Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Ki ni idile Kristẹni kan gbọdọ ṣe bi ọmọ wọn ba nilati lọ si ile-ẹkọ kan nibi ti itọni onisin ti jẹ́ kàn-ńpá?
Awọn Kristẹni obi kò ni ifẹ ninu jijẹ ki a gbin ẹkọ isin èké sinu awọn ọmọ wọn. Ṣugbọn awọn ipo kan lè wà nibi ti awọn ọmọ kò lè kọ̀ lati wà ninu yàrá ikawe kan nibi ti a ti nkọni ni isin, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko ni ṣajọpin ninu awọn iṣe ati ayẹyẹ isin èké.
Aburahamu ọ̀rẹ́ Ọlọrun fi awokọṣe rere kan lélẹ̀ fun awọn ọmọ niti itọni ti isin. Ó tọ́ awọn ọmọ rẹ̀ dagba ni Kenaani, nibi ti a ti yi wọn ká pẹlu ìṣìnà isin ati awọn aṣa “mímọ́” akoniniriira. (Fiwe Ẹkisodu 34:11-15; Lefitiku 18:21-30; Deutaronomi 7:1-5, 25, 26; 18:9-14.) Bi o tilẹ ri bẹẹ, oun ni orisun itọni isin fun idile rẹ̀. Ọlọrun ni idaniloju pe Aburahamu yoo “fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki wọn ki o maa pa ọna Oluwa [“Jehofa,” NW] mọ́ lati ṣe ododo.”—Jẹnẹsisi 18:19.
Gẹgẹ bi ọdọ kan, Jesu naa janfaani lati inu itọni idile ati ti ijọ ninu ijọsin tootọ. Nipa bayii, ó “npọ ni ọgbọn, ó sì ndagba, ó sì wà ni ojurere ni ọdọ Ọlọrun ati eniyan.”—Luuku 2:52.
Ni awọn apa ibi pupọ julọ ni ayé, awọn ọdọ Kristẹni ngba imọ ẹkọ ti ayé ni awọn ile-ẹkọ ti gbogbogboo. Kii ṣe gbogbo ohun ti a kọni ni ó wà ni ibamu kikun pẹlu otitọ Bibeli ati otitọ ti a filelẹ. Fun apẹẹrẹ, pupọ iran awọn ọdọ Kristẹni ni wọn ti lọ si awọn kilaasi ẹkọ nipa imọ ijinlẹ tabi ẹkọ imọ ijinlẹ nipa awọn ohun alaaye gẹgẹ bii apakan ipa ọna ẹkọ wọn deedee. Ọpọ julọ ninu wọn ti tipa bẹẹ di ẹni ti a ṣiju rẹ̀ paya si awọn aba ero ori ẹfoluṣọn ti ngbodekan ati awọn oju iwoye ti ó wemọ ọn nipa awọn orisun iwalaaye lori ilẹ-aye ti o jẹ “adanida.”
Bi o ti wu ki o ri, iṣijupaya yii kò yí awọn ọdọ Kristẹni wọnyi pada di alagbawi ẹfoluṣọn ti kò gbọlọrungbọ. Eese? Nitori pe ni ile ati ni awọn ipade Kristẹni, wọn ti gba isọfunni pipeye ṣaaju ti a gbeka ori Bibeli ti ó jẹ Ọrọ Ọlọrun ti a misi, eyi ti ó ṣeranlọwọ lati kọ ‘agbara imoye wọn lati mọ iyatọ laaarin ẹ̀tọ́ ati aitọ.’ (Heberu 5:14, NW) Pupọ awọn obi ni wọn ti ṣe ikẹkọọ lori ẹfoluṣọn pẹlu awọn ọmọ wọn eyi ti a kaju lọna wiwa deedee ninu idipọ iwe afunnilokun naa Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?a Bi a ti tipa bayii mura wọn silẹ, awọn ọmọ ile-ẹkọ wọnyi ko gba itọni yàrá ikawe nipa ẹfoluṣọn gẹgẹ bi ohun ti ó ṣee gbagbọ. Sibẹ wọn lè fihan ninu awọn idahun wọn ninu yàrá ikawe ati ninu idanwo pe wọn ntẹtisilẹ ti wọn sì le kọ́ awọn kulẹkulẹ ti a gbekalẹ. Awọn miiran tilẹ ni anfaani lati pese awọn alaye miiran ni ibamu pẹlu awọn otitọ ti a gbekalẹ ninu Bibeli lati ọwọ Ẹlẹdaa eniyan.—1 Peteru 3:15.
Bi o ti wu ki o ri, ki ni niti awọn akoko kilaasi ti a yasọtọ fun itọni nipa isin adugbo ti ó wọpọ tabi koda isin lapapọ?
Ko dabi ẹnipe iru itọni bẹẹ ni a o gbekalẹ laipọn sapakan, bii isọfunni lasan. Olukọ naa tilẹ le maa ṣe isin yẹn ki o sì tipa bẹẹ gbiyanju lati lo agbara idari lori ero inu ati ọkan-aya awọn akẹkọọ naa. Nitori naa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yan ki a yọnda awọn ọmọ wọn kuro ni awọn kilaasi itọni isin. Eyi le jẹ ki awọn ọmọ wọn le lo akoko ile-ẹkọ ni ọna ti o tubọ lere ninu lati pari awọn iṣẹ ẹkọ kilaasi miiran ti a fun wọn tabi lati ṣe ikẹkọọ ni ibi àkójọ iwe kíkà ile-ẹkọ naa.
Sibẹsibẹ, ni awọn ibomiran, iru awọn ibeere bẹẹ ni a ti kọ̀; ile-ẹkọ naa tabi awọn alaṣẹ ilu tilẹ le beere pe ki gbogbo awọn ọmọ wá ki wọn si pari ipa ọna ẹkọ isin kan ki wọn ba le di ẹni ti ó kẹkọọyege. Idile kọọkan gbọdọ pinnu funraawọn ohun ti wọn yoo ṣe ninu ọran yẹn.
Awọn kan ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun ni igba ti o ti kọja ti wà ninu awọn ipo ti wọn kò nifẹẹ si nibi ti wọn ti nilati farada didi ẹni ti a ṣipaya si awọn iṣe tabi awọn ikọnilẹkọọ ti isin nigba ti wọn ṣì wà ni aduroṣinṣin ti Ọlọrun tootọ naa. Iyẹn ni o ti lè jẹ ọran naa nipa Mose. A tọ ọ dagba gẹgẹ bi ọmọ-ọmọ Farao ti Ijibiti, oun ni a sì ‘kọ́ ni gbogbo ọgbọn ara Ijibiti.’ (Iṣe 7:20-22) Eyi ti o lè ṣeeṣe ki o ni ninu de iwọn kan awọn igbagbọ ati àṣà ti isin ti ó wọpọ ni Ijibiti. Ṣugbọn Mose ni a daabobo nipasẹ itọni ti o daraju ti o ṣe kedere pe o rigba lọdọ awọn idile rẹ̀ ati boya awọn ọmọ Heberu miiran.—Ẹkisodu 2:6-15; Heberu 11:23-26.
Tun ṣagbeyẹwo apẹẹrẹ ti awọn ọdọ Heberu mẹta naa, awọn olubakẹgbẹ Daniẹli, awọn ti a fun ni awọn itọni akanṣe ni Babiloni ti a sì fi ṣe oṣiṣẹ ijọba. (Daniẹli 1:6, 7) Wọn ko ni ominira lati ṣe tabi lati kọ̀ ohunkohun ti wọn ba fẹ. Ni akoko kan Ọba Nebukadinesa paṣẹ pe ki wọn pejọpọ pẹlu awọn oloye miiran ni ibi ère wura ti oun gbekalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, nibi ti a o ti ṣe awọn iṣe ifọkansin orilẹ-ede ẹni. Bawo ni awọn Heberu mẹta wọnyi ṣe dahunpada? A lè ni idaniloju pe wọn ki bá ti yan lati maṣe wà nibẹ, ṣugbọn eyiini ko ṣeeṣe.b Sibẹ wọn duro gẹgẹ bi oluṣotitọ si awọn igbagbọ wọn ati si Ọlọrun Olodumare. Ẹ̀rí ọkàn oniwa-bi-Ọlọrun wọn yọnda fun wọn lati wà nibẹ nigba ti wọn kọ pẹlu ipinnu lati maṣe kopa, tabi lọwọ ninu iṣe eyikeyii ti ó jẹ́ ti isin èké lẹnikọọkan.—Daniẹli 3:1-18.
Nigba ti ó ba pọndandan fun gbogbo awọn akẹkọọ lati wà ni kilaasi isin kan ati boya lati lè kẹkọọ debi ki wọn lè yege ninu awọn idanwo, awọn ọmọ lati inu idile awọn Kristẹni tootọ lè wa nibẹ, bi awọn mẹta wọnyẹn ṣe wà labẹ aṣẹ Nebukadinesa. Ṣugbọn awọn ọdọ Kristẹni yoo fi Ọlọrun si ipo kìn-ín-ní. Ki yoo si idi fun wọn lati pe gbolohun kọọkan ti ko tọna ti a ba sọ nija tabi aṣa kọọkan ti ko ba iwe mimọ mu ti awọn yooku lọwọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi awọn Heberu mẹta naa ko ti gbiyanju lati yọnusọ sii nigba ti awọn ti o kù ntẹriba fun ère wura naa. Sibẹsibẹ, awọn ọdọ Kristẹni funraawọn ko ni ṣajọpin ninu awọn iṣe ti ijọsin, awọn adura ajumọgba, awọn orin isin, ati iru awọn nǹkan bẹẹ.
Ó yẹ ki awọn ọdọ wọnyi lo araawọn de gongo ni awọn akoko miiran lati gba imọ ti ngbeniro ‘lati inu awọn ikọwe mimọ ti wọn lè sọ wọn di ọlọgbọn fun igbala nipasẹ igbagbọ ninu Kristi Jesu.’ (2 Timoti 3:15) Nipasẹ ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ọmọ wọn, awọn obi ni gbogbo igba gbọdọ maa fi iṣọra ṣabojuto ohun ti awọn itọni kilaasi naa ni ninu. Eyi yoo ran awọn agbalagba Kristẹni lọwọ lati ri ohun ti a nilati ṣatunṣe rẹ̀ tabi muṣe kedere lati inu Bibeli ki awọn ọmọ wọn ma baa di ẹni ti a dà lọkan rú tabi ṣì lọna.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Bibeli ko sọ nǹkankan nipa pe Daniẹli wà ni pẹtẹlẹ Dura. Boya ipo giga rẹ̀ ninu ijọba ni ó jẹ ki a yọọda rẹ lati maṣe lọ si ibẹ.