Kikore Awọn Olujọsin
APỌSITELI Johanu ni a fun ni iran kan nipa awọn iṣẹlẹ ti ń mi ayé tí yoo ṣẹlẹ “ni ọjọ Oluwa.” Ó rí Jesu Kristi Oluwa ti ọrun ti ń gẹṣin lọ si ogun jíjà ododo, ti a fi akọ-ẹṣin funfun kan yaworan rẹ̀—ó “ń ṣẹgun ati lati pari iṣẹgun rẹ̀.” Ohun akọkọ ti ó ṣe ni lati fi olori ọ̀tá Ọlọrun, Satani, sọko kuro ninu awọn ọrun si ayika ilẹ-aye yii. Satani dahunpada nipa kiko iyọnu ajakalẹ bá araye pẹlu ipakupa, ìyàn, ati aisan alailẹgbẹ, ti a fi awọn olugẹṣin ati ẹṣin iṣapẹẹrẹ wọn ṣapejuwe—aláwọ̀ pupa, dudu, ati ràndánràndán. (Iṣipaya 1:10, NW; 6:1-8; 12:9-12) Awọn ègbé wọnyi búgbàù lakọọkọ ni ọdun 1914 ó sì ti gasoke sii lati ìgbà yẹn wá. Laipẹ, a o dé ogogoro opin wọn nipa ohun ti Jesu ṣapejuwe gẹgẹ bi “ipọnju nla . . . , iru eyi ti kò sí lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ yii wá di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo sì sí.”—Matiu 24:3-8, 21.
Bawo ni awọn olujọsin Jehofa yoo ṣe maa baa lọ ni akoko yẹn? Iṣipaya ori 7, ẹsẹ 1 si 10 (NW), sọ nipa awọn ẹgbẹ́ ogun angẹli ti ‘ń di’ ẹfuufu iparun ‘mú ṣinṣin’ titi di ìgbà ti a bá tó kó awọn olujọsin wọnyi jọ. Laaarin akoko naa lati 1914, awọn ti ó kẹhin lori ilẹ-aye ninu Isirẹli tẹmi, ti iye wọn papọ jẹ́ 144,000, ni a kójọ. Ati lẹhin naa “sì wò ó! ogunlọgọ nla kan, ti eniyan kankan kò lè kaye, lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede ati ẹ̀yà ati eniyan ati ahọ́n.” Ogunlọgọ nla yii ti pọ̀ tó araadọta-ọkẹ bayii. Wọn duro ni ẹni itẹwọgba niwaju ìtẹ́ Ọlọrun nitori lilo igbagbọ ninu ẹ̀jẹ̀ Jesu ti ń ranipada, ẹni ti a pa bi ọdọ agutan alaimọwọmẹsẹ kan. “Wọn sì nbaa lọ ni kikigbe ni ohùn kíkan, wi pe: ‘Gbese ọpẹ fun igbala ni a jẹ Ọlọrun wa, ti ó jokoo lori itẹ, ati Ọdọ agutan naa.’” Awọn olujọsin onitara wọnyi ń baa lọ ni wiwi pe “Maa bọ!” fun awọn miiran sibẹ, awọn ti a kojọ tẹle e fun igbala la “ipọnju nla” já.—Iṣipaya 7:14-17; 22:17, NW.
“Lọ Si Gbogbo Ilẹ-Aye”
A lè sọ nipa awọn olujọsin onifọkansin wọnyi pe: “Ìró wọn jade lọ si gbogbo ilẹ-aye, ati awọn ọrọ wọn si ikangun ilẹ-aye gbígbé.” (Roomu 10:18, NW) Iṣẹ aṣekara wọn ni a ti bukun pẹlu eso pípẹtẹrí. Fun apẹẹrẹ:
Mexico rohin 335,965 awọn olujọsin Jehofa agbekankanṣiṣẹ nisinsinyi, ibisi ti o fẹrẹẹ tó ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan ni kiki ọdun mẹta pere! Ki ni o fa imugbooro nla kan bẹẹ? Akọsilẹ ti ó tẹle e lè ṣeranwọ lati ṣalaye. Ọdọmọkunrin kan ti njẹ Aurelio ni olutọju awọn ohun eelo ijọsin ninu ṣọọṣi Katoliki kan. Ni gbogbo ìgbà ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ba ti wá sinu abule yẹn, yoo lu aago ṣọọṣi lati fi kó irẹwẹsi bá ẹnikẹni kí wọn maṣe fetisilẹ si wọn. Nigba ti ó yá ó ra Jerusalem Bible ti Katoliki kan o sì bẹrẹ sii ka a, ṣugbọn kò loye rẹ̀. Lẹhin naa ni ọjọ kan ó ri ọrẹ rẹ̀ kan pẹlu ẹ̀dà Bibeli New World Translation ni abiya rẹ̀. Aurelio ba ọrẹ rẹ̀ wí, ati ni sisọ fun un pe Bibeli rẹ̀ jẹ́ èké, ó mu un lọ si ile oun tikaraarẹ lati fi Bibeli “tootọ” han an. Ọrẹ rẹ̀ wi pe: “Ka Ẹkisodu 20,” lẹhin naa ni ó sì fi ibẹ silẹ.
Ni bibẹrẹ pẹlu ori 1, olutọju awọn ohun eelo ijọsin ṣọọṣi naa ka Ẹkisodu lọ titi ti ó fi dé ori 20, ẹsẹ 4 ati 5. Àyà fò ó nipa ohun ti Bibeli Katoliki rẹ̀ wi nipa awọn ère. Lẹhin Mass ni ọjọ Sunday ti ó tẹle e, ó dojú awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ iwe naa nipa ère kọ alufaa. Lakọọkọ alufaa naa sọ pe oun funra oun wulẹ ń fọ̀wọ̀ fun awọn ère ni; oun kò jọsin wọn. Ni riri pe eyi kò tẹ Aurelio lọrun, alufaa naa fẹsun kikẹkọọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan an. Aurelio sẹ́ eyi ṣugbọn ó fikun un pe, “Nisinsinyi emi yoo ṣe bẹẹ!”
Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí tun wá si abule naa, Aurelio kàn wọn lara ó sì bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu wọn. Ó dawọ ṣiṣiṣẹ ninu ṣọọṣi duro ati ni oṣu mẹta ó tootun lati ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ile akọkọ ti ó bẹwo ni ti alufaa, ẹni ti ó ṣoro fun lati gba oju rẹ̀ gbọ nigba ti ó rí olutọju awọn ohun eelo ijọsin ṣọọṣi tẹlẹri naa ninu ila iṣẹ oniwaasu Ijọba kan. Alufaa naa halẹ mọ ọn pẹlu iyọkurolẹgbẹ, ṣugbọn Aurelio sọ fun un pe eyi ki yoo pọndandan niwọn bi oun ti fi ṣọọṣi naa silẹ ṣaaju akoko naa. Igbesẹ onigboya rẹ̀ fun ọpọlọpọ awọn ara abule naa ti wọn ti ń kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣaaju akoko yii niṣiiri. Aurelio ati awọn 21 miiran lati inu abule yẹn ni a bamtisi ni apejọpọ agbegbe ti ó tẹle e. Idagbasoke ni agbegbe yii yárakánkán gan-an debi pe kiki alagba kanṣoṣo ni ó wà larọọwọto lati ṣatunyẹwo awọn ibeere fun awọn olunaga fun anfaani iribọmi pẹlu awujọ yii.
“Ìró Wọn Jade Lọ”
Kò sí àjàbọ́ kankan kuro ninu iwaasu Ijọba naa. Katoliki ara Italy kan saba maa ń binu ni gbogbo ìgbà ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ba ti lọ sọdọ rẹ̀. Nitori naa nigba ti ile iṣẹ rẹ̀ gbé e lọ si Singapore, ó nimọlara pe nikẹhin a kò ni yọ oun lẹnu lati ọdọ wọn mọ́. Ṣugbọn si iyalẹnu rẹ̀, awọn Ẹlẹ́rìí wà nibẹ pẹlu. Nitori naa ó ra aja rírorò meji lati gbeja ko awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn wá tẹle e. Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí meji bẹ ile rẹ̀ wo, awọn aja wọnni bẹ́ jade gìjà. Awọn obinrin naa, ti a ti dáyàfò sá fun iwalaaye wọn, ni fiforile ibi ọtọọtọ ni orita ọna kan. Bi ọ̀kan lara awọn aja naa ti le e bá, ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí naa fi igbekuta gbá iwe pẹlẹbẹ meji mu ninu apo rẹ̀ ó sì tì í si ẹnu aja naa ti ó là silẹ. Nipa bayii, ó dawọ lile e duro, ó yipada, ó sì sare ṣẹ́ṣẹ̀ṣẹ́ pada sile.
Ni ọsẹ ti ó tẹle e, awọn Ẹlẹ́rìí meji kan naa ń ṣe ipadabẹwo si ile kan ni odikeji opopona naa. Olówó awọn aja naa wà ninu ọgba rẹ̀, ati pẹlu iyanu, ó ki awọn obinrin naa ó sì kesi wọn wọnu ile rẹ̀. Ó sọ fun wọn pe oun kò tii bá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọrọ tabi ka itẹjade wọn eyikeyii rí. Ṣugbọn o ti jẹ́ iyalẹnu fun un lati ri awọn iwe pẹlẹbẹ naa lẹnu ọ̀kan lara awọn aja rẹ̀. Ni alẹ yẹn o ti ka awọn iwe pẹlẹbẹ naa wọn sì ti fun un ni ìwúrí gidigidi. Bi o tilẹ jẹ pe oun ti jẹ́ Katoliki kan ni gbogbo igbesi-aye rẹ̀, ó sọ ifẹ rẹ̀ lati kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jade.
Niwọn bi a ti gbe ọkunrin naa pada si Italy, awọn iṣeto ni a ṣe fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati kẹkọọ pẹlu rẹ̀ nibẹ. Bi oun ati aya rẹ̀ ti bẹrẹ sii lọ si awọn ipade, alufaa pariṣi fi ibinu doju ihalẹmọni kọ wọn. Nigba ti ẹnikan fi ina si ọgba wọn, tọkọtaya naa já gbogbo ìdè pẹlu ṣọọṣi naa. Ọkunrin yii sọ nisinsinyi pe: “Mo ti ń jẹ́rìí fun ọpọlọpọ awọn mẹmba idile mi nitori pe mo fẹ ki wọn mọ pe Jehofa ni Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa.”
“Si Ìkangun Ilẹ-Aye Gbígbé”
Iriri miiran lati ìkangun ilẹ-aye kan fi bi a ṣe mọriri ihin-iṣẹ Ijọba naa tó ati bi ó ṣe nṣeranwọ lati yi igbesi-aye pada han. Nigba ti ó ń lọ si ìdálẹ́kọ̀ọ́ awọn alaboyun, Ẹlẹ́rìí kan ni Australia pade obinrin kan ti ó ni iwa ibajẹ pupọ, ti ó tilẹ ń kọ̀ lati dáwọ́ siga mimu duro lakooko iloyun rẹ̀. Ẹlẹ́rìí naa ni iṣarasihuwa rẹ̀ dà láàmú gan-an. Ó ṣẹlẹ pe wọn bi ọmọ wọn lakooko kan naa ninu yara ìgbẹ̀bí kan naa, nitori naa wọn ni aye lati sọrọ. Ó jọ bii pe obinrin naa ti ni ọpọlọpọ iṣoro lakooko ọmọde rẹ̀, ati nisinsinyi igbeyawo rẹ̀ wà ni bèbè tituka. Nitori naa, lẹhin jijade kuro ni ile-iwosan, Ẹlẹ́rìí naa bẹ obinrin naa wò ó sì bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ̀, ni lilo iwe naa Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ.
Ọkọ obinrin naa ti ń gbadura si Ọlọrun pe ki oun ri isin tootọ, ni fifi níwọ̀n-ìgbà-tí naa kun un pe: “Niwọn bi kii ba tii ṣe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!” Sibẹ, nigba ti ó ri mọ̀ pe aya oun ń kẹkọọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí, ó bẹrẹ sii beere awọn ibeere a sì ké sí i lati darapọ ninu ikẹkọọ naa. Eyi ni ó ṣe, ati laipẹ ó bẹrẹ sii lọ si awọn ipade ijọ. Nisinsinyi, tọkọtaya naa ni a ti bamtisi, ati ni kedere ipo igbeyawo wọn ti sunwọn sii lọpọlọpọ.
Awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile ti a gbekari iru iwe ikẹkọọ bẹẹ ti yọrisi kiko ọpọlọpọ awọn olujọsin titun jọ. Ni awọn ilẹ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nilati koju awọn iyipada afọtẹṣe, ogun abẹle, tabi awọn ikalọwọko ijọba, igbokegbodo ikẹkọọ Bibeli inu ile ti pọ sii. Ogun abẹle ru soke ni Angola fun ọpọlọpọ ọdun, awọn Ẹlẹ́rìí sì jiya inunibini ati inira gidigidi. Ni ibẹrẹ ọdun ti ó kọja, awọn irohin fihan pe, ni ipindọgba, akede kọọkan ń dari iye ti ó fẹrẹẹ to ikẹkọọ Bibeli inu ile mẹta, ṣugbọn awọn akede naa ni iwe ikẹkọọ Bibeli ti kò pọ. Awọn alaboojuto arinrin-ajo bẹ awujọ kekere kan wò ni ọjọ kọọkan, ni ṣiṣeto fun iṣẹ isin pápá ni ọsan ati awọn ipade ni irọlẹ kọọkan. Ẹ wo ayọ ti ó jẹ́ nigba ti ikoguntira dopin ti 42 tọọnu iwe ikẹkọọ Bibeli ti a nilo gidigidi sì dé lati South Africa! Dajudaju, ifẹ awọn arakunrin wọnni yoo “tubọ pọ gidigidi siwaju ati siwaju pẹlu imọ pipeye ati imoye kikun,” gẹgẹ bi o ti ṣeeṣe fun wọn nisinsinyi lati “rí àrídájú awọn ohun ti wọn ṣe pataki ju.” (Filipi 1:9, 10, NW) Iru iṣiri wo ni ó jẹ fun awọn wọnni ti wọn ni ọpọ yanturu aranṣe ikẹkọọ Bibeli lọwọ lati lo ẹkunrẹrẹ anfaani ipese ti Jehofa fi ore-ọfẹ tobẹẹ ṣe!—1 Timoti 4:15, 16.
Ayọ awọn olujọsin oluṣotitọ wọnyi ran wa leti awọn ọrọ Jesu ninu Iwaasu ori Oke pe: “Alayọ ni awọn wọnni ti aini wọn nipa tẹmi njẹ lọkan, niwọn bi ijọba awọn ọrun ti jẹ́ tiwọn. . . . Alayọ ni awọn wọnni ti a ti ṣe inunibini si nitori ododo, niwọn bi ijọba awọn ọrun ti jẹ́ tiwọn. . . . Ẹ maa yọ̀ ki ẹ sì fò soke fun ayọ, niwọn bi èrè yin ti pọ ninu awọn ọrun.” (Matiu 5:3-12) Ẹ wo ikore ti a ti ń kójọ ni Angola bayii!
Ni awọn agbegbe miiran ninu ayé, awọn ikalọwọko lori igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a tun ti dẹwọ rẹ̀ tabi mu kuro. Jesu sọ ni ọjọ rẹ̀ pe: “Loootọ ni ikore pọ, ṣugbọn awọn alágbàṣe [“awọn oṣiṣẹ,” NW] kò tó nǹkan.” (Matiu 9:37) Ẹ wo bi eyi ti jẹ́ otitọ tó lonii! Aini fun awọn oṣiṣẹ wà nibẹ nigba gbogbo. Inu wa dun pe ijọsin wa wémọ́ kikojọpọ ninu ikore naa. Kò si ayọ ti ó pọ ju kankan ti a lè ri lori ilẹ-aye lonii ju iṣẹ-isin onifọkansin ti ń meso jade si Jehofa Ọlọrun.
Bi o ti wu ki o ri, ki ni ó sun awọn olujọsin Jehofa si iru ayọ ati itara bẹẹ? Awa yoo ri i.