ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 13-18
  • Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Alayọ Ni Awọn Wọnni Ti Wọn Farada!
  • Gbigba Itilẹhin Lati Inu Ọrọ Oniṣiiri Jehofa
  • Fun Igbala Awọn Ẹlomiran
  • Fifi Iduroṣinṣin Maa Ba a Niṣo Ninu Eré-ìje Naa
  • O Lè Fara Dà á Dé Òpin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Ẹ Sáré ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Sá Eré Ìje Náà Dé Ìparí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 13-18

Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada

“Ẹ jẹ́ ki a fi ifarada sa eré-ìje ti a gbeka iwaju wa.”—HEBERU 12:1, NW.

1. (a) Ki ni a gbeka iwaju wa nigba ti a ṣe iyasimimọ si Jehofa Ọlọrun? (b) Iru eré-ìje wo ni Kristẹni kan gbọdọ murasilẹ fun?

NIGBA TI a ya araawa si mímọ́ fun Jehofa nipasẹ Jesu Kristi, Ọlọrun gbe eré-ìje kan ka iwaju wa, ki a sọ ọ lọna iṣapẹẹrẹ. Ni òpin eré-ìje naa, ẹbun kan ni a fun gbogbo awọn wọnni ti wọn pari rẹ̀ pẹlu aṣeyọri si rere. Ẹbun wo ni? Ìyè ainipẹkun! Lati jere ẹbun titobilọla yii, Kristẹni saresare naa nilati wà ni imurasilẹ, kii ṣe fun ere ayarasa kánmọ́kánmọ́, onigba kukuru kan, ṣugbọn fun eré ẹlẹmii ẹṣin kan. Nitori naa oun yoo nilo ifarada. Oun yoo nilati farada làálàá alakooko gigun eré-ìje naa funraarẹ ati awọn idena ti wọn bá nyọju lakooko eré-ìje naa.

2, 3. (a) Ki ni yoo ran wa lọwọ ninu sisa eré-ìje Kristẹni naa de opin? (b) Bawo ni ayọ ṣe ran Jesu lọwọ lati sa eré-ìje naa pẹlu ifarada?

2 Ki ni yoo ran wa lọwọ lati sa iru eré-ìje bẹẹ de opin? O dara, ki ni ó ran Jesu lọwọ lati farada a nigba ti oun jẹ eniyan lori ilẹ-aye? Oun ṣamulo okun inu lati inu animọ ayọ. Heberu 12:1-3 (NW) kà pe: “Nitori naa, nigba naa, nitori a ni awọsanma nla bẹẹ ti awọn ẹlẹrii yi wa ká, ẹ jẹ ki awa pẹlu mu gbogbo ẹrù wiwuwo ati ẹṣẹ ti nfi tirọruntirọrun dì mọ́ wa kuro, ẹ si jẹ ki a fi ifarada sá eré-ìje ti a gbeka iwaju wa, gẹgẹ bi a ti ntẹju mọ Olori Aṣoju ati Alaṣepe igbagbọ wa, Jesu. Nitori ayọ ti a gbeka iwaju rẹ̀ o farada òpó igi ìdálóró, o tẹmbẹlu itiju, o sì ti jokoo ni ọwọ ọtun ìtẹ́ Ọlọrun. Nitootọ, ẹ gbe e yẹwo finnifinni ẹni naa ti o ti farada iru ọrọ òdì bẹẹ lati ẹnu awọn ẹlẹṣẹ lodisi ire tiwọn funraawọn, ki ẹ ma baa ṣaarẹ ki ẹ si rẹwẹsi ninu ọkàn yin.”

3 Jalẹ gbogbo iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba rẹ̀, Jesu ni ó ṣeeṣe fun lati maa sá eré-ìje naa nitori ayọ Jehofa. (Fiwe Nehemaya 8:10.) Ayọ rẹ̀ ran an lọwọ lati farada iku onitiju lori opo igi idaloro paapaa, lẹhin eyi ti oun niriiri ayọ ti ko ṣee fẹnusọ ti didide kuro ninu oku ati gigoke lọ si ọwọ ọtun Baba rẹ̀, nibẹ lati bojuto iṣẹ Ọlọrun titi de ipari rẹ̀. Nipa ifarada rẹ̀ gẹgẹ bi eniyan niha ọdọ Ọlọrun, oun di ẹ̀tọ́ rẹ̀ fun ìyè ainipẹkun mú. Bẹẹni, gẹgẹ bi Luuku 21:19 (NW) ṣe sọ pe: “Nipa ifarada lọdọ yin ni ẹyin yoo jere ọkan yin.”

4. Iru apẹẹrẹ wo ni Jesu gbekalẹ fun awọn saresare ẹlẹgbẹ rẹ̀, ki ni awa sì gbọdọ pa ero inu wa mọ sori rẹ̀?

4 Jesu Kristi gbe awọn apẹẹrẹ rere julọ kalẹ fun awọn saresare ẹlẹgbẹ rẹ̀, apẹẹrẹ rẹ̀ sì mu un dá wa loju pe awa pẹlu lè jẹ aṣẹgun. (1 Peteru 2:21) Ohun ti Jesu sọ fun wa pe ki a ṣe, awa le ṣe e. Gẹgẹ bi oun ti farada a, awa pẹlu lè ṣe bẹẹ. Gẹgẹ bi awa si ti duro ninu iṣafarawe iduroṣinṣin rẹ̀, a gbọdọ pa ero-inu wa mọ sori ìdí ti a fi nilati jẹ alayọ. (Johanu 15:11, 20, 21) Kikun fun ayọ yoo ran wa lọwọ lati tẹpẹlẹ mọ ọn ninu sisa eré-ìje naa ninu iṣẹ-isin Jehofa titi di igba ti a ba tó ri ẹbun ologo ti ìyè ainipẹkun gbà.—Kolose 1:10, 11.

5. Bawo ni a ṣe le jẹ alayọ ki a sì fun wa lokun fun eré-ìje ti o wà niwaju wa?

5 Lati ran wa lọwọ lati tẹpẹlẹ mọ ọn ninu eré-ìje naa, Jehofa pese agbara ti o ju eyi ti ó rekọja agbara eniyan. Nigba ti a ba ṣenunibini si wa, agbara yẹn ati imọ nipa ìdí ti a fi lanfaani lati farada inunibini nfun wa lokun. (2 Kọrinti 4:7-9) Ohunkohun ti a ba farada nititori bibọla fun orukọ Ọlọrun ati titi ipo ọba alaṣẹ rẹ̀ lẹhin jẹ idi fun ayọ ti ẹnikẹni ko le gba lọ kuro lọwọ wa. (Johanu 16:22) Eyi ṣalaye idi ti awọn apọsiteli, lẹhin ti a ti nà wọn nipasẹ aṣẹ Sanhedrin awọn Juu fun jijẹrii si awọn ohun agbayanu ti Jehofa Ọlọrun ti ṣaṣepari rẹ̀ ni isopọ pẹlu Jesu, fi kun fun ayọ “nitori pe a ti kà wọn yẹ lati jẹ ẹni ti a tabuku si nitori orukọ rẹ̀.” (Iṣe 5:41, 42, NW) Ayọ wọn kò wá lati inu inunibini naa funraarẹ ṣugbọn lati inu itẹlọrun jijinlẹ inu lọhun-un ti mímọ̀ pe awọn nwu Jehofa ati Jesu.

6, 7. Eeṣe ti saresare Kristẹni naa fi le yọ ayọ nla ani nigba ti oun ba ni ipọnju paapaa, pẹlu abajade wo sì ni?

6 Agbara agbeniro miiran ninu igbesi-aye wa ni ireti naa tí Ọlọrun ti gbeka iwaju wa. Gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ ọ: “Ẹ jẹ ki a maa gbadun alaafia pẹlu Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹni ti a tun jere ọna iwọle wa nipa igbagbọ sinu inurere ailẹtọọsi yii ninu eyi ti a duro si nisinsinyi; ki a si maa yọ ayọ, ti a gbeka ireti ogo Ọlọrun. Kii si ṣe iyẹn nikan, ṣugbọn ẹ jẹ ki a maa yọ ayọ nigba ti a ba wà ninu ipọnju pẹlu, niwọn bi a ti mọ pe ipọnju nmu ifarada jade; ifarada ẹ̀wẹ̀, ipo itẹwọgba; ipo itẹwọgba, ẹ̀wẹ̀, ireti, ireti naa kii sii sinni lọ si ìjákulẹ̀.”—Roomu 5:1-5, NW.

7 Awọn ipọnju ninu araawọn kii mayọwa, sibẹ awọn eso alalaafia ti wọn nmu jade lẹhin naa nṣe bẹẹ. Awọn eso wọnyi ni ifarada, ipo ojurere, ireti, ati imuṣẹ ireti yẹn. Ifarada niha ọdọ wa yoo ṣamọna si gbigba ojurere atọrunwa. Nigba ti a ba ni ojurere Ọlọrun, a le fi igbọkanle nireti fun imuṣẹ awọn ileri tí oun ti ṣe. Ireti yii mu wa wà loju ipa ọna titọ o sì nfun wa niṣiiri labẹ ipọnju titi di igba ti ireti naa di eyi ti a muṣẹ.—2 Kọrinti 4:16-18.

Alayọ Ni Awọn Wọnni Ti Wọn Farada!

8. Eeṣe ti sáà iduro yii kii fii ṣe fifi akoko ṣofo fun wa?

8 Nigba ti a nduro de akoko ti a ti dá latọrunwa fun pinpin awọn ẹbun fun awọn saresare naa, awọn iyipada ti a nniriiri rẹ̀ wà. Iwọnyi jẹ isunwọnsii tẹmi ninu wa ti o jẹ jade lati inu didojukọ awọn idanwo pẹlu aṣeyọri si rere, wọn sì nmu wa jere ojurere lọdọ Ọlọrun. Wọn fi ohun ti a jẹ́ hàn wọn sì fun wa ni anfaani lati lo awọn animọ rere kan naa ti awọn oluṣotitọ igba atijọ, ni pataki Awofiṣapẹẹrẹ wa, Jesu Kristi fihan. Jakọbu ọmọ-ẹhin naa wi pe: “Ẹ ka gbogbo rẹ si ayọ, ẹyin ara mi, nigba ti ẹyin ba nba oniruuru idanwo pade, ni mímọ̀ gẹgẹ bi ẹyin ti mọ pe animọ igbagbọ yin yii ti a ti danwo nṣiṣẹ ifarada. Ṣugbọn ẹ jẹ ki ifarada ṣe iṣẹ rẹ pe perepere, ki ẹyin baa le pe perepere ki ẹ sì yè kooro ni gbogbo ọna, ki ẹ ma baa ṣe alaini ohunkohun.” (Jakobu 1:2-4, NW) Bẹẹni, a le reti lati ni oniruuru awọn adanwo, ṣugbọn eyi yoo ṣeranwọ lati mu wa maa mu awọn animọ titọ dagba. Awa tipa bayii fihan pe awa yoo wa ninu eré-ìje yii titi di igba ti a bá tó gba ẹbun naa, laika awọn iṣoro eyikeyii tí a bá pade sí.

9, 10. (a) Eeṣe ti awọn wọnni ti wọn nfarada adanwo fi jẹ alayọ, bawo si ni a ṣe gbọdọ dojukọ awọn idanwo? (b) Awọn wo ni alayọ igbaani, bawo si ni a ṣe le kà wá mọ wọn?

9 Abajọ, nigba naa, ti Jakọbu fi wi pe: “Alayọ ni ọkunrin naa ti nbaa niṣo ni fifarada adanwo, nitori nigba ti o ba di ẹni ti a tẹwọgba oun yoo gba ade ìyè, eyi ti Jehofa ṣeleri fun awọn wọnni ti nbaalọ ni fifẹran rẹ̀”! (Jakobu 1:12, NW) Ẹ jẹ ki a fi iṣedeedee dojukọ awọn adanwo, ki a dira pẹlu awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun ti yoo fun wa lokun lati bori wọn.—2 Peteru 1:5-8.

10 Ranti pe ọna ti Ọlọrun ngba ba wa lò kii ṣe titun tabi ṣajeji. “Awọsanma ti awọn ẹlẹrii” oluṣotitọ igba atijọ ni a bá lò ni ọna kan naa gẹgẹ bi wọn ti fi ẹ̀rí iduroṣinṣin wọn han fun Ọlọrun. (Heberu 12:1) Itẹwọgba Ọlọrun fun wọn ni a kọ silẹ ninu Ọrọ rẹ̀, a sì ka gbogbo wọn si alayọ nitori pe wọn dena ikọlu labẹ idanwo. Jakobu wi pe: “Ẹyin ara, ẹ mu awọn wolii, awọn ẹni ti wọn sọrọ ni orukọ Jehofa gẹgẹ bi apẹẹrẹ jijiya ibi ati mimusuuru. Wo o! Awa a maa pe awọn wọnni ti wọn ti farada a ni alayọ. Ẹyin ti gbọ ti ifarada Joobu ẹyin sì ti rí abayọri ti Jehofa fun un, pe Jehofa jẹ onijẹlẹnkẹ gidigidi ni ifẹni o sì jẹ alaaanu.” (Jakobu 5:10, 11, NW) A ti sọtẹlẹ pe lakooko awọn ọjọ ikẹhin lilekoko wọnyi, awọn kan yoo farahan ninu iran aye ti wọn yoo ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu iwatitọ, gan-an gẹgẹ bi awọn wolii wọnni ti ṣe ni awọn ọgọrọọrun ọdun igbaani. Inu wa kò ha dun lati jẹ awọn ẹni ti nṣe bẹẹ bi?—Daniẹli 12:3; Iṣipaya 7:9.

Gbigba Itilẹhin Lati Inu Ọrọ Oniṣiiri Jehofa

11. Bawo ni Ọrọ Ọlọrun ṣe le ran wa lọwọ lati farada a, eesitiṣe ti a kò fi gbọdọ dabii awọn ibi olokuuta ti àkàwé Jesu?

11 Pọọlu tọkasi aranṣe miiran ninu ifarada nigba ti o wi pe “nipasẹ ifarada onisuuru, ati nipasẹ iṣiri ti a ri lati inu Iwe mimọ, awa le di ireti wa mu pinpin.” (Roomu 15:4, The Twentieth Century New Testament. Otitọ naa, Ọrọ Ọlọrun, gbọdọ tagbongbo jinlẹ ninu wa ki a baa le mu idahunpada titọna jade ninu wa ni gbogbo igba. Awa ko jere rara nipa didabi ilẹ olokuuta ti a ṣapejuwe ninu owe Jesu nipa afunrugbin naa pe: “Awọn wọnyi sì ni a funrugbin sori awọn ibi olokuuta: gbara ti wọn sì ti gbọ́ ọrọ naa, wọn fi ayọ tẹwọgba a. Sibẹ wọn ko ni gbongbo ninu araawọn, ṣugbọn wọn nbaalọ fun akoko kan; nigba naa gbàrà ti ipọnju tabi inunibini bá dide nitori ọrọ naa, a mu wọn kọsẹ.” (Maaku 4:16, 17, NW) Otitọ lati inu Ọrọ Ọlọrun kò ta gbongbo jinlẹ ninu iru awọn bẹẹ; fun idi yii, ni akoko ipọnju, wọn ko le gba itilẹhin ninu rẹ̀ gẹgẹ bi orisun okun ati ireti tootọ.

12. Nipa ki ni a kò gbọdọ jẹ ẹni ti a tanjẹ nigba ti a ba ntẹwọgba ihinrere naa?

12 Olukuluku ti o tẹwọgba ihinrere Ijọba naa ko gbọdọ tan araarẹ jẹ nipa ohun ti yoo tẹle. Oun nawọ mu ipa ọna igbesi-aye kan ti yoo mu ipọnju ati inunibini wa. (2 Timoti 3:12) Ṣugbọn oun gbọdọ ka ‘gbogbo rẹ̀ sí ayọ’ lati ni anfaani fifarada oniruuru awọn adanwo fun didi Ọrọ Ọlọrun mu ṣinṣin ati sisọrọ nipa rẹ̀ fun awọn ẹlomiran.—Jakobu 1:2, 3.

13. Bawo ati fun idi wo ni Pọọlu fi layọ lori awọn Kristẹni ni Tẹsalonika?

13 Ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní, awọn aṣodisini ni Tẹsalonika ja ija igboro nitori iwaasu Pọọlu. Nigba ti Pọọlu lọ si Beroa awọn oninunibini wọnyi tẹle e débẹ̀ ki wọn baa le rú wahala pupọ sii sókè. Fun awọn oloootọ wọnni ti wọn wà lẹhin ni Tẹsalonika, apọsiteli ti a ṣe inunibini si naa kọwe pe: “Iṣẹ wa ni lati maa dupẹ lọwọ Ọlọrun nigba gbogbo nitori yin, ara, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitori pe igbagbọ yin ndagba gidigidi, ati ifẹ olukuluku yin gbogbo si araayin ndi pupọ; tobẹẹ ti awa tikaraawa nfi yin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori suuru ati igbagbọ yin ninu gbogbo inunibini ati wahala yin ti ẹyin nfarada.” (2 Tẹsalonika 1:3-5) Laika awọn ijiya lati ọwọ ọ̀tá sí, awọn Kristẹni Tẹsalonika dagba ninu awọn iwa bii ti Kristi wọn si pọ ni iye. Bawo ni iyẹn ṣe ṣeeṣe? Nitori pe wọn fa okun lati inu Ọrọ afunni niṣiiri ti Jehofa. Wọn ṣegbọran si aṣẹ Oluwa naa wọn sì sa eré-ìje naa pẹlu ifarada.—2 Tẹsalonika 2:13-17.

Fun Igbala Awọn Ẹlomiran

14. (a) Fun awọn idi wo ni a fi nbaa lọ pẹlu ayọ ninu iṣẹ-isin naa laika awọn inira sí? (b) Ki ni awa ngbadura fun, eesitiṣe?

14 Lakọọkọ nititori idalare Ọlọrun, a nfi iṣotitọ ati airahun farada awọn inira ati inunibini. Ṣugbọn idi alaimọtara-ẹni-nikan miiran wà ti a fi njuwọsilẹ fun iru awọn nǹkan bẹẹ: ki a baa le nasẹ awọn ihin Ijọba naa dé ọdọ awọn ẹlomiran ki a baa le gbe awọn akede fun Ijọba Ọlọrun pupọ sii dide lati ṣe “ipolongo itagbangba fun igbala.” (Roomu 10:10, NW) Awọn ti wọn wà lẹnu iṣẹ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun gbọdọ gbadura pe ki Oluwa ikore bukun iṣẹ wọn nipa pipese awọn akede Ijọba naa pupọ sii. (Matiu 9:38) Pọọlu kọwe si Timoti pe: “Awọn ohun ti iwọ gbọ lọdọ mi pẹlu itilẹhin ọpọ ẹlẹrii, awọn nǹkan wọnyi ni ki iwọ fi le awọn oloootọ eniyan lọwọ, ti awọn, ẹ̀wẹ̀, yoo si tootun ni kikun lati maa kọ́ awọn ẹlomiran. Gẹgẹ bi jagunjagun rere ti Kristi Jesu mu ipa tirẹ ninu jijiya ibi.”—2 Timoti 2:2, 3, NW.

15. Eeṣe ti a fi gbọdọ dari araawa bi jagunjagun ati awọn akopa “ninu eré-ìje?”

15 Jagunjagun kan ya araarẹ̀ sọtọ kuro ninu igbesi-aye onígbẹndẹ́kẹ ti awọn ara ilu ti kii ṣe ologun. Bakan naa, awa kò gbọdọ wé araawa pọ pẹlu àlàámọ̀rí awọn wọnni ti wọn ko si ninu ọmọ ogun Oluwa ṣugbọn nitootọ, ti wọn wà ni ìhà keji. Nipa bayii, Pọọlu kọwe si Timoti siwaju sii pe: “Ko si eniyan ti nṣiṣẹsin bi jagunjagun ti nfi iṣẹ òwò aye dí araarẹ̀ lọwọ, ki o baa le rí itẹwọgba ẹni naa ti o kọ orukọ rẹ̀ silẹ bii jagunjagun. Ju bẹẹ lọ, ani bi ẹnikẹni bá njijadu ninu eré-ìje, a kii dé e ni ade bikoṣe pe o ba ti jijadu ni ibamu pẹlu ofin idiwọn.” (2 Timoti 2:4, 5, NW) Ni lílàkàkà fun ijagunmolu ninu eré-ìje naa fun “ade iye,” awọn saresare gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu ki wọn sì yẹra fun ẹrù wiwuwo ati awọn ilọjupọ ti ko wulo. Ni ọna yii wọn le gbájú mọ́ mimu ihinrere igbala wa fun awọn ẹlomiran.—Jakobu 1:12; fiwe 1 Kọrinti 9:24, 25.

16. Ki ni a ko le dènà rẹ̀, ati fun anfaani ta ni a ṣe nfarada a?

16 Nitori pe a nifẹẹ Ọlọrun ati awọn ẹni bi agutan ti wọn nwa ọna lati ri i, a fi tayọtayọ farada a pẹlu ohun pupọ ki a baa le dé ọdọ awọn ẹlomiran pẹlu ihinrere igbala. Awọn ọ̀tá lè dènà wa fun wiwaasu Ọrọ Ọlọrun. Ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun ni a ko le dènà rẹ̀, sisọrọ nipa rẹ̀ fun igbala awọn ẹlomiran ni a ko sì le fi ẹwọn dè. Pọọlu ṣapejuwe fun Timoti idi ti oun fi muratan tobẹẹ lati dojukọ adanwo: “Ranti pe a ji Jesu Kristi dide kuro ninu oku o si jẹ lati inu iru ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere ti mo nwaasu; ni isopọ pẹlu eyi ti emi njiya ohun buburu titi de ìdè ẹwọn gẹgẹ bi oluṣe buburu. Bi o tilẹ ri bẹẹ, a ko de ọrọ Ọlọrun. Nitori eyi mo nbaa lọ ni fifarada ohun gbogbo nitori awọn ayanfẹ, pe ki awọn pẹlu le ri igbala ti nbẹ ni irẹpọ pẹlu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun.” (2 Timoti 2:8-10, NW) Lonii kii ṣe awọn aṣẹku kekere ti awọn wọnni ti wọn wà ni oju ila fun Ijọba ọrun nikan ni a ni lọkan ṣugbọn ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran ti Oluṣọ-agutan Rere pẹlu, Jesu Kristi, awọn ogunlọgọ ti wọn jere Paradise ilẹ-aye labẹ Ijọba Kristi.—Iṣipaya 7:9-17, NW.

17. Eeṣe ti a kò fi gbọdọ pa eré-ìje naa tì ki ni o sì nyọrisi bi a ba nba a lọ ninu eré-ìje naa titi dé opin?

17 Bi awa ba jẹ alápatì, a ki yoo ran araawa tabi ẹlomiran kankan lọwọ si igbala. Nipa fifarada a ninu eré-ìje Kristẹni naa, laika awọn iṣoro ti a nba pade si, a npa araawa mọ nigba gbogbo soju ila fun ẹbun naa a sì le ran awọn ẹlomiran lọwọ ni taarata si igbala, nigba ti a njẹ apẹẹrẹ ti okun asunniṣiṣẹ fun awọn ẹlomiran. Ohun yoowu ki o jẹ ireti wa, ti ọrun tabi ti ilẹ-aye, ẹmi ironu Pọọlu ti ‘lilepa lọ sibi opin eré-ìje naa fun ẹbun’ jẹ eyi ti o dara lati ṣafarawe.—Filipi 3:14, 15.

Fifi Iduroṣinṣin Maa Ba a Niṣo Ninu Eré-ìje Naa

18. Jijere ẹbun naa sinmi lori ki ni, ṣugbọn lati farada a titi de opin, ki ni a gbọdọ yẹra fun?

18 Dide òpin ipa ọna Kristẹni wa pẹlu ijagunmolu si idalare Jehofa ati jijere ẹbun naa ti oun ti fipamọ fun wa sinmi lori fifi iduroṣinṣin maa ba a niṣo jalẹjalẹ ẹkunrẹrẹ eré-ìje naa. Nitori naa, awa kò ni lè farada a bi a ba di ẹrù pa araawa pẹlu awọn ohun ti kii ṣiṣẹ fun ipa ọna ododo. Ani nigba ti a bá já iru awọn nǹkan bẹẹ kuro paapaa, awọn ohun ti a beere fun ṣì nbeere ohun pupọ tó lati beere fun gbogbo ipá ti a le sà. Nitori naa, Pọọlu funni nimọran pe: “Ẹ jẹ ki awa pẹlu mu gbogbo ẹrù wiwuwo ati ẹṣẹ ti o nfi tirọruntirọrun di mọ wa kuro, ẹ sì jẹ ki a fi ifarada sá eré-ìje ti a gbeka iwaju wa.” (Heberu 12:1, NW) Bii Jesu a ko gbọdọ nu ẹnu mọ awọn inira ti a nilati farada ṣugbọn ki a kà wọn sí iye taṣẹrẹ kan ti a nilati san fun ẹbun onidunnu naa.—Fiwe Roomu 8:18.

19. (a) Ọrọ idaniloju wo ni Pọọlu sọ jade ni bèbè igbesi-aye rẹ̀? (b) Gẹgẹ bi a ti sunmọ opin eré-ìje ifarada naa, idaniloju wo ni a gbọdọ ní nipa ẹ̀san rere ti a ṣeleri naa?

19 Sunmọ opin igbesi-aye rẹ̀, o ṣeeṣe fun Pọọlu lati wi pe: “Mo ti ja ija rere naa, mo ti sa eré-ìje naa de opin, mo ti pa igbagbọ mọ. Lati akoko yii lọ a ti tọju ade ododo silẹ fun mi.” (2 Timoti 4:7, 8, NW) A wà ninu eré-ìje ifarada yii lati jere ẹbun iye ayeraye. Bi ifarada wa ba dopin gan-an nitori pe eré-ìje naa jọ bi eyi ti o gùn ju ohun ti a reti lọ nigba ti a bẹrẹ rẹ̀, awa yoo kuna nigba ti a sunmọ jijere ẹ̀san rere ti a ṣeleri naa. Jẹ ki o da ọ loju. Ko si iyemeji kankan pe ẹ̀san rere naa wà nibẹ.

20. Ki ni o gbọdọ jẹ ipinnu wa titi di igba ti a ba de opin eré-ìje naa?

20 Nitori naa njẹ ki oju wa maṣe ṣaarẹ pẹlu wiwọna fun ipọnju nla lati bẹrẹ, ni mimu iparun wa fun Babiloni Nla lakọọkọ ati lẹhin naa iyooku eto-ajọ Eṣu. (2 Peteru 3:11, 12) Ni oju iwoye gbogbo awọn ami ti wọn ni ijẹpataki ti nbẹ layiika wa, njẹ ki awa maa wo iwaju ninu igbagbọ. Njẹ ki awa di agbara ifarada wa ni àmùrè, njẹ ki awa si maa fi akinkanju baa lọ ninu eré-ìje naa tí Jehofa Ọlọrun gbe ka iwaju wa, titi di igba ti a ba dé opin ti a sì jere ẹbun alayọ naa, si idalare Jehofa nipasẹ Jesu Kristi.

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Iru eré-ìje wo ni Kristẹni kan gbọdọ murasilẹ fun?

◻ Eeṣe ti ayọ fi ṣe pataki tobẹẹ ninu sisa eré-ìje naa?

◻ Fun awọn idi pataki wo ni a fi nbaa lọ ninu iṣẹ isin naa laika inira sí?

◻ Eeṣe ti a ko fi gbọdọ pa eré-ìje naa ti Ọlọrun gbeka iwaju wa tì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bi ẹni pe ninu eré-ìje ẹlẹmii ẹṣin kan, awọn Kristẹni gbọdọ farada a

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ni nínàgà fun “ade ìyè,” awọn saresare gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́