Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Lè Tumọsi Fun Ọ
JESU KRISTI kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Ki ijọba rẹ de.” (Matiu 6:10) A ti dari awọn ọrọ wọnni si Ọlọrun lemọlemọ tó nipasẹ awọn wọnni ti wọn sọ pe awọn jẹ́ ọmọlẹhin Jesu!
Bi o ti wu ki o ri, Jesu ṣe ju kíkọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati gbadura fun Ijọba Ọlọrun lọ. Ó fi Ijọba naa ṣe akori ọrọ pataki ninu iṣẹ iwaasu rẹ̀. Nitootọ, iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pe Ijọba Ọlọrun “ni a gbà ni gbogbogboo pe ó jẹ́ ẹṣin-ọrọ pataki ti ẹkọ Jesu.”
Nigba ti awọn ọmọlẹhin Kristi bá gbadura fun Ijọba naa, ki ni wọn ń gbadura fun niti gidi? Ki ni Ijọba Ọlọrun lè tumọsi fun wọn ati fun ọ? Oju wo sì ni Jesu fi wò ó?
Oju-Iwoye Jesu Nipa Ijọba Naa
Jesu sábà maa ń pe araarẹ ni “Ọmọ eniyan.” (Matiu 10:23; 11:19; 16:28; 20:18, 28) Eyi rán wa leti itọka wolii Daniẹli si “ọmọ eniyan.” Nipa iṣẹlẹ ọjọ-ọla kan ni ọrun, Daniẹli sọ pe: “Mo ri ni iran òru, si kiyesi i, ẹnikan bi ọmọ eniyan wá pẹlu awọsanma ọ̀run, o si wá sọdọ Ẹni-àgbà ọjọ naa, wọn si mú un sunmọ iwaju rẹ̀. A sì fi agbara ijọba, ati ogo, ati ijọba fun un, ki gbogbo eniyan, ati orilẹ, ati èdè, ki o lè maa sin in.”—Daniẹli 7:13, 14.
Ni sisọrọ nipa akoko naa nigba ti oun yoo gba ipo iṣakoso yii, Jesu sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀ pe: “Nigba ti Ọmọkunrin eniyan bá jokoo lori ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹyin tikaraayin ti ẹ ti tọ̀ mi lẹhin yoo jokoo pẹlu lori awọn ìtẹ́ mejila.” Jesu tun sọ pe: “Nigba ti Ọmọkunrin eniyan bá dé ninu ogo rẹ̀, . . . a o si kó gbogbo eniyan awọn orilẹ-ede jọ si iwaju rẹ̀, oun yoo sì yà wọn sọtọ kuro ninu araawọn, gan-an gẹgẹ bi oluṣọ agutan ti ń ya agutan sọtọ kuro ninu ewurẹ. . . . Awọn wọnyi [awọn alaiṣootọ] yoo sì lọ kuro sinu ikekuro ainipẹkun, ṣugbọn awọn olododo sinu ìyè ainipẹkun.”—Matiu 19:28; 25:31, 32, 46, New World Translation (Gẹẹsi).
Awọn itọka alasọtẹlẹ wọnyi si awọn ìtẹ́ ati gbogbo awọn awujọ orilẹ-ede fihan pe Ijọba naa jẹ́ akoso kan ninu eyi ti Jesu ati diẹ ninu awọn ọmọlẹhin rẹ̀ yoo ti ṣakoso lori araye. Akoso yẹn yoo ni agbara lati fi iku ké awọn alaiṣododo kuro. Labẹ iṣakoso Ijọba, bi o ti wu ki o ri, awọn wọnni ti wọn ni itẹsi ọkan siha ododo yoo gba ẹbun Ọlọrun ti ìyè ayeraye.
Ni kedere, nigba naa, Ijọba Ọlọrun jẹ́ iṣakoso ti ọrun ti a dá silẹ lọna atọrunwa. Ijọba naa kii ṣe ṣọọṣi, Iwe Mímọ́ kò sì yọnda fun oju-iwoye ti ayé nipa rẹ̀. Siwaju sii, iṣakoso tí Ọlọrun fi funni kò lè jẹ́ ohun kan ti ó wulẹ wà ninu ọkan-aya eniyan kan. Niwọn bi Ijọba Ọlọrun ti jẹ́ iṣakoso kan, kò di ohun kan ninu ọkan-aya wa nigba ti a bá tẹwọgba isin Kristẹni. Ṣugbọn eeṣe ti awọn kan fi ronu pe Ijọba naa jẹ́ ipo kan ti ó wémọ́ ọkan-aya?
Ijọba Naa Ha Wà Ninu Wa Bi?
Awọn kan nimọlara pe Ijọba naa wà ninu ọkan-aya wa nitori ọna ti awọn olùtúmọ̀ Bibeli kan ti gbà tumọ Luuku 17:21. Gẹgẹ bi New International Version (Gẹẹsi) ti wi, Jesu sọ nibẹ pe: “Ijọba Ọlọrun wà ninu yin.”
Ni ọna yii The Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ pe: “Bi o tilẹ jẹ́ pe a ń tọka sí i lemọlemọ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ‘iriri ero afinuro’ tabi ‘jíjẹ́ ki ero-ori nipa tẹmi gbanilọkan’ ti Jesu, itumọ yii sinmi ni pataki lori itumọ atijọ naa, ‘ninu yín,’ . . . ti a loye ninu ero itumọ ode-oni lọna ti kò yẹ sí ‘rẹ’ gẹgẹ bi ọrọ ẹlẹyọkan; ‘yín’ naa . . . jẹ́ ọrọ ẹlẹni pupọ (Jesu ń ba awọn Farisi sọrọ—ẹsẹ 20) . . . Ẹkọ naa pe ijọba Ọlọrun jẹ́ ipo inu lọhun-un ti ero-inu, tabi ti igbala ara-ẹni, tako ọrọ ayika ẹsẹ yii, ó sì tun tako gbogbo igbekalẹ ero ninu M[ajẹmu] T[itun].”
Alaye ẹsẹ iwe kan si Luuku 17:21 ninu New International Version fihan pe awọn ọrọ Jesu ni a lè tumọ si: “Ijọba Ọlọrun wà laaarin yín.” Awọn itumọ Bibeli miiran kà pe: “Ijọba Ọlọrun wà laaarin yín” tabi “wà ni aarin yín.” (The New English Bible; The Jerusalem Bible; Revised Standard Version [Gẹẹsi]) Ni ibamu pẹlu New World Translation of the Holy Scriptures, Jesu sọ pe: “Ijọba Ọlọrun wà ni aarin yín.” Jesu kò ní i lọkan pe Ijọba naa wà ninu ọkan-aya awọn Farisi onigbeeraga ti ó ń bá sọrọ. Kaka bẹẹ, gẹgẹ bii Mesaya ati Ọba-Tí-A-Yàn ti a ti ń wọ̀nà fun tipẹ naa, Jesu wà ni aarin wọn gan-an. Ṣugbọn akoko diẹ yoo kọja ṣaaju ki Ijọba Ọlọrun tó dé.
Igba Ti Yoo Dé
Awọn kan ninu awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi ni a ti yàn gẹgẹ bi ajumọ ṣakoso ninu Ijọba ọrun ti Mesaya. Bii ti Jesu, wọn kú ni oluṣotitọ si Ọlọrun a sì jí wọn dide si ìyè ti ẹmi ni ọrun. (1 Peteru 3:18) Ní kíkéré niye ni ifiwera, wọn yoo jẹ́ 144,000 awọn ọba ati alufaa ti a rà lati inu araye. (Iṣipaya 14:1-4; 20:6) Awọn alájùmọ̀ ṣakoso Jesu ní awọn apọsiteli rẹ̀ oluṣotitọ ninu.—Luuku 12:32.
Bi o ti ń bá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ sọrọ ni akoko kan, Jesu ṣeleri pe: “Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti ki yoo ri iku, titi wọn yoo fi ri Ọmọ eniyan ti yoo ma bọ̀ ni ijọba rẹ̀.” (Matiu 16:28) Lọna ti o fanilọkan mọra, ẹsẹ ti o tẹle e fihan pe ileri Jesu ni a muṣẹ ni iwọnba ọjọ diẹ péré lẹhin naa. Nigba naa ni ó mú mẹta ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ sori oke kan nibi ti o ti yirapada niwaju wọn, wọn sì tipa bayii rí iran rẹ̀ kan ninu ogo Ijọba. (Matiu 17:1-9) Ṣugbọn Ijọba naa ni a kò fidii rẹ̀ mulẹ ni akoko yẹn. Nigba wo ni iyẹn yoo ṣẹlẹ?
Ọ̀kan lara awọn àkàwé Jesu fihan pe a ki yoo gbé e gun ori ìtẹ́ ni kiakia gẹgẹ bii Mesaya Ọba. Ni Luuku 19:11-15 (NW), a kà pe: “Ó sọ apejuwe kan . . . nitori o sunmọ Jerusalẹmu wọn sì ń ronu pe ijọba Ọlọrun yoo fi araarẹ han lọgan. Nitori naa o wi pe: ‘Ọkunrin ọlọ́lá kan rin irin-ajo lọ si ilẹ jijinna réré kan lati gba agbara ọba síkàáwọ́ fun araarẹ ki o sì pada. Ni pipe awọn ẹrú rẹ̀ mẹwaa ó fun wọn ni mina mẹwaa o sì sọ fun wọn, “Ẹ ṣòwò titi emi yoo fi dé.” . . . Asẹhinwa-asẹhinbọ nigba ti o pada dé lẹhin ti o ti gba agbara ọba, ó paṣẹ pe ki a pe awọn ẹrú wọnyi ti oun ti fi owo fadaka fun wá sọdọ rẹ̀, ki oun lè mọ daju ohun ti wọn ti jere nipa igbokegbodo ìṣòwò.’”
Ni awọn ọjọ wọnni ó lè gba akoko gígùn fun ọkunrin kan lati rìnrìn-àjò lati Isirẹli lọ si Roomu, ki o duro ni ilu yẹn titi di ìgbà ti o bá gba agbara ọba, ki o sì pada si ilu ibilẹ rẹ̀ gẹgẹ bi ọba. Jesu ni “ọkunrin ọlọ́lá” naa. Oun yoo gba agbara gẹgẹ bi Ọba lati ọwọ Baba rẹ̀ ni ọrun ṣugbọn a ki yoo gbe e gun ori ìtẹ́ lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi Mesaya Ọba. Awọn ọmọlẹhin rẹ̀ yoo ṣe iṣẹ òwò nipa bíbá iṣẹ ti pipolongo ihinrere Ijọba naa lọ fun akoko gigun kan ṣaaju ki oun tó pada gẹgẹ bi Ọba.
Bi Ijọba Naa Ṣe Dé
Ki ni awọn olùfẹ́ Ọlọrun ń beere nigba ti wọn bá gbadura fun Ijọba rẹ̀ lati dé? Wọn ń beere niti gidi pe ki Ijọba ọrun gbé igbesẹ onipinnu nipa pipa awọn eto iṣakoso àtọwọ́dá eniyan ti o ti kuna lati gbé ni ibamu pẹlu ileri wọn lati mu alaafia ati aasiki wá run. Ni titọka si idagbasoke yii, wolii Daniẹli kọwe pe: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyi ni Ọlọrun ọrun yoo gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a ki yoo lè parun titi lae: a ki yoo si fi ijọba naa lé orilẹ-ede miiran lọwọ, yoo sì fọ́ gbogbo ijọba wọnyi tuutuu, yoo sì pa wọn run; ṣugbọn oun yoo duro titi laelae.” (Daniẹli 2:44) Nigba wo ni eyi yoo ṣẹlẹ?
Jesu sọtẹlẹ pe eyi yoo wáyé laaarin iran awọn wọnni ti yoo ṣẹlẹ́rìí ìrugùdùsókè àrà-ọ̀tọ̀ kan ninu awọn àlámọ̀rí eniyan. Nipa “wiwanihin-in” rẹ̀, Jesu funni ni “ami” alapa pupọ kan ti o ní ninu iru awọn idagbasoke bii ija-ogun alailẹgbẹ, isẹlẹ, ìyàn, àjàkálẹ̀-àrùn—bẹẹni, ati iwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun kari ayé.—Matiu, ori 24, 25; Maaku, ori 13; Luuku, ori 21.
Asọtẹlẹ Jesu wémọ́ awọn iṣẹlẹ ti ń ṣẹlẹ gan-an nisinsinyi—ni ọrundun lọna 20 wa. Fun idi yii, kò ni pẹ́ mọ́ ki Ijọba Ọlọrun tó mú awọn ibukun ńláǹlà wá fun araye. Iwọ lè wà lara awọn wọnni ti wọn yoo gbadun awọn anfaani iṣakoso Ijọba naa. Ṣugbọn ki tilẹ ni Ijọba Ọlọrun lè tumọsi fun ọ ati awọn olólùfẹ́ rẹ?
Awọn Ibukun Iṣakoso Ijọba
Ayọ yoo gbilẹ yíká ayé. Labẹ “ọrun titun kan”—Ijọba ti ọrun—ni “ayé titun kan,” awujọ eniyan yíká ayé ti awọn onigbọran ọmọ-abẹ́ Ijọba, yoo wà. “Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn,” ni apọsiteli Johanu kọwe. “Ọlọrun yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn.” Kì yoo sí idi fun ohunkohun bikoṣe ayọ, nitori ‘ki yoo si ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi irora mọ́.’—Iṣipaya 21:1-4.
Iku ki yoo sí mọ́. Okunfa ibanujẹ buburu yii ki yoo maa fi awọn ọ̀rẹ́ ati olólùfẹ́ wa dù wá mọ́. “Ikú ni ọ̀tá ikẹhin ti a o parun.” (1 Kọrinti 15:26) Ayọ wo ni yoo wà nigba ti ajinde awọn wọnni ti wọn wà ni iranti Ọlọrun bá rọpo isinku!—Johanu 5:28, 29.
Ilera jíjípépé yoo rọ́pò aisan ati ailera. Awọn ibusun ile-iwosan ki yoo kún fun awọn wọnni ti aisan ti ara-ìyára ati ti ọpọlọ ń yọ lẹnu mọ́. Ọ̀gá Oniṣegun naa, Jesu Kristi, yoo fi itoye ẹbọ irapada rẹ̀ silo “fun mimu awọn orilẹ-ede larada.” (Iṣipaya 22:1, 2; Matiu 20:28; 1 Johanu 2:1, 2) Iwosan ti o ṣe nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé jẹ́ kiki apẹẹrẹ ohun ti yoo ṣe nipasẹ Ijọba naa.—Fiwe Aisaya 33:24; Matiu 14:14.
Awọn ipese ounjẹ yoo pọ̀ yanturu. Gẹgẹ bi onisaamu ti wi, “ìkúnwọ́ ọkà ni yoo maa wà lori ilẹ; lori awọn òkè ńlá ni eso rẹ̀ yoo maa mì bii Lẹbanoni.” (Saamu 72:16) Si eyi, asọtẹlẹ wolii Aisaya fikun un pe: “Ati ni oke ńlá yii ni Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ ogun yoo se àsè ohun àbọ́pa fun gbogbo orilẹ-ede, àsè ọti waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa ti o kun [fun] ọ̀rá, ti ọti waini ti o tòrò lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” (Aisaya 25:6) Dajudaju, ìyàn kò ni fi ìyà jẹ awọn olugbe ilẹ̀-ayé labẹ iṣakoso Ijọba.
Gbogbo ilẹ̀-ayé yoo di paradise. Nipa bayii ni ileri Jesu fun oluṣe buburu onirobinujẹ yii yoo ni imuṣẹ pe: “Iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise.” (Luuku 23:43) Iwọ pẹlu lè gbadun ìyè ayeraye lori ilẹ̀-ayé yii, ilẹ̀-ayé kan ti a sọ di mímọ́ kuro lọwọ iwa buburu ti a sì yipada si ilẹ̀-ayé onigbaadun kan, ti o dabi ọgbà.—Johanu 17:3.
Awọn ireti agbayanu wọnyi ni a gbe ka iwaju gbogbo araye onigbọran. Bibeli, Ọrọ onimiisi Jehofa, funni ni awọn idaniloju onibukun wọnyi. Gbogbo eyi sì ni Ijọba Ọlọrun lè tumọsi fun ọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iwọ ha gba ohun ti Jesu sọ nipa Ijọba Ọlọrun gbọ́ bi?