ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/15 ojú ìwé 14-18
  • Ẹ Duro Pẹkipẹki Ti Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Duro Pẹkipẹki Ti Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Idahunpada Ni Ibamu Pẹlu Ete Ọlọrun
  • Awọn Apẹẹrẹ Ti Diduro Pẹkipẹki Ti Jehofa
  • Jesu, Awofiṣapẹẹrẹ Wa
  • Gbigbe Awọn Ẹrù-ìnira Wa Ka Jehofa
  • Adura ati Ireti Lati Maa Baa Lọ
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Láìdabọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ẹ Máa Gbé Ọwọ́ Ìdúróṣinṣin Sókè Nínú Àdúrà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/15 ojú ìwé 14-18

Ẹ Duro Pẹkipẹki Ti Jehofa

“Ẹ ni iforiti ninu adura.”—ROOMU 12:12, NW.

1. Ki ni ifẹ-inu Jehofa nipa adura, iṣiri wo ni apọsiteli Pọọlu sì fi funni nipa gbigbadura?

JEHOFA ni ‘Ọlọrun ti nfi ireti fun’ gbogbo awọn eniyan rẹ̀ oluṣotitọ. Gẹgẹ bi “Olugbọ adura,” oun nfetisilẹ si awọn ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ wọn fun iranlọwọ lati jere ireti alayọ ti ó gbé ka iwaju wọn. (Roomu 15:13; Saamu 65:2, NW) Ati nipasẹ Ọrọ rẹ̀, Bibeli, ó fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ niṣiiri lati wá si ọdọ rẹ̀ nigbakigba ti wọn bá fẹ. Oun wà nibẹ nigba gbogbo, ni fifẹ lati gba aniyan inu lọhun-un julọ wọn. Nitootọ, o fun wọn niṣiiri lati “ni iforiti ninu adura” ati lati “maa gbadura laisinmi.”a (Roomu 12:12; 1 Tẹsalonika 5:17, NW) Ó jẹ́ ifẹ-inu Jehofa pe ki gbogbo awọn Kristẹni maa ké pe e ninu adura ni gbogbo ìgbà, ni titu ọkan-aya wọn jade si i ati ni ṣiṣe bẹẹ ni orukọ Ọmọkunrin rẹ̀ olufẹ ọwọn, Jesu Kristi.—Johanu 14:6, 13, 14.

2, 3. (a) Eeṣe ti Ọlọrun fi ṣí wa leti lati “foriti i ninu adura”? (b) Idaniloju wo ni a ní pe Ọlọrun nfẹ ki a gbadura?

2 Eeṣe ti Ọlọrun fi fun wa ni iṣileti yii? Nitori awọn ikimọlẹ ati ẹrù iṣẹ igbesi-aye lè rìn wá mọlẹ tobẹẹ gẹẹ debi pe awa lè gbagbe lati gbadura. Tabi awọn iṣoro lè bo wa mọlẹ ki ó si mu wa dawọ yíyọ̀ ninu ireti duro ki a sì dakẹ gbigbadura. Ni oju iwoye awọn nǹkan wọnyi, a nilo irannileti ti nfun wa niṣiiri lati gbadura ati lati sunmọ orisun iranlọwọ ati itunu, Jehofa Ọlọrun wa pẹkipẹki gan-an.

3 Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe pe: “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun yoo sì sunmọ yin.” (Jakobu 4:8) Bẹẹni, Ọlọrun kò ga fiofio ju tabi jinna ju lati gbọ awọn ọrọ ti a darí si i, laika ipo aipe eniyan wa sí. (Iṣe 17:27) Siwaju sii, oun kii ṣe onídàágunlá ati aláìbìkítà. Onisaamu naa wi pe: “Oju Oluwa [“Jehofa,” NW] nbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn.”—Saamu 34:15; 1 Peteru 3:12.

4. Bawo ni a ṣe lè ṣakawe itẹtisilẹ Jehofa si adura?

4 Jehofa beere fun adura. A lè fi eyi wé ipejọpọ kan nibi ti awọn eniyan ti ó pọ ti nba araawọn sọrọ. Iwọ wà nibẹ, ni fifeti silẹ si bi awọn ẹlomiran ti nsọrọ. Ipa tirẹ jẹ ti ẹni ti nṣakiyesi. Ṣugbọn lẹhin naa ẹnikan yiju si ọ, ó pe orukọ rẹ, o sì doju awọn ọrọ rẹ kọ ọ. Eyi gba afiyesi rẹ ni ọna akanṣe kan. Bakan naa, Ọlọrun ntẹtisilẹ nigba gbogbo si awọn eniyan rẹ̀, nibikibi yoowu ki wọn wà. (2 Kironika 16:9; Owe 15:3) Nitori naa oun ngbọ awọn ọrọ wa, ni kikiyesi lọna idaabobo ati lọna onifẹẹ, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a bá kepe orukọ Ọlọrun ninu adura, afiyesi rẹ̀ ni a gbà, oun si pa afiyesi pọ si wa nisinsinyi ni ọna ti ó ṣe kedere. Nipa agbara rẹ̀, Jehofa tilẹ lè ṣawari ki ó si mọ adura ẹ̀bẹ̀ ti a ko sọ jade ti eniyan gbà ninu awọn ibi kọlọfin ti o farasin ninu ọkan-aya ati ero-inu rẹ̀. Ọlọrun mu un da wa loju pe oun yoo fà sunmọ gbogbo awọn wọnni ti wọn fi otitọ inu kepe orukọ rẹ ti wọn sì nwa ọna lati duro pẹkipẹki ti i.—Saamu 145:18.

Idahunpada Ni Ibamu Pẹlu Ete Ọlọrun

5. (a) Ki ni imọran naa “foriti ninu adura” fihan nipa awọn adura wa? (b) Bawo ni Ọlọrun ṣe ndahun awọn adura?

5 Imọran naa lati ni iforiti ninu adura fihan pe Jehofa nigba miiran lè yọnda wa lati maa baa lọ ni gbigbadura nipa ọran kan fun ìgbà kan ṣaaju ki idahun rẹ̀ tó ṣe kedere. A tilẹ lè ni itẹsi lati ṣaarẹ nipa bibẹ Ọlọrun fun ojurere tabi iṣeun ifẹ ti ó lè jọ bii pe a nilo gidigidi ṣugbọn ti a fi falẹ fun igba gigun. Fun idi yii, Jehofa parọwa fun wa ki a maṣe juwọsilẹ fun iru itẹsi eyikeyii bẹẹ ṣugbọn lati maa baa lọ ni gbigbadura. A gbọdọ maa baa lọ ni bibẹbẹ lọdọ rẹ̀ nipa awọn aniyan wa, nini igbọkanle pe oun bọwọ fun adura wa ti yoo sì kaju aini wa gidi, kii wulẹ ṣe ohun ti a ti lè dàrò. Laiṣiyemeji Jehofa Ọlọrun nmu awọn ẹ̀bẹ̀ wa wà deedee ni ibamu pẹlu awọn ete rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, awọn miiran ni a lè nipa le lori nipa ibeere wa. A lè fi ọran naa wé ti baba kan ti ọmọkunrin rẹ̀ beere fun kẹ̀kẹ́. Baba naa mọ pe bi oun bá ra kẹ̀kẹ́ naa fun ọmọkunrin yẹn, ọmọkunrin rẹ̀ miiran yoo fẹ́ ọ̀kan pẹlu. Niwọn ìgbà ti ọmọkunrin kan ti lè kere ju fun kẹ̀kẹ́ kan, baba naa lè pinnu lati maṣe ra eyikeyii ni akoko yẹn gan-an. Ni ọna ti o farajọra, ninu imọlẹ ete rẹ̀ ati pipinnu akoko awọn ọran, Baba wa ọrun pinnu ohun ti o darajulọ fun wa ati fun awọn ẹlomiran nitootọ.—Saamu 84:8, 11; fiwe Habakuku 2:3.

6. Apejuwe wo ni Jesu fifunni niti ọran adura, ki si ni iforiti ninu adura fihan?

6 Eyi ti ó yẹ fun afiyesi ni akawe ti Jesu funni niti aini fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ‘lati maa gbadura nigba gbogbo ki wọn ma sì saarẹ.’ Opó kan, ti kò ṣeeṣe fun lati ri idajọ-ododo gbà, foriti i ninu ibeere rẹ̀ lọdọ eniyan adajọ kan titi di ìgbà ti ó tó ri idajọ-ododo gbà nikẹhin. Jesu fikun un pe: “Dajudaju, nigba naa, Ọlọrun kò ha ni mu ki a ṣe idajọ-ododo fun awọn ayanfẹ rẹ̀?” (Luuku 18:1-7, NW) Iforiti ninu adura fi igbagbọ wa han, igbarale Jehofa wa, imuratan lati duro pẹkipẹki ti i ati lati gba adura ẹ̀bẹ̀ wa, ni fifi abajade le e lọwọ.—Heberu 11:6.

Awọn Apẹẹrẹ Ti Diduro Pẹkipẹki Ti Jehofa

7. Bawo ni a ṣe lè ṣafarawe igbagbọ Ebẹli ninu diduro pẹkipẹki ti Jehofa?

7 Bibeli kún fun awọn akọsilẹ adura tí awọn iranṣẹ Ọlọrun gbà. Iwọnyi ni ‘a ti kọ fun kíkọ́ wa, pe nipa suuru ati itunu iwe mimọ ki a lè ni ireti.’ (Roomu 15:4) Ireti wa ni a fun lokun nipa gbigbe apẹẹrẹ diẹ ti awọn wọnni ti wọn duro pẹkipẹki ti Jehofa yẹwo. Ebẹli rú ẹbọ itẹwọgba si Ọlọrun, ati bi o tilẹ jẹ pe a kò rohin adura kankan, oun laiṣiyemeji fi ọran lọ Jehofa ninu adura ki a ba a lè tẹwọgba ẹbọ rẹ̀. Heberu 11:4 wi pe: “Nipa igbagbọ ni Ebẹli rú ẹbọ si Ọlọrun ti ó sàn ju ti Keeni lọ, nipa eyi ti a jẹrii rẹ̀ pe olododo ni.” Ebẹli mọ nipa ileri Ọlọrun ni Jẹnẹsisi 3:15, ṣugbọn ni ifiwera pẹlu oun ti a mọ nisinsinyi, ohun ti ó mọ kere pupọ. Sibẹ, Ebẹli gbegbeesẹ lori imọ ti ó ni. Bẹẹni lonii, diẹ lara awọn wọnni ti wọn ṣẹṣẹ nfifẹ han ninu otitọ Ọlọrun kò tii ni imọ pupọ tó sibẹ, ṣugbọn wọn ngbadura wọn si nlo imọ ti wọn ni lọna rere julọ, gẹgẹ bi Ebẹli ti ṣe. Bẹẹni, wọn ngbegbeesẹ ninu igbagbọ.

8. Eeṣe ti a fi lè nidaaniloju pe Aburahamu duro pẹkipẹki ti Jehofa, ibeere wo sì ni a gbọdọ beere lọwọ araawa?

8 Iranṣẹ Ọlọrun oluṣotitọ miiran ni Aburahamu, “baba gbogbo awọn ti ó gbagbọ.” (Roomu 4:11) Lonii, ju ti igbakigba ri lọ, a nilo igbagbọ lilagbara, a sì nilati gbadura ninu igbagbọ, gẹgẹ bi Aburahamu ti ṣe. Jẹnẹsisi 12:8 wi pe ó mọ “pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa [“Jehofa,” NW] ó sì kepe orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW].” Aburahamu mọ orukọ Ọlọrun ó sì lo o ninu adura. Leralera oun fi otitọ inu foriti i ninu adura, ni pipe “orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ayeraye.” (Jẹnẹsisi 13:4; 21:33) Aburahamu nkepe Ọlọrun ninu igbagbọ eyi ti a mọ ọn daradara fun. (Heberu 11:17-19) Adura ran Aburahamu lọwọ lati maa baa lọ ni yíyọ̀ gidigidi ninu ireti Ijọba naa. Awa ha ntẹle apẹẹrẹ Aburahamu ti fiforiti i ninu adura bi?

9. (a) Eeṣe ti awọn adura Dafidi fi ṣanfaani pupọ fun awọn eniyan Ọlọrun lonii? (b) Ki ni ó le jẹ jade lati inu gbigbadura wa gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe lati duro pẹkipẹki ti Jehofa?

9 Dafidi tayọ niti fiforiti i ninu adura, awọn Saamu rẹ̀ sì ṣapejuwe ohun ti adura gbọdọ jẹ́. Fun apẹẹrẹ, awọn iranṣẹ Ọlọrun lè gbadura lọna bibojumu fun iru awọn nǹkan bii igbala tabi idande (3:7, 8; 60:5, NW), amọna (25:4, 5), aabo (17:8), idariji ẹṣẹ (25:7, 11, 18), ati ọkan-aya mimọgaara (51:10, NW). Nigba ti Dafidi nimọlara ipọnloju, ó gbadura pe: “Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀.” (86:4) A lè gbadura bakan naa fun ayọ ọkan-aya, ni mímọ̀ pe Jehofa fẹ pe ki a yọ̀ ninu ireti wa. Dafidi duro pẹkipẹki ti Jehofa ó sì gbadura pe: “Ọkàn mi ntọ ọ lẹhin gírígírí: ọwọ ọtun rẹ ni o gbe mi ró.” (63:8) Awa yoo ha duro pẹkipẹki ti Jehofa, gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe bi? Bi a ba ṣe bẹẹ, oun yoo dì wá mú bakan naa.

10. Awọn ironu aitọ wo ni Asafu onisaamu naa ní ní akoko kan, ṣugbọn ki ni ó wá mọ daju?

10 Bi awa bá nilati duro pẹkipẹki ti Jehofa, a nilati yẹra fun ṣiṣe ìlara awọn ẹni buburu nitori igbesi-aye onidẹra ati ọlọ́rọ̀ alumọọni wọn. Asafu onisaamu naa ni akoko kan nimọlara pe kò wulo kankan lati ṣiṣẹsin Jehofa, nitori awọn ẹni buburu “wà ni irọwọrọsẹ titilọ gbére.” Sibẹ, ó moye pe ironu oun kò tọna ati pe awọn ẹni buburu wà “lori ilẹ yíyọ́.” Ó mọ̀ daju pe kò si ohun ti ó dara ju diduro pẹkipẹki ti Jehofa, ó sì ṣalaye araarẹ fun Ọlọrun ni ọna yii pe: “Emi wà pẹlu rẹ nigba gbogbo; iwọ ti di ọwọ ọtun mi mú. Nitori, wo o! awọn ẹni naa gan-an ti nsa sẹhin kuro ni ọdọ rẹ yoo ṣegbe. . . . Ṣugbọn niti emi, sisunmọ Ọlọrun pẹkipẹki dara fun mi. Ninu Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ ni mo ti fi ìsádi mi si, lati polongo gbogbo awọn iṣẹ rẹ.” (Saamu 73:12, 13, 18, 23, 27, 28, NW) Dipo ṣiṣe ilara igbesi-aye onidẹra ti awọn ẹni buburu, awọn eniyan ti wọn kò ni ireti, ẹ jẹ ki a ṣafarawe Asafu ni diduro pẹkipẹki ti Jehofa.

11. Eeṣe ti Daniẹli fi jẹ apẹẹrẹ rere ti diduro pẹkipẹki ti Jehofa, bawo sì ni a ṣe lè farawe e?

11 Daniẹli foriti i pẹlu ipinnu ninu adura, ani ni oju ewu ti wiwa ninu iho kinniun nitori ṣiṣai naani awọn ikaleewọ ti a faṣẹ si lori adura. Ṣugbọn Jehofa “rán angẹli rẹ̀, ó sì di awọn kinniun naa lẹnu,” ni yíyọ Daniẹli ninu ewu. (Daniẹli 6:7-10, 22, 27) Daniẹli ni a bukun gidigidi nipa fifi ti o fi ori ti i ninu adura. Awa pẹlu ha foriti i ninu adura, paapaa nigba ti a ba dojukọ atako si iwaasu Ijọba wa?

Jesu, Awofiṣapẹẹrẹ Wa

12. (a) Ni ibẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, apẹẹrẹ wo ni Jesu gbekalẹ niti ọran adura, bawo sì ni eyi ṣe lè ṣanfaani fun awọn Kristẹni? (b) Ki ni adura awokọṣe Jesu ṣipaya nipa adura?

12 Gan-an lati ibẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ ti ilẹ-aye, Jesu ni a rí ti o gba adura. Iṣarasihuwa rẹ̀ ti ó kun fun adura nigba iribọmi rẹ̀ gbe apẹẹrẹ rere kalẹ fun awọn wọnni ti wọn nṣe iribọmi ninu omi ni akoko ode oni. (Luuku 3:21, 22) Ẹnikan lè gbadura fun iranlọwọ Ọlọrun lati ṣe ohun ti iribọmi inu omi ṣapẹẹrẹ. Jesu tun ran awọn ẹlomiran lọwọ lati tọ Jehofa lọ ninu adura. Ni akoko kan nigba ti ó wà ni ibikan bayii ti ó ngbadura, ọ̀kan lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ fun un lẹhin-ọ-rẹhin pe: “Oluwa, kọ́ wa bi a tií gbadura.” Jesu lẹhin naa sọ ohun ti a mọ ni gbogbogboo si adura awokọṣe naa, ninu eyi ti itotẹlera awọn koko ọrọ fihan pe orukọ ati ete Ọlọrun ni a gbọdọ fun ni afiyesi akọkọ. (Luuku 11:1-4) Nipa bayii, ninu awọn adura wa a nilati pa oju iwoye ati ìwà deedee mọ́, ni kika “awọn ohun ti ó ṣe pataki ju” sí. (Filipi 1:9, 10, NW) Niti tootọ, awọn akoko aini akanṣe wà tabi nigba ti a nilati bojuto iṣoro pato kan. Bii Jesu, awọn Kristẹni lè lọ sọdọ Ọlọrun ninu adura lati beere fun okun lati ṣe awọn iṣẹ-ayanfunni kan bayii tabi lati dojukọ awọn adanwo tabi ewu kan ni pataki. (Matiu 26:36-44) Nitootọ, adura ara ẹni lè kó o fẹrẹẹ jẹ gbogbo apa-iha igbesi-aye patapata mọra.

13. Bawo ni Jesu ṣe fi ijẹpataki gbigbadura fun awọn ẹlomiran han?

13 Nipa apẹẹrẹ rere rẹ̀, Jesu fi ijẹpataki gbigbadura nititori awọn ẹlomiran han. Ó mọ pe awọn ọmọ-ẹhin oun ni a o koriira ti a o sì ṣenunibini si, ani gẹgẹ bi a ti ṣe si oun. (Johanu 15:18-20; 1 Peteru 5:9) Nitori naa, oun bẹ Ọlọrun “lati maa ṣọ wọn nitori ẹni buburu naa.” (Johanu 17:9, 11, 15, 20, NW) Ati ni mímọ adanwo akanṣe ti o wà niwaju fun Peteru, ó sọ fun un pe: “Mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ rẹ ki o ma yẹ̀.” (Luuku 22:32) Ẹ wo bi ó ti ṣanfaani tó bi a ba foriti ninu gbigbadura fun awọn arakunrin wa, ni rironu nipa awọn ẹlomiran kii sì ṣe nipa awọn iṣoro ati ifẹ tiwa funraawa nikan!—Filipi 2:4; Kolose 1:9, 10.

14. Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu duro pẹkipẹki gan-an ti Jehofa jalẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ ori ilẹ-aye, bawo sì ni a ṣe lè farawe e?

14 Jalẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, Jesu foriti i ninu adura, ni diduro pẹkipẹki gan-an ti Jehofa. (Heberu 5:7-10) Ni Iṣe 2:25-28, (NW), apọsiteli Peteru ṣayọlo Saamu 16:8 ó sì fisilo fun Oluwa Jesu Kristi pe: “Nitori Dafidi wi nipa rẹ̀, ‘Mo ni Jehofa nigba gbogbo niwaju oju mi; nitori pe oun wà ni ọwọ ọtun mi ki emi má baa le mì lae.” Awa lè ṣe bakan naa. A lè gbadura pe ki Ọlọrun duro pẹkipẹki ti wa, a sì le fi igbọkanle wa ninu Jehofa han nipa fifi ero ori mu un wà niwaju oju wa nigba gbogbo. (Fiwe Saamu 110:5; Aisaya 41:10, 13.) Lẹhin naa awa yoo yẹra fun oniruuru iyọnu gbogbo, nitori pe Jehofa yoo tì wa lẹhin, a ki yoo sì bì ṣubu lae.

15. (a) Nititori ki ni awa kò gbọdọ kuna lae lati foriti i ninu adura? (b) Ikilọ wo ni a fi funni nipa idupẹ wa?

15 Njẹ ki awa maṣe kuna lae lati fi ọpẹ wa han si Jehofa fun gbogbo iwarere iṣeun rẹ̀ fun wa, bẹẹni, “inurere ailẹtọọsi titayọ ti Ọlọrun,” eyi ti ó ní ẹbun Ọmọkunrin rẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ irapada fun awọn ẹṣẹ wa ninu. (2 Kọrinti 9:14, 15, NW; Maaku 10:45; Johanu 3:16; Roomu 8:32; 1 Johanu 4:9, 10) Nitootọ, ni orukọ Jesu, ẹ maa “dupẹ nigba gbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba.” (Efesu 5:19, 20; Kolose 4:2; 1 Tẹsalonika 5:18) A gbọdọ ṣọra ki a maṣe jẹ ki idupẹ wa fun ohun ti a ní di òbu nitori pe ọwọ wa dí tobẹẹ fun ohun ti a kò ni tabi nitori awọn iṣoro ti ara ẹni.

Gbigbe Awọn Ẹrù-ìnira Wa Ka Jehofa

16. Nigba ti awọn ẹrù-ìnira kan bá nda wa laamu, ki ni a gbọdọ ṣe?

16 Titẹpẹlẹmọ adura fi ijinlẹ ifọkansin wa han. Nigba ti a ba kepe Ọlọrun, iyọrisi rẹ̀ lori wa jẹ daradara ani ṣaaju ki idahun kan tó wá lati ọdọ rẹ̀. Bi ẹrù-ìnira kan ba nda ọkan wa laamu, a lè duro pẹkipẹki ti Jehofa nipa titẹle imọran naa pe: “Gbé ẹrù-ìnira rẹ ka Jehofa funraarẹ, oun funraarẹ yoo sì mu ọ duro.” (Saamu 55:22, NW) Nipa gbigbe gbogbo awọn ẹrù-ìnira wa—awọn aniyan, idaamu ọkan, ijakulẹ, ibẹru, ati bẹẹ bẹẹ lọ—ka Ọlọrun, pẹlu igbagbọ kikun ninu rẹ̀, a ngba ọkan-aya piparọrọ, “alaafia Ọlọrun ti ó ju imọran gbogbo lọ.”—Filipi 4:4, 7; Saamu 68:19; Maaku 11:24; 1 Peteru 5:7.

17. Bawo ni a ṣe lè gba alaafia Ọlọrun?

17 Alaafia Ọlọrun yii ha nwa ni kiakia bi? Bi o tilẹ jẹ pe a lè ri itura diẹ gba lọgan, ohun ti Jesu sọ nipa gbigbadura fun ẹmi mimọ jasi otitọ nihin-in pẹlu: “Ẹ maa baa niṣo ni bibeere, a o sì fifun yin; ẹ maa baa niṣo ni wiwakiri, ẹyin yoo sì ri; ẹ maa baa niṣo ni kíkànkùn, a o sì ṣi i silẹ fun yin.” (Luuku 11:9-13, NW) Niwọn bi ẹmi mimọ ti jẹ ipasẹ ọna ti a ngba taari aniyan dànù, a nilati foriti i ninu bibeere fun alaafia Ọlọrun ati iranlọwọ rẹ̀ niti awọn ẹrù-ìnira wa. A lè ni idaniloju pe nipa titẹpẹlẹmọ ọn ninu adura, awa yoo ri itura ati iparọrọ ọkan-aya ti a fẹ gba.

18. Ki ni Jehofa nṣe fun wa bi a kò ba mọ ohun ti a o gbadura fun ninu ipo kan bayii niti gidi?

18 Ṣugbọn ki ni bi a kò bá mọ ohun ti a o gbadura fun niti gidi? Awọn ìmí-ẹ̀dùn inu lọhun-un wa saba maa ńwà laiṣee sọ nitori pe a kò loye ipo wa lọna kikun, tabi ohun ti a o gbekalẹ niwaju Jehofa rú wa loju. Nihin-in ni ẹmi mimọ ti lè ṣalagbawi fun wa. Pọọlu kọwe pe: “Nitori a kò mọ bi a tií gbadura gẹgẹ bi ó ti yẹ: ṣugbọn ẹmi tikaraarẹ nfi irora ti a kò lè fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa.” (Roomu 8:26) Bawo ni ó ṣe jẹ́ bẹẹ? Ninu Ọrọ Ọlọrun ni awọn asọtẹlẹ ati adura onimiisi ti ó niiṣe pẹlu ipo wa wà. Oun njẹ ki iwọnyi ṣalagbawi fun wa, ki a sọ ọ lọna bẹẹ. Oun tẹwọgba iwọnyi gẹgẹ bi ohun ti a o gbadura fun kiki bi a ba mọ itumọ wọn ninu ọran wa, ati bakan naa oun nmu wọn ṣẹ.

Adura ati Ireti Lati Maa Baa Lọ

19. Eeṣe ti adura ati ireti yoo fi maa baa lọ titilae?

19 Adura si Baba wa ọrun yoo maa baa lọ titilae, ni pataki niti idupẹ fun ayé titun ati gbogbo awọn ibukun rẹ̀. (Aisaya 65:24; Iṣipaya 21:5) Awa yoo tun maa baa lọ lati yọ̀ ninu ireti, nitori pe ireti ni iru awọn ọna kan yoo wà titilae. (Fiwe 1 Kọrinti 13:13.) Awọn ohun titun tí Jehofa yoo mu jade nigba ti oun kò ba wà labẹ Sabaati ọjọ isinmi ti ó gbekalẹ funraarẹ siha ilẹ-aye, a kò tilẹ lè finu ro o. (Jẹnẹsisi 2:2, 3) Fun gbogbo ayeraye, oun yoo ni awọn ohun iyanu onifẹẹ niwaju fun awọn eniyan rẹ̀, ọjọ-ọla sì ni awọn ohun titobilọla fun wọn ni ọna ṣiṣe ifẹ-inu rẹ̀.

20. Ki ni ó gbọdọ jẹ́ ipinnu wa, eesitiṣe?

20 Pẹlu iru ireti amọkanyọ bẹẹ niwaju wa, njẹ ki gbogbo wa duro pẹkipẹki ti Jehofa nipa iforiti ninu adura. Njẹ ki awa maṣe dakẹ didupẹ lọwọ Baba wa ọrun fun gbogbo awọn ibukun wa. Nigba ti ó ba ya, awọn ifojusọna wa ni ọwọ yoo tẹ̀ pẹlu ayọ, ani rekọja ohun ti a ti lè finu rò tabi fojusọna fun, nitori pe Jehofa lè “ṣe lọpọlọpọ yanturu gan-an rekọja gbogbo ohun ti awa beere fun tabi finu rò lọ.” (Efesu 3:20, NW) Ni oju iwoye eyi, nigba naa, ẹ jẹ ki a fi gbogbo iyin ati ogo ati ọpẹ titi ayeraye fun Jehofa Ọlọrun wa, “Olugbọ adura”!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ni ibamu pẹlu Webster’s New Dictionary of Synonyms, “Foriti ni gbogbo ìgbà fẹrẹẹ tumọsi animọ fifanimọra kan; ó ṣagbeyọ kíkọ̀ lati di ẹni ti ó rẹwẹsi nipa ikuna, iyemeji, tabi awọn iṣoro, ati ilepa oniduuroṣinṣin tabi ti titẹpẹlẹmọ ète tabi ìdáwọ́lé kan.”

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Eeṣe ti a fi nilati foriti ninu adura?

◻ Ki ni a kẹkọọ lati inu awọn apẹẹrẹ adura ṣaaju akoko Kristẹni?

◻ Ki ni apẹẹrẹ Jesu fi kọni nipa adura?

◻ Bawo ni a ṣe lè gbe ẹrù-ìnira wa ka Jehofa pẹlu iyọrisi wo sì ni?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Daniẹli foriti i ninu adura laika ìhalẹ̀mọ́ni ti sisọ ọ sinu iho kinniun si

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́