“Eto Ayé Titun” Ti Eniyan Ha Sunmọle Bi?
1. Bawo ni a ṣe fi ifẹ fun ominira oṣelu ti o tubọ pọ sii han sode ni awọn ọdun aipẹ yii?
LONII, araadọta-ọkẹ eniyan wà ninu ìdè ìsìnrú fun isin èké, ọpọlọpọ sì yàn lati maa baa lọ ni ọna yẹn. Lakooko kan naa, pupọ pupọ sii ń beere fun awọn ominira iṣelu. Awọn iṣẹlẹ aramanda-ọtọ ti awọn ọdun diẹ ti o ti kọja ni Ila-oorun Europe ati nibomiran ti ṣapejuwe pe awọn eniyan fẹ́ iru awọn ijọba kan ti ó tubọ lominira. Gẹgẹ bi iyọrisi eyi, ọpọlọpọ ń sọ pe sanmani titun ti ominira ti sunmọle. Ààrẹ United States pè é ni “eto ayé titun.” Nitootọ, awọn aṣaaju ayé nibi gbogbo ń sọ pe Ogun Tutu ati idije awọn ohun ìjà ogun ti parí ati pe ojúmọ́ sanmani titun ti alaafia ti mọ́ fun araye.—Fiwe 1 Tẹsalonika 5:3.
2, 3. Awọn ipo wo ni wọn ń ṣiṣẹ lodisi ominira tootọ?
2 Sibẹ, ani bi awọn isapa eniyan bá tilẹ yọrisi awọn nǹkan ìjà ti ó dinku ati iru iṣakoso ti ó tubọ lominira, ominira tootọ yoo ha wà niti gidi bi? Bẹẹkọ, nitori awọn iṣoro amáyàjáni tí ń bẹ ni gbogbo orilẹ-ede, titikan awọn ti o niiṣe pẹlu ijọba àdáwọ́jọpọ̀ṣe, nibi ti iye awọn otoṣi ti gasoke ti araadọta-ọkẹ sì ń ṣagbara lati rùúlà niti isunna-owo. Irohin Iparapọ Awọn Orilẹ-ede kan sọ pe laika awọn itẹsiwaju ninu imọ ijinlẹ ati imọ oogun si, lojoojumọ yika ayé ipindọgba 40,000 awọn ọmọ ń kú nitori àìjẹunrekánú tabi awọn àrùn ti wọn ṣee dènà. Ògbógi kan ninu pápá yii sọ pe: “Òṣì ti bẹrẹ sii ni animọ eto ọrọ̀-ajé ti ń halẹmọ ọjọ-ọla iran araye niti gidi.”
3 Ni afikun, awọn eniyan pupọ sii ju ti igbakigba ri lọ ni a ń palara nipasẹ awọn iwa-ọdaran ti ó tubọ ń rorò sii. Ikoriira ẹ̀yà-iran, oṣelu, ati isin ń pín oniruru orilẹ-ede sí ọtọọtọ. Ni awọn ibi kan ipo naa kò jinna si akoko ọjọ-ọla yẹn ti a ṣapejuwe ni Sekaraya 14:13, nigba ti awọn eniyan yoo “wà ninu ìdàrúdàpọ̀ ati ẹ̀rù tobẹẹ debi pe olukuluku [yoo] gbá ẹni ti ó wà lẹgbẹ rẹ̀ mú ti yoo sì fipa kọlù ú.” (Today’s English Version [Gẹẹsi]) Ilokulo òògùn ati awọn àrùn tí ibalopọ takọtabo ń ta látaré ń tànkálẹ̀. Araadọta-ọkẹ awọn eniyan ni AIDS ti ràn; ni awọn ilu United States nikan, iye ti ó ju 120,000 ti kú nitori rẹ̀ ná.
Ìdè-Ìsìnrú Fun Ẹṣẹ ati Ikú
4, 5. Laika awọn ominira ti ó wà lonii sí, iru ìdè ìsìnrú wo ni ó gbá gbogbo eniyan mú ṣinṣin sinu ìdè rẹ̀?
4 Bi o ti wu ki o ri, ani bi eyikeyii lara awọn ipo buburu wọnni kò bá wà, awọn eniyan ki yoo ni ominira tootọ sibẹ. Gbogbo eniyan yoo wà ninu ìdè-ìsìnrú sibẹ. Eeṣe ti ọ̀ràn fi ri bẹẹ? Lati ṣakawe: Ki ni bi awọn apàṣẹwàá kan ba mú olukuluku eniyan lori ilẹ̀-ayé lẹ́rú ti wọn sì pa gbogbo wọn? Nitootọ, ohun ti ó ṣẹlẹ si araye nigba ti awọn obi wa akọkọ ṣọtẹ si Ọlọrun ti wọn sì di ẹni ti a mú lẹ́rú fun iṣakoso atẹniloriba Eṣu niyẹn.—2 Kọrinti 4:4.
5 Nigba ti Ọlọrun dá eniyan, ó pète fun wọn lati gbé lori ilẹ̀-ayé titilae ninu ìjẹ́pípé, ninu paradise kan, gẹgẹ bi Jẹnẹsisi ori 1 ati 2 ti fihan. Ṣugbọn nitori iṣọtẹ Adamu babanla wa lodisi Ọlọrun, gbogbo wa wà labẹ idajọ ikú lati akoko naa ti a ti loyun wa: “Nipasẹ ọkunrin kan [Adamu, olori idile araye] ẹṣẹ wọ ayé ati iku nipasẹ ẹṣẹ, ti ikú sì tipa bayii dori gbogbo eniyan.” Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, “ikú ṣakoso gẹgẹ bi ọba.” (Roomu 5:12, 14, NW) Nitori naa laika bi ominira ti a lè ní funraawa ti pọ̀ tó sí, gbogbo wa wà ninu ìdè ìsìnrú si ẹṣẹ ati ikú.
6. Eeṣe ti imusunwọn sii ti kò tó nǹkan fi wà ninu gígùn iwalaaye ti a fojusọna fun lati igba ti a ti kọ Saamu 90:10?
6 Siwaju sii, iwalaaye ti a ní nisinsinyi mọ niwọn gan-an. Ani fun awọn ti wọn rìnnà kore, ó wulẹ jẹ́ iwọnba ẹwadun diẹ ni. Fun awọn ti wọn kò rìnnà kore, iwọnba ọdun diẹ lasan, tabi ki ó dín. Iwadii titun kan sì sọ pe: “Imọ ijinlẹ ati iṣegun ti sún gígùn iwalaaye eniyan ti a fojusọna fun dé opin rẹ̀ ti ó bá ìwà ẹ̀dá mu.” Eyi jẹ́ nitori pe eto igbekalẹ ajogunba wa ni a ti kọ́ aipe ati iku sinu rẹ̀ gẹgẹ bi iyọrisi ẹṣẹ Adamu. Ó ti bani ninu jẹ tó pe bi a bá walaaye lati di ẹni 70 tabi 80 ọdun, nigba ti o yẹ ki a tubọ maa gbọ́n sii ki ó sì tubọ ṣeeṣe fun wa lati gbadun iwalaaye, ara wa a maa kọṣẹ́ a o sì pari rẹ̀ si erupẹ!—Saamu 90:10.
7. Eeṣe ti awọn eniyan kò fi lè jẹ́ orisun ominira tootọ ti a fẹ́ ti a sì nilo lae?
7 Iru iṣakoso eniyan wo ni ó lè dènà iru imunisinru yii fun ẹṣẹ ati iku? Kò sí ọ̀kan. Kò sí awọn olóyè oṣiṣẹ ijọba, onimọ ijinlẹ, tabi dokita nibikibi ti ó lè sọ wá dominira kuro ninu awọn okunfa aisan, ọjọ ogbó, ati iku, bẹẹ ni ẹnikẹni kò lè mú ewu, aiṣedaajọ ododo, iwa-ọdaran, ebi, ati òṣì kuro. (Saamu 89:48) Bi o ti wu ki awọn eniyan ni ìpètepèrò rere tó, kò ṣeeṣe fun wọn lati jẹ́ orisun awọn ominira tootọ ti a ń fẹ ti a sì nilo.—Saamu 146:3.
Àṣìlò Ominira Ifẹ-Inu
8, 9. Ki ni o fi iran araye sinu ipo onibanujẹ rẹ̀ ti lọwọlọwọ?
8 Idile eniyan wà ninu ipo bibani ninujẹ yii nitori pe Adamu ati Efa ṣi ominira ifẹ-inu wọn lò. Peteru kìn-ín-ní 2:16 sọ, ni ibamu pẹlu The Jerusalem Bible (Gẹẹsi) pe: “Huwa bi ọkunrin olominira, má sì ṣe lo ominira rẹ gẹgẹ bi àwáwí fun iwa ibi.” Fun idi yii, ó ṣe kedere pe Ọlọrun kò pète pe ki ominira eniyan jẹ́ aláìláàlà. Wọn gbọdọ lò ó laaarin ààlà awọn ofin Ọlọrun, eyi ti ó jẹ́ ododo ti yoo sì ṣiṣẹ fun anfaani gbogbo eniyan. Awọn ààlà wọnni sì fẹ̀ tó lati yọnda fun ọpọ ominira yíyàn ti ara-ẹni, ki iṣakoso Ọlọrun maṣe jẹ́ eyi ti ń tẹniloriba.—Deutaronomi 32:4.
9 Bi o ti wu ki o ri, awọn obi wa akọkọ yàn lati pinnu ohun ti ó tọ́ ati ohun ti kò tọ́ funraawọn. Niwọn bi wọn ti mọ̀ọ́mọ̀ rìn jade kuro ninu iṣakoso Ọlọrun, ó fa itilẹhin rẹ̀ kuro lọdọ wọn. (Jẹnẹsisi 3:17-19) Wọn tipa bayii di alaipe, ti abajade eyi sì jẹ́ aisan ati ikú. Dipo ominira, araye wá sinu isinru fun ẹṣẹ ati ikú. Wọn tun di ọmọ abẹ́ fun èròkerò ti awọn oluṣakoso eniyan alaipe, ti wọn maa ń jẹ́ òǹrorò lọpọ ìgbà.—Deutaronomi 32:5.
10. Bawo ni Jehofa ṣe fi tifẹtifẹ bojuto awọn ọran?
10 Ọlọrun ti fayegba eniyan lati ṣe igbidanwo yii ninu ohun ti a lè gbagbọ pe ó jẹ́ ominira patapata fun kìkì sáà akoko ti ó láàlà kan. Ó mọ̀ pe awọn abajade naa yoo fihan rekọja iyemeji eyikeyii pe iṣakoso eniyan laisi Ọlọrun kò le kẹ́sẹjárí. Niwọn bi ifẹ-inu, ti a lò lọna ẹ̀tọ́, ti jẹ́ iru ohun iyebiye kan bẹẹ, Ọlọrun ninu ifẹ rẹ̀ fayegba ohun ti ó ti ṣẹlẹ fun igba kukuru dipo fifa ọwọ́ ẹbun ominira ifẹ-inu naa sẹhin.
‘Eniyan Kò Lè Tọ́ Ìṣísẹ̀ Rẹ̀’
11. Bawo ni ìtàn ṣe ti ìpéye Bibeli lẹhin?
11 Akọsilẹ ìtàn ti fi ìpéye Jeremaya ori 10, ẹsẹ 23 ati 24, (NW) han, eyi ti o wi pe: “Ki i ṣe ti eniyan ti ń rìn kódà lati dari ìṣísẹ̀ rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, Óò Jehofa.” Ìtàn tún ti fi ìpéye Oniwaasu 8:9 han, eyi ti o polongo pe: “Ẹnikan ń ṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.” Ó ti jẹ́ otitọ tó! Idile eniyan ti lọ lati ori ìjábá kan si omiran, ti opin rẹ̀ fun gbogbo eniyan sì jẹ́ sàárè. Apọsiteli Pọọlu ṣapejuwe ipo naa ní gẹlẹ nigba ti ó wi, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Roomu 8:22 pe: “Nitori awa mọ pe gbogbo ẹ̀dá ni o jumọ ń kerora ti o sì ń rọbi pọ titi di isinsinyi.” Bẹẹni, ominira kuro ninu awọn ofin Ọlọrun ti ṣokunfa ibi.
12. Ki ni ohun ti awọn orisun isọfunni ti ayé kan sọ nipa ominira patapata?
12 Iwe naa Inquisition and Liberty sọrọ lori ominira ni ọna yii: “Ninu araarẹ, ominira kò fi dandan jẹ́ iwarere kan: ki i ṣe ohun kan ti a nilati mú yangàn laisi itootun siwaju sii. Nitootọ, ó wulẹ lè jẹ́ ọ̀kan ninu iru imọtara-ẹni-nikan ti o jẹ́ alainilaari jù . . . Eniyan kì í ṣe ẹ̀dá olominira patapata, kò sì lè fọkàn dàníyàn jíjẹ́ bẹẹ, laimu iwa òmùgọ̀ lọwọ.” Ọmọ-ọba Philip ti England sì sọ lẹẹkan rí pe: “Ominira lati lọwọ ninu gbogbo èròkerò ati itẹsi adanida lè jẹ́ eyi ti ń fanimọra, ṣugbọn iriri fi kọni leralera, pe ominira laisi ikara-ẹni lọ́wọ́kò . . . ati ihuwa laisi igbatẹniro fun awọn ẹlomiran ni ọna ti ó daju julọ lati pa animọ igbesi-aye awujọ kan run, laika ohun ti ọrọ̀ rẹ̀ lè jẹ́ sí.”
Ta Ni Mọ̀ Julọ?
13, 14. Ta ni ẹnikanṣoṣo ti ó lè pese ominira tootọ fun idile eniyan?
13 Ta ni mọ ọna didara julọ ti a gbọdọ fi ṣeto ile kan—awọn obi onifẹẹ, ti wọn tootun, ti wọn sì niriiri ni tabi awọn ọdọmọde? Idahun naa ṣe kedere. Lọna kan naa, Ẹlẹdaa eniyan, Baba wa ọrun, mọ ohun ti ó dara julọ fun wa. Ó mọ bi a ṣe gbọdọ ṣeto ki a sì ṣakoso awujọ eniyan. Ó mọ bi a ṣe gbọdọ mú ominira ifẹ-inu wá sabẹ akoso lati mú awọn anfaani ominira tootọ wá fun olukuluku eniyan. Kiki Ọlọrun olodumare, Jehofa, ni ó mọ ọna lati gbà yọ idile eniyan jade kuro ninu ìdè-ìsìnrú rẹ̀ ki ó sì pese ominira tootọ fun gbogbo eniyan.—Aisaya 48:17-19.
14 Ninu Ọrọ rẹ̀, ni Roomu 8:21, Jehofa ṣe ileri onimiisi yii: “A o sọ ẹ̀dá tikaraarẹ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.” Bẹẹni, Ọlọrun ṣeleri lati sọ idile eniyan di ominira patapata kuro ninu ipo onibanujẹ rẹ̀ ti lọwọlọwọ. Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo jiroro bi eyi yoo ṣe ṣẹlẹ.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
(Ni ṣiṣatunyẹwo oju-iwe 3 si 8)
◻ Eeṣe ti awọn eniyan fi nimọlara lọna jijinlẹ nipa ominira?
◻ Ni awọn ọna wo ni a ti gbà sọ awọn eniyan di ẹrú jalẹ ìtàn?
◻ Eeṣe ti Jehofa fi fayegba ilokulo ominira ifẹ-inu fun akoko gigun tobẹẹ?
◻ Ta ni ẹnikanṣoṣo naa ti ó lè mu ominira tootọ wá fun gbogbo araye, eesitiṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gigun iwalaaye eniyan fi pupọ jẹ ọ̀kan naa gẹgẹ bi a ti sọ ni 3,500 ọdun sẹhin ni Saamu 90:10
[Credi Line]
Courtesy of the British Museum