ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/15 ojú ìwé 28-30
  • Awọn Apejuwe—Kọkọrọ kan Si Dídé Inu Ọkan-aya

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Apejuwe—Kọkọrọ kan Si Dídé Inu Ọkan-aya
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Apejuwe Ti Nkọni Lẹkọọ
  • Riri Awọn Apejuwe
  • Mimu Bibeli Jẹ Gidi
  • “Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
  • “Kì í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Máa Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/15 ojú ìwé 28-30

Awọn Apejuwe—Kọkọrọ kan Si Dídé Inu Ọkan-aya

DAFIDI ti nsa kiri fun ẹmi rẹ̀. Ọta rẹ̀ ni Sọọlu, ọba Isirẹli ti a fororo yan. Bi o ti wu ki o ri, Sọọlu jẹ ọkunrin ti o koriira Dafidi gidigidi, oun ni owú ti jẹrun. Ninu iwakiri apaniyan rẹ̀, ọba naa ti mu 3,000 awọn ọmọ ogun dani. Bi wọn ko ti tó nnkankan lẹgbẹẹ ọmọ ogun tọ̀hún, Dafidi ati awọn eniyan rẹ̀ ti sapamọ sinu iho kan ninu aginju.

Gẹgẹ bi Dafidi ati awọn eniyan rẹ̀ ti ṣurujọ sinu okunkun naa, ipo naa yipada si iṣẹlẹ ayanilẹnu kan. Ọba Sọọlu kó wọnu iho yii gan an lati tura. Dafidi yọ́ dide pẹlu ohun ija ni ọwọ rẹ̀, o lọ sọdọ olódì rẹ̀ ti ko lee gbeja araarẹ. Ṣugbọn si iyalẹnu awọn eniyan Dafidi, oun ko pa ọba naa. Oun wulẹ ké eti aṣọ awọleke Sọọlu ni. Ni kikabaamọ eyi paapaa, Dafidi wi pe: “Èèwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá bi emi ba ṣe nǹkan yii si oluwa mi, ẹni ti a ti fi ami ororo Oluwa [“Jehofa,” NW] yan, lati na ọwọ mi si i, nitori pe ẹni ami ororo Oluwa [“Jehofa,” NW] ni.”—1 Samuẹli 24:1-6.

Akọsilẹ Bibeli yii kọ́ni ni ẹkọ jijinlẹ kan nipa ọ̀wọ̀ fun aṣẹ lati ọdọ Ọlọrun. O tun wọnu ọkan-aya, boya lọna ti o gbeṣẹ sii ju imọran ti o ṣe taarata lọ. Iru bẹẹ ni agbara awọn isẹlẹ ti a ṣakọsilẹ ninu Ọrọ Ọlọrun fun itọni wa.—Roomu 15:4.

Lọna tí o ba a mu, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sapa lati ṣe ju sisọ otitọ nigba tí wọn bá nwaasu ihinrere, dari awọn ikẹkọọ Bibeli ile, sọ awọn ọrọ asọye ti Iwe mimọ, tabi jẹrii lọna aijẹ bí aṣa. Wọn ngbiyanju lati de inu ọkan-aya nipa sisọ awọn iriri ati lilo awọn apejuwe. Iwe Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun wọn ṣalaye pe: “Awọn apejuwe maa nru ifẹ soke wọn si ntẹnumọ awọn ero pataki. Wọn nru ironu ẹnikan soke wọn si njẹki o rọrun lati moye awọn ero titun. Awọn apejuwe ti a ṣe aṣayan wọn daradara ndarapọ mọ ọgbọn ironu pẹlu ìmí ẹdun. . . . Lẹẹkọọkan, a le lo apejuwe lati fi mu ẹtanu tabi ikunsinu kuro.”a—Oju-iwe 168.

Ninu iwe rẹ̀ Essentials of Public Speaking, Warren DuBois sọ pe: “Jẹ ki onkọwe tabi olubanisọrọ naa sọ ero rẹ̀ jade nipasẹ awọn iṣe tabi ọrọ awọn eniyan, ọrọ ẹkọ ti ko runisoke rara yoo bẹrẹ sii runisoke ti yoo sì tanijípẹ́pẹ́.” Nipa bayii, fifi irunisoke ati ìtanijípẹ́pẹ́ kun ihin-iṣẹ ti o lagbara ti o si nfunni ni iye tẹlẹ ni o daju pe yoo ran awọn Kristẹni ojiṣẹ lọwọ lati de inu ọkan-aya.

Awọn Apejuwe Ti Nkọni Lẹkọọ

Iru apejuwe wo ni o le gbeṣẹ daradara julọ? O saba maa njẹ ọkan ti a gbekari ohun ti awọn olufetisilẹ le yára mọ lọna ti o rọrun. Jesu Kristi fi apẹẹrẹ rere lelẹ ni ọna yii. Ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu sọ nipa iru awọn ohun ti o wọpọ bẹẹ gẹgẹ bi iyọ, fitila, ati awọn ẹyẹ. (Matiu 5:1–7:29) Fun apẹẹrẹ, olukuluku ni o mọ fitila ti nlo epo ororo olifi ti a saba maa ngbe sori ọpa fitila daradara. Nitori naa, awọn ọmọ-ẹhin Jesu gbọdọ ti mọ pe wọn nilati jẹ olugbe imọlẹ tẹmi kiri nigba ti o sọ fun wọn pe: “A kii tan fitila tan, ki a si fi i sabẹ oṣuwọn; bikoṣe lori ọpa fitila, a sì fi imọlẹ fun gbogbo ẹni ti nbẹ ninu ile. Ẹ jẹ ki imọlẹ yin ki o mọlẹ tobẹẹ niwaju eniyan, ki wọn ki o le maa ri iṣẹ rere yin, ki wọn ki o le maa yin baba yin ti nbẹ ni ọrun logo.” (Matiu 5:15, 16) Awọn apejuwe ti ko díjú ti o ba koko ẹkọ kan mu yoo ran awọn Kristẹni ojiṣẹ lọwọ lati mu awọn ero ati ẹkọ Bibeli ṣe kedere.

Boya awọn apejuwe Jesu ti o lagbara julọ pa afiyesi pọ sori awọn eniyan. Gbe awọn wọnni ti a kọ silẹ ninu Luuku ori 15 ati 16 yẹwo. Awọn akọwe ati awọn Farisi ti ri ariwisi si Jesu fun titẹwọgba awọn ẹlẹṣẹ ati awọn agbowo ode. Ni idahunpada, Jesu sọ awọn itan arunisoke nipa awọn eniyan. O sọrọ nipa oluṣọ agutan kan ti o ri agutan rẹ̀ ti o ti sọnu, obinrin kan ti o gba ẹyọ owo kan ti o ti sọnu pada, ọmọkunrin onínàákúnàá ti o pada si ile, ati iriju alaiṣootọ kan.

Awọn apejuwe ti wọn jẹ otitọ gidi ati awọn iriri ti nṣẹlẹ gidi ninu igbesi-aye le wulo gidigidi fun Kristẹni ojiṣẹ kan. Fun apẹẹrẹ, ṣakiyesi bi Alexander H. Macmillan, ẹni ti o ti rinrin ajo lọna gbigbooro gẹgẹ bi olubanisọrọ itagbangba fun 60 ọdun, ti ṣalaye otitọ Bibeli nipa awọn oku. Ni kete ṣaaju iku baba rẹ̀, ẹni ti o gbagbọ pe ọkan kii ku lae, Macmillan ni ijumọsọrọpọ pẹlu rẹ̀:

“Baba mi beere ibeere taarata naa lọwọ mi pe: ‘Ọmọ mi, emi yoo ha danikan wà ninu iboji nigba ti mo nduro de ijọba lati bẹrẹ iṣẹ rẹ̀ ti fifi ijẹpipe kun ilẹ-aye?’

“Iyẹn jẹ ibeere kan ti ọdọkunrin kan ko le dahun nirọwọrọsẹ si itẹlọrun agbalagba kan ti ko tii ronu gba ọna yẹn lọ rí.

“Ni ifesipada mo bi i leere pe: ‘Baba, ẹ ha sùn daadaa lalẹ ana bi?’

“O dahun pe, ‘Bẹẹni, ọmọ mi, lẹhin ti dokita fun mi ni oogun orun diẹ.’

“‘Ẹ ha nimọlara idanikanwa nigba ti ẹ wà loju orun bi?’

“‘Bẹẹkọ, emi ko ṣe bẹẹ. O wu mi ki nle sun ni gbogbo igba, nitori nigba naa emi ko nimọlara irora kankan.’”

A. H. Macmillan lẹhin naa ka Joobu 14:13-15 ati 3:17-19 fun baba rẹ̀ o si wi pe: “Nitori naa ṣe ẹ ri, baba, awọn oku wa ninu orun iku wọn ko si mọ ohunkohun nigba ti wọn wa ninu ipo yẹn, nitori naa bawo ni wọn ṣe le nimọlara idanikanwa?”

Ẹ wo ikọnilẹkọọ gbigbeṣẹ ti eyi jẹ! Bi iwọ ba jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, iwọ pẹlu le lo iwe mimọ ati awọn apejuwe lati fa ironu ati ọkan-aya mọra.

Riri Awọn Apejuwe

Ṣugbọn nibo ni iwọ ti le ri awọn apejuwe gbigbeṣẹ tabi awọn iriri igbesi-aye ti wọn ṣẹlẹ gan an nitootọ? Ọpọlọpọ ni o le mu jade lati inu iṣura iriri ara ẹni tirẹ. Fun apẹẹrẹ, aini ha wa fun ọ lati ṣapejuwe awọn ibukun igbagbọ, agbara adura, tabi ayọ iṣẹ-ojiṣẹ naa? Bi iwọ ba jẹ Kristẹni ti o ti ṣeyasimimọ, boya iwọ le sọ oniruuru awọn iṣẹlẹ ninu igbesi-aye tirẹ funraarẹ. Iwọ le gbọ awọn iriri rere ninu ipade ijọ tabi nigba ti iwọ ba nsọrọ pẹlu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ. Tabi iwọ le ka iriri afunni niṣiiri kan ninu Yearbook of Jehovah’s Witnesses. Ni tootọ, Watch Tower Publications Index pese ọna ti a le gba ri awọn iriri jakejado agbaye ti a tẹ jade.

Bawo ni iwọ ṣe le sọ iriri lọna ti o gbeṣẹ? Ohun kan niyii, dida iwọn ifojusọna kan silẹ yoo ran ọ lọwọ lati gba afiyesi awọn olufetisilẹ rẹ. Iwọ le nasẹ iriri kan nipa wiwi pe: “Aṣaaju-ọna kan kẹkọọ funraarẹ gan an bi Jehofa ti nbukun awọn wọnni ti wọn nigbẹkẹle ninu rẹ̀.” Lọgan, awọn olufetisilẹ rẹ yoo fẹ lati mọ awọn ibukun ti oniwaasu Ijọba alakooko kikun naa gbadun. Rii daju pe o sọ fun wọn.

Gbiyanju lati sọ iriri kan ni awọn ọrọ tirẹ funraarẹ. Pese kulẹkulẹ, nitori ṣiṣe bẹẹ nfi ipá alagbara kun itan kan. Nipa fifi ọrọ ya aworan awọn ipo ti o wémọ́ ọn sini lọkan, iwọ lè ru ọkàn awọn olufetisilẹ rẹ soke lọna ti o rọrun sii. Ṣugbọn ri i daju pe iwọ kò kó wọnu itan sisọ debi pe wọn kuna lati loye idi ti o fi nsọ iriri naa. Pẹlupẹlu, yẹra fun asọdun, nitori bi o tilẹ jẹ pe eyi le mu ki itan kan dunmọni sii, o le din iṣeegbagbọ rẹ̀ kù. Fun idi kan naa, yago fun ṣiṣe atunsọ ọrọ agbọsọ tabi sisọ awọn iriri ti o ko le fi ẹri rẹ̀ mulẹ.

Mimu Bibeli Jẹ Gidi

Awọn iriri akọnilẹkọọ julọ ni a ri ninu Bibeli funraarẹ. Fun apẹẹrẹ, ki a sọ pe o daniyan lati fihan akẹkọọ Bibeli kan tabi awujọ kan pe awọn ọmọ le mu iduro wọn fun Jehofa Ọlọrun. Iwọ le pinnu lati lo akọsilẹ naa ti ọmọbinrin ti a ko darukọ rẹ̀ ẹni ti o sọ fun aya Namani nipa Eliṣa wolii Jehofa. Lakọọkọ, ka itan naa ni 2 Ọba 5:1-5. Iwọ le beere lẹhin naa pe: “Bawo ni ẹ ti ro pe o ṣoro tó fun ọmọbinrin yii lati pa iwatitọ rẹ̀ si Ọlọrun mọ́ ni ilẹ ijọsin eke? Ko ha gba igboya fun un lati sọrọ lọna idaniloju nipa Jehofa ati wolii rẹ̀?”

Iwadii aṣeṣaaju le ti ran ọ lọwọ lati mu itan naa larinrin. Iwọ le ti ri isọfunni ti nbẹ labẹ akori naa NAAMAN, SYRIA, ati ELISHA ninu Watch Tower Publications Index gẹgẹ bi eyi ti nranni lọwọ. Awọn Itọka ẹsẹ ninu awọn Bibeli kan le ṣamọna rẹ lati inu akọsilẹ 2 Ọba si Saamu 148:12, 13, nibi ti a ti ka pe: “Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo eniyan ati awọn ọmọde; ki wọn ki o maa yin orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW]; nitori orukọ rẹ̀ nikan ni o ni ọla; ogo rẹ̀ bori aye ati ọrun.” Iru iṣiri wo ni eyi jẹ fun awọn ọdọ eniyan lati sọ ọrọ Ọlọrun pẹlu igboya!—Iṣe 4:29-31.

Bi iwọ ba jẹ Kristẹni ojiṣẹ kan, ‘fiyesilẹ nigba gbogbo si ikọnilẹkọọ rẹ’ ni ọna yii. (1 Timoti 4:16) Ma wulẹ sọ otitọ nikan—ṣapejuwe rẹ̀. Mu ki awọn akọsilẹ Bibeli gbé aworan yọ sọkan ki o si ni itumọ. Lo awọn iriri ati apejuwe ti o ba a mu wẹku. Iwọnyi ni ọna lati de inu ọkan-aya.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ ẹ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Bii Jesu, awọn Kristẹni ojiṣẹ ode oni le lo awọn apejuwe ti ngbe aworan yọ sọkan lati jẹ́ ihin-iṣẹ wọn ki wọn si de inu ọkan-aya

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́