Awọn Wolii Èké Lonii
JEREMAYA ṣiṣẹsin gẹgẹ bii wolii Ọlọrun ni Jerusalẹmu ni akoko kan nigba ti ilu naa kun fun ibọriṣa, iwa palapala, iwa ibajẹ, ati tita ẹjẹ alaiṣẹ silẹ. (Jeremaya 7:8-11) Kii ṣe oun nikan ni wolii agbekankanṣiṣẹ ni ìgbà yẹn, ṣugbọn ọpọjulọ awọn yooku jẹ́ aṣiṣẹsinra-ẹni ati oniwa ibajẹ. Ni ọna wo? Jehofa polongo pe: “Lati kekere wọn titi de ńlá wọn, gbogbo wọn ni o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati wolii titi de alufaa, gbogbo wọn ni ń ṣe èké. Wọn sì ti wo ọgbẹ ọmọbinrin eniyan mi fẹẹrẹ; wọn wi pe, Alaafia! Alaafia! nigba ti kò si alaafia.”—Jeremaya 6:13, 14.
Awọn wolii èké naa gbiyanju lati mu ki o farahan pe laika gbogbo iwa ibajẹ ninu ilẹ naa si, awọn nǹkan dara, awọn olugbe sì wà ni alaafia pẹlu Ọlọrun; ṣugbọn iyẹn kii ṣe bẹẹ. Idajọ Ọlọrun duro dè wọn, gẹgẹ bi Jeremaya ti fi aibẹru polongo. Wolii tootọ naa Jeremaya, kii ṣe awọn wolii èké, ni a dalare nigba ti awọn ọmọ ogun Babiloni pa Jerualẹmu run patapata ni 607 B.C.E., a pa tẹmpili run, awọn olugbe ni a sì pa tabi fipa kó lọ sí igbekun si Babiloni jijinna. Iwọnba diẹ ti o yẹ fun aanu ti a fi silẹ ni ilẹ naa sa lọ si Ijibiti.—Jeremaya 39:6-9; 43:4-7.
Ki ni awọn wolii èké ti ṣe? “Emi dojukọ awọn wolii, ni Oluwa [“Jehofa,” New World Translation (Gẹẹsi)] wi, ti o ń jí ọrọ mi, ẹnikinni lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀.” (Jeremaya 23:30) Awọn wolii èké jí ipá ati ìgbéṣẹ́ awọn ọrọ Ọlọrun nipa fifun awọn eniyan niṣiiri lati fetisilẹ si irọ́ dipo ikilọ tootọ lati ọdọ Ọlọrun. Wọn ń sọ, kii ṣe “iṣẹ iyanu ńlá Ọlọrun,” bikoṣe awọn ero tiwọn funraawọn, awọn ohun ti awọn eniyan naa fẹ lati gbọ. Ihin-iṣẹ Jeremaya jẹ́ lati ọdọ Ọlọrun nitootọ, bi awọn ọmọ Isirẹli bá sì ti gbegbeesẹ lori awọn ọrọ rẹ̀ ni, wọn ìbá ti là á já. Awọn wolii èké ‘jí awọn ọrọ Ọlọrun’ wọn sì ṣamọna awọn eniyan sinu ìjábá. Ó ri gan-an bi Jesu ti sọ nipa awọn aṣaaju isin alaiṣootọ ti ọjọ rẹ̀ pe: “Afọju ti ń fọna han afọju ni wọn. Bi afọju bá sì ń fọna han afọju, awọn mejeeji ni yoo ṣubu sinu iho.”—Iṣe 2:11; Matiu 15:14.
Gẹgẹ bi o ti ri ni ọjọ Jeremaya, awọn wolii èké ti wọn ń fi idaniloju sọ pe awọn ń ṣoju fun Ọlọrun Bibeli wà lonii; ṣugbọn awọn pẹlu jí awọn ọrọ Ọlọrun nipa wiwaasu awọn ohun ti o pín awọn eniyan níyà kuro ninu ohun tí Ọlọrun, nipasẹ Bibeli, sọ nitootọ. Ni ọna wo? Ẹ jẹ ki a dahun ibeere yẹn nipa lilo ẹkọ ipilẹṣẹ Bibeli nipa Ijọba naa, gẹgẹ bi ọ̀pá ìdiwọ̀n.
Otitọ Nipa Ijọba Naa
Ijọba Ọlọrun ni lajori ẹṣin-ọrọ ẹkọ Kristi, a sì mẹnukan an ni ìgbà ti ó ju ọgọrun-un lọ ninu awọn Ihinrere. Ni ibẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, Jesu sọ pe: “Emi kò lè ṣai ma waasu ijọba Ọlọrun fun ilu miiran pẹlu: nitori naa ni a ṣá ṣe ran mi.” Ó kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Ki ijọba rẹ de.”—Luuku 4:43; 11:2.
Nigba naa, ki ni Ijọba naa? Gẹgẹ bi The New Thayer’s Greek English Lexicon ti wi, ọrọ Giriiki ti a tumọ si “ijọba” ninu Bibeli tumọ lakọọkọ si, “agbara ọlọba, ipo ọba, ilẹ-ọba, iṣakoso” ati lẹẹkeji, “ipinlẹ ti ó wà labẹ iṣakoso ọba kan.” Lati inu eyi awa yoo pari ero lọna ti ó ba ọgbọn mu pe Ijọba Ọlọrun jẹ́ ijọba gidi ti Ọba kan ń dari. Eyi ha jẹ́ bí ọran naa ti rí bi?
Bẹẹni, ó jẹ́ bẹẹ, Ọba naa kìí sìí ṣe ẹlomiran ju Jesu Kristi lọ. Ṣaaju ìbí Jesu angẹli Geburẹli sọ fun Maria pe: “Oun yoo pọ̀, Ọmọ Ọga-ogo julọ ni a o si maa pè é: Oluwa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun un.” (Luuku 1:32) Gbígbà ti Jesu gba ìtẹ́ fihan pe oun jẹ́ Ọba, Oluṣakoso ijọba kan. Eyi ti ó tun ń fihan pe ijọba naa jẹ́ gidi ni asọtẹlẹ Aisaya pe: “A bí ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yoo sì wà ni ejika rẹ̀: . . . Ijọba yoo bí sii, alaafia kì yoo ni ipẹkun.”—Aisaya 9:6, 7.
Nibo ni Jesu ti ń ṣakoso? Ni Jerusalẹmu ha ni bi? Bẹẹkọ. Wolii Daniẹli ri iran Jesu ti ń gba Ijọba, iran rẹ̀ sì rí Jesu ni ọrun. (Daniẹli 7:13, 14) Eyi baramu pẹlu ọna ti Jesu gbà sọrọ nipa Ijọba naa. Oun niye ìgbà maa ń pe e ni “ijọba ọrun.” (Matiu 10:7; 11:11, 12) Ó tun bá ọrọ Jesu si Pilatu mu nigba ti Jesu wà ni ìgbẹ́jọ́ niwaju rẹ̀ pe: “Ijọba mi kii ṣe ti ayé yii: ìbáṣepé ijọba mi iṣe ti ayé yii, awọn onṣẹ mi ìbá jà, ki a ma baa fi mi lé awọn Juu lọwọ: ṣugbọn nisinsinyi ijọba mi kii ṣe lati ihin lọ.” (Johanu 18:36) Ojiṣẹ tabi alufaa rẹ ha ti fi kọ́ ọ pe Ijọba Jesu jẹ́ ijọba gidi kan, ti ń ṣakoso lati ọrun bi? Tabi ó ha ti fi kọ́ ọ pe Ijọba aa wulẹ jẹ́ ohun kan ti ó wà ninu ọkan-aya bi? Bi o ba ri bẹẹ, ó ti ń jí awọn ọrọ Ọlọrun mọ́ ọ lọwọ.
Ibatan wo ni ó wà laaarin iṣakoso Ijọba naa ati gbogbo oniruuru ijọba eniyan? Gẹgẹ bi The Encyclopedia of Religion, ti a tungbeyẹwo lati ọwọ Mircea Eliade ti wi, Alatun-unṣe-isin naa Martin Luther, nigba ti ó ń jiroro Ijọba naa, damọran pe: “Ijọba ayé . . . ni a tun lè pe ni ijọba Ọlọrun.” Awọn kan fikọni pe awọn eniyan, nipasẹ isapa tiwọn funraawọn, lè mu awọn ijọba eniyan dabii Ijọba Ọlọrun. Ni 1983 Ajọ Awọn Ṣọọṣi Agbaye [World Council of Churches] tẹnumọ ọn pe: “Gẹgẹ bi a ti jẹrii si ojulowo ifẹ wa fun alaafia pẹlu awọn igbesẹ pato, Ẹmi Ọlọrun lè lo awọn isapa alailagbara wa fun mimu awọn ijọba ayé yii tubọ sunmọ ijọba Ọlọrun.”
Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi pe, ninu Adura Oluwa (adura “Baba Wa”), Jesu kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura fun Ijọba Ọlọrun lati dé nigba yẹn nikan ni ó sì sọ fun wọn lati gbadura pe: “Ifẹ tirẹ [Ọlọrun] ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹ ni ní ayé.” (Matiu 6:10) Ni èdè miiran, kii ṣe nipa ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun ni awọn eniyan yoo fi jẹ́ ki Ijọba naa dé. Dide Ijọba naa ni ó fa ki ifẹ-inu Ọlọrun di ṣiṣe lori ilẹ-aye. Bawo?
Fetisilẹ si ohun ti asọtẹlẹ Daniẹli ori 2, ẹsẹ 44, sọ: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyi [awọn alakooso eniyan ni akoko opin] ni Ọlọrun ọrun yoo gbé ijọba kan kalẹ, eyi ti a ki yoo lè parun titi lae: . . . Yoo sì fọ́ gbogbo ijọba wọnyi tuutuu, yoo sì pa wọn run.” Abajọ ti Jesu fi sọ pe Ijọba oun kii ṣe ti apakan ayé yii! Kaka bẹẹ, Ijọba naa yoo pa awọn ijọba, awọn iṣakoso, ti ilẹ-aye yii yoo sì gba ipo wọn ninu ṣiṣakoso araye. Gẹgẹ bi iṣakoso araye tí Ọlọrun fifunni, yoo rí si i nigba naa pe ifẹ-inu Ọlọrun di ṣiṣe lori ilẹ-aye.
Idi fun iru igbesẹ mimuna bẹẹ ni apa ọdọ Ijọba naa ṣe kedere sii nigba ti a ba gbe ẹni ti idari ayé yii wà ni ọwọ rẹ̀ yẹwo. Apọsiteli Johanu kọwe pe: “Gbogbo ayé ni ó wà labẹ agbara ẹni buburu nì.” (1 Johanu 5:19) “Ẹni buburu nì” ni Satani Eṣu, ẹni ti Pọọlu pe ni “ọlọrun ayé yii.” (2 Kọrinti 4:4) Kò si ọna kankan ti a lè gba mọ awọn eto idasilẹ ninu ayé kan ti ọlọrun rẹ̀ jẹ́ Satani Eṣu mọ́ Ijọba Ọlọrun.
Eyi jẹ́ idi kan ti Jesu kò fi kowọnu iṣelu. Nigba ti awọn Juu olùfẹ́ orilẹ-ede gbiyanju lati sọ ọ́ di ọba, ó yẹra fun wọn. (Johanu 6:15) Gẹgẹ bi a ti ri i, oun fi àìfọ̀rọ̀ sabẹ ahọ́n sọ fun Pilatu pe: “Ijọba mi kii ṣe ti ayé yii.” Ati i ibamu pẹlu eyi, ó sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Wọn kii ṣe ti ayé, gẹgẹ bi emi kii tii ṣe ti ayé.” (Johanu 17:16) Nitori naa, awọn aṣaaju isin ti wọn kọni pe dídé Ijọba Ọlọrun ni a mu yára kánkán nipasẹ atunṣe ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan yii ti wọn sì fun awọn agbo agutan wọn niṣiiri lati ṣiṣẹ fun ète yẹn jẹ́ wolii èké. Wọn jale ipá ati igbéṣẹ́ ohun ti Bibeli sọ niti gidi.
Eeṣe Ti Ó Fi Ṣe Pataki?
Gbogbo eyi ha jẹ́ ariyanjiyan agbara ironujinlẹ kan bi? Ki a má ri i. Awọn ẹkọ ti kò tọna nipa Ijọba Ọlọrun ti ṣi ọpọlọpọ lọna o tilẹ ti nipa lori ọna itan paapaa. Fun apẹẹrẹ, itẹjade naa Théo, iwe gbédègbẹ́yọ̀ Roman Katoliki kan, sọ pe: “Awọn eniyan Ọlọrun wà lori ìrìn siha Ijọba kan ti ó jẹ́ ti Ọlọrun eyi tí Kristi dá silẹ lori ilẹ-aye . . . Ṣọọṣi ni iru-ọmọ Ijọba yii.” Mímọ Ṣọọṣi Katoliki mọ́ Ijọba Ọlọrun fún ṣọọṣi naa ni agbara ńláǹlà ninu ayé lakooko Sanmani Agbedemeji ti o kún fun igbagbọ ninu ohun asán. Ani lonii paapaa, awọn alaṣẹ ṣọọṣi gbiyanju lati nipa lori ọna ti awọn àlámọ̀rí ayé ń darisi, ni ṣiṣiṣẹ ni iṣojurere si awọn eto igbekalẹ oṣelu kan ati lilodi si awọn miiran.
Alálàyé kan gbé oju iwoye miiran ti ó gbilẹ lonii kalẹ nigba ti o wi pe: “Ijọba naa jẹ́ ọna iyipada tegbòtigaga nitori pe iyipada tegbòtigaga ni wíwá tí awọn eniyan ń wá papọ ninu iran eniyan titun kan, ti awọn ami atọrunwa kan ru sókè eyi ti a fifunni nipasẹ ọkunrin otitọ naa—Jesu . . . Gandhi . . . awọn Berrigan.” Kikọni pe Ijọba Ọlọrun ni a lè mu tẹsiwaju nipasẹ kùkùkẹ̀kẹ̀ oṣelu ati ṣiṣaifiyesi awọn okodoro otitọ nipa Ijọba Ọlọrun ti ṣamọna awọn aṣaaju isin lati fagagbaga ninu ilepa ipo oṣelu. Ó ti mu ki awọn miiran kowọnu làásìgbò ilu ti wọn tilẹ ń kopa ninu ogun jíjà awọn adàlúrú. Kò si ọ̀kankan ninu eyi ti ó wà ni ibamu pẹlu otitọ naa pe Ijọba naa kii ṣe apakan ayé yii. Awọn aṣaaju isin ti wọn sì kówọnú iṣelu jinlẹjinlẹ tobẹẹ jinna sí ṣiṣai jẹ́ apakan ayé, gẹgẹ bi Jesu ti sọ pe awọn ọmọ-ẹhin oun tootọ yoo jẹ́. Awọn wọnni ti wọn kọni pe Ijọba Ọlọrun ni a rigba nipasẹ igbokegbodo oṣelu jẹ́ wolii èké. Wọn ń jí ọrọ Ọlọrun mọ́ awọn eniyan lọwọ.
Bi awọn aṣaaju isin ninu Kristẹndọmu ba kọni ni ohun ti Bibeli sọ nitootọ, awọn agbo agutan wọn yoo mọ pe dajudaju Ijọba Ọlọrun yoo yanju awọn iṣoro bii òṣì, aisan, aidọgba ẹya iran, ati ininilara. Ṣugbọn yoo jẹ́ ni akoko titọ loju Ọlọrun ati ni ọna ti Ọlọrun. Kò ni jẹ́ nipasẹ atunṣe ti awọn eto igbekalẹ oṣelu, eyi ti yoo wá sopin nigba ti Ijọba naa bá dé. Bi awọn alufaa ṣọọṣi wọnyi ba jẹ́ wolii tootọ, wọn ìbá ti kọ́ awọn agbo agutan wọn pe nigba ti wọn ń duro de Ijọba Ọlọrun lati gbegbeesẹ, wọn lè ri iranlọwọ gidi, tí Ọlọrun fifunni, ti o gbeṣẹ lati bojuto awọn iṣoro tí awọn aidọgba inu ayé yii ṣokunfa.
Nikẹhin, wọn ìbá ti kọ́ awọn agbo agutan wọn pe awọn ipo ayé ti ń buru sii lori ilẹ-aye ti o fa ọpọ julọ inira ni a sọtẹlẹ ninu Bibeli ati pe wọn jẹ́ ami kan pe dídé Ijọba naa sunmọ tosi. Bẹẹni, Ijọba Ọlọrun yoo dásí ọna igbekalẹ oṣelu lọ́ọ́lọ́ọ́ laipẹ yoo sì rọpo rẹ̀. Iru ibukun wo ni iyẹn yoo jẹ́!—Matiu 24:21, 22, 36-39; 2 Peteru 3:7; Iṣipaya 19:11-21.
Araye Labẹ Ijọba Ọlọrun
Ki ni dídé Ijọba Ọlọrun yoo tumọsi fun araye? Ó dara, iwọ ha lè finuwoye araarẹ ti o ń gberanilẹ loroowurọ pẹlu àkọ̀tun okun? Kò si ẹni ti o mọ̀ tí ń ṣaisan tabi tí ń kú lọ. Ani awọn ololufẹ rẹ ti wọn ti kú paapaa ni a ti mu pada wá fun ọ nipasẹ ajinde. (Aisaya 35:5, 6; Johanu 5:28, 29) Kò si awọn idaamu tí iṣunna owo eto ọrọ ajé onimọtara-ẹni-nikan tabi aidọgba awọn eto igbekalẹ ọrọ aje ṣokunfa mọ́. Iwọ ni ile titunilara ati ọpọ jaburata ilẹ lati gbin ohun ti iwọ nilo lati fi bọ́ idile rẹ. (Aisaya 65:21-23) Iwọ lè rin lọ si ibikibi ni akoko eyikeyii ni ọsan tabi ni oru laisi ẹ̀rù ifipakọluni. Kò sí ogun mọ́ rara—kò sí ohunkohun ti yoo wu aabo rẹ lewu. Gbogbo eniyan ni ó ní ire didarajulọ rẹ lọkan. Awọn olubi ti lọ. Ifẹ ati ododo ni o gbilẹ. Iwọ ha lè finuwoye iru akoko kan bẹẹ bi? Eyi ni iru ayé ti Ijọba naa yoo mú wá.—Saamu 37:10, 11; 85:10-13; Mika 4:3, 4.
Eyi ha wulẹ jẹ́ ireti kan ti a gbekari ìṣìnà bi? Bẹẹkọ. Ka iwe mímọ́ ti a tọka si ninu ipinrọ ti ó ṣaaju, iwọ yoo sì rii pe ohun gbogbo ti a sọ nibẹ tan imọlẹ si awọn ileri pàtó ti Ọlọrun. Bi a ko bá tii fi aworan tootọ nipa ohun ti Ijọba Ọlọrun lè ṣe ti yoo sì ṣe fun araye yii han ọ titi fi di isinsinyi, nigba naa ẹnikan ti jí awọn ọrọ Ọlọrun mọ́ ọ lọwọ.
Ó muni layọ pe, kii ṣe ọranyan ki awọn nǹkan wà bẹẹ titi lọ fun ọ. Jesu sọ pe ni ọjọ wa “a o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si de.” (Matiu 24:14) Iwe irohin ti iwọ ń kà yii jẹ́ apakan iṣẹ iwaasu yẹn. A gba ọ niyanju lati yẹra fun didi ẹni ti a tanjẹ nipasẹ awọn wolii èké. Wo inu Ọrọ Ọlọrun jinlẹjinlẹ lati ri otitọ nipa Ijọba Ọlọrun. Nigba naa, mu araarẹ wa sabẹ Ijọba yẹn, eyi ti o jẹ ipese kan lati ọdọ Oluṣọ-agutan Nla naa, Jehofa Ọlọrun. Nitootọ, ó jẹ́ ireti kanṣoṣo fun araye, kò sì ni kùnà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Luther kọni pe iṣakoso eniyan ni a lè wò gẹgẹ bi Ijọba Ọlọrun
[Credit Line
Ifọwọsowọpọ ọlọ́làwọ́ ti Trustees of the British Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan onifẹẹ kan, Jehofa nipasẹ Ijọba rẹ̀ yoo mu awọn ipo ti eniyan kankan kò lè múwá wá