Iran 1914—Eeṣe Ti O Fi Ṣe Pataki?
“Awọn onkawe wá mọ̀ pe fun ọpọ ọdun ni a ti ń reti ki Iran yii wa si ipari pẹlu akoko ijangbọn ti o buru jai, a sì reti pe ki o bẹ́ sílẹ̀ lójijì ati pẹlu ipá laipẹ pupọ lẹhin oṣu October, 1914.”—Lati inu iwe irohin The Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, May 15, 1911.
LATI ọdun 1879 iwe irohin ti a mọ si The Watch Tower and Herald of Christ’s Presence nigba naa (ti a wá mọ̀ nisinsinyii si Ilé-Ìṣọ́nà tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa) maa ń fi ìgbà gbogbo tọkasi ọdun 1914 gẹgẹ bi ọdun abàmì kan ninu asọtẹlẹ Bibeli. Bi ọdun naa ti ń sunmọle, awọn onkawe ni a ránlétí pe: “akoko ijangbọn ti o buru jai” ni a lè reti.
Isọfunni yii ni a tẹjade yikaakiri lati ọwọ awọn Kristẹni, ti wọn gbé e karí òye wọn nipa “igba meje” naa ati “akoko awọn Keferi” ti a mẹnukan ninu Bibeli.a Wọn loye akoko yii pe o jẹ 2,520 ọdun—bẹrẹ lati ìgbà ìbìṣubú ijọba Dafidi ti atijọ ni Jerusalẹmu ti o sì pari ni oṣu October 1914.b—Daniẹli 4:16, 17; Luuku 21:24.
Ni October 2, 1914, Charles Taze Russell, alaga Watch Tower Bible and Tract Society ni ìgbà naa, fi tigboyatigboya kede pe: “Akoko awọn Keferi ti pari; awọn ọba wọn ti lo awọn ọjọ wọn pari.” Ẹ wo bi awọn ọrọ rẹ̀ ti jasi otitọ to! Ni October 1914 iṣẹlẹ kan ti ijẹpataki rẹ̀ mi ayé tìtì ti oju eniyan kò lè rí ṣẹlẹ ni ọrun. Jesu Kristi, Àrólé wiwa titilọ si “itẹ Dafidi,” bẹrẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi ọba lori gbogbo iran eniyan.—Luuku 1:32, 33; Iṣipaya 11:15.
‘Ṣugbọn,’ iwọ lè beere pe, ‘bi Kristi bá bẹrẹ sii ṣakoso ni 1914, eeṣe ti ipo awọn nǹkan lori ilẹ̀-ayé fi ń buru sii?’ Idi ni pe Satani ọta iran eniyan ti a kò lè fojuri ṣì wà laaye sibẹ. Titi di ọdun 1914, Satani ṣì lè lọ si ọrun. Ipo naa yipada pẹlu fifi idi Ijọba Ọlọrun mulẹ ni 1914. “Ogun si bẹsilẹ ni ọrun.” (Iṣipaya 12:7, NW) Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ni a ṣẹgun ti a si ju sisalẹ si ilẹ̀-ayé, pẹlu awọn abajade onijamba lori iran eniyan. Bibeli sọ tẹlẹ pe: “Ègbé ni fun ayé ati fun òkun! nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣá ni oun ní.”—Iṣipaya 12:12.
Ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., Jesu sọ pe wíwà nihin alaiṣeefojuri ti oun gẹgẹ bi Ọba titun ti ilẹ̀-ayé ni àmì ti o ṣee fojuri yoo samisi. Wọn bi í pe: “Ki ni yoo ṣe ami wíwà nihin rẹ̀ ati ti ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan?” Ki ni idahun rẹ̀? “Nitori orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede ati ijọba si ijọba, àìtó ounjẹ yoo si wà ati awọn ìsẹ̀lẹ̀ ni ibikan tẹle omiran. Gbogbo nǹkan wọnyi jẹ ibẹrẹ awọn ìroragógó idaamu.”—Matiu 24:3, 7, 8, New World Translation (Gẹẹsi).
Ni ibamu rẹgi, ogun naa ti o bẹsilẹ ni 1914 ni àìtó ounjẹ ti o buru gidigidi bárìn, niwọn bi a ti ṣediwọ fun ọ̀nà ìgbàpèsè ounjẹ fun eyi ti o lé ni ọdun mẹrin. Ki ni nipa ti “awọn ìsẹ̀lẹ̀ ni ibikan tẹle omiran”? Ni awọn ẹ̀wádún ti o tẹle 1914, awọn ìsẹ̀lẹ̀ aṣèparun ti kò din si mẹwaa ṣekupa ohun ti o ju 350,000 eniyan lọ. (Wo apoti.) Ni tootọ, iran 1914 niriiri “ibẹrẹ awọn ìroragógó idaamu.” Ati lati ìgbà naa wá awọn ìroragógó idaamu ti ṣekọlu leralera ni awọn ọ̀nà bii ijaba lọna ti iṣẹda, ìyàn, ati ọpọlọpọ ogun.
Bi o tilẹ ri bẹẹ, irohin naa nipa ifidi Ijọba Ọlọrun mulẹ ni 1914 jẹ irohin rere nitori Ijọba naa yoo gba ayé yii silẹ lọwọ iparun. Bawo? Yoo mu gbogbo isin eke, alagabagebe, awọn ijọba oniwa ibajẹ, ati agbara idari buburu ti Satani kuro. (Daniẹli 2:44; Roomu 16:20; Iṣipaya 11:18; 18:4-8, 24) Ju bẹẹ lọ, yoo mu ayé titun kan ninu eyi ti “ododo yoo gbe” wọle wá.—2 Peteru 3:13.
Laipẹ lẹhin Ogun Agbaye I, awọn Akẹkọọ Bibeli olotiitọ ọkàn, bi a ti ṣe mọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa lọhun-un, bẹrẹ sii loye anfaani wọn nipa ìhà miiran ninu àmì wíwà nihin-in Jesu gẹgẹ bi Ọba. Jesu Kristi sọtẹlẹ pe: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì de.”—Matiu 24:14.
Lati ibẹrẹ kekere ni 1919, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń baa lọ láìdáwọ́dúró lati mu “ihinrere yii” gbooro kaakiri. Gẹgẹ bi abajade eyi, araadọta ọkẹ lati eyi ti o ju 200 ilẹ ni a ti ń kojọ nisinsinyi gẹgẹ bi awọn ọmọ-abẹ Ijọba Ọlọrun. Ẹ si wo iru awọn ibukun ti ń duro de awọn ọmọ-abẹ wọnyi! Ijọba naa yoo mu ogun, ìyàn, ìwà ọ̀daràn, ati itẹniloriba wá sopin. Yoo tilẹ ṣẹ́pá aisan ati iku!—Saamu 46:9; 72:7, 12-14, 16; Owe 2:21, 22; Iṣipaya 21:3, 4.
Ṣaaju ki iran 1914 to kọja lọ, iṣẹ iwaasu naa yoo ti ṣaṣepari ète rẹ̀. Jesu sọtẹlẹ pe, “Nigba naa ni ipọnju nla yoo wà, iru eyi ti kò si lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ ki yoo sì sí. Bi kò sì ṣe pe a ké ọjọ wọnni kúrú, kò si ẹda tí ìbá le là á; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ ni a o fi ké ọjọ wọnni kuru.”—Matiu 24:21, 22.
Maṣe ṣe aṣiṣe naa tí iran ti o ṣaaju ọdun 1914 ṣe. Awọn nǹkan ki yoo maa fi ìgbà gbogbo baa lọ bi wọn ti ṣe wà bayi. Awọn iyipada aṣeni-ní-háà ń bẹ niwaju. Ṣugbọn awọn ifojusọna agbayanu wà, fun awọn wọnni ti wọn huwa ọlọgbọn.
Fetisilẹ, nigba naa, si awọn ọrọ wolii atijọ naa pe: “Ẹ wá Oluwa [“Jehofa,” NW], gbogbo ẹyin ọlọkantutu ayé, ti ń ṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwà-pẹ̀lẹ́: boya a o pa yin mọ́ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Sefanaya 2:3) Bawo ni a ṣe lè lo imọran yii? Awọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o tẹle e yoo dahun ibeere yẹn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Oju-ewe akọle ati orukọ ontẹwe ninu iwe Scenario of the Photo-Drama of Creation, 1914.
b Fun kulẹkulẹ siwaju sii, wo ori 16 iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn Isẹlẹ ninu Ẹ̀wádún Ti O Tẹle 1914
Ọjọ: Ọgangan Isẹlẹ: Iye Oku:
January 13, 1915 Avezzano, Italy 32,600
January 21, 1917 Bali, Indonesia 15,000
February 13, 1918 Kwangtung Province, China 10,000
October 11, 1918 Puerto Rico (iha iwọ-oorun) 116
January 3, 1920 Veracruz, Mexico 648
September 7, 1920 Reggio di Calabria, Italy 1,400
December 16, 1920 Ningsia Province, China 200,000
March 24, 1923 Szechwan Province, China 5,000
May 26, 1923 Iran (iha ariwa si ila-oorun) 2,200
September 1, 1923 Tokyo-Yokohama, Japan 99,300
Lati inu itolẹsẹẹsẹ ti “Significant Earthquakes of the World” ninu iwe naa Terra Non Firma, lati ọwọ James M. Gere ati Haresh C. Shah.