke rẹ̀ di kíkọ mọ̀nà, wọn si funfun rekọja ju eyi ti afọṣọ eyikeyii lori ilẹ-aye le mu wọn funfun. Pẹlupẹlu, Elija pẹlu Mose farahan wọn, wọn si nba Jesu sọrọpọ. Lọna idahunpada Peteru wi fun Jesu pe: ‘Rabi, o jẹ rere fun wa lati wa nihin in, nitori naa jẹ ki a gbé agọ mẹta naro, ọ̀kan fun ọ ati ọ̀kan fun Mose ati ọ̀kan fun Elija.’ Niti tootọ, oun ko mọ idahun ti oun nilati fun wọn pada, nitori pe ẹru ti ba wọn gbáà. Awọsanmọ kan si gbarajọ, o ṣiji bo wọn, ohùn kan si jade lati inu awọsanmọ naa: ‘Eyi ni ọmọkunrin mi, aayo-olufẹ, ẹ fetisilẹ si i.’ Bi o ti wu ki o ri, lojiji wọn wo yika wọn ko si ri ẹnikankan pẹlu wọn mọ, afi Jesu nikan.”—Maaku 9:2-8, NW.
Rò ó wò ná! Oju Jesu ntan gẹgẹ bi oorun gan an. (Matiu 17:2) Awọn ẹwu awọleke rẹ̀ ńkọ mọ̀nà, “funfun rekọja ju eyi ti afọṣọ eyikeyii lori ilẹ-aye le mu wọn funfun.” Didun ohùn alagbara ti Ọlọrun funraarẹ ńwá eyi ti nṣe ipolongo nipa Ọmọkunrin rẹ̀. Iṣẹlẹ agbayanu wo ni eyi jẹ!
Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ nihin in si “pa larada” tumọsi “lati yipada si irú miiran.” O si tun farahan ni Roomu 12:2, nibi ti a ti gba awọn Kristẹni nimọran lati “yipada” nipa yiyi ero inu wọn pada.—An Expository Dictionary of New Testament Words, by W. E. Vine, Idipọ Kẹrin, oju-iwe 148.
Bẹẹni, iṣẹlẹ amunijigiri ṣẹlẹ nigba ti a pa Jesu larada nigba kan lẹhin ayẹyẹ Irekọja ti 32 C.E. Ki ni o ṣamọna si iṣẹ iyanu yii? O ha ni ete akanṣe bi? Eeṣe ti o fi wémọ́ Mose ati Elija? Bawo si ni ipalarada Kristi ṣe nipa lori rẹ?
Awọn Iṣẹlẹ Ti Wọn Ṣaaju
Ṣaaju ki Jesu to goke lọ sori oke naa, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wà ni ayika Kesaria Filipi. Niwọn bi ilu yii ti jẹ nǹkan bii ibusọ 15 siha ariwa iwọ oorun Oke Amoni, ipalarada naa ti le ṣẹlẹ lori ọkan lara awọn gongo giga fíofío rẹ̀.
Nigba tí o nrin lọ sori “oke giga” naa Jesu bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leere pe: “Ta ni awọn eniyan wi pe mo jẹ?” Wọn fesipada pe: “Johanu Oniribọmi, ati awọn miiran, Elija, sibẹsibẹ awọn miiran, Ọkan ninu awọn wolii.” Lẹhin naa Jesu beere pe: “Ṣugbọn, ẹyin, ta ni ẹyin wi pe mo jẹ?” Peteru fesipada pe: “Iwọ ni Kristi.” Nipa bẹẹ, Jesu “paṣẹ fun wọn laiyẹhun pe ki wọn maṣe sọ nipa oun fun ẹnikẹni. Pẹlupẹlu, o bẹrẹ sii kọ́ wọn lẹkọọ pe ọmọkunrin eniyan gbọdọ faragba ọpọ ijiya ki a si ṣa a tì lati ọwọ awọn alagba ọkunrin ati awọn olori alufaa ati awọn akọwe ki a si pa a, ki o si dide ni ọjọ mẹta lẹhin naa.”—Maaku 8:27-31, NW.
Jesu nbaa lọ lati ṣe ileri yii pe: “Awọn kan wa lara awọn wọnni ti wọn duro nihin in ti ki yoo tọ́ iku wo rara titi wọn yoo kọkọ fi ri ijọba Ọlọrun ti o ti de ninu agbara.” (Maaku 9:1, NW; Matiu 16:28) Ileri yii ni a mu ṣẹ ni “ọjọ mẹfa lẹhin naa,” nigba ti Jesu ngbadura ti a si pa a larada niwaju Peteru, Jakọbu, ati Johanu. Luuku wi pe eyi ṣẹlẹ ni “ọjọ mẹjọ” lẹhin naa, o dabi ẹni pe oun fi ọjọ ileri yẹn ati ọjọ imuṣẹ rẹ̀ kun un.—Matiu 17:1, 2; Maaku 9:2; Luuku 9:28.
Kii Ṣe Àlá Tabi Aijootọ
Ipalarada Jesu kii ṣe àlá kan. Awọn apọsiteli mẹta kì bá tí lá àlá kan naa, Jesu si pe e ni “iran.” Iyẹn ko tumọsi aijootọ, nitori ọrọ Giriiki ti a lo ni Matiu 17:9 ni a tumọsi “iran” nibomiran. (Iṣe 7:31) Nitori naa awọn oluṣakiyesi naa jí kalẹ rekete, ati pẹlu oju ati eti wọn, wọ́n ri wọ́n si gbọ ohun ti nṣẹlẹ niti gidi.—Luuku 9:32.
Peteru ti o jí kalẹ ṣugbọn ti ko mọ ohun ti yoo sọ, damọran gbigbe agọ mẹta naro—ọkọọkan fun Jesu, Mose, ati Elija. (Luuku 9:33) O han gbangba pe awọsanmọ ti o gbarajọ gẹgẹ bi Peteru ti nsọrọ fi wiwa ti Ọlọrun wà lori oke naa han gẹgẹ bi o ti ri ni agọ ajọ ninu aginju. (Ẹkisodu 40:34-38; Luuku 9:34) O si daju pe awọn apọsiteli naa ko si loju oorun nigba ti “Ọlọrun, Baba” polongo pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, ẹni naa ti a ti yan. Ẹ fetisilẹ sii.”—2 Peteru 1:17, 18; Luuku 9:35, NW.
Idi Ti A Fi Ri Mose
Nigba ti ipalarada naa ṣẹlẹ, Mose “ko mọ ohun kan,” nitori pe oun ti ku ni ọpọlọpọ ọrundun ṣaaju. (Oniwaasu 9:5, 10) Bii Dafidi, oun ni a ko tii ji dide ati nitori naa ko wa nibẹ tikaraarẹ. (Iṣe 2:29-31) Ṣugbọn eeṣe ti a fi rí Mose pẹlu Kristi ninu iran yii?
Ọlọrun ti sọ fun Mose pe: “Emi yoo gbe wolii kan dide fun wọn laaarin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi yoo si fi ọrọ mi si i ni ẹnu, oun yoo si sọ fun wọn gbogbo eyi ti mo palaṣẹ.” (Deutaronomi 18:18) Ni pato Peteru lo asọtẹlẹ yii fun Jesu Kristi. (Iṣe 3:20-23) Yatọ si Jesu, Mose ni wolii titobi julọ ti Ọlọrun ran si orilẹ-ede Isirẹli.
Ijọra wa laaarin Mose ati Jesu Kristi, Mose Titobiju naa. Fun apẹẹrẹ, nigba ti wọn jẹ ọmọ ọwọ, iwalaaye awọn mejeeji ni a fi sinu ewu lati ọwọ awọn oluṣakoso onroro, ṣugbọn Ọlọrun ri sii pe awọn ọmọ ọwọ naa ni a dásí (Ẹkisodu 1:20–2:10; Matiu 2:7-23) Awọn ọkunrin mejeeji lo 40 ọjọ ni gbigbaawẹ ni ibẹrẹ iṣẹ igbesi-aye wọn gẹgẹ bi iranṣẹ akanṣe fun Jehofa. (Ẹkisodu 24:18; 34:28; Deutaronomi 9:18, 25; Matiu 4:1, 2) Awọn mejeeji, Mose ati Jesu sì tun ṣe iṣẹ iyanu nipasẹ agbara Ọlọrun.—Ẹkisodu 14:21-31; 16:11-36; Saamu 78:12-54; Maaku 4:41; Luuku 7:18-23; Johanu 14:11.
Ọlọrun lo Mose lati da Isirẹli nide kuro ni Ijibiti, ani gẹgẹ bi Jesu ṣe mu idasilẹ tẹmi wá. (Ẹkisodu 12:37-14:31; Johanu 8:31, 32) Mose lanfaani lati ṣalarina majẹmu Ofin laaarin Ọlọrun ati awọn ọmọ Isirẹli, nigba ti Jesu jẹ Alarina majẹmu titun. (Ẹkisodu 19:3-9; 34:3-7; Jeremaya 31:31-34; Luuku 22:20; Heberu 8:3-6; 9:15) Jehofa ti lo Mose lati ṣe orukọ kan fun Araarẹ niwaju awọn ọmọ Isirẹli, awọn Ijibiti, ati awọn miiran gan an gẹgẹ bi Jesu Kristi ti gbe orukọ mimọ Jehofa ga. (Ẹkisodu 9:13-17; 1 Samuẹli 6:6; Johanu 12:28-30; 17:5, 6, 25, 26) Nipa jijẹ ki Mose farahan pẹlu Jesu ti a palarada, Ọlọrun fihan pe Kristi yoo ṣiṣẹsin ninu ipo wọnyi ni iwọn titobi nla gan an.
Idi Ti Elija Fi Farahan
Bi o tilẹ jẹ pe wolii Elija ti o ti ku ni a ko tii ji dide, o ba a mu pe oun nilati farahan ninu iran ipalarada naa. Elija ṣe iṣẹ titobi ni mimu ijọsin tootọ padabọsipo ati dida orukọ Jehofa lare laaarin awọn ọmọ Isirẹli. Jesu Kristi ṣe ohun kan naa nigba ti o wà lori ilẹ-aye yoo si ṣe ju bẹẹ lọ lati mu isin mimọ gaara padabọsipo ati lati da orukọ Baba rẹ̀ ti ọrun lare nipasẹ Ijọba ti Mesaya naa.
Wolii Malaki fihan pe iṣẹ Elija jẹ ojiji fun igbokegbodo ọjọ ọla. Nipasẹ Malaki, Ọlọrun wi pe: “Wo o, emi yoo ran wolii Elija si yin, ki ọjọ ńláǹlà Oluwa [“Jehofa,” NW], ati ọjọ ti o ni ẹru to de. Yoo si pa ọkan awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkan awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o ma baa wa fi aye gegun un.”—Malaki 4:5, 6.
Asọtẹlẹ yii ni imuṣẹ kekere ninu iṣẹ Johanu Oniribọmi. Jesu tọka si eyi lẹhin ipalarada naa, nigba ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ beere idi ti awọn akọwe fi wi pe Elija nilati kọkọ wá—ṣaaju ifarahan Mesaya naa. Jesu wi pe: “Lootọ ni, Elija yoo tete kọ́ dé, yoo si mu nǹkan gbogbo padasipo. Ṣugbọn mo wi fun yin pe, Elija ti de ná, wọn ko si mọ ọn, ṣugbọn wọn ti ṣe ohunkohun ti o wu wọn si i. Gẹgẹ bẹẹ naa pẹlu ni ọmọ eniyan yoo jiya pupọ lọdọ wọn.” Akọsilẹ naa fikun un pe: “Nigba naa ni o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisi ni ẹni ti o nsọrọ rẹ̀ fun wọn.—Matiu 17:10-13.
Johanu ṣe iṣẹ bi ti Elija nigba ti o baptisi awọn Juu ti wọn ronupiwada awọn ẹṣẹ wọn si majẹmu Ofin naa. Ni pataki ju, Johanu jẹ ẹni ti a ran ṣaaju Mesaya o si fi Jesu Kristi han. (Matiu 11:11-15; Luuku 1:11-17; Johanu 1:29) Ṣugbọn eeṣe ti iṣẹ Johanu fi jẹ kiki imuṣẹ kekere ti asọtẹlẹ Malaki?
Ninu iran yii, Elija ni a ri ti nsọrọ pẹlu Jesu. Eyi jẹ lẹhin iku Johanu Baptisi, ti ntipa bayii tọka sii pe iṣẹ Elija ni a o ṣe ni ọjọ iwaju. Ju bẹẹ lọ, asọtẹlẹ naa fihan pe iṣẹ yii ni a o ṣe ṣaaju “ọjọ ńláǹlà Oluwa [“Jehofa,” NW], ati ọjọ ti o ni ẹ̀rù.” Iṣẹlẹ ti nsunmọle lọna yiyara kankan yẹn ní “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ní Har–Magẹdọni, tabi Amagẹdọni nínú. (Iṣipaya 16:14-16) Iyẹn tumọ si pe ifidimulẹ Ijọba Ọlọrun ti ọrun ni ọjọ iwaju ni iṣẹ kan ti o ṣe rẹgi pẹlu awọn igbokegbodo Elija ati olugbapo rẹ̀, Eliṣa, yoo ṣaaju. Ni ohun ti o sì ti ju ọrundun kan, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ode oni ti nṣe iṣẹ kan ti o wémọ́ imupadabọsipo ijọsin mimọgaara ati gbigbe orukọ Ọlọrun ga.—Saamu 145:9-13; Matiu 24:14.
Ete Rẹ̀
Ipalarada naa ti gbọdọ fokun fun Jesu fun awọn ijiya ati iku ti ó kù diẹ ki oun farada. Gbigbọ ti ó gbọ tí Baba rẹ̀ ọrun sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi Ọmọkunrin Rẹ̀ ti o tẹwọgba gbọdọ ti fun igbagbọ Jesu lokun. Ṣugbọn ki ni ipalarada naa ṣe fun awọn yooku?
Ipalarada Jesu tun fun igbagbọ awọn onworan lokun. O tẹ ẹ mọ wọn lọkan pe Jesu Kristi ni ọmọkunrin Ọlọrun. Nitootọ, niwọn igba ti Olori Agbọrọsọ ti Jehofa, Ọrọ naa, ṣì wa laaarin wọn nigba naa, wọn gbọ ohùn Ọlọrun funraarẹ ti o polongo pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, aayo-olufẹ, ẹni ti mo ti tẹwọgba.” Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa ti ṣe ijẹrii ti o farajọ eyi nigba ti a baptisi Jesu, lakooko ipalarada naa Ọlọrun fi kun un pe awọn ọmọ-ẹhin naa nilati fetisi Ọmọkunrin Rẹ̀.—Matiu 3:13-17, NW; 17:5; Johanu 1:1-3, 14.
Ipalarada naa fun igbagbọ lokun ni ọna miiran. Lakooko iran naa, Jesu, “Mose,” ati “Elija” sọrọ nipa “ijadelọ naa ti a yàn pe ki [Kristi] muṣẹ ni Jerusalẹmu.” (Luuku 9:31, NW) “Ijadelọ” ni a tumọ lati inu iru ọrọ Giriiki naa eʹxo·dos. Igberalọ yii, tabi ijadelọ, ni kedere wémọ́ iku Jesu ati ajinde rẹ̀ nipasẹ Ọlọrun si iwalaaye tẹmi. (1 Peteru 3:18) Nitori naa ipalarada naa fun igbagbọ ninu ajinde Kristi lokun. Ni pataki ni o gbe igbagbọ ró nipa pipese ẹri didaniloju pe Jesu yoo jẹ Ọba Ijọba ti Mesaya Ọlọrun. Ju bẹẹ lọ, iran naa fihan pe Ijọba naa yoo jẹ́ ologo.
Ifarahan naa tun fun igbagbọ asọtẹlẹ inu Iwe mimọ lokun. Ni ohun ti o to ọdun 32 lẹhin naa (ni nǹkan bi 64 C.E.), Peteru ṣì ranti iriri yii o si kọwe pe: “Bẹẹkọ, kii ṣe nipa títẹ̀lé awọn itan ti a fi ọgbọn ayinike humọ lẹ́hìn ni awa fi mu yin mọ agbara ati wiwa nihin in Jesu Kristi Oluwa wa, ṣugbọn o jẹ nipa didi ti awa di ẹlẹrii olufojuri itobilọla rẹ. Nitori o ti gba ọla ati ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigba ti a jẹrii ọrọ bi iru iwọnyi si i nipa ogo titobilọla naa pe: ‘Eyi ni ọmọkunrin mi, aayo-olufẹ mi, ẹni ti emi tikaraami ti tẹwọgba.’ Bẹẹni, ọrọ wọnyi ni awa gbọ ti a njẹrii lati ọrun wa nigba ti awa wà pẹlu rẹ ni ori oke mimọ naa. Nitori naa a mu ki ọrọ asọtẹlẹ naa tubọ daniloju; ẹyin sii nṣe daradara ni fifiye sii gẹgẹ bii si fitila ti ntan ni ibi ṣiṣokunkun kan, titi ojumọ fi mọ ti irawọ ọsan si yọ ninu ọkan-aya yin.”—2 Peteru 1:16-19, NW.
Itumọ Rẹ̀ Fun Ọ
Bẹẹni, Peteru ri ipalarada Jesu gẹgẹ bi imudaniloju alagbara ti ọrọ alasọtẹlẹ Ọlọrun. Apọsiteli Johanu tun ti le sọrọ kan iran yii nigba ti o wi pe: “Ọrọ naa si di ara, oun si nba wa gbe, (awa si nwo ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bibi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wa,) ó kun fun oore-ọfẹ ati otitọ.” (Johanu 1:14) Lọna ti o farajọra, ipalarada naa le gbe igbagbọ ró ninu ọrọ alasọtẹlẹ ti Jehofa.
Ipalarada ati awọn iṣẹlẹ ti o so pọ mọ ọn le fun igbagbọ rẹ lokun pe Jesu Kristi ni Ọmọkunrin Ọlọrun ati Mesaya ti a ṣeleri naa. O le tubọ fun igbagbọ rẹ ninu ajinde Jesu si iwalaaye tẹmi ninu ọrun lokun. Iran ayanilẹnu yii nilati tun mu igbagbọ rẹ pọ sii ninu ijọba Ọlọrun, nitori ipalarada naa jẹ iritẹlẹ ogo Kristi ati agbara Ijọba.
Ni pataki o jẹ afungbagbọ lokun lati mọ pe ipalarada Kristi tọka si ọjọ wa, nigba ti wiwa nihin in Jesu jẹ otitọ gidi. (Matiu 24:3-14) Lati 1914 oun ti nṣakoso gẹgẹ bi Ọba Ọlọrun ti a yan sipo ninu awọn ọrun. Aṣẹ ati agbara ti Ọlọrun fi fun un ni yoo mulo laipẹ lodisi gbogbo awọn ọta iṣakoso atọrunwa, ni ṣiṣi ọna silẹ fun aye titun kan. (2 Peteru 3:13) Iwọ le gbadun awọn ibukun ailopin rẹ̀ bi iwọ ba lo igbagbọ ninu awọn ohun agbayanu ti a fihan ninu ipalarada Jesu Kristi.