ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/1 ojú ìwé 18-23
  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹru Oniwa-bi-Ọlọrun Ṣẹgun
  • Gbígbégbèésẹ̀ Ni Ibẹru Jehofa
  • Fẹ́ Rere, Koriira Buburu
  • Bẹru Jehofa Ki O Sì Yin in Logo
  • Fi Ogo Fun Ọlọrun Titi Ayeraye
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bẹ̀rù Jèhófà, Kí o Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Àǹfààní Bíbẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/1 ojú ìwé 18-23

Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀

“Ta ni ki yoo bẹru rẹ nitootọ, Jehofa, ti kì yoo sì yin orukọ rẹ logo, nitori pe iwọ nikan ni aduroṣinṣin?”—IṢIPAYA 15:4, NW.

1, 2. (a) Bawo ni Jehofa ṣe ṣí ibode ibu omi ọrun silẹ ni 1991? (b) Iriri igbesi-aye wo ni o sun ojihin iṣẹ Ọlọrun oluṣotitọ kan lati funni ni imọran naa pe: “Bẹru Jehofa”? (Tun wo 1991 Yearbook, oju-iwe 187 si 189.)

JEHOFA ‘ṣí ibode ibu omi ti awọn ọrun silẹ ó sì tú ibukun jade niti gidi titi di ìgbà ti kò fi si aini kankan mọ.’ Awọn ọrọ wọnni ni a lè fisilo leralera lẹẹkansii fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni awọn akoko aipẹ yii. (Malaki 3:10, NW) Fun apẹẹrẹ, laaarin ọdun iṣẹ-isin 1991, itara ọkàn awọn Ẹlẹ́rìí tí nṣebẹwo ati awọn olùpéjọpọ̀ adugbo pọ̀ gidigidi ninu ibakẹgbẹpọ Kristẹni ni awọn apejọpọ akanṣe ti a ṣe yika ayé—lati ori awọn Apejọpọ “Ede Mimọgaara” ni Buenos Aires ni South America ati Manila, Taipei, ati Bangkok ni Gábàsì titi di awọn Apejọpọ “Olùfẹ́ Ominira” ni Budapest, Prague, ati Zagreb (August 16-18, 1991) ni Ila-oorun Europe.

2 Irú ayọ wo ni o jẹ́ fun awọn ayanṣaṣoju lati oke okun lati pade awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ onigba pipẹ ni awọn ibi wọnni! Fun apẹẹrẹ, ni Bangkok, Frank Dewar—ti ó jẹ́ akede Ijọba kanṣoṣo ti ó wà ni Thailand ni akoko kan—sọ nipa 58 ọdun iṣẹ-isin ojihin iṣẹ Ọlọrun rẹ̀. Awọn igbokegbodo rẹ̀ bẹrẹ lati erekuṣu okun Pacific si Guusu Ila-oorun Aṣia, ati wọnú China paapaa. Ó ti dojukọ awọn ewu latori ọkọ̀ rírì, awọn ẹranko ẹhanna ninu igbó kìjikìji, awọn àrùn ilẹ olooru, ati ijọba oníkà ti awọn aṣaaju ologun alaṣẹ kànńpá ti Japan. Nigba ti a beere lọwọ rẹ̀ imọran ti yoo fifun awọn alapeejọpọ, idahunpada rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ti ó rọrun: “Bẹru Jehofa!”

3. Eeṣe ti a fi nilati fi ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun han?

3 “Bẹru Jehofa!” Bawo ni o ti ṣe pataki tó fun gbogbo wa lati mu ibẹru pipeye dagba! “Ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ni ipilẹṣẹ ọgbọn.” (Saamu 111:10) Ibẹru yii kii ṣe ifoya oníjìnnìjìnnì fun Jehofa. Kaka bẹẹ, ó jẹ́ ọ̀wọ̀ jijinlẹ kan fun ọla-nla amunibẹru ọlọwọ ati awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀, ti a gbekari ijinlẹ oye ti a gbà nipasẹ ikẹkọọ Ọrọ Ọlọrun. Ni Iṣipaya 15:3, 4 (NW), orin Mose ati ti Ọdọ-agutan polongo pe: “Titobi ati agbayanu ni awọn iṣẹ rẹ, Jehofa Ọlọrun, Olodumare. Ododo ati otitọ ni awọn ọna rẹ, Ọba ayeraye. Ta ni ki yoo bẹru rẹ nitootọ, Jehofa, ti ki yoo sì yin orukọ rẹ logo, nitori pe iwọ nikan ni aduroṣinṣin?” Ni iduroṣinṣin ti awọn olujọsin rẹ̀, Jehofa ní “iwe iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], ti wọn sì ń ṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” A fi ìyè ainipẹkun san èrè fun wọn.—Malaki 3:16; Iṣipaya 20:12, 15.

Ibẹru Oniwa-bi-Ọlọrun Ṣẹgun

4. Idande igbaani wo ni o nilati fun wa niṣiiri lati bẹru Jehofa?

4 Nigba ti Isirẹli yan jade kuro ni Ijibiti ti Farao, Mose fihan kedere pe Jehofa nikan ni oun bẹru. Laipẹ, awọn ọmọ Isirẹli ni a kámọ́ saaarin meji Okun Pupa ati ẹrọ ologun alagbara ti Ijibiti. Ki ni wọn lè ṣe? “Mose sì wí fun awọn eniyan naa pe, Ẹ má bẹru, ẹ duro jẹẹ, ki ẹ sì ri igbala OLUWA [“Jehofa,” NW], ti yoo fihan yin ni oni: nitori awọn ara Ijibiti ti ẹyin rí ni oni yii, ẹyin kì yoo sì tun ri wọn mọ laelae. Nitori ti OLUWA [“Jehofa,” NW] yoo jà fun yin, ki ẹyin ki o sì pa ẹnu yin mọ.” Lọna iyanu, Jehofa pín omi naa niya. Awọn ọmọ Isirẹli yan la isalẹ abẹ okun kọja. Lẹhin naa omi naa rọ́ walẹ lẹẹkansii. Ẹgbẹ́ ogun Farao ni a parun patapata. Jehofa gba orilẹ-ede olubẹru Ọlọrun yẹn là, nigba ti ó mu idajọ ṣẹ lori Ijibiti atabuku si Ọlọrun ni igba kan naa. Bakan naa lonii, oun yoo fi iduroṣinṣin rẹ̀ han gbangba ninu dídá awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ olubẹru Ọlọrun nide kuro ninu ayé Satani.—Ẹkisodu 14:13, 14; Roomu 15:4.

5, 6. Awọn iṣẹlẹ wo ni akoko Joṣua ni o fihan pe a nilati bẹru Jehofa dipo eniyan?

5 Lẹhin Ijadelọ kuro ni Ijibiti, Mose rán awọn amí 12 lọ si Ilẹ Ileri. Awọn mẹwaa ni jìnnìjìnnì bò ni riri awọn olugbe ti wọn dabi òmìrán wọn sì gbiyanju lati yi Isirẹli lọkan pada kuro ninu wiwọnu ilẹ naa. Ṣugbọn awọn meji yooku, Joṣua ati Kalẹbu, rohin pe: “Ilẹ naa dara gidigidi. Bi OLUWA [“Jehofa,” NW] ba fẹ́ wa, njẹ yoo mu wa wọ inu ilẹ naa yii, yoo sì fii fun wa, ilẹ ti ń ṣàn fun wàrà ati fun oyin. Ṣugbọn ẹ maṣe ṣọtẹ si OLUWA [“Jehofa,” NW], bẹẹ ni ki ẹ maṣe bẹru awọn eniyan ilẹ naa; nitori pe ounjẹ wa ni wọn; aabo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA [“Jehofa,” NW] sì wà pẹlu wa: ẹ maṣe bẹru wọn.”—Numeri 14:7-9.

6 Bi o ti wu ki o ri, awọn ọmọ Isirẹli wọnni juwọsilẹ fun ibẹru eniyan. Gẹgẹ bi iyọrisi, wọn kò dé ilẹ ileri naa lae. Ṣugbọn Joṣua ati Kalẹbu, papọ pẹlu iran titun ti awọn ọmọ Isirẹli, lanfaani lati wọ ilẹ ayanlaayo yẹn wọn sì ro awọn ọgba ajara ati oko olifi rẹ̀. Ninu ọrọ idagbere rẹ̀ fun awọn eniyan Isirẹli ti wọn pejọ, Joṣua fun wọn ni imọran yii: “Njẹ nitori naa ẹ bẹru OLUWA [“Jehofa,” NW], ki ẹ sì maa sin in ni ododo ati ni otitọ.” Joṣua sì fi kun un pe: “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA [“Jehofa,” NW] ni awa yoo maa sin.” (Joṣua 24:14, 15) Iru awọn ọrọ afunni niṣiiri wo ni eyi jẹ́ fun awọn olori idile ati gbogbo awọn miiran ti wọn bẹru Jehofa gẹgẹ bi a ti mura lati kọja sinu ayé titun ododo ti Ọlọrun!

7. Bawo ni Dafidi ṣe tẹnumọ ijẹpataki bibẹru Ọlọrun?

7 Ọmọdekunrin oluṣọ agutan naa Dafidi tun fi ibẹru awofiṣapẹẹrẹ fun Jehofa han nigba ti o pe Golayati nija ni orukọ Ọlọrun. (1 Samuẹli 17:45, 47) Lori akete iku rẹ̀, Dafidi lè polongo pe: “Ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] sọ ọrọ nipa mi, ọrọ rẹ̀ si nbẹ ni ahọn mi. Ọlọrun Isirẹli ní, Apata Isirẹli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakooso eniyan lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun, yoo sì dabi imọlẹ owurọ nigba ti oorun bá là, owurọ ti kò ni ìkùukùu.” (2 Samuẹli 23:2-4) Ibẹru Ọlọrun yii ni o ti poora laaarin awọn alakooso ayé yii, ẹ si wo bi iyọrisi rẹ̀ ti banininujẹ tó! Bawo ni yoo ti yatọ tó nigba ti Jesu, “Ọmọ Dafidi,” ba ń ṣakoso ilẹ-aye ninu ibẹru Jehofa!—Matiu 21:9.

Gbígbégbèésẹ̀ Ni Ibẹru Jehofa

8. Eeṣe ti Juda fi ṣaṣeyọrisirere labẹ Jehoṣafati, ti ó tọka si ki ni fun oni?

8 Ni nǹkan bii ọgọrun-un ọdun mẹjọ lẹhin iku Dafidi, Jehoṣafati di ọba ni Juda. Nihin-in lẹẹkansii ni a ti rí ọba kan ti ó ṣiṣẹsin ni ibẹru Jehofa. Ó mu ètò iṣakoso Ọlọrun padabọsipo ni Juda, ó fi awọn onidaajọ sipo jakejado ilẹ naa, ó sì fun wọn ni awọn itọni wọnyi: “Ẹyin kò dajọ fun eniyan bikoṣe fun Oluwa [“Jehofa,” NW], ti ó wà pẹlu yin ninu ọran idajọ. Njẹ nisinsinyi, jẹ ki ẹ̀rù Oluwa [“Jehofa,” NW] ki ó wà lara yin; ẹ maa ṣọra, ki ẹ sì ṣee; nitori kò si aiṣedeedee kan lọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun wa, tabi ojuṣaaju eniyan, tabi gbigba abẹtẹlẹ. . . . Bayii ni ki ẹyin ki ó maa ṣe, ni ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], ni otitọ, ati pẹlu ọkàn pipe.” (2 Kironika 19:6-9) Nipa bayii, Juda ṣaṣeyọrisirere ninu ibẹru Jehofa, gan-an gẹgẹ bi awọn eniyan Ọlọrun ti janfaani nipa iṣẹ-isin awọn alaboojuto oníyọ̀ọ́nú lonii.

9, 10. Bawo ni Jehoṣafati ṣe ṣẹgun ninu ibẹru Jehofa?

9 Bi o ti wu ki o ri, Juda ni awọn ọta. Awọn wọnyi pinnu lati pa orilẹ-ede Ọlọrun rẹ́. Apapọ awọn agbo ologun ti Amoni, Moabu, ati Oke Seiri rọ́ wa sinu ipinlẹ Judia wọn sì halẹ mọ Jerusalẹmu. Ó jẹ́ ẹgbẹ́ ogun alagbara kan. Jehoṣafati yiju si Jehofa ninu adura “gbogbo Juda sì duro niwaju Oluwa [“Jehofa,” NW], pẹlu awọn ọmọ wẹẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn.” Lẹhin naa, ni idahun si adura yẹn, ẹmi Jehofa wa sori Jahasiẹli ọmọ Lefi naa, ẹni ti o wi pe: “Bayii ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wí fun yin, ẹ maṣe bẹru, bẹẹ ni ki ẹ má sì ṣe fòyà nitori ọpọlọpọ eniyan yii; nitori ogun naa kii ṣe tiyin bikoṣe ti Ọlọrun. Lọ́la sọkalẹ tọ̀ wọn: . . . ẹyin kò ni jà ni ọran yii; ẹ tẹ́gun, ẹ duro jẹẹ, ki ẹ sì ri igbala Oluwa [“Jehofa,” NW] lọdọ yin, iwọ Juda ati Jerusalẹmu: ẹ maṣe bẹru, bẹẹ ni ki ẹ má sì ṣe fòyà: lọ́la, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo sì pẹlu yin.”—2 Kironika 20:5-17.

10 Ni owurọ ọjọ keji, awọn ọkunrin Juda dide ni kutukutu. Gẹgẹ bi wọn ti figbọran jade lọ lati pade ọta wọn, Jehoṣafati dide duro ó sì wi pe: “Ẹ gbọ́ temi, ẹyin ará Juda, ati ẹyin olugbe Jerusalẹmu. Ẹ gba Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun yin gbọ́, bẹẹ ni a o fi ẹsẹ yin mulẹ; ẹ gba awọn wolii rẹ̀ gbọ́, bẹẹ ni ẹyin yoo ṣe rere.” Ni yiyan niwaju awọn ọkunrin ologun naa, awọn olorin si Jehofa kọrin ni àkọpọ̀ pe: “Ẹ yin Oluwa [“Jehofa,” NW]: nitori ti aanu [“iṣeun-ifẹ,” NW] rẹ̀ duro laelae.” Jehofa fi iṣeun-ifẹ yẹn han nipa dída awọn agbo ologun ọta naa sinu iru idarudapọ bẹẹ debi pe wọn pa araawọn ẹnikinni keji run raurau. Bi awọn ọkunrin Juda ṣe wá sí ilé-ìṣọ́nà ninu aginju, kiki ẹ̀kùrẹ̀ ara oku awọn ọta ni ó ṣẹku.—2 Kironika 20:20-24.

11. Niti ibẹru, bawo ni awọn orilẹ-ede ṣe yatọ si awọn eniyan Ọlọrun?

11 Nigba ti awọn orilẹ-ede ti wọn wà layiika gbọ idande oniṣẹ iyanu yii, “ibẹru Ọlọrun” dé bá wọn. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, orilẹ-ede ti ó ṣegbọran ni ibẹru Jehofa nisinsinyi ni “isinmi yikaakiri.” (2 Kironika 20:29, 30) Bakan naa, nigba ti Jehofa ba mu idajọ ṣẹ ni Amagẹdọni, awọn orilẹ-ede yoo wà ninu ibẹru Ọlọrun ati Amudaajọṣẹ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, wọn kò sì ni lè duro ni ọjọ ńlá ibinu atọrunwa.—Iṣipaya 6:15-17.

12. Bawo ni a ti ṣe san èrè fun ibẹru Jehofa ni awọn akoko ijimiji?

12 Ibẹru pipeye fun Jehofa ń mu awọn èrè jìgbìnnì wá. Noa “fi ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun han ó sì kan aaki kan fun igbala agbo-ile rẹ̀.” (Heberu 11:7, NW) Ati niti awọn Kristẹni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní, a ṣakọsilẹ rẹ̀ pe, tẹle sáà akoko inunibini, ijọ naa “wọ inu ìgbà alaafia kan, a ń gbe e ró; bi o sì ti ń rìn ni ibẹru Jehofa ati ninu itunu ẹmi mímọ́ ó ń baa niṣo ni didi pupọ sii”—lọpọlọpọ gẹgẹ bi ó ti ń ṣe ni Ila-oorun Europe lonii.—Iṣe 9:31, NW.

Fẹ́ Rere, Koriira Buburu

13. Kiki lọna wo ni a le gba niriiri ibukun Jehofa?

13 Jehofa jẹ́ rere latokedelẹ. Fun idi yii, “ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ni ikoriira ibi.” (Owe 8:13) A ti kọ ọ nipa Jesu pe: “Iwọ fẹ ododo, iwọ sì koriira ẹṣẹ; nitori naa ni Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi ororo ayọ yàn ọ́.” (Heberu 1:9) Gẹgẹ bii ti Jesu, bi awa ba fẹ ibukun Jehofa, a gbọdọ ṣe họ́ọ̀ si iwa buburu, iwa palapala, iwa ipa, ati iwọra ayé onigbeeraga Satani. (Fiwe Owe 6:16-19.) A gbọdọ nífẹ̀ẹ́ ohun ti Jehofa fẹ́ ki a sì koriira ohun ti ó koriira. A gbọdọ bẹru lati ṣe ohun ti yoo mu Jehofa banujẹ. “Nipa ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], eniyan a kuro ninu ibi.”—Owe 16:6.

14. Bawo ni Jesu ṣe pese awokọṣe kan fun wa?

14 Jesu fi awokọṣe lelẹ fun wa ki a baa lè tẹle ipasẹ rẹ̀ timọtimọ. “Ẹni, nigba ti a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigba ti o jiya, ti kò sì kilọ; ṣugbọn o fi ọran rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe idajọ ododo lọwọ.” (1 Peteru 2:21-23) Ninu ibẹru Jehofa, awa pẹlu le farada awọn ẹgan, ẹlẹ́yà, ati inunibini, ti ayé Satani ń da lé wa lori.

15. Eeṣe ti a fi nilati bẹru Jehofa dipo awọn wọnni ti wọn le pa ara?

15 Ni Matiu 10:28 (NW), Jesu rọ̀ wa pe: “Ẹ má sì ṣe bẹru awọn ẹni ti ń pa ara ṣugbọn ti wọn ko le pa ọkàn; ṣugbọn kaka bẹẹ ẹ bẹru ẹni ti o lè pa ati ọkàn ati ara run ninu Gẹhẹna.” Ani bi ọta bá nilati pa ẹni ti ń bẹru Jehofa, oró iku jẹ fun igba diẹ. (Hosea 13:14) Nigba ti ó ba di ẹni ti a ji dide, ẹni naa yoo lè sọ pe: “Ikú, oró rẹ dà? Isà-òkú, iṣẹgun rẹ dà?”—1 Kọrinti 15:55.

16. Bawo ni Jesu ṣe bẹru Jehofa ti o sì fi ogo fun un?

16 Jesu funraarẹ pese apẹẹrẹ titayọ fun gbogbo awọn ti wọn nífẹ̀ẹ́ ododo Jehofa ti wọn sì koriira ohun ti ó jẹ buburu. Ibẹru rẹ̀ fun Jehofa ni a fihan ninu awọn ọrọ ikẹhin rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi a ti ri i ni Johanu 16:33 pe: “Nǹkan wọnyi ni mo ti sọ fun yin tẹlẹ, ki ẹyin ki o lè ni alaafia ninu mi. Ninu ayé, ẹyin yoo ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tujuka; mo ti ṣẹgun ayé.” Akọsilẹ Johanu ń ba a lọ pe: “Nǹkan wọnyi ni Jesu sọ, ó sì gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ó sì wi pe, Baba, wakati naa dé: yin Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yin ọ logo pẹlu . . . emi ti fi orukọ rẹ han fun awọn eniyan ti iwọ ti fi fun mi lati inu ayé wá.”—Johanu 17:1-6.

Bẹru Jehofa Ki O Sì Yin in Logo

17. Ni awọn ọna wo ni a lè gba ṣafarawe apẹẹrẹ Jesu?

17 Awa lonii ha lè ṣafarawe apẹẹrẹ afunni niṣiiri Jesu bi? Dajudaju a lè ṣe bẹẹ ninu ibẹru Jehofa! Jesu ti sọ orukọ olokiki ati awọn animọ Jehofa di mímọ̀ fun wa. Ni bibẹru Jehofa gẹgẹ bi Oluwa Ọba-alaṣẹ wa, a gbe e ga leke gbogbo awọn ọlọrun miiran, ti ó ni Mẹtalọkan ijinlẹ ti Kristẹndọmu, alailorukọ ninu. Jesu ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu ibẹru pipeye, ni kíkọ̀ lati di ẹni ti a kẹ́dẹ mú ninu ìkẹkùn ibẹru eniyan ti ń kú. “Ni awọn ọjọ rẹ̀ ninu ẹran-ara Kristi jirẹẹbẹ o sì tun gba awọn adura ẹbẹ si Ẹni naa ti o le gba a la lọwọ iku, pẹlu igbe kikankikan ati omije, a sì gbọ́ tirẹ nitori ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀.” Bii Jesu, njẹ ki awa pẹlu bẹru Jehofa gẹgẹ bi a ti ń baa lọ lati kọ́ igbọran lati inu awọn ohun ti a ń jiya rẹ̀—pẹlu igbala ainipẹkun nigba gbogbo gẹgẹ bi gongo wa.—Heberu 5:7-9, NW.

18. Bawo ni a ṣe le ṣe iṣẹ-isin mímọ́ si Ọlọrun pẹlu ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun?

18 Lẹhin naa ninu lẹta yẹn si awọn Kristẹni ara Heberu, Pọọlu gba awọn Kristẹni ẹni ami ororo niyanju pe: “Ni riri i pe awa yoo gba ijọba kan ti a kò lè mi, ẹ jẹ ki a maa baa lọ lati ni inurere ailẹtọọsi, nipa eyi ti a lè maa ṣe iṣẹ-isin mimọ fun Ọlọrun lọna itẹwọgba pẹlu ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun ati ibẹru ọlọwọ.” Lonii, “ogunlọgọ nla” naa ń ṣajọpin ninu iṣẹ-isin mímọ́ yẹn. Ki ni o sì ni ninu? Lẹhin jijiroro inurere ailẹtọọsi Jehofa ni pipese ẹbọ Ọmọkunrin Rẹ̀, Jesu Kristi, Pọọlu wi pe: “Nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigba gbogbo, eyi ni eso ètè wa, ti ń jẹwọ orukọ rẹ.” (Heberu 12:28, NW; 13:12, 15) Ni imọriri fun inurere ailẹtọọsi Jehofa, ó yẹ ki a fẹ́ lati lo gbogbo wakati ti ó bá ṣeeṣe ninu iṣẹ-isin mímọ́ rẹ̀. Gẹgẹ bi awọn alabaakẹgbẹ aduroṣinṣin ti awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti o kù, awọn ogunlọgọ nla lonii ń ṣaṣepari apa ti ó fi jàn-ànràn jan-anran pọ̀ julọ ninu iṣẹ-isin yẹn. Awọn wọnyi ka igbala sí ti Ọlọrun ati Kristi, gẹgẹ bi wọn ti duro lọna iṣapẹẹrẹ niwaju itẹ Ọlọrun, wọn “ń ṣe iṣẹ-isin mímọ́ ọlọwọ sii ni ọsan ati ni oru.”—Iṣipaya 7:9, 10, 15.

Fi Ogo Fun Ọlọrun Titi Ayeraye

19, 20. Iru ibẹru meji wo ni yoo han gbangba ni “ọjọ Jehofa”?

19 Ọjọ ologo ti idalare Jehofa ń yara sunmọtosi! “Ṣa kiyesi, ọjọ naa ń bọ, ti yoo maa jó bi ina ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yoo dabi àkékù koriko: ọjọ naa ti ń bọ yoo sì jó wọn run, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ ogun wí.” Akoko ajalu yẹn ni “ọjọ ńláǹlà Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Malaki 4:1, 5) Yoo fi “idaamu” kọlu ọkan-aya awọn eniyan buburu, awọn wọnyi “ki yoo sì le sálà.”—Jeremaya 8:15; 1 Tẹsalonika 5:3.

20 Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan Jehofa, ni a misi nipasẹ iru ibẹru yiyatọ kan. Angẹli ti a fi “ihinrere ainipẹkun” lé lọwọ ti faṣẹ ké sí wọn pẹlu ohùn rara, ni wiwi pe: “Ẹ bẹru Ọlọrun, ki ẹ sì fi ogo fun un; nitori ti wakati idajọ rẹ̀ dé.” (Iṣipaya 14:6, 7) Awa yoo duro ni ibẹru ọlọwọ fun idajọ yẹn bi ooru ajónigbẹ ti Amagẹdọni ti ń sun ayé Satani deeru. Ibẹru pipeye ti Jehofa ni a o tẹ̀ mọ ọkan-aya wa lọna ti kò le parẹ. Njẹ ki a ṣoju rere sí wa nigba naa lati ri araawa laaarin ‘awọn ẹni igbala ti wọn ti ké pe orukọ Jehofa’!—Joẹli 2:31, 32; Roomu 10:13.

21. Awọn ibukun wo ni ibẹru Jehofa yoo ṣamọna si?

21 Awọn ibukun agbayanu yoo tẹle e, titi kan “ọdun ìyè” ti ó nasẹ lọ titi gbogbo ayeraye! (Owe 9:11; Saamu 37:9-11, 29) Nitori naa, yala ireti wa jẹ́ lati jogun Ijọba naa tabi lati ṣiṣẹsin ninu ilẹ akoso rẹ̀ ori ilẹ-aye, ẹ jẹ ki a maa baa lọ nisinsinyi lati ṣe iṣẹ-isin mímọ́ si Ọlọrun pẹlu ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun ati ibẹru ọlọwọ. Ẹ jẹ ki a maa baa lọ lati fi ogo fun orukọ mímọ́ rẹ̀. Pẹlu iyọrisi onibukun wo sì ni? Idupẹ titilae pe a fi imọran ọlọgbọn naa sọkan nigba gbogbo lati bẹru Jehofa!

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Ki ni “ibẹru Jehofa” tumọsi?

◻ Bawo ni ibẹru Ọlọrun ṣe ṣanfaani fun awọn eniyan rẹ igbaani?

◻ Awokọṣe ibẹru oniwa-bi-Ọlorun wo ni Jesu fi silẹ fun wa?

◻ Bawo ni a ṣe lè pa iwatitọ mọ ninu ibẹru Jehofa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ninu iwe Iṣipaya, awọn arakunrin Jesu ni a ri ti wọn ń kọ “orin Mose,” orin kan ti ń yin Jehofa logo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ẹgbẹ́ ogun Jehoṣafati ṣẹgun ninu ibẹru Jehofa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọdun ìyè ti o nasẹ lọ titi gbogbo ayeraye yoo jẹ èrè awọn wọnni ti wọn bẹru Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́