ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/1 ojú ìwé 20-22
  • Ki Ni Kọkọrọ sí Isin Kristẹni Tootọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ki Ni Kọkọrọ sí Isin Kristẹni Tootọ?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Isunniṣe Titọna Kan
  • Ifẹ Ninu Aye Onimọtara Ẹni Nikan
  • Ifẹ Ninu Ijọ
  • Mimu Ifẹ Wa Fun Ẹnikinni Keji Lagbara Sii
  • Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìfẹ́—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/1 ojú ìwé 20-22

Ki Ni Kọkọrọ sí Isin Kristẹni Tootọ?

LONII, awọn eniyan pupọ sii nfidaloju sọ pe awọn jẹ mẹmba isin kristẹni ju     awujọ isin eyikeyii miiran lọ ninu aye. Ṣugbọn igbagbọ awọn ti wọn pe araawọn ni Kristẹni wọnyi forigbari, wọn ko sì ṣọkan, ati nigbamiran wọn tilẹ npa araawọn. Ni kedere, ọpọlọpọ ni kii ṣe Kristẹni tootọ. Jesu sọ pe ni ọjọ wa, ọpọlọpọ yoo sọ fun un pe, “Oluwa, Oluwa,” lede miiran wọn yoo sọ pe Kristẹni ni awọn jẹ́, sibẹ oun yoo wi fun wọn pe: “Emi ko mọ yin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹyin oniṣẹ ẹṣẹ.” (Matiu 7:21, 23) Dajudaju, ko si ọkankan ninu wa ti yoo fẹ lati wà laaarin awọn wọnyi! Nitori naa bawo ni a ṣe le mọ bi a ba jẹ Kristẹni tootọ?

Otitọ naa ni pe, ọpọlọpọ nǹkan ni a nilo lati jẹ Kristẹni tootọ. Kristẹni tootọ nilati ni igbagbọ lilagbara nitori pe “laisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wù ú [Ọlọrun].” (Heberu 11:6) Igbagbọ lilagbara yẹn ni awọn iṣe titọna nilati bá rin. Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kilọ pe “igbagbọ laisi iṣẹ́ jẹ oku.” (Jakobu 2:26) Ju bẹẹ lọ, Kristẹni kan nilati mọyi aṣẹ “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu naa.” (Matiu 24:45-47, NW) Ṣugbọn kọkọrọ naa si isin Kristẹni tootọ jẹ ohun kan ti o yatọ si awọn nǹkan wọnyi.

Ki ni kọkọrọ naa? Apọsiteli Pọọlu ṣalaye ninu lẹta rẹ̀ akọkọ si awọn ara kọrinti pe: “Bi mo ba nfi awọn ede ahọn eniyan ati ti angẹli fọ̀ ṣugbọn ti emi ko ni ifẹ, mo ti di ẹyọ idẹ kan ti ndun tabi aro ti npariwo gooro. Bi mo ba sì ni ẹbun isọtẹlẹ ti mo si di ojulumọ gbogbo awọn aṣiri mimọ ati gbogbo imọ, bi mo ba si ni gbogbo igbagbọ tobẹẹ ti mo le ṣi awọn oke nla nipo pada, ṣugbọn ti emi ko ni ifẹ, emi ko jamọ nǹkan. Bi mo ba si fi gbogbo ohun ìní mi funni lati bọ́ awọn ẹlomiran, bi mo bá sì fi araami funni, ki emi baa le ṣogo, ṣugbọn ti emi ko ni ifẹ, emi ko jere rara.”—1 Kọrinti 13:1-3, NW.

Nitori naa ifẹ ni kọkọrọ naa si isin Kristẹni tootọ. Igbagbọ, awọn iṣẹ, ati ibakẹgbẹpọ titọna ṣekoko, ó jẹ koṣeemani. Ṣugbọn laisi ifẹ, iniyelori wọn ni a ko le rí. Eeṣe ti iyẹn fi ri bẹẹ.

Ni pataki, ó jẹ nitori iru Ọlọrun ti a njọsin. Apọsiteli Johanu ṣapejuwe Jehofa, Ọlọrun isin Kristẹni tootọ naa ninu awọn ọrọ wọnyi: “Ọlọrun jẹ ifẹ.” (1 Johanu 4:8, NW) Jehofa ní ọpọlọpọ awọn animọ miiran, iru bii agbara, idajọ ododo, ati ọgbọn, ṣugbọn niwọn bi oun ti jẹ Ọlọrun ifẹ lọna ti o gajulọ, iru awọn eniyan wo ni oun yoo fẹ́ ki awọn olujọsin rẹ jẹ́? Dajudaju, awọn ẹni ti wọn nṣafarawe rẹ̀ ti wọn si nmu ifẹ dagba.—Matiu 5:44, 45; 22:37-39.

Isunniṣe Titọna Kan

Bẹẹni, ifẹ nmu ki awọn Kristẹni dabii Ọlọrun ti wọn njọsin. O tumọ si pe awọn ete ọkan wọn farajọ awọn ete ọkan Ọlọrun. Ete ọkan wo leke gbogbo rẹ̀ ni o sun Jehofa lati ran Jesu wa sori ilẹ-aye lati fun wa lanfaani lati jere iye ayeraye? Ifẹ. “Ọlọrun fẹ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o be gba a gbọ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.” (Johanu 3:16) Nigba naa, ki ni o nilati jẹ ete ọkan wa ninu ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun? Lẹẹkan sii, ifẹ. “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ mọ.”—1 Johanu 5:3.

O ha ṣeeṣe lati ṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu ete ọkan ti ko tọna bi? Bẹẹni. Pọọlu mẹnukan awọn kan ni ọjọ rẹ ti wọn nṣiṣẹsin lati inu ilara ati ibanidije. (Filipi 1:15-17) Iyẹn le ṣẹlẹ si wa. Aye yii kun fun ibanidije gan an, ẹmi yẹn si le ràn wá. A le ni igberaga lati ronu pe a jẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ti o sànjù tabi pe a le fi iwe ikẹkọọ pupọ sode ju awọn ẹlomiran lọ. A le fi awọn anfaani iṣẹ-isin wa wé iwọnni ti awọn ẹlomiran ngbadun ki a si di olujọ ara-ẹni loju—tabi onilara. Alagba kan le jẹ ojowu nipa ipo aṣẹ rẹ̀, ani titi dori koko didina itẹsiwaju ọdọkunrin kan ti o lẹ́bùn. Ifẹ fun èrè ara-ẹni le sun wa lati mu ibadọrẹẹ pẹlu awọn Kristẹni ti wọn lọ́rọ̀ dagba nigba ti a nfoju pa awọn otoṣi rẹ́.

Awọn nǹkan wọnyi le ṣẹlẹ nitori pe a jẹ alaipe. Bi o ti wu ki o ri, bi a ba ṣe ifẹ ni olori isunniṣe wa—bii ti Jehofa, awa yoo bá iru awọn itẹsi bẹẹ jà. Imọtara ẹni nikan, ifẹ lati fi ogo fun araawa, tabi igberaga ọ̀yájú le ṣiji bo ifẹ, debi pe awa ‘ko ni jere rara.’—Owe 11:2; 1 Kọrinti 13:3, NW.

Ifẹ Ninu Aye Onimọtara Ẹni Nikan

Jesu wi pe awọn ọmọlẹhin oun ‘ki yoo jẹ apakan aye.’ (Johanu 17:14) Bawo ni a ṣe le yẹra fun jijẹ ẹni ti a bo mọlẹ nipa agbara idari aye ti o yi wa ka? Ifẹ yoo ran wa lọwọ. Fun apẹẹrẹ, lonii awọn eniyan jẹ “olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ.” (2 Timoti 3:4) Johanu kilọ fun wa ki a maṣe dabi iyẹn. O wi pe: “Ẹ maṣe fẹran aye, tabi ohun ti nbẹ ninu aye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aye, ifẹ ti Baba ko si ninu rẹ̀. Nitori ohun gbogbo ti nbẹ ni aye, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ oju, ati irera aye, kii ṣe ti Baba, bikoṣe ti aye.”—1 Johanu 2:15, 16.

Sibẹ, ko rọrun lati yi ẹ̀hìn wa pada si “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” ati “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ oju.” Awọn nǹkan wọnyi ni a nifẹẹ ni pato nitori pe wọn fa ẹran-ara wa mọra. Ju bẹẹ lọ, ọpọ jaburata oriṣiriṣi faaji ni wọn wa lonii ju bi wọn ti wa ni ọjọ Johanu lọ, nitori naa bi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ oju ba jẹ iṣoro nigba naa, o jẹ bẹẹ ni pataki nisinsinyi.

O runi lọkan soke pe, ọpọlọpọ awọn faaji ode oni tí aye npese ni ko ṣaitọna ninu araawọn. Ko si ohun ti o ṣaitọ pẹlu nini ile titobi kan, ọkọ ayọkẹlẹ daradara kan, apoti tẹlifiṣọn kan, eelo sitẹrio kan. Bẹẹni ko rú ofin Bibeli eyikeyii lati lọ si irin ajo ti o jinna, ti o gbadunmọni ki a si ni awọn isinmi rirunisoke lẹnu iṣẹ. Nigba naa, ki ni koko ikilọ Johanu? Ohun kan ni pe, bi iru awọn nǹkan bẹẹ ba di eyi ti o ṣe pataki jù fun wa, wọn yoo mu ẹmi imọtara ẹni nikan, ọrọ alumọọni, ati igberaga dagba ninu wa. Isapa lati ṣiṣẹ owo lati ni wọn sì le dí wa lọwọ ninu iṣẹ-isin wa si Jehofa. Ani gbigbadun iru awọn nǹkan bẹẹ paapaa ngba akoko, nigba ti o sì jẹ́ pe iwọn akoko ti o bọgbọnmu fun isinmi nmu itura wá, akoko wa mọniwọn, ni oju iwoye iṣẹ-aigbọdọmaṣe wa lati kẹkọọ Bibeli, padepọ pẹlu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ ẹni fun ijọsin, ati lati waasu ihinrere Ijọba naa.—Saamu 1:1-3; Matiu 24:14; 28:19, 20; Heberu 10:24, 25.

Ni sanmani ọrọ̀ alumọọni yii, o gba ipinnu lati ‘fi Ijọba Ọlọrun si ipo akọkọ’ ki a si dena ‘lilo aye yii dé ẹkunrẹrẹ’ (Matiu 6:33; 1 Kọrinti 7:31) Igbagbọ lilagbara yoo ran wa lọwọ. Ṣugbọn ni pataki, ojulowo ifẹ fun Jehofa ati fun awọn aladuugbo wa yoo fun wa lokun lati dena awọn ẹtan naa ti, wọn lè dí wa lọwọ ninu ‘ṣiṣaṣepari iṣẹ-ojiṣẹ wa lẹkun-unrẹrẹ nigba ti wọn ko ṣaitọ ninu araawọn.’ (2 Timoti 4:5) Laisi iru ifẹ bẹẹ, iṣẹ ojiṣẹ wa le fi tirọruntirọrun joro di isapa gbà má sọ pe oòrọ́wọ́ mi.

Ifẹ Ninu Ijọ

Jesu tẹnumọ ijẹpataki ifẹ nigba ti o wi pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin nṣe, nigba ti ẹyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:35) Eeṣe ti awọn alagba fi nilati lo iru akoko pupọ tobẹẹ ni didari ati riran awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ wọn lọwọ bi wọn ko ba ni ifẹ wọn? Eeṣe ti ijọ yoo fi farada ailera awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ wọn—pẹlu ti awọn alagba—bi kii ba ṣe nitori ifẹ? Ifẹ sun awọn Kristẹni lati ran araawọn lọwọ ni ọna ti ara nigba ti wọn ba gbọ pe awọn miiran wa ninu aini. (Iṣe 2:44, 45) Lakooko inunibini, awọn Kristẹni ndaabobo araawọn wọn si nku fun araawọn paapaa. Eeṣe? Nitori ifẹ.—Johanu 15:13.

Nigba miiran awọn ẹ̀rí titobi julọ ti ifẹ maa ńwá lọna awọn ohun kekere. Alagba kan, ti o ti wa labẹ ikimọlẹ nitori ọpọlọpọ ẹru-iṣẹ, ni Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan tun lè tọ̀ wá ki o si sọ asọtunsọ ẹsun kan ti o dabi ẹni pe kò jamọ pataki rara loju alagba naa. O ha yẹ ki alagba naa binu bi? Dipo jijẹ ki eyi di okunfa fun iyapa, oun fi suuru ati inurere ba arakunrin rẹ̀ lo. Wọn jiroro ọran naa papọ, o si tun fun ibadọrẹẹ wọn lokun sii. (Matiu 5:23, 24; 18:15-17) Dipo ki ẹnikọọkan maa rinkinkin mọ awọn ẹtọ rẹ̀, gbogbo wa gbọdọ gbiyanju lati mu ẹmi inurere tí Jesu damọran dagba, ni jijẹ ẹni ti o muratan lati dari ji arakunrin wọn ni “igba mẹtadinlọgọrin.” (Matiu 18:21, 22, NW) Fun idi yii, awọn Kristẹni gbiyanju kára lati fi aṣọ ifẹ bo araawọn, “nitori o jẹ ide irẹpọ pipe.”—Kolose 3:14, NW.

Mimu Ifẹ Wa Fun Ẹnikinni Keji Lagbara Sii

Bẹẹni, ifẹ ni isunniṣe titọna fun ṣiṣiṣẹsin Jehofa. Ifẹ yoo fun wa lokun lati pa araawa mọ lọtọ kuro ninu aye, ifẹ yoo si rii daju pe ijọ ṣì jẹ ti Krsitẹni nitootọ. Nigba ti ko din iniyelori ijafafa ku, yoo ran awọn wọnni ti wọn wà ni ipo aṣẹ lọwọ lati maṣe di ẹni ti ọran ijafafa wọ lọkan tobẹẹ debi ti wọn yoo fi gbagbe inurere ati iwatutu ninu biba awọn ẹlomiran lo. Ifẹ nran gbogbo wa lọwọ lati “jẹ onigbọran si awọn wọnni ti nmu ipo iwaju . . . ki a sì tẹriba.”—Heberu 13:17, NW.

Apọsiteli Peteru rọ wa lati ni “ifẹ gbigbona” fun araawa nitori pe “ifẹ nbo ọpọlọpọ ẹṣẹ mọlẹ.” (1 Peteru 4:8, NW) Bawo ni a ṣe le ṣe eyi? Eniyan ni a da ni aworan Ọlọrun o si tipa bayii ni agbara adanida kan lati fi ifẹ hàn. Ṣugbọn iru ifẹ ti a nsọrọ nipa rẹ nihin in nilo afikun ohun kan. Nitootọ, oun ni lajori eso ẹmi Ọlọrun. (Galatia 5:22) Fun idi yii, lati mu ifẹ dagba, a nilati ṣí araawa paya fun ẹmi mimọ Ọlọrun. Bawo? Nipa kikẹkọọ Bibeli, eyi ti a misi nipasẹ ẹmi Jehofa. (2 Timoti 3:16) Nipa gbigbadura fun ẹmi Jehofa lati gbe ifẹ wa ró fun Jehofa ati fun awọn arakunrin wa. Ati nipa kikẹgbẹpọ pẹlu ijọ Kristẹni, nibi ti ẹmi naa ti ntu jade lọfẹẹ.

A tun nilati ṣayẹwo araawa ki a baa le ri awọn iṣe ati ironu alainifẹẹ eyikeyii. Ranti pe, ifẹ jẹ animọ tí ọkan-aya nfihan, ati pe “ọkan [“ọkan-aya,” NW] eniyan kun fun ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, o sì buru jai!” (Jeremaya 17:9) Laika gbogbo iranlọwọ ti Jehofa nfi fun wa sí, awa yoo huwa lọna ainifẹẹ ni awọn igba miiran. A lè sọrọ pẹlu ohùn lile lọna ti ko pọndandan si Kristẹni ẹlẹgbẹ wa kan, tabi ara wa lè bùmáṣọ ki a sì di ẹni ti a ṣẹ̀ nipa ohun kan ti a sọ. Fun idi yii, o dara fun wa lati tun adura Dafidi naa sọ pe: “Ọlọrun, wadii mi, ki o sì mọ ọkan mi: dán mi wò, ki o sì mọ iro mi: ki o sì wo bi ọna buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọna ainipẹkun.”—Saamu 139:23, 24.

Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, “ifẹ kii yẹ̀ lae.” (1 Kọrinti 13:8) Bi a ba sọ ninifẹẹ araawa daṣa, a ko ni jẹ alaikunju iwọn lae ni akoko idanwo. Ifẹ ti o wa laaarin awọn eniyan Ọlọrun fikun paradise tẹmi ti o wà lonii gidigidi. Kiki awọn wọnni ti wọn nifẹẹ araawọn lọna gbigbona lati inu ọkan ni yoo ri idunnu ninu gbigbe ninu aye titun. Fun idi yii, ṣafarawe Jehofa ni fifi iru ifẹ bẹẹ han sode ki o si tipa bayii fun ide irẹpọ lokun. Mu ifẹ dagba, ki o si ní kọkọrọ naa si isin Kristẹni tootọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́