Iṣẹ-ojiṣẹ Kan Fun Ọ Bi?
JEHOFA ti fi iwa ọlawọ rẹ̀ han ninu ṣiṣepese ayé lọna pipe fun igbadun iwalaaye wa. Oun fi iwa ọlawọ jẹ́ ki awọn ipese wọnyi wà ani lẹhin ti Adamu ati Efa ṣọtẹ. Ju eyiini lọ, oun ti fi ifẹ rẹ̀ titayọ han ni rírán Ọmọkunrin rẹ̀ lati gba awọn eniyan onigbagbọ la kuro lọwọ ìjábá ẹṣẹ.—Matiu 5:45; Johanu 3:16.
Bawo ni a ṣe lè dahunpada si iru ifẹ bẹẹ? Jesu sọ pe a gbọdọ fẹ́ Jehofa Ọlọrun wa pẹlu gbogbo ọkan-aya, ọkàn, ero inu, ati agbara wa. Eyi dabaa pe a jẹ ẹ́ ni gbese ijọsin ati iṣotitọ wa ati pe a gbọdọ gbe igbesi-aye wa ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀.—Maaku 12:30; 1 Peteru 4:2.
Ṣugbọn ki ni ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun ni ninu? Iṣẹ-isin kan ha wà ti a lè ṣe fun un—iṣẹ-ojiṣẹ kan ti a nilati ṣajọpin ninu rẹ̀ bi?
Aini Kan Fun Awọn Ojiṣẹ
Awọn ṣọọṣi ti ṣi awọn eniyan lọna niti bi wọn ṣe lè jọsin ki wọn sì ṣiṣẹsin Ọlọrun. Sibẹ, Bibeli fihan pe isin tootọ kanṣoṣo ni ó wà, “Oluwa kan, igbagbọ kan, bamtisim kan; Ọlọrun kan ati Baba eniyan gbogbo.” Jesu sọ pe: “Awọn olujọsin tootọ yoo jọsin Baba ni ẹmi ati ni otitọ.” Nitori bẹẹ a gba wọn niyanju pe: “Gbogbo yin nilati maa sọrọ ni ifohunṣọkan, ati . . . ki iyapa ki o maṣe sí laaarin yin.”—Efesu 4:3-6; Johanu 4:23; 1 Kọrinti 1:10, NW.
Iṣina niti ohun ti ó jẹ isin tootọ bẹrẹ ni Edeni nigba ti Satani pe ẹtọ ipo ọba-alaṣẹ Jehofa nija nipa gbigbe ibeere dide si ọna iṣakoso Ọlọrun. (Jẹnẹsisi 3:1-6, 13) Satani nisinsinyi wa mu atako yii si Ọlọrun duro pẹlu awọn ẹkọ ayédèrú ti a tankalẹ nipasẹ awọn ẹlẹtan ojiṣẹ isin ti wọn “npa araawọn dà si ojiṣẹ ododo.” Nitori naa Bibeli sọ pe: “Olufẹ, ẹ maṣe gba gbogbo ẹmi [“ọrọ onimiisi,” NW] gbọ, . . . nitori awọn wolii èké pupọ ti jade lọ sinu aye.”—2 Kọrinti 11:14, 15, NW; 1 Johanu 4:1.
Ó muni layọ pe, Ọlọrun ti gbe awọn igbesẹ lati yanju ariyanjiyan iṣakoso yii. Bi o ti ran Ọmọkunrin rẹ̀ lati ra iran eniyan pada, oun nisinsinyi ti fi Jesu jẹ Ọba Ijọba Ọlọrun ti ọrun, pẹlu aṣẹ lati pa Satani ati awọn wolii, tabi awọn ojiṣẹ rẹ̀ run. Eyi yoo mu un daju pe ifẹ Ọlọrun ni a ṣe ni aye, si ibukun ayeraye awọn eniyan onigbọran.—Daniẹli 7:13, 14; Heberu 2:9.
Satani ti ṣokunkun bo awọn otitọ wọnyi. (2 Kọrinti 4:4) Nipa bayii, aini wà fun wa lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun, ni titudii aṣiri awọn èké Satani ati jijẹrii si otitọ. Jehofa kò fi ipa mu wa sinu iṣẹ isin yii. Oun fẹ ki awa, gẹgẹ bii ti Jesu, fi araawa ṣe ọrẹ atinuwa lati inu imọriri fun un ati fun ohun ti oun ti ṣe fun wa.—Saamu 110:3; Heberu 12:1-3.
Iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni
Jesu “nla gbogbo ilu ati ileto lọ, o nwaasu, o nro ihin ayọ Ijọba Ọlọrun.” (Luuku 8:1) O tun kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati jẹ ojiṣẹ bí oun ó sì ran wọn jade lati waasu. (Matiu 10:1-14, 27) Lẹhin naa, o fi aṣẹ fun wọn lati maa ba iṣẹ ojiṣẹ naa lọ de awọn opin ilẹ-aye.—Matiu 28:19, 20; Iṣe 1:8.
Iṣẹ aṣẹ yii sinmi lori awọn Kristẹni tootọ, ẹmi Ọlọrun sì nsun wọn lati waasu. Gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni Pẹntikọsi 33 C.E., gbogbo awọn ti wọn tẹwọgba ihinrere naa tẹwọgba ẹrù iṣẹ lati jẹwọ igbagbọ wọn nigbangba.—Iṣe 2:1-4, 16-21; Roomu 10:9, 13-15.
Bi o ti wu ki o ri, ọpọlọpọ eniyan kò le ri araawọn gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun. Peter, ọ̀kan ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wi pe: “Awọn ọkunrin ni ilẹ Germany saba maa nro o pe ó rẹlẹ si ipo ọla wọn lati sọrọ nipa isin. ‘Awọn alufaa ni ó ni iyẹn lati ṣe,’ ni wọn sọ.” Gẹgẹ bi Tony, ojihin iṣẹ Ọlọrun fun ọpọ ẹwadun ti sọ, awọn eniyan ni ilẹ England ti wi pe: “Ohun ti ẹ nsọ dara, mo sì rò pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ eniyan daradara. Ṣugbọn lati lọ waasu lati ẹnu ọna de ẹnu ọna—emi ko lè ṣe iyẹn ṣáá.” Ben ṣe ikẹkọọ Bibeli fun ìgbà diẹ pẹlu ọkunrin ara Nigeria kan ẹni ti o wi fun un pe: “Emi kò le fi araami han ni wiwaasu nigbangba lati ile de ile; ṣugbọn mo lè fun ijọ yin ni owo lati ṣeranwọ fun awọn ti wọn nfẹ lati ṣe iyẹn.” Bẹẹni, pupọ eniyan ni ó ṣalaini igbagbọ ati idaniloju ti a nilo fun iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni.
Bi o tilẹ ri bẹẹ, iwaasu ni gbangba ni ẹrù iṣẹ gbogbo ẹni ti ó wa ninu ijọ Kristẹni, laika ọjọ ori tabi ẹ̀yà ẹ̀dá sí. Kii ṣe kiki fun awọn alagba ati awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, awọn ti wọn ‘mu ipo iwaju,’ ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn Kristẹni lapapọ. Olukuluku ni a gba niyanju: “Ẹ jẹ ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigba gbogbo, eyiini ni, eso ètè ti nṣe ikede ni gbangba fun orukọ rẹ̀. . . . Ẹ jẹ onigbọran si awọn ti nmu ipo iwaju laaarin yin.”—Heberu 13:15, 17, NW.
Nigba ti ó nba awujọ oniruuru awọn eniyan sọrọ ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu wi pe: “Kii ṣe gbogbo ẹni ti npe mi ni Oluwa, Oluwa, ni yoo wọle Ijọba ọrun; bikoṣe ẹni ti nṣe ifẹ ti Baba mi ti nbẹ ni ọrun.” Ni akoko miiran oun fihan pe ṣiṣe ifẹ Ọlọrun yoo ni wiwaasu fun awọn alaigbagbọ ninu. Awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nrọ ọ lati dawọ wiwaasu fun awọn ara Samaria kan duro ki oun ba lè jẹun, ṣugbọn oun wi pe: “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o ran mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.”—Matiu 7:21; Johanu 4:27-38.
Ó Ha Gbọdọ Jẹ́ Iṣẹ Igbesi-aye Rẹ Bi?
Awọn eniyan saba maa nyan lati lepa ounjẹ ati ọrọ̀ nipa ti ara. Ṣugbọn ṣaaju ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu gba awọn olugbọ rẹ̀ nimọran lodisi lilepa iru awọn nǹkan wọnyi pẹlu aniyan. “Ṣugbọn,” oun wi pe, “ẹ to iṣura jọ fun araayin ni ọrun . . . Ẹ tete maa wá ijọba Ọlọrun naa, ati ododo [Ọlọrun].”—Matiu 6:20, 33.
Kikọkọ wa Ijọba naa ko tumọsi jijẹki awọn ire miiran ṣe pataki ju iṣẹ-ojiṣẹ wa lọ. Sibẹsibẹ, ṣiṣe eyi ko tumọsi titi ohun gbogbo miiran sode. Fun apẹẹrẹ, Bibeli gbaninimọran lati maṣe ṣá awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe ti idile tì. A ni iru iṣẹ aigbọdọmaṣe bẹẹ bii ti gbogbo eniyan. Lati ṣá wọn tì jẹ́ lati huwa ni ọna kan ti ó tako igbagbọ Kristẹni. (1 Timoti 5:8) Bi o tilẹ ri bẹẹ, a gbọdọ ṣe gbogbo eyi ti a ba lè ṣe lọna ti ó tọ ninu iṣẹ ojiṣẹ naa bi a ti nbojuto awọn ẹrù iṣẹ miiran ni ọna ti ó wà deedee.
Jesu wi pe: “A o sì waasu ihinrere ijọba yii . . . lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì de.” (Matiu 24:14) Ayika ọrọ asọtẹlẹ yẹn fi imuṣẹ rẹ si ọjọ wa. Lati 1914 ihinrere naa ni pe Ijọba naa ni a ti fun ni agbara lati gbegbeesẹ nititori ipo ọba-alaṣẹ Jehofa ati lodi si Satani ati ayé rẹ̀. (Iṣipaya 11:15-18) A gbọdọ ronu gidigidi lori awọn ohun ti eyi lè wá yọrisi. Opin yoo de, a sì gbọdọ mu iṣẹ iwaasu naa ṣẹ ṣaaju igba naa. Ọpọlọpọ ẹmi ni o wa ninu ewu; awa lè ṣeranwọ lati gba pupọ ninu wọn là.
Ẹ Nàgà Fun Iṣẹ-ojiṣẹ Kan Ti Ó Tubọ Kunrẹrẹ Sii
Ọpọlọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn ya wakati mẹwaa tabi ju bẹẹ lọ sọtọ ni oṣooṣu fun ṣiṣajọpin ihinrere naa pẹlu awọn ẹlomiran. Ẹgbẹẹgbẹrun nlo wakati meji tabi ju bẹẹ lọ ni ọjọ kan ni wiwaasu gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, ti awọn miiran sì nṣiṣẹsin titilọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna alakooko kikun ati aṣaaju-ọna akanṣe. Wọn mọriri ijẹ kanjukanju iṣẹ yii wọn sì nfẹ lati kó ipa kikun julọ ti o le ṣeeṣe lati sọ ọ di ṣiṣe ki opin ayé alailayọ yii to dé.
Iwọ ha jẹ alaapọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa bayii bi? Nigba naa naga fun ipin kikun sii ninu iṣẹ-isin naa. Mu igboṣaṣa rẹ sunwọn sii ninu iwaasu ati kikọni, ni gbigbiyanju lati ṣe aṣepari pupọ sii ninu iṣẹ ojiṣẹ naa. Bi iwọ ba wà ni ipo lati di aṣaaju-ọna, ṣe bẹẹ. Bi ipo rẹ lootọ ko ba gbà ọ laaye lati ṣe bẹẹ, nigba naa gbà awọn ti wọn lè ṣee niyanju lati naga fun iṣẹ isin yii.
Bi iwọ kii ba ṣe Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ si Jehofa, maṣe sọ pe iṣẹ-ojiṣẹ naa kò wà fun ọ. Ọkunrin miiran ti njẹ Peter, onimọ ẹrọ kan, fi tokuntokun lodisi ki iyawo rẹ̀ ṣajọpin ihinrere naa pẹlu awọn ẹlomiran. “Bawo ni mo ṣe lè jẹ ki iyawo mi maa waasu lati ile de ile?” ni oun yoo beere. Lẹhin ọpọlọpọ ọdun ṣiṣakiyesi idaniloju rẹ̀ ti o fidii mulẹ nipa otitọ Ọrọ Ọlọrun, oun pinnu lati kẹkọọ Bibeli pẹlu. Nisinsinyi, bii iyawo rẹ̀, oun jẹ́ ojiṣẹ ihinrere naa, ti o ti ya araarẹ si mimọ, ti a si ti bamtisi.
Nitori naa maṣe dena araarẹ ninu ẹrù iṣẹ ṣiṣiṣẹsin Jehofa. A gbà ọ́ niyanju lati kẹkọọ Bibeli ki o sì darapọ pẹlu awọn Kristẹni tootọ ni awọn ipade wọn. Eyi yoo ràn ọ́ lọ́wọ́ lati mu igbesi-aye rẹ wà ni ibamu pẹlu ododo Ọlọrun ati lati gbe igbagbọ ti ó lagbara sii ró ninu awọn ete rẹ. Bi iwọ ba ni ilọsiwaju ninu eyi, iwọ yoo tootun lati jẹ́ ojiṣẹ Ọlọrun. Iwọ nigba naa yoo ni anfaani lati ṣajọpin ninu mimu aṣẹ Jesu yii ṣẹ: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ si sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin ki ẹ maa kọ́ wọn lati kiyesi ohun gbogbo ti mo ti paṣẹ fun yi.”—Matiu 28:19, 20, NW.
Bẹẹni, iṣẹ-ojiṣẹ kan wà ti iwọ lè ṣajọpin ninu rẹ̀, ó sì jẹ́ kanjukanju ju ti igbakigba ri lọ fun ọ lati ṣe bẹẹ.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Nọọsi kan ti ó ni idile kan lati bojuto wi pe: “Mo nrinrin-ajo ni eyi ti o ju wakati kan ni ojoojumọ lọ si ile iwosan nibi ti mo ti nṣiṣẹ, nitori naa mo ronu pe emi kò lè ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ. Ṣugbọn mo farabalẹ ṣeto awọn igbokegbodo mi lati ṣajọpin ninu iṣẹ-isin pápá ni kutukutu ni ojoojumọ ṣaaju lilọ si ibi iṣẹ, laaarin awọn akoko isinmi, ati awọn ọjọ ti nko ba sí lẹnu iṣẹ. Ẹ lè woye ayọ mi nigba ti, ni opin oṣu kan, emi ti lo 117 wakati ninu wiwaasu! Mo fi 263 iwe irohin sode, 22 asansilẹ owo fun awọn iwe irohin ti mo si lè bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli 3.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Michael ni awọn ọmọ kekeke meje, oun sì ni iṣẹ ṣiṣeegbarale kan ni ile-ẹkọ giga kan ni ilẹ Nigeria. Oun tun jẹ alagba kan ninu ijọ Kristẹni. Oun ṣajọpin oju iwoye kan naa pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn Ẹlẹ́rìí:
“Mo wo iṣẹ-ojiṣẹ naa gẹgẹ bi iṣẹ igbesi-aye mi mo si maa nsaba ranti pe Pọọlu wi pe: ‘Emi gbìn, Apolo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun nii mu ibisi wa.’ Emi ati iyawo mi ‘gbìn’ lakooko ijiroro ranpẹ nipa ihinrere naa lati ile de ile. A ‘bomirin’ nipa pipada lọ si ọdọ awọn ti wọn fifẹhan lati kọ́ wọn lati inu Bibeli, gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ pe ki a ṣe. Ikẹkọọ Bibeli ni ọsọọsẹ ti ran eyi ti iye wọn pọ pupọ lọwọ—ninu awọn ọran kan gbogbo idile—lati wa si imọ otitọ.”