ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/1 ojú ìwé 8-13
  • Ni Igbẹkẹle Ninu Apa Igbala Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ni Igbẹkẹle Ninu Apa Igbala Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apa Igbala Ọlọrun Lẹnu Iṣẹ
  • Iranlọwọ Ninu Ijọ
  • Iranlọwọ Nigba ti Awọn Idẹwo Ba Dojukọ Wa
  • Iranlọwọ Ninu Awọn Ọran Ti Ara-ẹni
  • Kuro Ninu Gbogbo Idaamu
  • Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • 1 Kọ́ríńtì 10:13—“Olódodo Ni Ọlọ́run”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò
    Jí!—2014
  • “Kí ẹ Má Bàa Bọ́ Sínú Ìdẹwò”
    Ẹ Máa Ṣọ́nà!
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/1 ojú ìwé 8-13

Ni Igbẹkẹle Ninu Apa Igbala Jehofa

“Óò Jehofa, di apa wa ni òròòwúrọ̀, bẹẹni, igbala wa ni akoko idaamu.”—AISAYA 33:2, NW.

1. Ni itumọ wo ni Jehofa gba ni apa agbara kan?

JEHOFA ní apa alagbara kan. Nitootọ, niwọn igba ti “Ọlọrun jẹ ẹmi,” kii ṣe apa ẹlẹran ara. (Johanu 4:24, NW) Ninu Bibeli, apa iṣapẹẹrẹ naa duro fun lile lo agbara. Nipa bayii, apa rẹ̀ ni Ọlọrun fi da awọn eniyan rẹ̀ nide. Nitootọ, ‘bi oluṣọ agutan kan, Ọlọrun ṣamọna ogunlọgọ awọn eniyan rẹ̀. Pẹlu apa rẹ̀ ó kó awọn ọdọ agutan jọ, ati ni oókan-aya rẹ̀ ni o ngbe wọn.’ (Aisaya 40:11; Saamu 23:1-4) Ẹ wo o bi awọn eniyan Jehofa ti nimọlara aabo tó ninu apa onifẹẹ rẹ!—Fiwe Deutaronomi 3:24.

2. Awọn ibeere wo ni wọn yẹ fun igbeyẹwo wa nihin in?

2 Bawo ni apa Jehofa ṣe gba awọn eniyan rẹ la, ni igba ti o kọja ati ni isinsinyi? Itilẹhin wo ni Ọlọrun fifun wọn gẹgẹ bi ijọ kan? Eesitiṣe ti awọn eniyan rẹ̀ fi le ni igbẹkẹle ninu apa igbala rẹ̀ laaarin gbogbo idaamu?

Apa Igbala Ọlọrun Lẹnu Iṣẹ

3. Agbara ta ni Iwe mimọ ka idande Isirẹli kuro ni Ijibiti si?

3 Ṣaaju ki ó tó dá awọn ọmọ Isirẹli nide ni oko ẹru Ijibiti ni 3,500 ọdun sẹhin, Ọlọrun sọ fun wolii Mose pe: “Nitori naa wi fun awọn ọmọ Isirẹli pe, emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW], emi yoo si mu yin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Ijibiti, emi yoo si yọ yin kuro ni oko ẹrú wọn, emi yoo si fi apa nínà ati idajọ nla da yin ni ide.” (Ẹkisodu 6:6) Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti wi, Ọlọrun mu awọn ọmọ Isirẹli jade kuro ni Ijibiti ‘pẹlu apa giga.’ (Iṣe 13:17) Awọn ọmọkunrin Kora ka ìṣẹ́gun Ilẹ Ileri si ti Ọlọrun, ni wiwi pe: “Wọn ko ní ilẹ naa nipa idà araawọn, bẹẹni kii ṣe apa wọn ni o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtun rẹ ati apa rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitori ti iwọ ni ifẹ rere si wọn.”—Saamu 44:3.

4. Bawo ni a ṣe san ẹsan rere fun igbẹkẹle ninu apa igbala Jehofa ni akoko ìfínràn awọn ara Asiria?

4 Apa Jehofa tun wa si iranlọwọ awọn eniyan rẹ ni akoko ìfínràn awọn ara Asiria. Ni akoko yẹn wolii Aisaya gbadura pe: “Óò Jehofa, fi ojurere ha si wa. Ninu rẹ ni a fi ireti wa si. Di apa wa ni oroowurọ, bẹẹni, igbala wa ni akoko idaamu.” (Aisaya 33:2, NW) Adura yẹn ni a dahun nigba ti angẹli Ọlọrun pa 185,000 ni ibudo awọn ara Asiria, ni mimu ki ọba Senakeribu bẹsẹ rẹ̀ sọrọ ‘pẹlu itiju’ kuro ni Jerusalẹmu. (2 Kironika 32:21; Aisaya 37:33-37) Gbigbẹkẹle apa igbala Jehofa ni a saba maa nsan ẹsan rere fun.

5. Ki ni apa agbara Ọlọrun ṣe fun awọn Kristẹni ti a ṣe inunibini sí ni ipari Ogun Agbaye Kìn-ín-ní?

5 Apa alagbara ti Ọlọrun gba awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti a ṣe inunibini sí là ni ipari Ogun Agbaye Kìn-ín-ní. Ni 1918 orile-iṣẹ ti Ẹgbẹ Oluṣakoso ni awọn ọta wọn gbejako, awọn arakunrin ti a sì mọ̀ daradara ni a fi sẹwọn. Nitori ibẹru awọn agbara aye, awọn ẹni ami ororo fẹrẹẹ dawọ iṣẹ ijẹrii wọn duro patapata. Ṣugbọn wọn gbadura fun imusọji rẹ̀ ati fun iwẹmọ kuro ninu ẹṣẹ àìṣiṣẹ́mọ́ ati àìmọ́ nitori ibẹru. Ọlọrun dahun pada nipa mimu ki a dá awọn arakunrin ti a fi sẹwọn silẹ, ti a sì dá wọn lare tẹle e ni kete lẹhin naa. Gẹgẹ bi iyọrisi otitọ ti a sọ ni apejọpọ wọn ni 1919 ati itujade ẹmi Ọlọrun amuni gbekankan ṣiṣẹ, awọn ẹni ami ororo ni a mu sọji fun iṣẹ-isin onigboya si Jehofa ni imuṣẹ ikẹhin ti Joẹli 2:28-32.—Iṣipaya 11:7-12.

Iranlọwọ Ninu Ijọ

6. Bawo ni a ṣe mọ pe o ṣeeṣe lati farada ipo kan ti ndanniwo ninu ijọ kan?

6 Bi Ọlọrun ti nti eto-ajọ rẹ̀ lẹhin lapapọ, apa rẹ di awọn ẹnikọọkan ninu rẹ mú. Nitootọ, awọn ipo ko si ni ijẹpipe ninu ijọ eyikeyii nitori pe gbogbo eniyan jẹ alaipe. (Roomu 5:12) Nitori naa diẹ lara awọn iranṣẹ Jehofa le niriiri ipo ti ndanniwo ninu ijọ nigbamiran. Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe Geọsi ṣe “iṣẹ igbagbọ” ni gbigba awọn arakunrin ti nṣebẹwo pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe, Diotirefe ko gbà wọn o si tilẹ gbiyanju lati le awọn ẹlẹmii alejo ṣiṣe jade kuro ninu ijọ. (3 Johanu 5, 9, 10) Sibẹ, Jehofa ran Geọsi ati awọn miiran lọwọ lati maa baa lọ ni fifi ẹmi alejo ṣiṣe han ni itilẹhin iṣẹ iwaasu Ijọba naa. Igbarale Ọlọrun pẹlu adura nilati ran wa lọwọ lati maa baa lọ ni ṣiṣe awọn iṣẹ igbagbọ nigba ti a nduro de e lati mu ipo ti o le maa dan igbagbọ wa wò tọ́.

7. Laika awọn ipo wo si ninu ijọ Kọrinti ni awọn Kristẹni aduroṣinṣin ti de oju ila iyasimimọ wọn si Ọlọrun?

7 Ki a sọ pe o darapọ pẹlu ijọ Kọrinti ọgọrun un ọdun kìn-ín-ní. Ni akoko kan, iyapa halẹmọ iṣọkan rẹ̀, ifaaye gba iwa palapala si fi ẹmi rẹ̀ sinu ewu. (1 Kọrinti 1:10, 11; 5:1-5) Awọn onigbagbọ fa araawọn lọ si ile ẹjọ aye, awọn kan sì ṣe wótòwótò lori oniruuru awọn ọran. (1 Kọrinti 6:1-8; 8:1-13) Rogbodiyan, owu, ibinu, ati rudurudu mu igbesi-aye ṣoro. Awọn kan tilẹ gbe ibeere dide si aṣẹ Pọọlu wọn si tẹmbẹlu agbara isọrọ rẹ̀. (2 Kọrinti 10:10) Sibẹ, awọn aduroṣinṣin ti wọn darapọ mọ ijọ yẹn de oju ila iyasimimọ wọn si Ọlọrun ni akoko adanniwo yẹn.

8, 9. Ki ni a gbọdọ ṣe bi ipo ti ndanniwo kan ba dojukọ wa ninu ijọ?

8 Bi ipo ti ndanniwo kan ba dide, a nilati wà timọtimọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun. (Fiwe Johanu 6:66-69.) Ẹ jẹ ki a mu suuru pẹlu araawa, ni mimọ pe o ngba awọn kan ni akoko gigun lati gbe “animọ iwa titun naa” wọ ki wọn si fi iyọnu, inurere, irẹlẹ ero-inu, iwatutu, ati ipamọra wọ araawọn ni aṣọ. Nigba ti o tun jẹ pe awọn iranṣẹ Ọlọrun yatọ si araawọn ni ipilẹ, gbogbo wa nilati maa fi ifẹ han ki a si jẹ adarijini.—Kolose 3:10-14.

9 Lẹhin ọpọlọpọ ọdun iṣẹ-isin si Jehofa, arakunrin kan wi pe: “Bi ohun kan ba ti jẹ eyi ti o ṣe pataki julọ fun mi, o jẹ ọran sisunmọ eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri timọtimọ. Iriri mi ibẹrẹ kọ́ mi ni bi o ti jẹ alaiyekooro tó nipa tẹmi lati gbarale ironu eniyan. Lọgan ti ọkan mi ti mu ipinnu gbọnyingbọnyin lori koko yẹn, mo pinnu lati wa pẹlu eto-ajọ olotiitọ naa. Ọna miiran wo ni ẹnikan le gba ri ojurere ati ibukun Jehofa?” Iwọ ha ṣikẹ anfaani rẹ ti ṣiṣiṣẹsin Jehofa pẹlu awọn eniyan alayọ rẹ̀ bakan naa bi? (Saamu 100:2) Bi o ba ri bẹẹ, iwọ ko ni jẹ ki ohunkohun fà ọ́ lọ kuro ninu eto-ajọ Ọlọrun tabi pa ipo ibatan rẹ run pẹlu Ẹni naa ti apa rẹ̀ ngba gbogbo awọn ti o nifẹẹ rẹ̀ là.

Iranlọwọ Nigba ti Awọn Idẹwo Ba Dojukọ Wa

10. (a) Bawo ni adura ṣe nran awọn eniyan Ọlọrun lọwọ lati dojukọ idẹwo? (b) Idaniloju wo ni Pọọlu fi funni ni 1 Kọrinti 10:13?

10 Gẹgẹ bi awọn eniyan oloootọ ti darapọ mọ eto-ajọ Ọlọrun, a ni iranlọwọ rẹ̀ lakooko adanwo. Fun apẹẹrẹ, oun nran wa lọwọ lati pa iwatitọ wa mọ sii nigba ti idẹwo ba dojukọ wa. Dajudaju, awa nilati gbadura ni ibamu pẹlu awọn ọrọ Jesu pe: “Maṣe mu wa bọ́ sinu idẹwo, ṣugbọn gbà wa kuro lọwọ ẹni buburu nì,” Satani Eṣu. (Matiu 6:9-13, NW) Niti gidi, awa ntipa bayii sọ fun Ọlọrun pe ki o maṣe yọnda wa lati kuna nigba ti a ba ndan wa wo lati ṣaigbọran si i. Oun tun ndahun awọn adura wa fun ọgbọn lati bori awọn adanwo. (Jakobu 1:5-8) Awọn iranṣẹ Jehofa sì le ni idaniloju iranlọwọ rẹ̀, nitori Pọọlu wi pe: “Ko si idẹwo kan ti o tii ba yin, bikoṣe iru eyi ti o mọ niwọn fun eniyan: ṣugbọn olododo ni Ọlọrun, ẹni ti ki yoo jẹ ki a dan yin wo ju bi ẹyin ti le gba a; ṣugbọn ti yoo si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idẹwo naa, ki ẹyin ki o baa le gba a.” (1 Kọrinti 10:13) Ki ni orisun iru idẹwo bẹẹ, bawo si ni Ọlọrun ṣe nṣe ọna atiyọ?

11, 12. Awọn idẹwo wo ni awọn ọmọ Isirẹli juwọsilẹ fun, bawo si ni a ṣe le janfaani lati inu awọn iriri wọn?

11 Idẹwo nwa lati inu awọn ipo ti o le mu wa jẹ alaiṣootọ si Ọlọrun. Pọọlu wi pe: “Nǹkan wọnyi si jasi apẹẹrẹ fun awa, ki awa ki o ma baa ṣe ifẹkufẹẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn [ọmọ Isirẹli] pẹlu ti ṣe ifẹkufẹẹ. Bẹẹni ki ẹyin ki o má sì jẹ abọriṣa, bi awọn miiran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, awọn eniyan naa jokoo lati jẹ ati lati mu, wọn si dide lati ṣire. Bẹẹni ki awa ki o maṣe ṣe agbere gẹgẹ bi awọn miiran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbaa mọkanla le ẹgbẹrun eniyan si ṣubu ni ọjọ kan. Bẹẹni ki awa ki o maṣe dan Oluwa [“Jehofa,” NW] wo, gẹgẹ bi awọn miiran ninu wọn ti dan an wò, ti a si fi ejo run wọn. Bẹẹni ki ẹyin ki o maṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miiran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn.”—1 Kọrinti 10:6-10.

12 Awọn ọmọ Isirẹli ṣe ifẹkufẹẹ ohun buburu nigba ti wọn juwọsilẹ fun idẹwo lati jẹ oniwọra ni kíkó ati jijẹ aparo ti Ọlọrun pese lọna iyanu. (Numeri 11:19, 20, 31-35) Ni iṣaaju, wọn di abọriṣa nigba ti aisi nitosi Mose gbé idẹwo ti lilọwọ ninu ijọsin ọmọ maluu dide. (Ẹkisodu 32:1-6) Ẹgbẹẹgbẹrun ṣegbe nitori pe wọn ṣubu labẹ idẹwo wọn si ṣe agbere pẹlu awọn obinrin Moabu. (Numeri 25:1-9) Nigba ti awọn ọmọ Isirẹli yọnda fun idẹwo ti wọn sì kùn nipa iparun Kora, Datani, Abiramu, ati awọn ẹlẹgbẹ wọn ọlọtẹ, 14,700 parun lati inu ijiya ti a fi ranṣẹ lati ọrun wá. (Numeri 16:41-49) A le janfaani lati inu awọn iriri bẹẹ bi a ba mọ pe ko si ọkankan ninu awọn idẹwo wọnyi ti o tobi ju debi pe awọn ọmọ Isirẹli ko le dena wọn. Wọn iba ti ṣe bẹẹ bi wọn ba ti lo igbagbọ, ti kun fun imoore fun itọju onifẹẹ Ọlọrun, ki wọn si ti mọriri ìtọ̀nà Ofin rẹ̀. Lẹhin naa apa Jehofa iba ti gbà wọn là, ani gẹgẹ bi o ti lè gbà wá là.

13, 14. Bawo ni Jehofa ṣe nṣe ọna atiyọ nigba ti awọn iranṣẹ rẹ ba dojukọ idẹwo?

13 Gẹgẹ bii Kristẹni, a dojukọ awọn idẹwo ti o wọpọ fun araye. Sibẹ, a le wa ni oloootọ si Ọlọrun nipa gbigbadura fun iranlọwọ ati ṣiṣiṣẹ lati dena idẹwo. Ọlọrun jẹ oloootọ, oun ki yoo si jẹ ki a dan wa wo rekọja ohun tí a le farada. Bi a ba jẹ aduroṣinṣin ti Jehofa, ki yoo ṣoro ṣe fun wa lae lati ṣe ifẹ inu rẹ̀. Oun nṣe ọna atiyọ nipa fifun wa lokun lati dena idẹwo. Fun apẹẹrẹ, nigba ti a ba ṣe inunibini si wa, a le dan wa wò lati juwọsilẹ ninu ireti bibọ lọwọ idaniloro tabi iku. Ṣugbọn bi awa ba ni igbẹkẹle ninu apa alagbara ti Jehofa, idẹwo ki yoo dori koko kan nibi ti oun ko ti ni le sọ igbagbọ wa di alagbara ki o si fun wa ni okun ti o tó lati pa iwatitọ wa mọ. Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti wi: “A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara ko ni wa: a ndaamu wa, ṣugbọn a ko sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a ko kọ̀ wa silẹ; a nrẹ wa silẹ, ṣugbọn a ko si pa wa run.”—2 Kọrinti 4:8, 9.

14 Jehofa tun ngbe awọn eniyan rẹ̀ ró nipa lilo ẹmi rẹ̀ gẹgẹ bi arannileti ati olukọ kan. O nmu awọn koko inu Iwe mimọ wa si ọkan o si nran wa lọwọ lati mọ bi a o ti ṣe fi wọn si ilo ki a ba le dena idẹwo. (Johanu 14:26) Awọn oluṣotitọ iranṣẹ Jehofa loye ariyanjiyan ti idẹwo kan ni ninu a ko si tan wọn jẹ sinu titẹle ipa ọna aitọ. Ọlọrun ti ṣe ọna atiyọ nipa fifun wọn lagbara lati farada ani titi de oju iku paapaa lai juwọsilẹ fun idẹwo. (Iṣipaya 2:10) Yatọ si riran awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, Jehofa nlo awọn angẹli rẹ̀ nititori eto-ajọ rẹ̀.—Heberu 1:14.

Iranlọwọ Ninu Awọn Ọran Ti Ara-ẹni

15. Iranlọwọ ara-ẹni wo ni a le ri ninu Orin Solomọni?

15 Awọn wọnni ti wọn ndarapọ mọ eto-ajọ Jehofa ní iranlọwọ rẹ̀ ninu awọn ọran ara-ẹni. Fun apẹẹrẹ, awọn kan le maa gbiyanju lati ni olubaṣegbeyawo Kristẹni kan. (1 Kọrinti 7:39) Bi ijakulẹ kan ba wà, yoo ṣe iranwọ lati ronu nipa Solomọni ọba Isirẹli. Oun kuna lati jere itẹwọgba omidan Ṣulamaiti kan ninu igbeyawo nitori pe o nifẹẹ oluṣọ agutan rirẹlẹ kan. Akọsilẹ ọba naa nipa ọran yii ni a le pe ni Orin Ifẹ Solomọni Ti A Jakulẹ. Omi le bọ́ loju wa bi awọn isapa onimọlara ifẹ tiwa funraawa ba jẹ alaileso ninu ọran kan, ṣugbọn Solomọni la ijakulẹ rẹ̀ já awa pẹlu sì le ṣe bẹẹ. Ẹmi Ọlọrun le tì wa lẹhin lati fi ikora-ẹni-nijanu ati awọn animọ oniwa bi Ọlọrun miiran han. Ọrọ rẹ̀ ran wa lọwọ lati tẹwọgba otitọ ti o saba maa nronilara naa pe ẹnikan ko le ni ifẹni elere ifẹ fun ẹnikan ṣaa. (Orin Solomoni 2:7; 3:5) Sibẹ, Orin Solomọni fihan pe o lè ṣeeṣe lati rí onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ti o nifẹẹ wa gidigidi. Ni pataki jù, “orin awọn orin” yii ni a mu jootọ ninu ifẹ Oluṣọ agutan Rere naa, Jesu Kristi fun “iyawo” rẹ̀ tii ṣe 144,000 awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni ami ororo.—Orin Solomọni 1:1; Iṣipaya 14:1-4; 21:2, 9; Johanu 10:14.

16. “Wahala nipa ti ara” ti awọn Kristẹni ti o ti gbeyawo nniriiri rẹ̀ le ní ki ni ninu?

16 Ani awọn wọnni ti wọn fẹ onigbagbọ paapaa ni “wahala nipa ti ara.” (1 Kọrinti 7:28) Awọn aniyan ati aájò ti o wemọ ọkọ ati aya ati awọn ọmọ yoo wà. (1 Kọrinti 7:32-35) Amodi lè mu ẹru inira ati ìgalára wá. Inunibini tabi inira niti ọran inawo le mu ki o ṣoro fun baba kan ti o jẹ́ Kristẹni lati pese awọn koṣeemani igbesi-aye fun idile rẹ̀. A le pin awọn obi ati awọn ọmọ niya nipa ifisẹwọn, awọn kan ni a le daloro ani ki a tilẹ pa wọn paapaa. Ṣugbọn ninu gbogbo iru awọn ipo bẹẹ, awa le dena idẹwo lati sẹ́ igbagbọ bi a ba ni igbẹkẹle ninu apa igbala Jehofa niti gidi.—Saamu 145:14.

17. Iṣoro idile wo ni Ọlọrun mu ki Isaaki ati Rebeka lè farada?

17 Ó lè beere pe ki awa farada awọn adanwo kan fun akoko gigun. Fun apẹẹrẹ, ọmọ kan le fa idaamu ọkan ba awọn obi rẹ̀ oniwa-bi-Ọlọrun nipa gbigbe alaigbagbọ kan niyawo. Iyẹn ṣẹlẹ ninu idile Isaaki babanla naa ati aya rẹ̀ Rebeka. Ọmọkunrin wọn Isọ ẹni 40 ọdun fẹ́ awọn obinrin Heti meji ti wọn jẹ “ibanujẹ fun Isaaki ati Rebeka.” Nitootọ, “Rebeka sì wi fun Isaaki pe, agara aye mi dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakọbu [ọmọkunrin wọn keji] ba fẹ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi iru awọn wọnyi tii ṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yii, aye mi o ha ti ri?” (Jẹnẹsisi 26:34, 35; 27:46) Lọna ti o ṣe kedere, ọkan ododo Rebeka ni a daloro nipa iṣoro ti nbaa lọ yii. (Fiwe 2 Peteru 2:7, 8.) Sibẹ, apa Jehofa di Isaaki ati Rebeka mu, ni fifun wọn lagbara lati farada adanwo yii nigba ti wọn npa ipo ibatan alagbara mọ pẹlu Rẹ.

18. Ki ni adanwo ara-ẹni ti C. T. Russell farada pẹlu iranlọwọ Ọlọrun?

18 O nninilara nigba ti mẹmba idile kan ti o ti ṣeribọmi ba dẹwọ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. (Fiwe 2 Timoti 2:15.) Sibẹ, awọn kan tilẹ ti farada pipadanu olubaṣegbeyawo kan nipa tẹmi, gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Charles T. Russell, aarẹ Watch Tower Society akọkọ. Aya rẹ̀ já ide rẹ̀ pẹlu Society o sì kọ̀ ọ́ silẹ ni 1897, lẹhin ohun ti o sunmọ ọdun 18 igbeyawo. O beere ẹtọ ofin fun ipinya labẹ ofin ni 1903, a si fọwọsi i ni 1908. Ibanujẹ Russell ṣe kedere nigba ti o sọ fun un ninu lẹta ti o kọ laipẹ lẹhin ti wọn pinya pe: “Mo ti gbadura kikankikan si Oluwa nitori rẹ. . . . Emi ki yoo di ẹru inira rù ọ́ pẹlu akọsilẹ ibanujẹ mi, tabi gbiyanju lati ru imọlara ibanikẹdun rẹ soke nipa ṣiṣapejuwe imọlara mi ni kulẹkulẹ, bi o ti jẹ pe mo nri awọn aṣọ rẹ ati awọn nǹkan miiran ti o nmu iru ẹni ti o jẹ tẹlẹ wa sọkan mi ni kedere—ẹni ti o kun fun ifẹ ati ibanikẹdun ati iranlọwọ—ti nfi ẹmi Kristi han. . . . Jàre, gbe ohun ti emi fẹ sọ yẹwo taduratadura. Sì ni idaniloju pe ohun ti o dun mi julọ, imọlara jijinlẹ mi, kii ṣe idanikanwa temi funraami fun iyoku irin-ajo igbesi-aye, ṣugbọn iṣubu rẹ, ẹni ọwọn mi, ipadanu ayeraye rẹ, titi de ibi ti mo le ri dé.” Laika iru irora ọkan bẹẹ si, Russell ni itilẹhin Ọlọrun titi de opin iwalaaye rẹ ori ilẹ-aye. (Saamu 116:12-15) Jehofa maa ndi awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin mú nigba gbogbo.

Kuro Ninu Gbogbo Idaamu

19. Ki ni a gbọdọ ranti bi awọn iṣoro ti ndanilaamu ba wa pẹtiti?

19 Awọn eniyan Jehofa mọ ọn si “Ọlọrun awọn iṣe igbala,” Ẹni “ti nba wa gbe ẹru lojoojumọ.” (Saamu 68:19, 20, NW) Nitori naa, gẹgẹ bi awọn oluṣeyasimimọ ti nkẹgbẹpọ pẹlu eto-ajọ rẹ ori ilẹ-aye, ẹ maṣe jẹ ki a juwọ silẹ lae fun ainireti bi awọn iṣoro ti ndanilaamu ba wa pẹtiti. Ranti pe “Ọlọrun ni aabo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju.” (Saamu 46:1) Igbẹkẹle wa ninu rẹ̀ ni a nsan ẹsan rere fun nigba gbogbo. Dafidi wi pe, “Emi ṣe àfẹ́rí Oluwa [“Jehofa,” NW], o si gbohun mi; o si gba mi kuro ninu gbogbo ibẹru mi. . . . Ọkunrin olupọnju yii kigbe, Oluwa [“Jehofa,” NW] sì gbóhùn rẹ̀, o si gba a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀.”—Saamu 34:4-6.

20. Awọn ibeere wo ni wọn ṣì wa fun igbeyẹwo?

20 Bẹẹni, baba wa ọrun ngba awọn eniyan rẹ̀ là kuro ninu gbogbo idaamu. O nti eto-ajọ rẹ ti ori ilẹ-aye lẹhin, ni pipese iranlọwọ ninu awọn ọran ijọ ati àlàámọ̀rí ara-ẹni. Nitootọ, “Oluwa [“Jehofa,” NW] ki yoo ṣa awọn eniyan rẹ̀ tì.” (Saamu 94:14) Ṣugbọn ẹ jẹ ki a tun gbe awọn ọna miiran yẹwo ninu eyi ti Jehofa ngba ran awọn eniyan rẹ lọwọ lẹnikọọkan. Bawo ni Baba wa ọrun ṣe nfokun fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti nṣaisan, ti wọn ni irẹwẹsi ọpọlọ, tí ibanujẹ ọ̀fọ̀ bo mọlẹ, tabi ti wọn ni idaamu ọkan nitori awọn iṣina tiwọn? Gẹgẹ bi a o ti ri i, ninu awọn ọran wọnyi pẹlu, bakan naa, a ni idi lati gbarale apa agbara Jehofa.

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Bawo ni apa Jehofa ṣe mú igbala wá ni awọn akoko igbaani?

◻ Bawo ni Jehofa ṣe nran awọn eniyan rẹ̀ lọwọ ninu ijọ lonii?

◻ Iranlọwọ wo ni Ọlọrun pese ninu awọn àlàámọ̀rí ara-ẹni?

◻ Ki ni awa nilati ṣe bi awọn iṣoro ti ndanilaamu ba wà pẹtiti?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọlọrun mu awọn ọmọ Isirẹli jade kuro ni Ijibiti “pẹlu apa giga”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́