Ìjúbà Awọn Ère—Ariyanjiyan Kan
NI IBIKAN ni Poland, ọkunrin kan ti fẹrẹẹ ṣetan fun irin-ajo rẹ̀. Sibẹ, oun ṣi gbọdọ bikita fun kulẹkulẹ pataki kan. Ó kunlẹ siwaju ère Jesu, ó ṣe irubọ, ó sì gbadura fun aabo lakooko awọn irin-ajo rẹ̀.
Ni ẹgbẹẹgbẹrun ibusọ jinna réré, ni Bangkok, Thailand, iwọ lè ri ayẹyẹ akọkọ ti iṣẹlẹ pataki ọdọọdun ti a ń ṣe deedee ninu isin Buddha, ni akoko oṣupa àrànmọ́jú ni May. Lakooko ayẹyẹ naa ère Buddha kan ni a gbé kiri yipo awọn opopona.
Iwọ ti gbọdọ mọ̀ pé ìjúbà awọn ère, gẹgẹ bi a ti ṣẹṣẹ ṣapejuwe rẹ̀ tán yii, jẹ́ eyi ti o tankalẹ. Araadọta-ọkẹ awọn eniyan niti gidi ń foribalẹ niwaju awọn ère. Fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun awọn ère ni a ti wo gẹgẹ bi ọna pataki lati tubọ sunmọ Ọlọrun.
Ki ni èrò rẹ nipa ìlò awọn ère ninu ijọsin? Ìjúbà awọn ère ha tọna tabi ṣaitọna bi? Ki ni imọlara Ọlọrun nipa rẹ̀? Ẹ̀rí kankan ha wà pe oun tẹwọgba iru ijọsin bẹẹ bi? Boya iwọ gẹgẹ bi ẹnikan kò tii ronu pupọ lori iru awọn ibeere bẹẹ. Sibẹ, bi iwọ bá mọyì nini ibatan kan pẹlu Ọlọrun, ó yẹ ki o rí idahun si wọn.
A gbà pe, fun ọpọlọpọ ni eyi kò ti jẹ́ ọran kan ti o rọrun lati yanju. Ni tootọ, ó ti jẹ́ koko ọrọ ariyanjiyan gbigbona ati oniwa ipa nigba miiran fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun. Fun apẹẹrẹ, lẹhin lọhun un ni ọdun 1513 B.C.E., aṣaaju Heberu naa Mose pa ère oniwura ti ọmọ maluu kan run ó sì ti fi idà ṣekupa iye ti ó tó 3,000 awọn ọkunrin ti wọn ń júbà rẹ̀.—Ẹkisodu, ori 32.
Atako lilekoko si lilo awọn ère ni a kò fi mọ sọdọ awọn Juu. Awọn opitan igbaani ti tọju awọn itan-arosọ ti Takhmūrūp, oluṣakoso Paṣia kan ti a sọ pe ó gbé ipolongo gbigbooro lodisi ìjúbà awọn ère jade ni ọpọ ọgọrun-un ọdun ṣaaju Mose. Ni China ọba onítàn-arosọ igbaani kan ni a rohin rẹ̀ pe o gbéjà ologun ko aworan ère awọn oniruuru ọlọrun. Lẹhin ti ó pa awọn ère naa run tan, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìjúbà ère awọn ọlọrun ti a fi amọ̀ ṣe gẹgẹ bi iwa omugọ. Lẹhin naa, nigba ti Muhammadu ṣì wà ni ọmọde, awọn Arab ti wọn lodisi ìlò awọn ère ninu ijọsin ń bẹ. Ipa ti wọn ni lori Muhammadu ṣeranwọ fun iduro rẹ̀ lori ibọriṣa ni awọn ọdun lẹhin naa. Ninu Kuraani, Muhammadu kọni pe ibọriṣa jẹ́ ẹṣẹ ti kò ni idariji, pe awọn abọriṣa ni a kò nilati gbadura fun, ati pe igbeyawo pẹlu awọn abọriṣa ni a kàléèwọ̀.
Ani ninu Kristẹndọmu paapaa awọn ẹni ayọri-ọla ninu isin ti ọrundun keji, kẹta, kẹrin, ati karun-un C.E., iru bii Irenaeus, Origen, Eusebius ti Caesarea, Epiphanius, ati Augustine, tako ìlò awọn ère ninu ijọsin. Ni nǹkan bi ibẹrẹ ọrundun kẹrin C.E., ní Elvira, Spain, awujọ awọn biṣọọbu gbé ọpọlọpọ awọn ipinnu pataki kan lodisi ìjúbà awọn ère jade. Igbimọ ti Elvira olokiki yii yọrisi kíka awọn ère leewọ ninu awọn ṣọọṣi ati fifidii awọn ijiya melookan lodisi awọn olujọsin ère mulẹ.
Awọn Olùpa-Ère-Run
Idagbasoke yii ni o ṣi ọna silẹ fun ọ̀kan lara awọn ariyanjiyan titobi julọ ninu ìtàn: ariyanjiyan ti awọn olùpa-ère-run ti ọrundun kẹjọ ati ikẹsan-an. Opitan kan sọ pe “ariyanjiyan gbigbona” yii “wà fun ọrundun kan ati aabọ, ó sì mu ijiya ti ko ṣee fẹnusọ wá” ati pe ó jẹ́ “ọ̀kan lara awọn okunfa ojú ẹsẹ fun iyapa laaarin ilẹ-ọba Ila-oorun ati Iwọ-oorun.”
Ọrọ naa “olùpa-ère-run” wá lati inu awọn ọrọ Giriiki naa eikon, ti o tumọ si “ère,” ati klastes, ti o tumọ si “olùfọ́.” Ní bíbá orukọ rẹ̀ mu, isapa ti a papọ ṣe yii lodi si awọn ère ní imukuro ati iparun awọn ère jakejado Europe ninu. Awọn ofin melookan ti o lodi si ère ni a fi lélẹ̀ lati fagile ìlò awọn ère ninu ijọsin. Ìjúbà awọn ère di ọran gbigbona ti oṣelu ti o fa awọn olu-ọba ati poopu, awọn olori ogun ati biṣọọbu wọnu ogun ẹkọ isin gidi.
Eyi sì ju ogun ọlọrọ-ẹnu lasan lọ. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, lati ọwọ McClintock ati Strong, sọ pe lẹhin ti Olu-ọba Leo Kẹta ti ṣofin lodisi ìlò awọn ère ninu ṣọọṣi, awọn eniyan “wọ́ tìrìgàngàn dide lodi si iṣofin yẹn, rúkèrúdò oniwa ipa, paapaa ní Constantinople sì,” di iṣẹlẹ ojoojumọ. Iforigbari laaarin awọn agbo ọmọ ogun ọlọba ati awọn eniyan yọrisi ifiya iku jẹni ati ipakupa. Awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ni a ṣe inunibini sí lọna rírorò. Ọpọ ọgọrun-un ọdun lẹhin naa, ní ọrundun kẹrindinlogun, ọpọ awọn ijiyan itagbangba wáyé ni Zurich, Switzerland, lori ọran ère ninu awọn ṣọọṣi. Gẹgẹ bi iyọrisi, ofin kan ti o fi dandan beere fun imukuro gbogbo awọn ère ninu awọn ṣọọṣi ni a ṣe. Awọn alatun-unṣe kan ni a mọ̀ bí ẹni mowo fun dídá ti wọn dẹbi fun ijọsin ère lọna gbigbona janjan ati oniwa ipa nigba pupọ.
Ani lonii paapaa iyapa gbigbooro laaarin awọn ẹlẹkọọ isin ode oni nipa ìlò awọn ère ninu ijọsin ni o wà. Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo ran ọ lọwọ lati ṣe idiyele yala awọn ère lè ran eniyan lọwọ niti gidi lati tubọ sunmọ Ọlọrun.