Ipo Poopu—Kristi Ni Ó Ha Dá a Silẹ Bi?
“LAAARIN Peteru, biṣọọbu ti Roomu akọkọ, ati John Paul keji, poopu wa isinsinyi, ìlà gigun gbọọrọ ti awọn poopu onipo-ajulọ ni ó wà—ohun ti o ju 260 lọ, nitootọ.” Bẹẹ ni mẹmba Katoliki naa Anthony Foy wí ninu The Southern Cross, iwe irohin ọsọọsẹ ti Katoliki kan fun iha guusu Africa. Ó nba a lọ pe: “Ìlà poopu ti kò já yii ni a lè fi idaloju yiju si, nigba ti a ba sọ fun wa lati fẹri han pe Ṣọọṣi Katoliki ni Jesu dá silẹ.”
Njẹ a lè fi idaloju sọ pe ìlà gigun ti awọn poopu yii bẹrẹ pẹlu apọsiteli Peteru bi? Gẹgẹ bi ẹkọ isin Katoliki ti wi, awọn poopu mẹrin, Linus, Anacletus, Clement Kìn-ín-ní, ati Evaristus, ni a sọ pe wọn gbapo Peteru titi di ọdun 100 C.E. Bibeli mẹnukan Kristẹni kan ti a npe ni Linusi ti ó gbé ni Roomu. (2 Timoti 4:21) Bi o ti wu ki o ri, kò si ohunkohun lati damọran pe Linusi, tabi ẹnikẹni miiran, jẹ agbapò poopu fun Peteru. Apọsiteli Johanu, ẹni ti o kọ awọn iwe marun un ti Bibeli ni ẹwadun ti o kẹhin ọgọrun un ọdun kìn-ín-ní, ko ṣe ìtọ́ka kankan si eyikeyii ninu awọn ti a fẹnu lasan pe ni agbapò Peteru loke yii. Nitootọ, bi agbapò Peteru kan bá wà, yiyan ti ó bọgbọnmu ki yoo ha jẹ Johanu funraarẹ bi?
Niti ijẹwọ naa pe Peteru ni biṣọọbu Roomu akọkọ, ko si ẹ̀rí kankan pe oun tilẹ ṣebẹwo si ilu yẹn. Nitootọ, Peteru funraarẹ sọ pe oun kọ lẹta oun akọkọ lati Babiloni. (1 Peteru 5:13) Ariyanjiyan Katoliki pe Peteru lo “Babiloni” gẹgẹ bi ìtọ́ka alaṣiiri si Roomu jẹ́ alailẹsẹnilẹ. Babiloni gidi wà ni ọjọ Peteru. Siwaju sii, Babiloni ni iwọn awujọ awọn Juu ti wọn pọ diẹ. Niwọn bi Jesu ti yan Peteru lati dari iwaasu rẹ̀ sí awọn Juu ti a kọ nílà, ni taarata, ó bọgbọnmu patapata lati gbagbọ pe Peteru bẹ Babiloni wò fun ete yii.—Galatia 2:9.
Ṣakiyesi, pẹlu, pe Peteru kò fi igbakanri tọka si araarẹ gẹgẹ bi ẹnikan ju apọsiteli Kristi lọ. (2 Peteru 1:1) Ko si ibi kankan ninu Bibeli ti a ti pè é ni “Baba Mimọ,” “Poopu Onipo-ajulọ,” tabi “Poopu” (Latin, papa, ede isọrọ ifẹni fun “Baba”). Kaka bẹẹ, oun fi tirẹlẹ tirẹlẹ rọ̀ mọ́ awọn ọrọ Jesu ní Matiu 23:9, 10: “Ẹ ma sì ṣe pe ẹnikan ni baba yin ni aye: nitori ẹnikan ni Baba yin, ẹni ti nbẹ ni ọrun. Ki a ma sì ṣe pe yin ni olukọni: nitori ọkan ni Olukọni yin, ani Kristi.” Peteru kò tẹwọgba ìjúbà funni. Nigba ti Kọniliu balogun ọ̀rún ti Roomu “wolẹ ni ẹsẹ rẹ̀, o si fori balẹ fun un . . . , Peteru gbé e dide, ó ní, Dide; eniyan ni emi tikaraami pẹlu.”—Iṣe 10:25, 26.
Niti 260 awọn poopu ti a sọ, alufaa Foy gbà pe: “Ọpọlọpọ ni ó ti jẹ́ alaiyẹ fun ipo akoso giga wọn.” Ninu igbiyanju lati dá eyi lare, iwe naa New Catholic Encyclopedia wi pe: “Ohun ti ó ṣe pataki fun awọn ete iṣakoso ni ipo akoso naa, kii sii ṣe ihuwasi ara ẹni ti poopu kọọkan. Oun funraarẹ ti lè jẹ ẹni mímọ́ kan, aṣe buruku ṣe rere kan, tabi ẹni buburu kan paapaa.” Ṣugbọn iwọ ha gbagbọ pe Kristi yoo lo iru awọn eniyan bẹẹ lati ṣoju fun un bi?
Ohunkohun yoowu ki o ṣẹlẹ, itẹnumọ naa pe ipo poopu ni Jesu dasilẹ ni a kò wulẹ tilẹhin ninu Bibeli. Gẹgẹ bi iwe naa Encyclopedia of Religion ti wi, ani awọn akẹkọọjinlẹ Katoliki ode oni paapaa gbà pe “Ko sí ẹ̀rí taarata kankan lati inu iwe mimọ pe Jesu fidii ipo poopu mulẹ gẹgẹ bii ipo akoso ti ó wà pẹtiti kan laaarin ṣọọṣi.